Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 69:1-5

Fún adarí orin. Tí ohùn “Àwọn Lílì.” Ti Dafidi.

69 Gbà mí, Ọlọ́run,
    nítorí omi ti kún dé ọrùn mi.
Mo ń rì nínú irà jíjìn,
    níbi tí kò sí ibi ìfẹsẹ̀lé.
Mo ti wá sínú omi jíjìn;
    ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀.
Agara dá mi, mo ń pè fún ìrànlọ́wọ́;
    ọ̀fun mí gbẹ, ojú mi ṣú,
nígbà tí èmi dúró de Ọlọ́run mi.
(A)Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí
    wọ́n ju irun orí mi; lọ
púpọ̀ ni àwọn ọ̀tá mi láìnídìí,
    àwọn tí ń wá láti pa mí run
A fi ipá mú mi
    láti san ohun tí èmi kò jí.

Ìwọ mọ òmùgọ̀ mi, Ọlọ́run;
    ẹ̀bi mi kò pamọ́ lójú rẹ.

Saamu 69:30-36

30 Èmi yóò fi orin gbé orúkọ Ọlọ́run ga
    èmi yóò fi ọpẹ́ gbé orúkọ rẹ̀ ga.
31 Eléyìí tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn ju ọ̀dá màlúù lọ
    ju akọ màlúù pẹ̀lú ìwo rẹ̀ àti bàtà rẹ̀.
32 Àwọn òtòṣì yóò rí, wọn yóò sì yọ̀:
    Ẹ̀yin yóò wá Ọlọ́run, ọkàn yín yóò sì wà láààyè!
33 Olúwa, gbọ́ ti aláìní,
    kì ó sì kọ àwọn ìgbèkùn sílẹ̀.

34 Kí ọ̀run àti ayé yìn ín,
    Òkun àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀,
35 Nítorí tí Ọlọ́run yóò gba Sioni là
    yóò sì tún àwọn ìlú Juda wọ̀nyí kọ́.
Kí wọn ó lè máa gbé ibẹ̀,
    kí wọn ó lè máa ní ní ilẹ̀ ìní.
36 Àwọn ọmọ ọmọ ọ̀dọ̀ ni yóò máa jogún rẹ̀,
    àwọn tí ó fẹ́ orúkọ rẹ ni yóò máa gbé inú rẹ̀.

Gẹnẹsisi 17:1-13

Májẹ̀mú Ilà abẹ́ kíkọ

17 Ní ìgbà tí Abramu di ẹni ọ̀kàn-dínlọ́gọ́rùnún (99) ọdún, Olúwa farahàn án, ó sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run alágbára (Eli-Ṣaddai), máa rìn níwájú mi, kí o sì jẹ́ aláìlábùkù. Èmi yóò sì fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú rẹ. Èmi yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀ gidigidi.”

Abramu sì dojúbolẹ̀, Ọlọ́run sì wí fún un pé. “Ní ti èmi, májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ nìyí. Ìwọ yóò di baba orílẹ̀-èdè púpọ̀. (A)A kì yóò pe orúkọ rẹ̀ ní Abramu mọ́, bí kò ṣe Abrahamu, nítorí, mo ti sọ ọ́ di baba orílẹ̀-èdè púpọ̀. Èmi yóò mú ọ bí si lọ́pọ̀lọpọ̀, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ni èmi yóò sì mú ti ara rẹ jáde wá, àwọn ọba pẹ̀lú yóò sì ti inú rẹ jáde. (B)Èmi yóò sì gbé májẹ̀mú mi kalẹ̀ láàrín tèmi tìrẹ, ní májẹ̀mú ayérayé àti láàrín irú-ọmọ rẹ ní ìran-ìran wọn, láti máa ṣe Ọlọ́run rẹ àti ti irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ. (C)Gbogbo ilẹ̀ Kenaani níbi tí ìwọ ti ṣe àjèjì ni èmi yóò fi fún ọ àti fún irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ láéláé, Èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.”

Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Abrahamu pé, “Ìwọ máa pa májẹ̀mú mi mọ́, ìwọ àti irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ àti àwọn ìran tí ó ń bọ̀. 10 (D)Èyí ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ àti ìran rẹ lẹ́yìn rẹ, májẹ̀mú tí ẹ̀yin yóò máa pamọ́. Gbogbo ọkùnrin yín ni a gbọdọ̀ kọ ní ilà. 11 (E)Ẹ̀yin yóò kọ ara yín ní ilà, èyí ni yóò jẹ́ ààmì májẹ̀mú láàrín tèmi tiyín. 12 Ní gbogbo ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn, gbogbo ọkùnrin ni a gbọdọ̀ kọ ni ilà ní ọjọ́ kẹjọ tí a bí wọn, àti àwọn tí a bí ní ilé rẹ, tàbí tí a fi owó rà lọ́wọ́ àwọn àjèjì, àwọn tí kì í ṣe ọmọ rẹ̀. Èyí yóò sì jẹ́ májẹ̀mú láéláé tí yóò wà láàrín Èmi àti irú-ọmọ rẹ. 13 Ìbá à ṣe ẹni tí a bí nínú ilé rẹ, tàbí ẹni tí o fi owó rà, a gbọdọ̀ kọ wọ́n ní ilà; májẹ̀mú mí lára yín yóò jẹ́ májẹ̀mú ayérayé.

Romu 4:1-12

Abrahamu gba ìdáláre nípa ìgbàgbọ́

Ǹjẹ́ kín ni àwa ó ha wí nípa Abrahamu, baba wa ti o ṣàwárí èyí? Májẹ̀mú láéláé jẹ́rìí sí i wí pé, a gba Abrahamu là nípa ìgbàgbọ́. (A)Nítorí bí a bá dá Abrahamu láre nípa iṣẹ́, ó ní ohun ìṣògo; ṣùgbọ́n kì í ṣe níwájú Ọlọ́run. (B)Ìwé Mímọ́ ha ti wí? “Abrahamu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.”

(C)Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó ṣiṣẹ́, a kò ka èrè náà sí oore-ọ̀fẹ́ bí kò ṣe sí ẹ̀tọ́ rẹ̀. (D)Ṣùgbọ́n fún ẹni tí kò ṣiṣẹ́, tí ó sì ń gba ẹni tí ó ń dá ènìyàn búburú láre gbọ́, a ka ìgbàgbọ́ rẹ̀ sí òdodo. Gẹ́gẹ́ bí Dafidi pẹ̀lú ti pe olúwa rẹ̀ náà ní ẹni ìbùkún, ẹni tí Ọlọ́run ka òdodo fún láìsí ti iṣẹ́.

(E)Wí pé, “Ìbùkún ni fún àwọn
    ẹni tí a dárí ìrékọjá wọn jì,
    tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀.
Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà
    ẹni tí Olúwa kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí lọ́rùn.”

Ìbùkún yìí ha jẹ́ ti àwọn akọlà nìkan, tàbí ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú? Nítorí tí a wí pé, Abrahamu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un. 10 Báwo ni a ṣe kà á sí i? Nígbà tí ó wà ní ìkọlà tàbí ní àìkọlà? Kì í ṣe ni ìkọlà, ṣùgbọ́n ní àìkọlà ni. 11 (F)Ó sì gbé ààmì ìkọlà àti èdìdì òdodo ìgbàgbọ́ tí ó ní nígbà tí ó wà ní àìkọlà kí ó lè ṣe baba gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́, bí a kò tilẹ̀ kọ wọ́n ní ilà kí a lè ka òdodo sí wọn pẹ̀lú. 12 Àti baba àwọn tí ìkọlà tí kì í ṣe pé a kàn kọlà fún nìkan, ṣùgbọ́n tiwọn ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tí baba wa Abrahamu ní, kí a tó kọ ọ́ nílà.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.