Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 27

Ti Dafidi.

27 Olúwa ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi;
    ta ni èmi yóò bẹ̀rù?
Olúwa ni ibi ìsádi ẹ̀mí mi,
    ẹ̀rù ta ni yóò bà mí?

Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú kọjú ìjà sí mi
    láti jẹ ẹran-ara mi,
àní àwọn ọ̀tá mi àti àwọn abínúkú mi,
    wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.
Bí ọmọ-ogun tilẹ̀ yí mi ká tí wọ́n sì dìde sí mi,
    ọkàn mi kì yóò bẹ̀rù;
bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi,
    nínú èyí ni ọkàn mi yóò le.

Ohun kan ni mo béèrè lọ́dọ̀ Olúwa,
    òhun ni èmi yóò máa wá kiri:
kí èmi kí ó le wà ní ilé Olúwa
    ní ọjọ́ ayé mi gbogbo,
kí èmi: kí ó le kíyèsi ẹwà Olúwa,
    kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹmpili rẹ̀.
Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njú
    òun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ rẹ̀;
níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́;
    yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta.

Ní ìsinsin yìí, a ti gbé orí mi sókè
    ga ju ti àwọn ọ̀tá mi lọ tí ó yí mí ká;
èmi yóò rú ẹbọ nínú àgọ́ rẹ, ẹbọ ariwo àti ti ayọ̀;
    èmi yóò kọrin àní orin dídùn sí Olúwa.

Gbọ́ ohùn mi nígbà tí ẹ̀mí bá à ń pè, Háà! Olúwa,
    ṣe àánú fún mi kí o sì dá mi lóhùn;
“Wá,” ọkàn mi wí pé, “wá ojú u rẹ̀.”
    Ojú rẹ, Olúwa, ni èmí ń wá.
Má ṣe fi ojú rẹ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi,
    má ṣe fi ìbínú sá ìránṣẹ́ rẹ tì;
    ìwọ tí o ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi,
Má ṣe fi mí sílẹ̀, má sì ṣe kọ̀ mí,
    háà! Ọlọ́run ìgbàlà mi.
10 Bí ìyá àti baba bá kọ̀ mí sílẹ̀,
    Olúwa yóò tẹ́wọ́ gbà mí.
11 Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, Olúwa,
    kí o sì sìn mi lọ sí ọ̀nà tí ó tẹ́jú
    nítorí àwọn ọ̀tá mi.
12 Má ṣe fi mí lé ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi lọ́wọ́,
    nítorí àwọn ẹlẹ́rìí èké ti dìde sí mi,
    wọ́n sì mí ìmí ìkà.

13 Èmi ní ìgbàgbọ́ pé,
    èmi yóò rí ìre Olúwa
    ní ilẹ̀ alààyè.
14 Dúró de Olúwa;
    kí ó jẹ alágbára, kí o sì mú ọkàn le
    àní dúró de Olúwa.

Malaki 2:10-3:1

10 Baba kan náà kí gbogbo wa ha ní? Ọlọ́run kan náà kọ́ ni ó dá wa bí? Nítorí kín ni àwa ha ṣe sọ májẹ̀mú àwọn baba wa di aláìmọ nípa híhu ìwà àrékérekè olúkúlùkù sí arákùnrin rẹ̀?

11 Juda ti ń hùwà àrékérekè, a sì ti hùwà ìríra ní Israẹli àti ni Jerusalẹmu: nítorí Juda tí sọ ìwà mímọ́ Olúwa di aláìmọ́, èyí tí ó fẹ́, nípa gbígbé ọmọbìnrin ọlọ́run àjèjì ni ìyàwó. 12 Ní ti ẹni tí ó ṣe èyí, ẹni tí ó wù kí ó jẹ, kí Olúwa kí ó gé e kúrò nínú àgọ́ Jakọbu, bí ó tilẹ̀ mú ẹbọ ọrẹ wá fún Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

13 Èyí ni ohun mìíràn tí ẹ̀yin sì túnṣe: Ẹ̀yin fi omijé bo pẹpẹ Olúwa mọ́lẹ̀. Ẹ̀yin sọkún, ẹ̀yin sì ba ara jẹ́ nítorí tì Òun kò ka ọrẹ yín sí mọ́, tàbí kí ó fi inú dídùn gba nǹkan yìí lọ́wọ́ yín. 14 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, “Nítorí kín ní?” Nítorí Olúwa ti ṣe ẹlẹ́rìí láàrín ìwọ àti láàrín aya èwe rẹ, ẹni tí ìwọ ti ń hùwà ẹ̀tàn sí i: bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkejì rẹ ni òun jẹ́, àti aya májẹ̀mú rẹ.

15 Ọlọ́run kò ha ti ṣe wọ́n ní ọ̀kan? Ni ara àti ni ẹ̀mí tirẹ̀ ni. Èéṣe tí Ọlọ́run da yín lọ́kàn? Kí òun bá à lè wá irú-ọmọ bí ti Ọlọ́run. Nítorí náà, ẹ tọ́jú ẹ̀mí yín, ẹ má sì ṣe hùwà ẹ̀tàn sí aya èwe yín.

16 “Ọkùnrin tí ó bá kórìíra, tí ó sì kọ ìyàwó rẹ̀,” Ṣe ìwà ipá sí ẹni tí ó yẹ kí ó dá ààbò bò, ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí, Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun.

Nítorí náà, ẹ ṣọ́ ẹ̀mí yín, kí ẹ má ṣe hùwà ẹ̀tàn.

Ọjọ́ ìdájọ́

17 Ẹ̀yin ti fi ọ̀rọ̀ yín dá Olúwa ní agara.

Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, “Nínú kín ni àwa fi dá a ní agara?”

Nígbà tí ẹ̀yìn wí pé, “Gbogbo ẹni tí ó ṣe ibi, rere ni níwájú Olúwa, inú rẹ̀ sì dùn sí wọn,” tàbí “Níbo ni Ọlọ́run ìdájọ́ gbé wà?”

Rírán Mesiah náà

(A)“Wò ó, Èmi yóò ran ìránṣẹ́ mi, yóò tún ọ̀nà ṣe ṣáájú mi. Nígbà náà ni Olúwa, tí ẹ̀yin ń wa, yóò dé ni òjijì sí tẹmpili rẹ̀; àní oníṣẹ́ májẹ̀mú náà, tí inú yín dùn sí, yóò dé,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

Luku 1:5-17

Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ibí Johanu onítẹ̀bọmi

(A)Nígbà ọjọ́ Herodu ọba Judea, àlùfáà kan wà, láti ìran Abijah, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Sekariah: aya rẹ̀ sì ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Aaroni, orúkọ rẹ̀ a sì máa jẹ́ Elisabeti. Àwọn méjèèjì sì ṣe olódodo níwájú Ọlọ́run, wọ́n ń rìn ní gbogbo òfin àti ìlànà Olúwa ní àìlẹ́gàn. Ṣùgbọ́n wọn kò ní ọmọ, nítorí tí Elisabeti yàgàn; àwọn méjèèjì sì di arúgbó.

Ó sì ṣe, nígbà tí ó ń ṣe iṣẹ́ àlùfáà níwájú Ọlọ́run ni àkókò tirẹ̀ (B)Bí ìṣe àwọn àlùfáà, ipa tirẹ̀ ni láti máa fi tùràrí jóná, nígbà tí ó bá wọ inú tẹmpili Olúwa lọ. 10 Gbogbo ìjọ àwọn ènìyàn sì ń gbàdúrà lóde ní àkókò sísun tùràrí.

11 (C)Angẹli Olúwa kan sì fi ara hàn án, ó dúró ní apá ọ̀tún pẹpẹ tùràrí. 12 Nígbà tí Sekariah sì rí i, orí rẹ̀ wú, ẹ̀rù sì bà á. 13 (D)Ṣùgbọ́n angẹli náà wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, Sekariah: nítorí tí àdúrà rẹ gbà; Elisabeti aya rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin kan fún ọ, ìwọ ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Johanu. 14 Òun yóò sì jẹ́ ayọ̀ àti ìdùnnú fún ọ: ènìyàn púpọ̀ yóò sì yọ̀ sí ìbí rẹ. 15 (E)Nítorí òun ó pọ̀ níwájú Olúwa, kì yóò sì mu ọtí wáìnì, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sì mu ọtí líle; yóò sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àní láti inú ìyá rẹ̀ wá. 16 Òun ó sì yí ènìyàn púpọ̀ padà nínú àwọn ọmọ Israẹli sí Olúwa Ọlọ́run wọn. 17 (F)Ẹ̀mí àti agbára Elijah ni Olúwa yóò sì fi ṣáájú rẹ̀ lọ, láti pa ọkàn àwọn baba dà sí ti àwọn ọmọ, àti ti àwọn aláìgbọ́ràn sí ọgbọ́n àwọn olóòtítọ́; kí ó le pèsè àwọn ènìyàn tí a múra sílẹ̀ de Olúwa.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.