Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Adúra ti Dafidi.
86 Gbọ́, Olúwa, kí o sì dá mi lóhùn,
nítorí mo jẹ́ tálákà àti aláìní.
2 Dáàbò bò ayé mi, nítorí a ti yà mí sọ́tọ̀ fún ọ:
ìwọ ni Ọlọ́run mi,
gbà ìránṣẹ́ rẹ là
tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.
3 Ṣàánú fún mi, Olúwa,
nítorí èmi ń pè ọ́ ní gbogbo ọjọ́.
4 Mú ayọ̀ wà fún ìránṣẹ́ rẹ,
nítorí ìwọ, Olúwa,
ni mo gbé ọkàn mí sókè sí.
5 Ìwọ ń dáríjì, ìwọ sì dára, Olúwa,
ìwọ sì ṣàánú fún gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́,
6 Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa;
tẹ́tí sí ẹkún mi fún àánú.
7 Ní ọjọ́ ìpọ́njú mi èmi yóò pè ọ́,
nítorí ìwọ yóò dá mi lóhùn.
8 Nínú àwọn òrìṣà kò sí ẹni tí ó dàbí i rẹ, Olúwa:
kò sí àwọn iṣẹ́ tí a lè fiwé tìrẹ.
9 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ dá
yóò wá, láti wá jọ́sìn níwájú rẹ, Olúwa;
wọn ó mú ògo wà fún orúkọ rẹ̀.
10 Nítorí pé ìwọ tóbi, ìwọ sì ń ṣe ohun ìyanu;
ìwọ nìkan ni Ọlọ́run.
11 Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, Olúwa,
èmi ó sì máa rìn nínú òtítọ́ rẹ;
fún mi ní ọkàn tí kì í yapa,
kí èmi kí ó ba lè bẹ̀rù orúkọ rẹ.
12 Èmi ó yìn ọ́, Olúwa Ọlọ́run mi, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;
èmi ó fògo fún orúkọ rẹ títí láé
13 Nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ si mi;
ìwọ ti gbà mí kúrò nínú ọ̀gbun isà òkú.
14 Àwọn onígbèéraga ń dojúkọ mí, Ọlọ́run;
àti ìjọ àwọn alágbára ń wá
ọkàn mi kiri,
wọn kò sì fi ọ́ pè.
15 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, jẹ́ aláàánú àti Ọlọ́run olójúrere,
Ó lọ́ra láti bínú, Ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ àti òtítọ́.
16 Yípadà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi;
fún àwọn ènìyàn rẹ ní agbára
kí o sì gba ọ̀dọ́mọkùnrin ìránṣẹ́bìnrin rẹ là.
17 Fi ààmì hàn mí fún rere,
kí àwọn tí ó kórìíra mi lè ri,
kí ojú lè tì wọ́n, nítorí ìwọ Olúwa
ni ó ti tù mí nínú.
27 Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìpẹ̀kun ìlú náà, Samuẹli wí fún Saulu pé, “Sọ fún ìránṣẹ́ náà kí ó máa lọ ṣáájú u wa,” ìránṣẹ́ náà sì ṣe bẹ́ẹ̀, “ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó dúró díẹ̀, kí èmi kí ó lè sọ ọrọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún ọ.”
10 Samuẹli sì mú ìgò kékeré tí òróró wà nínú rẹ̀, ó sì dà á sí orí Saulu. Ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu, wí pé, “Olúwa kò ha tí fi òróró yàn ọ ní olórí lórí ohun ìní rẹ̀? 2 Bí ìwọ bá kúrò lọ́dọ̀ mi lónìí, ìwọ yóò bá ọkùnrin méjì pàdé lẹ́bàá ibojì Rakeli ní Ṣelṣa, ní agbègbè Benjamini. Wọ́n yóò sọ fún ọ pé, ‘Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ìwọ jáde lọ láti wá ní wọn tí rí. Nísinsin yìí, baba à rẹ tí dákẹ́ kò ronú nípa wọn mọ́, ó sì ń dààmú nípa à rẹ. Ó ń béèrè, “Kí ni èmi yóò ṣe nípa ọmọ mi?” ’
3 “Nígbà náà, ìwọ yóò lọ láti ibẹ̀ títí yóò fi dé ibi igi ńlá Tabori. Ọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run ní Beteli yóò pàdé rẹ níbẹ̀. Ọ̀kan yóò mú ọmọ ewúrẹ́ mẹ́ta lọ́wọ́, èkejì, ìṣù àkàrà mẹ́ta àti ẹ̀kẹta yóò mú ìgò wáìnì. 4 Wọ́n yóò kí ọ, wọn yóò sì fún ọ ní ìṣù àkàrà méjì, tí ìwọ yóò gbà lọ́wọ́ wọn.
5 “Lẹ́yìn náà, ìwọ yóò lọ sí òkè Ọlọ́run, níbi tí ẹgbẹ́ ogun àwọn Filistini wà. Bí ìwọ ti ń súnmọ́ ìlú náà, ìwọ yóò bá àwọn wòlíì tí ó tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ bọ̀ láti ibi gíga, pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn, tambori àti fèrè àti haapu níwájú wọn, wọn yóò sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀. 6 Ẹ̀mí Olúwa yóò sì bà lé ọ, ìwọ yóò sì sọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú wọn, ìwọ yóò sì di ẹni ọ̀tọ̀. 7 Bí ìwọ bá ti rí ààmì wọ̀nyí, ṣe ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá bà láti ṣe, nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.
8 “Lọ ṣáájú mi sí Gilgali. Èmi yóò sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ wá láti rú ẹbọ sísun àti láti rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀, ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ dúró fún ọjọ́ méje títí èmi yóò fi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ láti sọ fún ọ ohun tí ó yẹ tí ìwọ yóò ṣe.”
Má ṣe dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́
14 Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́: nítorí ìdàpọ̀ kín ni òdodo ní pẹ̀lú àìṣòdodo? Ìdàpọ̀ kín ni ìmọ́lẹ̀ sì ní pẹ̀lú òkùnkùn? 15 Ìrẹ́pọ̀ kín ni Kristi ní pẹ̀lú Beliali? Tàbí ìpín wó ni ẹni tí ó gbàgbọ́ ní pẹ̀lú aláìgbàgbọ́? 16 (A)Ìrẹ́pọ̀ kín ni tẹmpili Ọlọ́run ní pẹ̀lú òrìṣà? Nítorí ẹ̀yin ní tẹmpili Ọlọ́run alààyè; gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti wí pé:
“Èmi á gbé inú wọn,
èmi o sì máa rìn láàrín wọn,
èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn,
wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi.”
17 (B)Nítorí náà,
“Ẹ jáde kúrò láàrín wọn,
kí ẹ sì yá ara yín si ọ̀tọ̀,
ni Olúwa wí.
Ki ẹ má ṣe fi ọwọ́ kan ohun àìmọ́;
Èmi ó sì gbà yín.”
18 Àti,
(C)“Èmi o sì jẹ́ Baba fún yín,
Ẹ̀yin ó sì jẹ́ ọmọkùnrin mi àti ọmọbìnrin mi!
ní Olúwa Olódùmarè wí.”
7 Nítorí náà, ẹ̀yin olùfẹ́, bí a ti ní àwọn ìlérí wọ̀nyí, ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ara àti ti ẹ̀mí, kí a sọ ìwà mímọ́ dí pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.