Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Adúra ti Dafidi.
86 Gbọ́, Olúwa, kí o sì dá mi lóhùn,
nítorí mo jẹ́ tálákà àti aláìní.
2 Dáàbò bò ayé mi, nítorí a ti yà mí sọ́tọ̀ fún ọ:
ìwọ ni Ọlọ́run mi,
gbà ìránṣẹ́ rẹ là
tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.
3 Ṣàánú fún mi, Olúwa,
nítorí èmi ń pè ọ́ ní gbogbo ọjọ́.
4 Mú ayọ̀ wà fún ìránṣẹ́ rẹ,
nítorí ìwọ, Olúwa,
ni mo gbé ọkàn mí sókè sí.
5 Ìwọ ń dáríjì, ìwọ sì dára, Olúwa,
ìwọ sì ṣàánú fún gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́,
6 Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa;
tẹ́tí sí ẹkún mi fún àánú.
7 Ní ọjọ́ ìpọ́njú mi èmi yóò pè ọ́,
nítorí ìwọ yóò dá mi lóhùn.
8 Nínú àwọn òrìṣà kò sí ẹni tí ó dàbí i rẹ, Olúwa:
kò sí àwọn iṣẹ́ tí a lè fiwé tìrẹ.
9 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ dá
yóò wá, láti wá jọ́sìn níwájú rẹ, Olúwa;
wọn ó mú ògo wà fún orúkọ rẹ̀.
10 Nítorí pé ìwọ tóbi, ìwọ sì ń ṣe ohun ìyanu;
ìwọ nìkan ni Ọlọ́run.
11 Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, Olúwa,
èmi ó sì máa rìn nínú òtítọ́ rẹ;
fún mi ní ọkàn tí kì í yapa,
kí èmi kí ó ba lè bẹ̀rù orúkọ rẹ.
12 Èmi ó yìn ọ́, Olúwa Ọlọ́run mi, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;
èmi ó fògo fún orúkọ rẹ títí láé
13 Nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ si mi;
ìwọ ti gbà mí kúrò nínú ọ̀gbun isà òkú.
14 Àwọn onígbèéraga ń dojúkọ mí, Ọlọ́run;
àti ìjọ àwọn alágbára ń wá
ọkàn mi kiri,
wọn kò sì fi ọ́ pè.
15 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, jẹ́ aláàánú àti Ọlọ́run olójúrere,
Ó lọ́ra láti bínú, Ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ àti òtítọ́.
16 Yípadà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi;
fún àwọn ènìyàn rẹ ní agbára
kí o sì gba ọ̀dọ́mọkùnrin ìránṣẹ́bìnrin rẹ là.
17 Fi ààmì hàn mí fún rere,
kí àwọn tí ó kórìíra mi lè ri,
kí ojú lè tì wọ́n, nítorí ìwọ Olúwa
ni ó ti tù mí nínú.
Hagari àti Iṣmaeli
16 Sarai, aya Abramu kò bímọ fún un, ṣùgbọ́n ó ní ọmọ ọ̀dọ̀ obìnrin ará Ejibiti kan tí ń jẹ́ Hagari. 2 Nítorí náà, Sarai wí fún Abramu pé, “Kíyèsi i Olúwa ti sé mi ní inú, èmi kò sì bímọ, wọlé tọ ọmọ ọ̀dọ̀ mi lọ, bóyá èmi yóò le ti ipasẹ̀ rẹ̀ ní ọmọ.”
Abramu sì gba ohun tí Sarai sọ. 3 Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí Abramu ti ń gbé ni Kenaani ni Sarai mú ọmọbìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Hagari, tí í ṣe ará Ejibiti fún Abramu ọkọ rẹ̀ láti fi ṣe aya. 4 Abramu sì bá Hagari lòpọ̀, ó sì lóyún.
Nígbà tí ó sì ti mọ̀ pé òun lóyún, ó bẹ̀rẹ̀ sì ní kẹ́gàn ọ̀gá rẹ̀. 5 Nígbà náà ni Sarai wí fún Abramu pé, “Ìwọ ni ó jẹ́ kí ẹ̀gbin yìí máa jẹ mí, mo fa ọmọ ọ̀dọ̀ mi lé ọ lọ́wọ́, nígbà tí ó sì rí i pé òun lóyún, mo di ẹni ẹ̀gàn ní ojú rẹ̀. Kí Olúwa kí ó ṣe ìdájọ́ láàrín tèmi tìrẹ.”
6 Abramu dáhùn pé, “Ìwọ ló ni ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ, ṣe ohunkóhun tí ó bá tọ́ ní ojú rẹ sí i.” Nígbà náà ni Sarai fi ìyà jẹ Hagari, ó sì sálọ.
7 Angẹli Olúwa sì rí Hagari ní ẹ̀gbẹ́ ìsun omi ní ijù, ìsun omi tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà tí ó lọ sí Ṣuri. 8 Ó sì wí pé, “Hagari, ìránṣẹ́ Sarai, níbo ni o ti ń bọ̀, níbo sì ni ìwọ ń lọ?”
Ó sì dáhùn pé, “Mo ń sálọ kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá mi Sarai ni.”
9 Angẹli Olúwa sì wí fún un pé, “Padà lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ kí o sì tẹríba fún un.” 10 Angẹli Olúwa náà sì fi kún fún un pé, “Èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, ìran rẹ kì yóò sì lóǹkà.”
11 Angẹli Olúwa náà sì wí fún un pé,
“Ìwọ ti lóyún, ìwọ yóò sì bí
ọmọkùnrin kan,
ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Iṣmaeli,
nítorí tí Olúwa ti rí ìpọ́njú rẹ.
12 Òun yóò jẹ́ oníjàgídíjàgan ènìyàn
ọwọ́ rẹ̀ yóò wà lára ènìyàn gbogbo,
ọwọ́ ènìyàn gbogbo yóò sì wà lára rẹ̀,
yóò sì máa gbé ní ìkanra
pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀.”
13 Ó sì pe orúkọ Olúwa tí o bá sọ̀rọ̀ ní, “Ìwọ ni Ọlọ́run tí ó rí mi,” nítorí tí ó wí pé, “Mo ti ri ẹni tí ó rí mi báyìí.” 14 Nítorí náà ni a ṣe ń pe kànga náà ní Beeri-Lahai-Roi: kànga ẹni alààyè tí ó rí mi. Ó wà ní agbede-méjì Kadeṣi àti Beredi.
Àwọn ọmọdé àti Jesu
15 (A)Wọ́n sì gbé àwọn ọmọ ọwọ́ tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú, kí ó lè gbé ọwọ́ lé wọn; ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rí i, wọ́n ń bá wọn wí. 16 Ṣùgbọ́n Jesu pè wọ́n sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má sì ṣe dá wọn lẹ́kun: nítorí tí irú wọn ni ìjọba Ọlọ́run. 17 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbà ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré, kì yóò wọ inú rẹ̀ bí ó ti wù kí ó rí.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.