Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 89:1-4

Maskili ti Etani ará Esra.

89 Èmi kọrin títóbi ìfẹ́ Olúwa títí láé;
    pẹ̀lú ẹnu mi ní èmi yóò jẹ́ kí a mọ òtítọ́ rẹ láti ìran dé ìran.
Èmi ó wí pé, ìfẹ́ rẹ dúró títí láé,
    pé ìwọ gbe òtítọ́ rẹ kalẹ̀ ní ọ̀run fúnrarẹ̀.
(A)Ìwọ wí pé, “Èmi ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn àyànfẹ́ mi
    mo ti búra fún Dafidi ìránṣẹ́ mi.
‘Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ múlẹ̀ títí láé
    èmí ó sì máa gbe ìtẹ́ rẹ ró láti ìran dé ìran.’ ”

Saamu 89:19-26

19 Nígbà náà ni ìwọ sọ̀rọ̀ nínú ìran, sí àwọn olóòtítọ́ rẹ, wí pé:
    “Èmi ti gbé adé kalẹ̀ sórí ẹni tí ó lágbára,
    èmi ti gbé ẹni tí a yàn láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ga.
20 (A)Èmi ti rí Dafidi ìránṣẹ́ mi;
    pẹ̀lú òróró mímọ́ mi ni mo fi yàn án;
21 Ìgbà gbogbo ni ọwọ́ mi yóò máa wà pẹ̀lú rẹ̀
    apá mí yóò sì fi agbára fún un.
22 Àwọn ọ̀tá kì yóò borí rẹ̀,
    àwọn ènìyàn búburú kì yóò rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀
23 Èmi yóò run àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ
    èmi yóò lu àwọn tí ó kórìíra rẹ bolẹ̀
24 Òtítọ́ mi àti ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ yóò wà pẹ̀lú rẹ
    àti ní orúkọ mi ni a ó gbé ìwo rẹ ga.
25 Èmi ó gbé ọwọ́ rẹ lórí Òkun
    àti ọwọ́ ọ̀tún rẹ lórí àwọn odo ńlá
26 Òun yóò kígbe sí mi pé, ‘ìwọ ni baba mi, Ọlọ́run mi, àti àpáta ìgbàlà mi!’

Onidajọ 13:2-24

Ọkùnrin ará Sora kan wà, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Manoa láti ẹ̀yà Dani. Aya rẹ̀ yàgàn kò sì bímọ. Angẹli Olúwa fi ara han obìnrin náà, ó sì wí fún un pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ yàgàn, ìwọ kò sì tí ì bímọ, ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan. (A)Báyìí rí i dájúdájú pé ìwọ kò mu wáìnì tàbí ọtí líle kankan àti pé ìwọ kò jẹ ohun aláìmọ́ kankan, nítorí ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan. Má ṣe fi abẹ kan orí rẹ̀, nítorí pé Nasiri (ẹni ìyàsọ́tọ̀) Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò jẹ́, ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún Ọlọ́run láti ọjọ́ ìbí rẹ̀. Òun ni yóò bẹ̀rẹ̀ ìdáǹdè àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní ọwọ́ àwọn ará Filistini.”

Nígbà náà ni obìnrin náà tọ ọkọ rẹ̀ lọ, o sì sọ fún un wí pé, “Ènìyàn Ọlọ́run kan tọ̀ mí wá. Ó jọ angẹli Ọlọ́run, ó ba ènìyàn lẹ́rù gidigidi. Èmi kò béèrè ibi tí ó ti wá, òun náà kò sì sọ orúkọ rẹ̀ fún mi. Ṣùgbọ́n ó sọ fún mi wí pé, ‘Ìwọ yóò lóyún, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, fún ìdí èyí, má ṣe mu wáìnì tàbí àwọn ọtí líle mìíràn bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ má ṣe jẹ ohunkóhun tí í ṣe aláìmọ́, nítorí pé Nasiri Ọlọ́run ni ọmọ náà yóò jẹ́ láti ọjọ́ ìbí rẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.’ ”

Nígbà náà ni Manoa gbàdúrà sí Olúwa wí pé, “Háà Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ènìyàn Ọlọ́run tí ìwọ rán sí wa padà tọ̀ wá wá láti kọ́ wa bí àwa yóò ti ṣe tọ́ ọmọ tí àwa yóò bí náà.”

Ọlọ́run fetí sí ohùn Manoa, angẹli Ọlọ́run náà tún padà tọ obìnrin náà wá nígbà tí ó wà ní oko: Ṣùgbọ́n ọkọ rẹ̀ Manoa kò sí ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. 10 Nítorí náà ni obìnrin náà ṣe yára lọ sọ fún ọkọ rẹ̀ pé, “Ọkùnrin tí ó fi ara hàn mí ní ọjọ́sí ti tún padà wá.”

11 Manoa yára dìde, ó sì tẹ̀lé aya rẹ̀, nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ọkùnrin náà ó ní, “Ǹjẹ́ ìwọ ni o bá obìnrin yìí sọ̀rọ̀?”

Ọkùnrin náà dáhùn pé “Èmi ni.”

12 Manoa bi ọkùnrin náà pé, “Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ kí ni yóò jẹ́ ìlànà fún ìgbé ayé àti iṣẹ́ ọmọ náà?”

13 Angẹli Olúwa náà dáhùn wí pé, “Aya rẹ gbọdọ̀ ṣe gbogbo ohun tí mo ti sọ fún un 14 kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí ó bá ti inú èso àjàrà jáde wá, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ mu wáìnì tàbí àwọn ọtí líle mìíràn tàbí jẹ ohunkóhun tí ó bá jẹ́ aláìmọ́. Ó ní láti ṣe ohun gbogbo tí mo ti pàṣẹ fún un.”

15 Manoa sọ fún angẹli Olúwa náà pé, “Jọ̀wọ́ dára dúró títí àwa yóò fi pèsè ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan fún ọ.”

16 Angẹli Olúwa náà dá Manoa lóhùn pé, “Bí ẹ̀yin tilẹ̀ dá mi dúró, Èmi kì yóò jẹ ọ̀kankan nínú oúnjẹ tí ẹ̀yin yóò pèsè. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá fẹ́ ẹ pèsè ọrẹ ẹbọ sísun, kí ẹ sì fi rú ẹbọ sí Olúwa.” (Manoa kò mọ̀ pé angẹli Olúwa ní i ṣe.)

17 Manoa sì béèrè lọ́wọ́ angẹli Olúwa náà pé, “Kí ni orúkọ rẹ, kí àwa bá à lè fi ọlá fún ọ nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ?”

18 Ṣùgbọ́n angẹli Olúwa náà dáhùn pé, “Èéṣe tí ìwọ ń béèrè orúkọ mi? Ìyanu ni, ó kọjá ìmọ̀.” 19 Lẹ́yìn náà ni Manoa mú ọ̀dọ́ ewúrẹ́, pẹ̀lú ẹbọ ọkà, ó sì fi rú ẹbọ lórí àpáta kan sí Olúwa. Nígbà tí Manoa àti ìyàwó dúró tí wọn ń wò Olúwa ṣe ohun ìyanu kan. 20 Bí ẹ̀là ahọ́n iná ti là jáde láti ibi pẹpẹ ìrúbọ náà sí ọ̀run, angẹli Olúwa gòkè re ọ̀run láàrín ahọ́n iná náà. Nígbà tí wọ́n rí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, Manoa àti aya rẹ̀ wólẹ̀ wọ́n sì dojúbolẹ̀. 21 Nígbà tí angẹli Olúwa náà kò tún fi ara rẹ̀ han Manoa àti aya rẹ̀ mọ́, Manoa wá mọ̀ pé angẹli Olúwa ni.

22 Manoa sọ fún aya rẹ̀ pé, “Dájúdájú àwa yóò kú nítorí àwa ti fi ojú rí Ọlọ́run.”

23 Ṣùgbọ́n ìyàwó rẹ̀ dáhùn pé, “Bí Olúwa bá ní èrò àti pa wá kò bá tí gba ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà wa, tàbí fi gbogbo nǹkan wọ̀nyí hàn wá tó sọ nǹkan ìyanu yìí fún wa.”

24 (B)Obìnrin náà sì bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Samsoni. Ọmọ náà dàgbà Olúwa sì bùkún un.

Johanu 7:40-52

40 (A)Nítorí náà nígbà tí ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ èyí ni wòlíì náà.”

41 Àwọn mìíràn wí pé, “Èyí ni Kristi náà.”

Ṣùgbọ́n àwọn kan wí pé kínla, “Kristi yóò ha ti Galili wá bí? 42 (B)Ìwé mímọ́ kò ha wí pé, Kristi yóò ti inú irú-ọmọ Dafidi wá, àti Bẹtilẹhẹmu, ìlú tí Dafidi ti wá?” 43 Bẹ́ẹ̀ ni ìyapa wà láàrín ìjọ ènìyàn nítorí rẹ̀. 44 (C)Àwọn mìíràn nínú wọn sì fẹ́ láti mú un; ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbé ọwọ́ lé e.

Àìgbàgbọ́ àwọn adarí Júù

45 Ní ìparí, àwọn ẹ̀ṣọ́ tẹmpili padà tọ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi lọ, wọ́n sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi mú un wá?”

46 (D)Àwọn ẹ̀ṣọ́ dáhùn wí pé, “Kò sí ẹni tí ó tí ì sọ̀rọ̀ bí ọkùnrin yìí rí!”

47 Nítorí náà àwọn Farisi dá wọn lóhùn pé, “A ha tan ẹ̀yin jẹ pẹ̀lú bí? 48 Ǹjẹ́ nínú àwọn ìjòyè, tàbí àwọn Farisi ti gbà á gbọ́ bí? 49 Ṣùgbọ́n ìjọ ènìyàn yìí, tí ko mọ òfin di ẹni ìfibú.”

50 (E)Nikodemu ẹni tí ó tọ Jesu wá lóru rí, tí ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú wọn sì sọ fún wọn pé, 51 “Òfin wa ha ń ṣe ìdájọ́ ènìyàn kí ó tó gbọ́ ti ẹnu rẹ̀ àti kí ó tó mọ ohun tí ó ṣe bí?”

52 (F)Wọ́n dáhùn wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ pẹ̀lú wá láti Galili bí? Wá kiri, kí o sì wò nítorí kò sí wòlíì kan tí ó ti Galili dìde.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.