Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 90:1-8

ÌWÉ KẸRIN

Saamu 90–106

Àdúrà Mose ènìyàn Ọlọ́run

90 Olúwa, ìwọ ti jẹ́ ibùgbé wa ní gbogbo ìran dé ìran.
Kí a tó bí àwọn òkè ńlá
    àti kí ìwọ tó dá ilẹ̀ àti ayé,
láti ayérayé dé ayérayé ìwọ ni Ọlọ́run.

Ìwọ yí ènìyàn padà sí erùpẹ̀,
    wí pé “Padà sí erùpẹ̀, ìwọ ọmọ ènìyàn.”
(A)Nítorí pé ìgbà tí ẹgbẹ̀rún ọdún bá kọjá lójú rẹ,
    bí àná ni ó rí, bí ìgbà ìṣọ́ kan lóru.
Ìwọ gbá ènìyàn dànù nínú oorun ikú;
    wọ́n dàbí koríko tuntun ní òwúrọ̀.
Lóòtítọ́, ní òwúrọ̀, ó yọ tuntun
    ní àṣálẹ́ ni yóò gbẹ, tí yóò sì rẹ̀ dànù.

A pa wá run nípa ìbínú rẹ
    nípa ìbínú rẹ ara kò rọ̀ wá.
Ìwọ ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa ka iwájú rẹ,
    àti ohun ìkọ̀kọ̀ wa nínú ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ,

Saamu 90:9-11

Gbogbo ọjọ́ wa ń kọjá lọ lábẹ́ ìbínú rẹ;
    àwa ń lo ọjọ́ wa lọ bí àlá tí à ń rọ́.
10 Àádọ́rin ọdún ni iye ọjọ́ ọdún wá,
    bi ó sì ṣe pé nípa agbára
tí wọn bá tó ọgọ́rin ọdún,
    agbára nínú làálàá pẹ̀lú ìbànújẹ́ ni,
nítorí pé a kò ní pẹ́ gé e kúrò,
    àwa a sì fò lọ.
11 Ta ni ó mọ agbára ìbínú rẹ?
    Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rù rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú rẹ.

Saamu 90:12

12 Kọ́ wa bí a ti ń kaye ọjọ́ wa dáradára,
    kí àwa ba à lè fi ọkàn wa sípa ọgbọ́n.

Esekiẹli 7:10-27

10 “ ‘Ọjọ́ náà dé!
    Kíyèsi ó ti dé!
Ìparun ti bú jáde,
    ọ̀pá ti tanná,
    ìgbéraga ti rúdí!
11 Ìwà ipá ti di ọ̀pá ìwà búburú;
    ọ̀pá láti jẹ ẹni búburú ní ìyà.
Kò sí nínú wọn tí yóò ṣẹ́kù,
    tàbí nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn,
kò sí nínú ọrọ̀ wọn,
    kò sí ohun tí ó ní iye.
12 Àkókò náà dé!
    Ọjọ́ náà ti dé!
Kí òǹrajà má ṣe yọ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni ki òǹtajà má ṣe ṣọ̀fọ̀;
    nítorí, ìbínú gbígbóná wà lórí gbogbo ènìyàn.
13 Nítorí pé òǹtajà kì yóò rí gbà padà
    dúkìá èyí tó tà
    níwọ̀n ìgbà ti àwọn méjèèjì bá wà láààyè.
    Nítorí ìran tó kan gbogbo ènìyàn yìí
    kò ní yí padà.
Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kò sí ọ̀kan nínú wọn
    tí yóò gba ara rẹ̀ là.

14 “ ‘Wọ́n ti fọn ìpè ogun,
    tí wọ́n sì pèsè ohun gbogbo sílẹ̀,
ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò lọ ojú ogun,
    nítorí ìbínú gbígbóná mi ti wà lórí gbogbo ènìyàn.
15 Idà wà ní ìta,
    àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìyàn wà nílé,
idà yóò pa ẹni tó bá wà ní orílẹ̀-èdè,
    àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìyàn yóò pa ẹni tó bá wà ní ìlú.
16 Gbogbo àwọn tí ó bọ́ nínú wọn yóò sálà,
    wọn yóò sì wà lórí òkè.
Bí i àdàbà inú Àfonífojì,
    gbogbo wọn yóò máa ṣọ̀fọ̀,
    olúkúlùkù nítorí àìṣedéédéé rẹ̀.
17 Gbogbo ọwọ́ yóò rọ,
    gbogbo orúnkún yóò di aláìlágbára bí omi.
18 Wọn yóò wọ aṣọ ọ̀fọ̀,
    ẹ̀rù yóò sì bò wọ́n mọ́lẹ̀,
ìtìjú yóò mù wọn,
    wọn yóò sì fá irun wọn.

19 “ ‘Wọn yóò dà fàdákà wọn sí ojú pópó,
    wúrà wọn yóò sì dàbí èérí
fàdákà àti wúrà wọn
    kò ní le gbà wọ́n
    ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná Olúwa.
Wọn kò ní le jẹun tẹ́ ra wọn lọ́rùn
    tàbí kí wọn kún ikùn wọn pẹ̀lú oúnjẹ
    nítorí pé ó ti di ohun ìkọ̀sẹ̀ fún wọn.
20 Wọ́n ń ṣe ìgbéraga pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́ wọn tí ó lẹ́wà,
    wọn sì ti fi ṣe òrìṣà,
wọn sì tún ya àwòrán ìríra wọn níbẹ̀.
    Nítorí náà, èmi yóò sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí di aláìmọ́ fún wọn.
21 Èmi yóò sì fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe ìjẹ fún àjèjì
    àti ìkógun fún àwọn ènìyàn búburú ayé,
    wọn yóò sì sọ ọ́ di aláìmọ́.
22 Èmi yóò gbójú mi kúrò lára wọn,
    àwọn ọlọ́ṣà yóò sì sọ ibi ìṣúra mi di aláìmọ́;
àwọn ọlọ́ṣà yóò wọ inú rẹ̀,
    wọn yóò sì bà á jẹ́.

23 “ ‘Rọ ẹ̀wọ̀n irin!
    Nítorí pé ilẹ̀ náà kún fún ẹ̀ṣẹ̀ ìtàjẹ̀ sílẹ̀,
    ìlú náà sí kún fún ìwà ipá.
24 Èmi yóò mú kí orílẹ̀-èdè ti ó búburú jùlọ
    láti jogún ilé wọn.
Èmi yóò sì fi òpin sí ìgbéraga àwọn alágbára,
    ibi mímọ́ wọn yóò sì di bíbàjẹ́.
25 Nígbà tí ìpayà bá dé,
    wọn yóò wá àlàáfíà, kì yóò sì ṣí
26 Wàhálà lórí wàhálà yóò dé,
    ìdágìrì lórí ìdágìrì.
Nígbà náà ni wọn yóò wá ìran lọ́dọ̀ wòlíì,
    ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ òfin yóò parun lọ́dọ̀ àlùfáà,
    bẹ́ẹ̀ ni ìmọ̀ràn yóò ṣègbé lọ́dọ̀ àwọn àgbàgbà.
27 Ọba yóò ṣọ̀fọ̀,
    ọmọ-aládé yóò wà láìní ìrètí,
    ọwọ́ àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà yóò wárìrì.
Èmi yóò ṣe é fún wọn gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn,
    èmi yóò ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìgbékalẹ̀ wọn.

Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa.’ ”

Matiu 12:43-45

43 (A)“Nígbà tí ẹ̀mí búburú kan bá jáde lára ènìyàn, a máa rìn ní ibi gbígbẹ́, a máa wá ibi ìsinmi, kò sì ní rí i. 44 Nígbà náà ni ẹ̀mí náà yóò wí pé, ‘Èmi yóò padà sí ara ọkùnrin tí èmí ti wá.’ Bí ó bá sì padà, tí ó sì bá ọkàn ọkùnrin náà ni òfìfo, a gbà á mọ́, a sì ṣe é ní ọ̀ṣọ́. 45 Nígbà náà ni yóò lọ, yóò sì mú ẹ̀mí méje mìíràn pẹ̀lú ara rẹ̀, tí ó burú ju òun fúnra rẹ̀ lọ. Gbogbo wọn yóò sì wá sí inú rẹ̀, wọn yóò máa gbé ibẹ̀. Ìgbẹ̀yìn ọkùnrin náà a sì burú ju ìṣáájú rẹ̀ lọ; Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí fún ìran búburú yìí pẹ̀lú.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.