Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 23

Saamu ti Dafidi.

23 Olúwa ni Olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní.
    (A)Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù
Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́;
    Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò
Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodo
    nítorí orúkọ rẹ̀.
Bí mo tilẹ̀ ń rìn
    Láàrín àfonífojì òjìji ikú,
èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan;
    nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi;
ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ
    wọ́n ń tù mí nínú.

Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú mi
    ní ojú àwọn ọ̀tá à mi;
ìwọ ta òróró sí mi ní orí;
    ago mí sì kún àkúnwọ́sílẹ̀.
Nítòótọ́, ìre àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn
    ní ọjọ́ ayé è mi gbogbo,
èmi yóò sì máa gbé inú ilé Olúwa
    títí láéláé.

Isaiah 22:1-8

Àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa Jerusalẹmu

22 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó jẹ mọ́ Àfonífojì ìran:

Kí ni ó ń dààmú yín báyìí,
    tí gbogbo yín fi gun orí òrùlé lọ?
Ìwọ ìlú tí ó kún fún rúkèrúdò,
    ìwọ ìlú àìtòrò òun rògbòdìyàn
a kò fi idà pa àwọn òkú rẹ,
    bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kú ní ojú ogun.
Gbogbo àwọn olórí i yín ti jùmọ̀ sálọ;
    a ti kó wọn nígbèkùn láìlo ọfà.
Ẹ̀yin tí a mú ni a ti kó lẹ́rú papọ̀,
    lẹ́yìn tí ẹ ti sá nígbà tí ọ̀tá ṣì wà
    lọ́nà jíjìn réré.
Nítorí náà ni mo wí pé, “Yípadà kúrò lọ́dọ̀ mi:
    jẹ́ kí n sọkún kíkorò.
Má ṣe gbìyànjú àti tù mí nínú
    nítorí ìparun àwọn ènìyàn mi.”

Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan
    tí rúkèrúdò, rògbòdìyàn àti ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀
    ní Àfonífojì ìmọ̀,
ọjọ́ tí a ń wó ògiri lulẹ̀
    àti sísun ẹkún lọ sí àwọn orí òkè.
Elamu mú apó-ọfà lọ́wọ́,
    pẹ̀lú àwọn agun-kẹ̀kẹ́-ogun àti àwọn ẹṣin,
    Kiri yọ àpáta rẹ̀ síta.
Àyànfẹ́ Àfonífojì rẹ kún fún kẹ̀kẹ́ ogun,
    àwọn ẹlẹ́ṣin ni a gbá jọ sí ẹnu-bodè ìlú.

Gbogbo ààbò Juda ni a ti ká kúrò.
Ìwọ sì gbójú sókè ní ọjọ́ náà
    sí àwọn ohun ìjà ní ààfin ti inú aginjù,

1 Peteru 5:1-5

Sí àwọn alàgbà àti àwọn ọ̀dọ́kùnrin

Àwọn alàgbà tí ń bẹ láàrín yín ni mo gbànímọ̀ràn, èmi ẹni tí ń ṣe alàgbà bí ẹ̀yin, àti ẹlẹ́rìí ìyà Kristi, àti alábápín nínú ògo tí a ó fihàn: Ẹ máa tọ́jú agbo Ọlọ́run tí ń bẹ láàrín yín, ẹ máa bojútó o, kì í ṣe àfipáṣe, bí kò ṣe tìfẹ́tìfẹ́; kó má sì jẹ́ fún èrè ìjẹkújẹ, bí kò ṣe pẹ̀lú ìpinnu tí ó múra tan. Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe bí ẹni tí ń lo agbára lórí ìjọ, ṣùgbọ́n kí ẹ ṣe ara yín ní àpẹẹrẹ fún agbo. Nígbà tí olórí Olùṣọ́-àgùntàn bá sì fi ara hàn, ẹ̀yin ó gba adé ògo ti kì í sá.

(A)Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ tẹríba fún àwọn alàgbà. Àní, gbogbo yín ẹ máa tẹríba fún ara yín kí ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ wọ ara yín ní aṣọ: nítorí,

“Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn agbéraga,
    ṣùgbọ́n ó ń fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.”

1 Peteru 5:12-14

Àwọn ìkíni ìkẹyìn

12 Nítorí Sila, arákùnrin wa olóòtítọ́ gẹ́gẹ́ bí mo ti kà á sí, ni mo kọ̀wé kúkúrú sí i yín, tí mo ń gbà yín níyànjú, tí mo sì ń jẹ́rìí pé, èyí ni òtítọ́ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run: ẹ dúró ṣinṣin nínú rẹ̀.

13 Ìjọ tí ń bẹ ní Babeli, tí a yàn, pẹ̀lú kí yín, bẹ́ẹ̀ sì ni Marku ọmọ mi pẹ̀lú.

14 Ẹ fi ìfẹ́nukonu ìfẹ́ kí ara, yín.

Àlàáfíà fún gbogbo yín tí ẹ wà nínú Kristi.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.