Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 63

Saamu ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú aginjù Juda.

63 Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi,
    nígbà gbogbo ni mo ń ṣàfẹ́rí rẹ,
òǹgbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi,
    ara mi fà sí ọ,
ní ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tí ń ṣàárẹ̀
    níbi tí kò sí omi.

Èmi ti rí ọ ní ibi mímọ́,
    mo rí agbára àti ògo rẹ.
Nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ayé lọ,
    ètè mi yóò fògo fún ọ.
Èmi ó yìn ọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè,
    èmi ó gbé ọwọ́ sókè, èmi ó sì pe orúkọ rẹ.
A ó tẹ́ ọkàn mi lọ́rùn bí ọlọ́ràá oúnjẹ;
    pẹ̀lú ètè ìyìn, ẹnu mi yóò yìn ọ́.

Nígbà tí mo rántí rẹ lórí ibùsùn mi;
    èmi ń ronú rẹ títí ìṣọ́ òru.
Nítorí ìwọ ni ìrànlọ́wọ́ mi,
    mo kọrin níbi òjìji ìyẹ́ apá rẹ.
Ọkàn mí fà sí ọ:
    ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbé mi ró.

Àwọn tí ó ń wá ọkàn mí ni a ó parun;
    wọn ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé.
10 Wọn ó ti ọwọ́ idà ṣubú
    wọn ó sì di jíjẹ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀.

11 Ṣùgbọ́n ọba yóò yọ̀ nínú Ọlọ́run
    ẹni tí ó fi orúkọ Ọlọ́run búra yóò ṣògo
    ṣùgbọ́n ẹnu àwọn òpùrọ́ la ó pamọ́.

Amosi 8:7-14

Olúwa ti fi ìgbéraga Jakọbu búra pé: “Èmi kì yóò gbàgbé ọ̀kan nínú ohun tí wọ́n ṣe.

“Ǹjẹ́ ilẹ̀ náà kì yóò ha wárìrì fún èyí?
    Àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ kì yóò ha ṣọ̀fọ̀?
Gbogbo ilẹ̀ yóò ru sókè bí omi Naili,
    yóò sì ru ú sókè pátápátá bí ìkún omi
    a ó sì tì í jáde, a ó sì tẹ̀ ẹ́ rì gẹ́gẹ́ bí odò Ejibiti.

“Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa Olódùmarè wí,

“Èmi yóò mú oòrùn wọ̀ ní ọ̀sán,
    Èmi yóò mú kí ayé ṣókùnkùn ní ọ̀sán gangan.
10 Èmí yóò yí àsè ẹ̀sìn yín padà sí ọ̀fọ̀,
    gbogbo orin yín ni èmi yóò sọ di ẹkún.
Èmi yóò mú kí gbogbo yín wọ aṣọ ọ̀fọ̀,
    kí a sì fá orí yín.
Èmi yóò mú kí ìgbà náà rí bí ìṣọ̀fọ̀ fún ọmọkùnrin
    kan ṣoṣo tí a bí àti òpin rẹ̀ bí ọjọ́ kíkorò.

11 “Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa Olódùmarè wí,
    “nígbà tí èmi yóò rán ìyàn sí ilẹ̀ náà,
kì í ṣe ìyàn oúnjẹ tàbí òǹgbẹ fún omi.
    Ṣùgbọ́n ìyàn gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa.
12 Àwọn ènìyàn yóò rìn kiri láti Òkun dé Òkun
    wọn yóò sì máa rìn ká láti gúúsù sí àríwá,
wọn yóò máa wá ọ̀rọ̀ Olúwa
    ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí i.

13 “Ní ọjọ́ náà

“àwọn arẹwà wúńdíá àti àwọn alágbára ọ̀dọ́mọkùnrin
    yóò dákú fún òǹgbẹ omi.
14 Àwọn tí ó fi ẹ̀ṣẹ̀ Samaria búra,
    tí wọ́n sì wí pé, ‘Bí ó ti dájú pé ọlọ́run rẹ ń bẹ láààyè, ìwọ Dani,’
    Bí ó ti dájú pè ọlọ́run rẹ ń bẹ láààyè, ìwọ Beerṣeba
Wọ́n yóò ṣubú,
    Wọn kì yóò si tún dìde mọ.”

1 Kọrinti 14:20-25

20 (A)Ará, ẹ má ṣe jẹ ọmọdé ni òye, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ ọmọdé ní àrankàn, ṣùgbọ́n ni òye ẹ jẹ́ àgbà. 21 (B)A tí kọ ọ́ nínú òfin pé,

“Nípa àwọn aláhọ́n mìíràn
    àti elétè àjèjì
ní èmi ó fi ba àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀;
    síbẹ̀ wọn kì yóò gbọ́ tèmi,”
ni Olúwa wí.

22 Nítorí náà àwọn ahọ́n jásí ààmì kan, kì í ṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́, bí kò ṣe fún àwọn aláìgbàgbọ́: ṣùgbọ́n ìsọtẹ́lẹ̀ kì í ṣe fún àwọn tí kò gbàgbọ́ bí kò ṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́. 23 Ǹjẹ́ bí gbogbo ìjọ bá péjọ sí ibi kan, tí gbogbo wọn sí ń fi èdè fọ̀, bí àwọn tí ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláìgbàgbọ́ bá wọlé wá, wọn kí yóò ha wí pé ẹ̀yin ń ṣe òmùgọ̀? 24 Ṣùgbọ́n bí gbogbo yín bá ń sọtẹ́lẹ̀, ti ẹnìkan tí kò gbàgbọ́ tàbí tí ko ni ẹ̀kọ́ bá wọlé wá, gbogbo yin ní yóò fi òye ẹ̀ṣẹ̀ yé e, gbogbo yin ní yóò wádìí rẹ̀. 25 Bẹ́ẹ̀ ní a ó sì fi àṣírí ọkàn rẹ̀ hàn; bẹ́ẹ̀ ni òun ó sì dojúbolẹ̀, yóò sí sin Ọlọ́run yóò sì sọ pé, “Nítòótọ́ Ọlọ́run ń bẹ láàrín yín!”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.