Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 125

Orin fún ìgòkè.

125 Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò dàbí òkè Sioni,
    tí a kò lè ṣí ní ìdí, bí kò ṣe pé ó dúró láéláé
Bí òkè ńlá ti yí Jerusalẹmu ká,
    bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yí ènìyàn ká
    láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.

Nítorí tí ọ̀pá àwọn ènìyàn búburú
    kì yóò bà lé ìpín àwọn olódodo;
kí àwọn olódodo kí ó máa ba à
    fi ọwọ́ wọn lé ẹ̀ṣẹ̀.

Olúwa ṣe rere fún àwọn ẹni rere,
    àti fún àwọn tí àyà wọn dúró ṣinṣin.
Bí ó ṣe ti irú àwọn tí wọn yà sí ipa ọ̀nà wíwọ́ wọn;
    Olúwa yóò jẹ́ kí wọn lọ pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.

Ṣùgbọ́n àlàáfíà yóò wà lórí Israẹli.

2 Ọba 2:9-22

Nígbà tí wọ́n rékọjá, Elijah sì wí fún Eliṣa pé, “Sọ fún mi, kí ni èmi lè ṣe fún ọ kí ó tó di wí pé wọ́n gbà mí kúrò lọ́dọ̀ rẹ?”

“Jẹ́ kí èmi kí ó jogún ìlọ́po méjì ẹ̀mí rẹ.” Ó dá a lóhùn.

10 “Ìwọ ti béèrè ohun tí ó ṣòro,” Elijah wí pé, “Síbẹ̀ tí ìwọ bá rí mi nígbà tí a bá gbà mí kúrò lọ́wọ́ rẹ, yóò jẹ́ tìrẹ bí bẹ́ẹ̀ kọ́ kò ní rí bẹ́ẹ̀.”

11 (A)Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń rìn lọ tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ pọ̀, lọ́gán kẹ̀kẹ́ iná àti ẹṣin iná yọ sí wọn ó sì ya àwọn méjèèjì nípa, Elijah sì gòkè lọ sí ọ̀run pẹ̀lú àjà. 12 Eliṣa rí èyí ó sì kígbe sókè, “Baba mi! Baba mi! Kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin Israẹli!” Eliṣa kò sì rí i mọ́. Ó sì mú aṣọ ara rẹ̀ ó sì fà wọ́n ya sọ́tọ̀.

13 Ó sì mú agbádá tí ó ti jábọ́ láti ọ̀dọ̀ Elijah ó sì padà lọ, ó sì dúró lórí bèbè Jordani. 14 Ó sì mú agbádá náà tí ó jábọ́ láti ọwọ́ rẹ̀, ó sì lu omi pẹ̀lú rẹ̀. “Níbo ni Olúwa Ọlọ́run Elijah wà?” Ó béèrè. Nígbà tí ó lu omi náà, ó sì pín sí apá ọ̀tún àti sí òsì, Eliṣa sì rékọjá.

15 Àwọn ọmọ wòlíì láti Jeriko, tí wọ́n ń wò, wí pé, “Ẹ̀mí Elijah sinmi lé Eliṣa.” Wọ́n sì lọ láti lọ bá a, wọ́n sì dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀. 16 “Wò ó,” wọ́n wí pé, “Àwa ìránṣẹ́ ni àádọ́ta ọkùnrin alágbára. Jẹ́ kí wọ́n lọ láti lọ wá ọ̀gá rẹ wá. Bóyá ẹ̀mí Olúwa ti gbé e sókè, ó sì gbé e kalẹ̀ lórí òkè ńlá tàbí lórí ilẹ̀.”

“Rárá,” Eliṣa dá a lóhùn pé, “Má ṣe rán wọn.”

17 Ṣùgbọ́n wọ́n rọ̀ ọ́ títí ojú fi tì í láti gbà. Ó wí pé, “Rán wọn.” Wọ́n sì rán àádọ́ta ènìyàn tí ó wá a fún ọjọ́ mẹ́ta ṣùgbọ́n wọn kò rí i. 18 Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ Eliṣa, tí ó dúró ní Jeriko, ó wí fún wọn pé, “Ṣé èmi kò sọ fún un yín kí ẹ má lọ?”

Ìwòsàn omi

19 Àwọn ọkùnrin ìlú wí fún Eliṣa, pé “Wò ó, olúwa wa, ìtẹ̀dó ìlú yìí dára, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti rí i, ṣùgbọ́n omi náà burú, ilẹ̀ náà sì sá.”

20 Ó sì wí pé, “Mú àwokòtò tuntun fún mi wá, kí o sì mú iyọ̀ sí inú rẹ̀.” Wọ́n sì gbé e wá fún un.

21 Nígbà náà ó sì jáde lọ sí ibi orísun omi, ó sì da iyọ̀ sí inú rẹ̀, ó wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Èmi ti wo omi yìí sàn. Kò ní mú ikú wá mọ́ tàbí mú ilẹ̀ náà sá.’ ” 22 Omi náà sì ti dára ni mímu títí di òní, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Eliṣa ti sọ.

Ìṣe àwọn Aposteli 3:17-4:4

17 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ará, mo mọ̀ pé nípa àìmọ̀ ni ẹ̀yin fi ṣe é, gẹ́gẹ́ bí àwọn olórí yín pẹ̀lú ti ṣe. 18 Ṣùgbọ́n báyìí ni Ọlọ́run ti ṣe ìmúṣẹ àwọn ohun tí ó ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu gbogbo àwọn wòlíì pé, Kristi rẹ̀ yóò jìyà. 19 Nítorí náà ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì yípadà sí Ọlọ́run, kí a lè pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́, kí àkókò ìtura bá a lè ti ọ̀dọ̀ Olúwa wá, 20 àti kí ó ba à lè rán Kristi tí a ti yàn fún yín tẹlẹ̀: àní Jesu. 21 Ẹni tí ọ̀run kò lé ṣàìmá gbà títí di ìgbà ìmúpadà ohun gbogbo, tí Ọlọ́run ti sọ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ tí wọn ti ń bẹ nígbà tí ayé ti ṣẹ̀. 22 (A)Mose wí pé, ‘Olúwa Ọlọ́run yín yóò gbé wòlíì kan dìde fún yín nínú àwọn arákùnrin yín, bí èmi; òun ni ẹ̀yin yóò máa gbọ́ tirẹ̀ ní ohun gbogbo tí yóò máa sọ fún un yín. 23 (B)Yóò sì ṣe, olúkúlùkù ọkàn ti kò bá gbọ́ ti wòlíì náà, òun ni a ó parun pátápátá kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.’

24 “Àní, gbogbo àwọn wòlíì láti Samuẹli wá, àti àwọn tí ó tẹ̀lé e, iye àwọn tí ó ti sọ̀rọ̀, wọn sọ ti ọjọ́ wọ̀nyí pẹ̀lú. 25 (C)Ẹ̀yin ni ọmọ àwọn wòlíì, àti ti májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti bá àwọn baba yín dá nígbà tí ó wí fún Abrahamu pé, ‘Láti ipasẹ̀ irú àwọn ọmọ rẹ̀ ni a ó ti bùkún fún gbogbo ìdílé ayé.’ 26 Nígbà ti Ọlọ́run jí Jesu Ọmọ rẹ̀ dìde, ó kọ́ rán an sí i yín láti bùkún fún un yín, nípa yíyí olúkúlùkù yín padà kúrò nínú ìwà búburú rẹ̀.”

Peteru àti Johanu níwájú àwọn Sadusi

Bí wọn sì tí ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, àwọn àlùfáà àti olórí ẹ̀ṣọ́ tẹmpili àti àwọn Sadusi dìde sí wọn. Inú bí wọn, nítorí tí wọn kọ́ àwọn ènìyàn, wọ́n sì ń wàásù àjíǹde kúrò nínú òkú nínú Jesu. Wọn sì nawọ́ mú wọn, wọn sì tì wọ́n mọ́ ilé túbú títí ó fi dí ọjọ́ kejì; nítorí tí alẹ́ ti lẹ́ tan. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà gbàgbọ́; iye àwọn ọkùnrin náà sì tó ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (5,000).

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.