Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Tí ohùn “Àwọn Lílì.” Ti Dafidi.
69 Gbà mí, Ọlọ́run,
nítorí omi ti kún dé ọrùn mi.
2 Mo ń rì nínú irà jíjìn,
níbi tí kò sí ibi ìfẹsẹ̀lé.
Mo ti wá sínú omi jíjìn;
ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀.
3 Agara dá mi, mo ń pè fún ìrànlọ́wọ́;
ọ̀fun mí gbẹ, ojú mi ṣú,
nígbà tí èmi dúró de Ọlọ́run mi.
4 (A)Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí
wọ́n ju irun orí mi; lọ
púpọ̀ ni àwọn ọ̀tá mi láìnídìí,
àwọn tí ń wá láti pa mí run
A fi ipá mú mi
láti san ohun tí èmi kò jí.
5 Ìwọ mọ òmùgọ̀ mi, Ọlọ́run;
ẹ̀bi mi kò pamọ́ lójú rẹ.
30 Èmi yóò fi orin gbé orúkọ Ọlọ́run ga
èmi yóò fi ọpẹ́ gbé orúkọ rẹ̀ ga.
31 Eléyìí tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn ju ọ̀dá màlúù lọ
ju akọ màlúù pẹ̀lú ìwo rẹ̀ àti bàtà rẹ̀.
32 Àwọn òtòṣì yóò rí, wọn yóò sì yọ̀:
Ẹ̀yin yóò wá Ọlọ́run, ọkàn yín yóò sì wà láààyè!
33 Olúwa, gbọ́ ti aláìní,
kì ó sì kọ àwọn ìgbèkùn sílẹ̀.
34 Kí ọ̀run àti ayé yìn ín,
Òkun àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀,
35 Nítorí tí Ọlọ́run yóò gba Sioni là
yóò sì tún àwọn ìlú Juda wọ̀nyí kọ́.
Kí wọn ó lè máa gbé ibẹ̀,
kí wọn ó lè máa ní ní ilẹ̀ ìní.
36 Àwọn ọmọ ọmọ ọ̀dọ̀ ni yóò máa jogún rẹ̀,
àwọn tí ó fẹ́ orúkọ rẹ ni yóò máa gbé inú rẹ̀.
14 Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu kòkòrò,
ìwọ Israẹli kékeré,
nítorí Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́,”
ni Olúwa wí,
olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.
15 “Kíyèsi, Èmi yóò sọ ọ́ di òòlù ìpakà tuntun,
tí ó mú ti eyín rẹ̀ mú, ìwọ yóò lu àwọn òkè ńlá,
ìwọ yóò fọ́ wọn túútúú,
a ó sì sọ òkè kékeré di ìyàngbò.
16 Ìwọ yóò fẹ́ wọn, afẹ́fẹ́ yóò sì gbá wọn mú,
àti ẹ̀fúùfù yóò sì fẹ́ wọn dànù
Ṣùgbọ́n ìwọ yóò yọ̀ nínú Olúwa
ìwọ yóò sì ṣògo nínú Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.
17 “Àwọn tálákà àti aláìní wá omi,
ṣùgbọ́n kò sí;
ahọ́n wọn gbẹ fún òǹgbẹ.
Ṣùgbọ́n Èmi Olúwa yóò dá wọn lóhùn;
Èmi, Ọlọ́run Israẹli, kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀.
18 Èmi yóò mú kí odò kí ó sàn ní ibi gíga
àti orísun omi ní àárín Àfonífojì.
Èmi yóò sọ aṣálẹ̀ di adágún omi,
àti ilẹ̀ tí ó gbẹ gidigidi di orísun omi.
19 Èmi yóò fi sínú aṣálẹ̀
igi kedari àti kasia, maritili àti olifi.
Èmi yóò gbin junifa sí inú aginjù,
igi firi àti sípírẹ́ṣì papọ̀
20 tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn yóò fi rí i tí wọn yóò sì fi mọ̀,
kí wọn ṣàkíyèsí kí ó sì yé wọn,
pé ọwọ́ Olúwa ni ó ti ṣe èyí,
àti pé Ẹni Mímọ́ Israẹli ni ó ti dá èyí.
Jesu jẹ́ Ọ̀dọ́-Àgùntàn Ọlọ́run
29 (A)Ní ọjọ́ kejì, Johanu rí Jesu tí ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run, ẹni tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ! 30 Èyí ni ẹni tí mo ń sọ nígbà tí mo wí pé, ‘Ọkùnrin kan tí ń bọ̀ wá lẹ́yìn mi, tí ó pọ̀jù mí lọ, nítorí tí ó ti wà ṣáájú mi.’ 31 Èmi gan an kò sì mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n ìdí tí mo fi wá ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi ni kí a lè fi í hàn fún Israẹli.”
32 (B)Nígbà náà ni Johanu jẹ́rìí sí i pé: “Mo rí Ẹ̀mí sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá bí àdàbà, tí ó sì bà lé e. 33 Èmí kì bá tí mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe pé ẹni tí ó rán mi láti fi omi bamitiisi sọ fún mi pé, ‘Ọkùnrin tí ìwọ rí tí Ẹ̀mí sọ̀kalẹ̀ tí ó bà lé lórí ni ẹni tí yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi.’ 34 Èmi ti rí i, mo sì jẹ́rìí pé, èyí ni Ọmọ Ọlọ́run.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.