Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.
85 Ìwọ fi ojúrere hàn fún ilé rẹ, Olúwa;
ìwọ mú ohun ìní Jakọbu bọ̀ sí ipò.
2 Ìwọ dárí àìṣedéédéé àwọn ènìyàn rẹ jì
ìwọ sì bó ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀. Sela.
8 Èmi ó gbọ́ ohun tí Olúwa Ọlọ́run yóò wí;
ó ṣèlérí àlàáfíà fún àwọn ènìyàn rẹ̀, àní ẹni mímọ́ rẹ̀:
Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí wọn padà sí àìmoye.
9 Nítòótọ́ ìgbàlà rẹ̀ súnmọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
pé kí ògo rẹ̀ kí ó lè gbé ní ilẹ̀ wa.
10 Ìfẹ́ àti òtítọ́ parapọ̀;
òdodo àti àlàáfíà fẹnu ko ara wọn.
11 Òtítọ́ ń sun jáde láti ilẹ̀ wá
òdodo sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run.
12 Olúwa yóò fi ohun dídára fún ni nítòótọ́,
ilẹ̀ wa yóò sì mú ìkórè rẹ̀ jáde.
13 Òdodo síwájú rẹ lọ
o sì pèsè ọ̀nà fún ìgbésẹ̀ rẹ̀.
Ìpè Jeremiah
4 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé,
5 (A)Kí ó tó di pé mo dá ọ láti inú ni mo ti mọ̀ ọ́n,
kí ó sì tó di pé a bí ọ ni mo ti yà ọ́ sọ́tọ̀.
Mo yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí wòlíì fún àwọn orílẹ̀-èdè.
6 Mo sọ pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè, ọmọdé ni mí, èmi kò mọ bí a ṣe é sọ̀rọ̀.”
7 Olúwa sọ fún mi pé, “Má ṣe sọ pé, ‘Ọmọdé lásán ni mí.’ O gbọdọ̀ ní láti lọ sí ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí mo rán ọ sí, kí o sì sọ ohun tí mo pàṣẹ fún ọ.” 8 (B)Olúwa sì wí pé má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí tí èmi wà pẹ̀lú rẹ èmi ó sì gbà ọ́.
9 Olúwa sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi kàn mí lẹ́nu, ó sì wí fún mi pé nísinsin yìí mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí inú ẹnu rẹ 10 (C)Wò ó, mo yàn ọ́ lórí àwọn orílẹ̀-èdè àti ìjọba gbogbo láti fàtu, láti wó lulẹ̀, láti bàjẹ́, láti jágbà, láti máa kọ́, àti láti máa gbìn.
Ìjọ ní Antioku
19 (A)Nítorí náà àwọn tí a sì túká kiri nípasẹ̀ inúnibíni tí ó dìde ní ti Stefanu, wọ́n rìn títí de Fonisia, àti Saipurọsi, àti Antioku, wọn kò sọ ọ̀rọ̀ náà fún ẹnìkan bí kò ṣe fún kìkì àwọn Júù. 20 Ṣùgbọ́n àwọn kan ń bẹ nínú wọn tí ó jẹ́ ará Saipurọsi àti Kirene; nígbà tí wọ́n dé Antioku, wọ́n sọ̀rọ̀ fún àwọn Helleni pẹ̀lú, wọ́n ń wàásù ìròyìn ayọ̀ nípa Jesu Olúwa. 21 Ọwọ́ Olúwa sì wà pẹ̀lú wọn: ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì gbàgbọ́, wọ́n sì yípadà sí Olúwa.
22 Ìròyìn nípa wọn sì dé etí ìjọ ti ó wà ni Jerusalẹmu; wọ́n sì rán Barnaba lọ títí dé Antioku; 23 Nígbà ti ó dé ti ó sì rí ẹ̀rí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, ó yọ̀, ó sì gba gbogbo wọn níyànjú pé, pẹ̀lú ìpinnu ọkàn ni kí wọn fi ara mọ́ Olúwa. 24 Nítorí òun jẹ́ ènìyàn rere, ó sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti fún ìgbàgbọ́; ènìyàn púpọ̀ ni a sì kà kún Olúwa.
25 Barnaba sì jáde lọ sí Tarsu láti wá Saulu, 26 nígbà tí ó sì rí i, ó mú un wá sí Antioku. Fún ọdún kan gbáko ni wọ́n fi ń bá ìjọ péjọpọ̀, tí wọ́n sì kọ́ ènìyàn púpọ̀. Ní Antioku ni a sì kọ́kọ́ ti pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ni “Kristiani.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.