Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 148

148 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa láti ọ̀run wá,
    Ẹ fi ìyìn fún un níbi gíga.
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin ọmọ-ogun rẹ̀
Ẹ fi ìyìn fún un,
    oòrùn àti òṣùpá
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.
Ẹ fi ìyìn fún un,
    ẹ̀yin ọ̀run àti àwọn ọ̀run gíga
    àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run.

Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa
    nítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn
Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláé
    ó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já.

Ẹ yin Olúwa láti ilẹ̀ ayé wá
    ẹ̀yin ẹ̀dá inú Òkun títóbi
    àti ẹ̀yin ibú Òkun
Mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyín
    ìdí omi àti àwọn ìkùùkuu,
    ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ;
Òkè ńlá àti gbogbo òkè kéékèèkéé,
    igi eléso àti gbogbo igi kedari,
10 Àwọn ẹranko ńlá àti ẹran ọ̀sìn
    gbogbo ohun afàyàfà àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́:
11 Àwọn ọba ayé àti ènìyàn ayé gbogbo
    àwọn ọmọ-aládé àti gbogbo àwọn onídàájọ́ ayé,
12 Ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin
    àwọn arúgbó àti àwọn ọmọdé.

13 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa
    nítorí orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ní ọlá
    ògo rẹ̀ kọjá ayé àti ọ̀run
14 Ó sì gbé ìwo kan sókè fún àwọn ènìyàn rẹ̀,
    ìyìn fún gbogbo ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àní fún àwọn ọmọ Israẹli,
    àwọn ènìyàn tí ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Òwe 9:1-12

Ìpè ti ọgbọ́n àti àìgbọ́n

Ọgbọ́n ti kọ́ ilé rẹ̀,
    ó ti gbẹ́ òpó o rẹ̀ méjèèjì,
ó ti fi ilé pọn tí, ó ti fọ̀nà rokà.
    Ó sì ti ṣètò o tábìlì oúnjẹ rẹ̀
ó ti rán àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ jáde, ó sì ń pè,
    láti ibi tí ó ga jù láàrín ìlú.
“Jẹ́ kí gbogbo àwọn aláìgbọ́n wọ ibí wá!”
    Ó ń wí fún àwọn tí kò lọ́gbọ́n pé
“Wá, ẹ wá fẹ́ oúnjẹ mi
    sì mu wáìnì tí mo ti pò.
Fi ìwà àìmọ̀kan rẹ sílẹ̀ ìwọ yóò sì yè;
    rìn ní ọ̀nà òye.

“Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹlẹ́gàn wí, kọ lẹ́tà sí àbùkù
    ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹni búburú wí kọ lẹ́tà sí èébú.
Má ṣe bá ẹlẹ́gàn wí, àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò kórìíra rẹ.
    Bá ọlọ́gbọ́n wí yóò sì fẹ́ràn rẹ;
kọ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì gbọ́n sí i
    kọ́ olódodo ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì fi kún ìmọ̀ rẹ̀.

10 “Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n,
    ìmọ̀ nípa Ẹni mímọ́ ni òye.
11 Nítorí nípasẹ̀ mi ọjọ́ rẹ yóò gùn
    ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún yóò sì kún ọjọ́ ayé rẹ.
12 Bí ìwọ bá gbọ́n, ọgbọ́n rẹ yóò fún ọ ní èrè:
    bí ìwọ bá jẹ́ ẹlẹ́gàn, ìwọ nìkan ni yóò jìyà.”

2 Peteru 3:8-13

(A)Ṣùgbọ́n, olùfẹ́, ẹ má ṣe gbàgbé ohun kan yìí, pé ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Olúwa bí ẹgbẹ̀rún ọdún ni ó rí, àti ẹgbẹ̀rún ọdún bí ọjọ́ kan. Olúwa kò fi ìlérí rẹ̀ jáfara, bí àwọn ẹlòmíràn ti ka ìjáfara sí; ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé, bí kò ṣe kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.

10 Ṣùgbọ́n ọjọ́ Olúwa ń bọ̀ wá bí olè ní òru; nínú èyí tí àwọn ọ̀run yóò kọjá lọ pẹ̀lú ariwo ńlá, àti àwọn ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run yóò sì ti inú ooru gbígbóná gidigidi di yíyọ́, ayé àti àwọn iṣẹ́ tí ó wà nínú rẹ̀ yóò sì jóná túútúú.

11 Ǹjẹ́ bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ti yọ́ bẹ́ẹ̀, irú ènìyàn wo ni ẹ̀yin ìbá jẹ́ nínú ìwà mímọ́ gbogbo àti ìwà-bí-Ọlọ́run. 12 (B)Kí ẹ máa retí, kí ẹ sì máa múra gírí de dídé ọjọ́ Ọlọ́run, nítorí èyí tí àwọn ọ̀run yóò gbiná, tí wọn yóò di yíyọ́, tí àwọn ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ yóò sì ti inú ooru gbígbóná gidigidi di yíyọ́. 13 (C)Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀, àwa ń retí àwọn ọ̀run tuntun àti ayé títún nínú èyí tí òdodo ń gbé.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.