Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 46

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Gẹ́gẹ́ bí ti alamoti. b Orin.

46 Ọlọ́run ni ààbò àti agbára wa
    ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ìgbà ìpọ́njú.
Nítorí náà àwa kì yóò bẹ̀rù, bí a tilẹ̀ ṣí ayé ní ìdí,
    tí òkè sì ṣubú sínú Òkun.
Tí omi rẹ̀ tilẹ̀ ń hó tí ó sì ń mì
    tí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ń mì pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀. Sela.

Odò ńlá kan wà tí ṣíṣàn rẹ̀ mú inú ìlú Ọlọ́run dùn,
    ibi mímọ́, níbi ti Ọ̀gá-ògo ń gbé.
Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, kò ní yẹ̀:
    Ọlọ́run yóò ràn án lọ́wọ́ ní kùtùkùtù òwúrọ̀.
Àwọn orílẹ̀-èdè ń bínú, àwọn ilẹ̀ ọba ṣubú,
    ó gbé ohun rẹ̀ sókè, ayé yọ̀.

Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wà pẹ̀lú wa,
    Ọlọ́run Jakọbu ni ààbò wa.

Ẹ wá wo iṣẹ́ Olúwa
    irú ahoro tí ó ṣe ní ayé.
O mú ọ̀tẹ̀ tán de òpin ilẹ̀ ayé
    ó ṣẹ́ ọrun, ó sì gé ọ̀kọ̀ sí méjì
ó fi kẹ̀kẹ́ ogun jóná
10 Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ní Ọlọ́run.
A ó gbé mi ga nínú àwọn orílẹ̀-èdè
    A ó gbé mi ga ní ayé.

11 Ọlọ́run alágbára wà pẹ̀lú wa
    Ọlọ́run Jakọbu sì ni ààbò wa.

Òwe 8:1-21

Ọgbọ́n n fi ìpè síta

(A)Ǹjẹ́ ọgbọ́n kò ha ń kígbe síta?
    Òye kò ha ń gbé ohùn rẹ sókè?
Ní ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà
    ní ìkóríta, ní ó dúró;
Ní ẹgbẹ́ ibodè tí ó wọ ìlú,
    ní ẹnu ibodè ni ó ń kígbe sókè:
Sí i yín ẹ̀yin ènìyàn, ní mo ń kígbe pè;
    Mo gbé ohun mi sókè sí gbogbo ènìyàn,
Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ kọ́gbọ́n;
    ẹ̀yin aṣiwèrè, ẹ gba òye.
Ẹ gbọ́, nítorí tí èmi ó sọ̀rọ̀ ohun iyebíye;
    Èmí ṣí ètè mi láti sọ ohun tí ó tọ́,
Ẹnu mi ń sọ ohun tí í ṣe òtítọ́,
    nítorí ètè mi kórìíra ibi.
Gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi ni ó tọ́,
    kò sí èyí tí ó jẹ́ ẹ̀tàn tàbí àyídáyidà níbẹ̀
Fún olóye gbogbo rẹ̀ ni ó tọ̀nà;
    wọ́n jẹ́ aláìlẹ́gàn fún gbogbo ẹni tí ó ní ìmọ̀.
10 Yan ẹ̀kọ́ mi dípò fàdákà,
    ìmọ̀ dípò o wúrà àṣàyàn,
11 Nítorí ọgbọ́n ṣe iyebíye jù iyùn lọ,
    kò sí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ tí a sì le fiwé e.

12 “Èmi, ọgbọ́n ń gbé pẹ̀lú òye;
    mo ní ìmọ̀ àti ọgbọ́n-inú.
13 Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìkórìíra ibi
    mo kórìíra ìgbéraga àti agídí,
    ìwà ibi àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.
14 Ìmọ̀ràn àti ọgbọ́n tí ó yè kooro jẹ́ tèmi
    mo ní òye àti agbára.
15 Nípasẹ̀ mi ni ọba ń ṣàkóso
    tí àwọn aláṣẹ sì ń ṣe òfin tí ó dára
16 Nípasẹ̀ mi àwọn ọmọ-aládé ń ṣàkóso
    àti gbogbo ọlọ́lá tí ń ṣàkóso ilẹ̀ ayé.
17 Mo fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn mi
    àwọn tí ó sì wá mi rí mi.
18 Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wà
    ọrọ̀ tí í tọ́jọ́ àti ìgbéga rere.
19 Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ;
    ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ.
20 Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo,
    ní ojú ọ̀nà òtítọ́,
21 Mò ń fi ọrọ̀ fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn mi
    mo sì ń mú kí ilé ìṣúra wọn kún.

Marku 3:13-19

Jesu yan àwọn aposteli méjìlá

13 (A)Jesu gun orí òkè lọ, ó sì pe àwọn kan tí ó yàn láti wà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá. 14 Ó yan àwọn méjìlá, kí wọn kí ó lè wà pẹ̀lú rẹ̀, àti kí ó lè rán wọn lọ láti wàásù 15 àti láti lágbára láti lé àwọn ẹ̀mí Èṣù jáde.

16 (B)Wọ̀nyí ni àwọn méjìlá náà tí ó yàn:

Simoni (ẹni ti ó sọ àpèlé rẹ̀ ní Peteru)

17 Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu arákùnrin rẹ̀ (àwọn ẹni tí Jesu sọ àpèlé wọ́n ní Boanaji, èyí tí ó túmọ̀ sí àwọn ọmọ àrá).

18 Àti Anderu,

Filipi,

Bartolomeu,

Matiu,

Tomasi,

Jakọbu ọmọ Alfeu,

Taddeu,

Simoni tí ń jẹ́ Sealoti (ọ̀kan nínú àwọn ẹgbẹ́ tí o ń ja fun òmìnira àwọn Júù).

19 (C)Àti Judasi Iskariotu, ẹni tí ó fi í hàn níkẹyìn.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.