Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 35:1-10

Ti Dafidi.

35 Olúwa, gbógun ti àwọn tí ń gbóguntì mí;
    kí o sì kọ ojú ìjà sí àwọn tí ó ń bá mi í jà!
Di asà àti àpáta mú,
    kí o sì dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi!
Fa idà àti ọ̀kọ̀ yọ
    kí o sì dojúkọ àwọn tí ń lé mi.
Sọ fún ọkàn mi pé,
    “Èmi ni ìgbàlà rẹ.”

Kí wọn kí ó dààmú,
    kí a sì ti àwọn tí ń lépa ọkàn mi lójú;
kí a sì mú wọn padà,
    kí a sì dààmú àwọn tí ń gbèrò ìpalára mi.
Jẹ́ kí wọn dàbí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́,
    kí angẹli Olúwa kí ó máa lé wọn kiri.
Jẹ́ kí ọ̀nà wọn kí ó ṣókùnkùn, kí ó sì máa yọ́,
    kí angẹli Olúwa kí ó máa lépa wọn!

Nítorí pé, ní àìnídìí ni wọ́n dẹ àwọ̀n wọn sílẹ̀ fún mi,
    ní àìnídìí ni wọ́n wa kòtò sílẹ̀ fún ọkàn mi.
Kí ìparun kí ó wá sí orí rẹ̀ ní òjijì.
    Àwọ̀n rẹ̀ tí ó dẹ, kí ó mú òun tìkára rẹ̀;
    kí wọn ṣubú sínú kòtò sí ìparun ara rẹ̀.
Nígbà náà ni ọkàn mi yóò yọ̀ nínú Olúwa,
    àní, yóò sì máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ̀.
10 Gbogbo egungun mi yóò wí pé,
    “Ta ni ó dàbí ì ìwọ Olúwa?
O gba tálákà lọ́wọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ,
    tálákà àti aláìní lọ́wọ́ ẹni tí ń fi ṣe ìkógun?”

Numeri 22:22-28

22 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run bínú gidigidi, angẹli Olúwa sì dúró lójú ọ̀nà láti dojú ìjà kọ ọ́. Balaamu ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ lọ, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ méjì sì wà pẹ̀lú rẹ̀. 23 Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà sì rí angẹli Olúwa tí ó dúró ní ojú ọ̀nà pẹ̀lú idà tí a fàyọ ní ọwọ́ rẹ̀, ó kọjú kúrò ní ọ̀nà lọ sínú oko. Balaamu sì lù ú pé kí ó gbé òhun padà lọ sí ojú ọ̀nà.

24 Nígbà náà angẹli Olúwa dúró ní ojú ọ̀nà tóóró láàrín ọgbà àjàrà, pẹ̀lú ògiri ní ọ̀nà méjèèjì. 25 Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí angẹli Olúwa, ó lẹ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ ògiri, ó sì rún ẹsẹ̀ Balaamu mọ́ ògiri. Nígbà náà, ó tún nà án, lẹ́ẹ̀kan sí i.

26 Nígbà náà angẹli Olúwa súnmọ́ wájú ó sì dúró níbi ọ̀nà tóóró níbi tí kò ti sí ọ̀nà láti yípadà, bóyá ní ọ̀tún tàbí òsì. 27 Nígbà tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rí angẹli Olúwa, ó sì jókòó ní abẹ́ Balaamu, inú sì bí i tó sì nà án pẹ̀lú ọ̀pá rẹ̀. 28 Nígbà náà Olúwa ṣí ẹnu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì sọ fún Balaamu pé, “Kí ni mo ṣe fún ọ tí o fi nà mí lẹ́ẹ̀mẹ́ta?”

1 Kọrinti 7:32-40

32 (A)Nínú gbogbo nǹkan tí ẹ bá ń ṣe ni mo tí fẹ́ kí ẹ sọ ara yín di òmìnira lọ́wọ́ àníyàn. Ọkùnrin tí kò ní ìyàwó le lo àkókò rẹ̀ láti fi ṣiṣẹ́ fún Olúwa, yóò sì má ronú bí ó ti ṣe le tẹ́ Olúwa lọ́rùn. 33 Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ó bá tí ṣe ìgbéyàwó kò le ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí ó ní láti ronú àwọn nǹkan rẹ̀ nínú ayé yìí àti bí ó ti ṣe le tẹ́ aya rẹ̀ lọ́rùn, 34 dájúdájú, ìfẹ́ rẹ̀ pín sí ọ̀nà méjì. Bákan náà ló rí fún obìnrin tí a gbé ní ìyàwó àti wúńdíá. Obìnrin tí kò bá tí ì délé ọkọ a máa tọ́jú ohun tí ṣe ti Olúwa, kí òun lè jẹ́ mímọ́ ní ara àti ní ẹ̀mí. Ṣùgbọ́n ọmọbìnrin tí a bá ti gbé níyàwó, a máa ṣe ìtọ́jú ohun tí ṣe ti ayé, bí yóò ti ṣe le tẹ́ ọkọ rẹ̀ lọ́rùn. 35 Mo ń sọ èyí fún àǹfààní ara yín kì í ṣe láti dá yín lẹ́kun ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè gbé ní ọ̀nà tí ó tọ́ kí ẹ sì lè máa sin Olúwa láìsí ìyapa ọkàn.

36 Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun kò ṣe ohun tí ó yẹ sí wúńdíá rẹ̀ ti ìpòùngbẹ rẹ si pọ si, bí ó bá sí tọ́ bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí ó ṣe bí ó tí fẹ́, òun kò dẹ́ṣẹ̀, jẹ́ kí wọn gbé ìyàwó. 37 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó dúró ṣinṣin ni ọkàn rẹ̀, tí kò ní àìgbọdọ̀ má ṣe, ṣùgbọ́n tí ó ní agbára lórí ìfẹ́ ara rẹ̀, tí ó sì ti pinnu ní ọkàn rẹ̀ pé, òun ó pa wúńdíá ọmọbìnrin òun mọ́, yóò ṣe rere. 38 Bẹ́ẹ̀ sì ní ẹni tí ó fi wúńdíá ọmọbìnrin fún ni ní ìgbéyàwó, ó ṣe rere; ṣùgbọ́n ẹni tí kò fi fún ni ní ìgbéyàwó ṣe rere jùlọ.

39 (B)A fi òfin dé obìnrin níwọ̀n ìgbà tí òun pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ wà láààyè, bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó ní òmìnira láti ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ọkùnrin mìíràn, tí ó bá wù ú ó sì gbọdọ̀ jẹ́ ti Olúwa. 40 (C)Ṣùgbọ́n nínú èrò tèmi obìnrin náà yóò ní ayọ̀ púpọ̀, tí kò bá ṣe ìgbéyàwó mìíràn mọ́. Mo sì rò pé mo ń fún un yín ní ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Ọlọ́run nígbà tí mo ń sọ nǹkan wọ̀nyí.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.