Revised Common Lectionary (Complementary)
Ọkàn tí o bá sẹ̀ ni yóò kú
18 Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: 2 (A)“Kín ni ẹ̀yin rò tí ẹ̀yin fi ń pa òwe nípa Israẹli wí pé:
“ ‘Àwọn baba ti jẹ èso àjàrà kíkan,
eyín àwọn ọmọ sì kan.’
3 “Bí mo ti wà láààyè ni Olúwa Olódùmarè wí, ẹ̀yin kí yóò pa òwe yìí mọ́ ni Israẹli. 4 (B)Nítorí pé èmi ló ní gbogbo ọkàn, ọkàn baba tèmi bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ọmọ pàápàá jẹ tèmi, ọkàn tó bá ṣẹ̀ ní yóò kú.
25 “Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀yin tún wí pe, ‘ọ̀nà Olúwa kò gún.’ Gbọ́ nísinsin yìí ìwọ ilé Israẹli: ọ̀nà mi ni kò ha gún? Kì í wa ṣé pé ọ̀nà tiyín gan an ni kò gún? 26 Bí olódodo ba yípadà kúrò nínú olódodo rẹ̀, tó sì dẹ́ṣẹ̀, yóò ku fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, yóò kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá. 27 Ṣùgbọ́n bi ènìyàn búburú bá yípadà kúrò nínú ìwà búburú tó ti ṣe, tó sì ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó yẹ, yóò gba ẹ̀mí rẹ̀ là. 28 Nítorí pé ó ronú lórí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá, ó sì yípadà kúrò nínú wọn, nítòótọ́ ni yóò yè; kì yóò sí kú 29 Síbẹ̀, ilé Israẹli wí pé, ‘Ọ̀nà Olúwa kò gún.’ Ọ̀nà mi kò ha tọ́ bí ilé Israẹli? Kì í wa ṣe pè ọ̀nà tiyín gan an ni ko gún?
30 “Nítorí náà, ilé Israẹli, èmi yóò da yín lẹ́jọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ẹnìkọ̀ọ̀kan yín bá ṣe rí ni Olúwa Olódùmarè wí. Ẹ yípadà! Kí ẹ si yí kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni ìrékọjá kì yóò jẹ́ ọ̀nà ìṣubú yín. 31 (A)Ẹ kọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ti ẹ ti dá sílẹ̀, kí ẹ sì gba ọkàn àti ẹ̀mí tuntun. Nítorí kí ló fi máa kú, ilé Israẹli? 32 (B)Nítorí pé inú mi kò dùn sí ikú ẹnikẹ́ni ni Olúwa Olódùmarè wí. Nítorí náà, ẹ yípadà kí ẹ sì yè!
Ti Dafidi.
25 Olúwa,
ìwọ ni mo gbé ọkàn mi sókè sí.
2 Ọlọ́run, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ;
Má ṣe jẹ́ kí ojú ó tì mí
Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí.
3 Ẹni tí ó dúró tì ọ́
ojú kì yóò tì í,
àwọn tí ń ṣẹ̀ láìnídìí
ni kí ojú kí ó tì.
4 Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, Olúwa,
kọ mi ní ipa tìrẹ;
5 ṣe amọ̀nà mi nínú òtítọ́ ọ̀ rẹ, kí o sì kọ́ mi,
Nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi;
ìwọ ni mo dúró tì ní gbogbo ọjọ́.
6 Rántí, Olúwa àánú àti ìfẹ́ ẹ̀ rẹ̀ ńlá,
torí pé wọ́n ti wà ní ìgbà àtijọ́
7 Má ṣe rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi
tàbí ìrékọjá mi;
gẹ́gẹ́ bí i ìfẹ́ ẹ rẹ̀ rántí mi
nítorí tí ìwọ dára, Ìwọ! Olúwa.
8 Rere àti ẹni ìdúró ṣinṣin ní Olúwa:
nítorí náà, ó kọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọ̀nà náà.
9 Ó ṣe amọ̀nà àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni ohun tí ó dára,
ó sì kọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ ní ọ̀nà rẹ̀.
Kọ́ ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Kristi
2 (A)Bí ìwọ bá ní ìmúlọ́kànle nítorí pé ìwọ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi, bi ìtùnú kan bá wà nínú ìfẹ́ rẹ̀, bí ìdàpọ̀ Ẹ̀mí kan bá wà, bí ìyọ́nú àti ìṣeun bá wà, 2 síbẹ̀ ẹ mú ayọ̀ mi kún nínú ìṣọ̀kan yín, nípa ìfẹ́ kan náà, wíwà ní ẹ̀mí kan náà àti ète kan náà. 3 (B)Ẹ má ṣe ohunkóhun nínú ìlépa ara tàbí ògo asán, ṣùgbọ́n ní ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn kí olúkúlùkù ro àwọn ẹlòmíràn sí ẹni ti ó sàn ju òun lọ. 4 Kí olúkúlùkù yín má ṣe ro ohun ti ara rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ti ẹlòmíràn pẹ̀lú.
5 (C)Nínú ìbáṣepọ̀ yin pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, ẹ ni irú ìlépa ọkàn náà bí ti Kristi Jesu.
6 Ẹni tí, bí o tilẹ̀ jẹ́ ìrísí Ọlọ́run,
kò kà á sí ohun tí ìbá fi ìwọra gbámú láti bá Ọlọ́run dọ́gba.
7 Ṣùgbọ́n ó bọ́ ògo rẹ̀ sílẹ̀,
ó sì mú àwọ̀ ìránṣẹ́,
a sì ṣe é ni àwòrán ènìyàn.
8 Ó sì wà ní àwòrán ènìyàn,
ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀,
o sì tẹríba títí de ojú ikú,
àní ikú lórí àgbélébùú.
9 (D)Nítorí náà, Ọlọ́run
ti gbé e ga sí ipele tí ó ga jùlọ,
ó sì ti fi orúkọ kan ti ó borí gbogbo orúkọ fún un
10 Pé ni orúkọ Jesu ni kí gbogbo eékún máa wólẹ̀,
ní ọ̀run, àti ní orí ilẹ̀ ayé àti ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé,
11 Àti pé kí gbogbo ahọ́n jẹ́wọ́ pé, Jesu Kristi ni Olúwa,
fún ògo Ọlọ́run Baba.
Títàn gẹ́gẹ́ bí àwọn ìràwọ̀
12 Nítorí náà ẹ̀yin ará mi, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti ń gbọ́rọ̀ nígbà gbogbo, kì í ṣe nígbà ti mo wà lọ́dọ̀ yín nìkan, ṣùgbọ́n pàápàá nísinsin yìí tí èmi kò sí ni àárín yín, ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì, 13 (E)Nítorí pé Ọlọ́run ni ó n ṣiṣẹ́ nínú yín, láti fẹ́ àti láti ṣiṣẹ́ fún ète rere rẹ̀.
A béèrè àṣẹ tí Jesu ń lò
23 (A)Jesu wọ tẹmpili, nígbà tí ó ń kọ́ni, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù tọ̀ ọ́ wá. Wọ́n béèrè pé “nípa àṣẹ wo ni o fi ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí? Ta ni ó sì fún ọ ni àṣẹ yìí?”
24 Jesu sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èmi yóò si bí yin léèrè ohun kan, bí ẹ̀yin bá lé sọ fún mi, nígbà náà èmi yóò sọ fún yín, àṣẹ tí Èmi fi ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí. 25 Níbo ni ìtẹ̀bọmi Johanu ti wa? Láti ọ̀run wá ni, tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn.”
Wọ́n sì bá ara wọn gbèrò pé, “Bí àwa bá wí pé láti ọ̀run wá ni, òun yóò wí fún wa pé, ‘Èéha ti ṣe tí ẹ̀yin kò fi gbà á gbọ́?’ 26 (B)Ní ìdàkejì, bí àwa bá sì sọ pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn, àwa bẹ̀rù ìjọ ènìyàn, nítorí gbogbo wọ́n ka Johanu sí wòlíì.’ ”
27 Nítorí náà wọ́n sì dá Jesu lóhùn pé, “Àwa kò mọ̀.”
Nígbà náà ni ó wí pé, “Nítorí èyí, èmi kò ní sọ àṣẹ tí èmi fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí fún yín.
Òwe àwọn ọmọ méjì
28 (C)“Kí ni ẹ rò nípa eléyìí? Ọkùnrin kan ti ó ní àwọn ọmọkùnrin méjì. Ó sọ fún èyí ẹ̀gbọ́n pé, ‘Ọmọ, lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà lónìí.’
29 “Ó sì dá baba rẹ̀ lóhùn pé, ‘Èmi kò ní í lọ,’ ṣùgbọ́n níkẹyìn ó yí ọkàn padà, ó sì lọ.
30 “Nígbà náà ni baba yìí tún sọ fún èyí àbúrò pé, ‘Lọ ṣiṣẹ́ ní oko.’ Ọmọ náà sì sọ pé, ‘Èmi yóò lọ, baba,’ ṣùgbọ́n kò lọ rárá.
31 “Nínú àwọn méjèèjì yìí, èwo ni ó ṣe ìfẹ́ baba wọn?”
Gbogbo wọn sì fohùn ṣọ̀kan pé, “Èyí ẹ̀gbọ́n ni.”
Jesu wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, àwọn agbowó òde àti àwọn panṣágà yóò wọ ìjọba ọ̀run síwájú yín. 32 Nítorí Johanu tọ́ yin wá láti fi ọ̀nà òdodo hàn yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbà á gbọ́, ṣùgbọ́n àwọn agbowó òde àti àwọn panṣágà ronúpìwàdà, bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ rí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ wọ̀nyí, ẹ kọ̀ láti ronúpìwàdà, ẹ kò gbà á gbọ́.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.