Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Ti Dafidi.
27 Olúwa ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi;
ta ni èmi yóò bẹ̀rù?
Olúwa ni ibi ìsádi ẹ̀mí mi,
ẹ̀rù ta ni yóò bà mí?
2 Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú kọjú ìjà sí mi
láti jẹ ẹran-ara mi,
àní àwọn ọ̀tá mi àti àwọn abínúkú mi,
wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.
3 Bí ọmọ-ogun tilẹ̀ yí mi ká tí wọ́n sì dìde sí mi,
ọkàn mi kì yóò bẹ̀rù;
bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi,
nínú èyí ni ọkàn mi yóò le.
4 Ohun kan ni mo béèrè lọ́dọ̀ Olúwa,
òhun ni èmi yóò máa wá kiri:
kí èmi kí ó le wà ní ilé Olúwa
ní ọjọ́ ayé mi gbogbo,
kí èmi: kí ó le kíyèsi ẹwà Olúwa,
kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹmpili rẹ̀.
5 Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njú
òun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ rẹ̀;
níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́;
yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta.
6 Ní ìsinsin yìí, a ti gbé orí mi sókè
ga ju ti àwọn ọ̀tá mi lọ tí ó yí mí ká;
èmi yóò rú ẹbọ nínú àgọ́ rẹ, ẹbọ ariwo àti ti ayọ̀;
èmi yóò kọrin àní orin dídùn sí Olúwa.
7 Gbọ́ ohùn mi nígbà tí ẹ̀mí bá à ń pè, Háà! Olúwa,
ṣe àánú fún mi kí o sì dá mi lóhùn;
8 “Wá,” ọkàn mi wí pé, “wá ojú u rẹ̀.”
Ojú rẹ, Olúwa, ni èmí ń wá.
9 Má ṣe fi ojú rẹ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi,
má ṣe fi ìbínú sá ìránṣẹ́ rẹ tì;
ìwọ tí o ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi,
Má ṣe fi mí sílẹ̀, má sì ṣe kọ̀ mí,
háà! Ọlọ́run ìgbàlà mi.
10 Bí ìyá àti baba bá kọ̀ mí sílẹ̀,
Olúwa yóò tẹ́wọ́ gbà mí.
11 Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, Olúwa,
kí o sì sìn mi lọ sí ọ̀nà tí ó tẹ́jú
nítorí àwọn ọ̀tá mi.
12 Má ṣe fi mí lé ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi lọ́wọ́,
nítorí àwọn ẹlẹ́rìí èké ti dìde sí mi,
wọ́n sì mí ìmí ìkà.
13 Èmi ní ìgbàgbọ́ pé,
èmi yóò rí ìre Olúwa
ní ilẹ̀ alààyè.
14 Dúró de Olúwa;
kí ó jẹ alágbára, kí o sì mú ọkàn le
àní dúró de Olúwa.
7 Ipa ọ̀nà àwọn olódodo tẹ́jú
Ìwọ tó dúró ṣinṣin, ìwọ mú ọ̀nà
àwọn olódodo ṣe geere.
8 Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, rírìn ní ọ̀nà òfin rẹ
àwa dúró dè ọ́;
orúkọ rẹ àti òkìkí rẹ
àwọn ni ohun tí ọkàn wa ń fẹ́.
9 Ọkàn mi ń pòùngbẹẹ̀ rẹ ní ọ̀gànjọ́ òru;
ní òwúrọ̀ ni ẹ̀mí mi ń ṣàfẹ́rí rẹ.
Nígbà tí ìdájọ́ rẹ bá sọ̀kalẹ̀ sórí ayé
àwọn ènìyàn yóò kọ́ ìṣòdodo.
10 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fi oore-ọ̀fẹ́ hàn sí àwọn ìkà
wọn kò kọ́ láti sọ òdodo;
kódà ní ilẹ̀ àwọn tí ó dúró ṣinṣin wọ́n
tẹ̀síwájú láti máa ṣe ibi
wọn kò sì ka ọláńlá Olúwa sí.
11 Olúwa, ti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè
ṣùgbọ́n àwọn kò rí i.
Jẹ́ kí wọ́n rí ìtara rẹ fún àwọn ènìyàn rẹ
kí ojú kí ó tì wọ́n;
jẹ́ kí iná tí a fi pamọ́ fún àwọn
ọ̀tá rẹ jó wọn run.
12 Olúwa, ìwọ fi àlàáfíà lélẹ̀ fún wa;
ohun gbogbo tí a ti ṣe yọrí ìwọ ni
ó ṣe é fún wa.
13 Olúwa Ọlọ́run wa, àwọn olúwa mìíràn
lẹ́yìn rẹ ti jẹ ọba lé wa lórí,
ṣùgbọ́n orúkọ rẹ nìkan ni àwa fi ọ̀wọ̀ fún.
14 Wọ́n ti kú báyìí, wọn ò sí láààyè mọ́;
gbogbo ẹ̀mí tí ó ti kọjá lọ wọ̀nyí kò le dìde mọ́.
Ìwọ jẹ́ wọ́n ní ìyà o sì sọ wọ́n di asán,
Ìwọ pa gbogbo ìrántí wọn rẹ́ pátápátá.
15 Ìwọ ti mú orílẹ̀-èdè gbòòrò, Olúwa;
ìwọ ti mú orílẹ̀-èdè bí sí i.
Ìwọ ti gba ògo fún ara rẹ;
ìwọ ti sún gbogbo àwọn ààlà ilẹ̀ sẹ́yìn.
37 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, ọkàn wọn gbọgbẹ́, wọn sì wí fún Peteru àti àwọn aposteli yòókù pé, “Ará, kín ni àwa yóò ṣe?”
38 Peteru sì wí fún wọn pé, “Ẹ ronúpìwàdà, kí a sì bamitiisi olúkúlùkù yín ní orúkọ Jesu Kristi fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ yín. Ẹ̀yin yóò sì gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ 39 (A)Nítorí fún yín ni ìlérí náà, àti fún àwọn ọmọ yín, àti fún gbogbo àwọn tí ó jìnnà réré, àní gbogbo àwọn tí Olúwa Ọlọ́run wa yóò pè.”
40 Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ púpọ̀ mìíràn ni ó fi ń kìlọ̀ tí ó sì ń fi ń rọ̀ wọ́n wí pé, “Ẹ gba ara yín là lọ́wọ́ ìran àrékérekè yìí.” 41 Nítorí náà àwọn tí ó fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ a bamitiisi wọn, lọ́jọ́ náà a sì kà ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọkàn kún wọn.
Ìsọ̀kan àwọn ará tí o gbàgbọ́
42 Wọ́n sì dúró ṣinṣin nínú ẹ̀kọ́ àwọn aposteli, àti ní ìdàpọ̀, ní bíbu àkàrà àti nínú àdúrà.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.