Revised Common Lectionary (Complementary)
7 Tún wa yípadà, ìwọ, Ọlọ́run alágbára;
jẹ́ kí ojú rẹ tàn sí wa,
kí a ba à lè gbà wá là.
8 Ìwọ mú àjàrà jáde láti Ejibiti;
ìwọ lé àwọn kèfèrí jáde, o sì gbìn ín.
9 Ìwọ ṣí ààyè sílẹ̀ fún un,
ìwọ sì mu ta gbòǹgbò jinlẹ̀
ó sì kún ilẹ̀ náà.
10 A bò àwọn òkè mọ́lẹ̀ òkè pẹ̀lú òjìji rẹ̀,
ẹ̀ka rẹ̀ dàbí kedari Ọlọ́run.
11 O yọ ẹ̀ka rẹ̀ sínú Òkun,
ọwọ́ rẹ̀ sí odò ńlá nì.
12 Èéṣe tí ìwọ fi wó odi rẹ̀
tí àwọn ènìyàn tí ó ń kọjá fi ń ṣa èso rẹ̀?
13 Ìmàdò láti inú igbó ń bá a jẹ́
àti ẹranko igbó ń jẹ ẹ́ run.
14 Yípadà sí wa, àwa ń bẹ̀ ọ́, Ọlọ́run alágbára!
Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì wò ó!
Kí o sì bẹ àjàrà yìí wò,
15 Gbòǹgbò èyí tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ti gbìn,
àti ẹ̀ka tí ìwọ ti mú lágbára fún ara rẹ.
Jerusalẹmu lábẹ́ ìgbèkùn
6 “Ẹ̀yin ènìyàn Benjamini, sá sí ibi ààbò!
Ẹ sá kúrò ní Jerusalẹmu,
Ẹ fọn fèrè ní Tekoa!
Kí ẹ gbé ààmì sókè lórí Beti-Hakeremu!
Nítorí àjálù farahàn láti àríwá,
àní ìparun tí ó lágbára.
2 Èmi yóò pa ọmọbìnrin Sioni run,
tí ó jẹ́ arẹwà àti ẹlẹgẹ́.
3 Olùṣọ́-àgùntàn pẹ̀lú agbo wọn yóò gbóguntì wọ́n.
Wọn yóò pa àgọ́ yí wọn ká,
olúkúlùkù yóò máa jẹ ní ilé rẹ̀.”
4 “Ẹ ya ará yín sí mímọ́ láti bá a jagun!
Dìde, kí a kọlù ú ní ìgbà ọ̀sán!
Ṣùgbọ́n ó ṣe, nítorí ọjọ́ lọ tán,
ọjọ́ alẹ́ náà sì gùn sí i.
5 Nítorí náà, ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a kọlù ú ní àṣálẹ́
kí a sì ba odi alágbára rẹ̀ jẹ́.”
6 Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí:
“Ẹ ké àwọn igi náà lulẹ̀
kí ẹ sì mọ odi ààbò yí Jerusalẹmu ká.
Èyí ni ìlú títóbi tí a ó bẹ̀wò,
nítorí pé ó kún fún ìninilára.
7 Gẹ́gẹ́ bí kànga ṣe ń da omi inú rẹ̀ sílẹ̀,
náà ni ó ń tú ìwà búburú rẹ̀ jáde.
Ìwà ipá àti ìparun ń tún pariwo nínú rẹ̀;
nígbà gbogbo ni àìsàn àti ọgbẹ́ rẹ̀ ń wà níwájú mi.
8 Ìwọ Jerusalẹmu, gba ìkìlọ̀
kí Èmi kí ó má ba à lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ,
kí n sì sọ ilẹ̀ rẹ di ahoro,
tí kò ní ní olùgbé.”
9 Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:
“Jẹ́ kí wọn pèsè ìyókù Israẹli
ní tónítóní bí àjàrà;
na ọwọ́ rẹ sí àwọn ẹ̀ka nì lẹ́ẹ̀kan sí i
gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ti í kó èso àjàrà jọ.”
10 Ta ni ẹni tí mo lè bá sọ̀rọ̀ àti
tí mo lè fún ní ìmọ̀ràn? Ta ni
yóò tẹ́tí sílẹ̀ sí mi? Etí wọn
ti di, nítorí náà wọn kò lè gbọ́.
Ọ̀rọ̀ Olúwa, jẹ́ ohun búburú sí wọn,
wọn kò sì ní inú dídùn nínú rẹ̀.
40 (A)Nítorí náà nígbà tí ọ̀pọ̀ nínú ìjọ ènìyàn gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ èyí ni wòlíì náà.”
41 Àwọn mìíràn wí pé, “Èyí ni Kristi náà.”
Ṣùgbọ́n àwọn kan wí pé kínla, “Kristi yóò ha ti Galili wá bí? 42 (B)Ìwé mímọ́ kò ha wí pé, Kristi yóò ti inú irú-ọmọ Dafidi wá, àti Bẹtilẹhẹmu, ìlú tí Dafidi ti wá?” 43 Bẹ́ẹ̀ ni ìyapa wà láàrín ìjọ ènìyàn nítorí rẹ̀. 44 (C)Àwọn mìíràn nínú wọn sì fẹ́ láti mú un; ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbé ọwọ́ lé e.
Àìgbàgbọ́ àwọn adarí Júù
45 Ní ìparí, àwọn ẹ̀ṣọ́ tẹmpili padà tọ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi lọ, wọ́n sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin kò fi mú un wá?”
46 (D)Àwọn ẹ̀ṣọ́ dáhùn wí pé, “Kò sí ẹni tí ó tí ì sọ̀rọ̀ bí ọkùnrin yìí rí!”
47 Nítorí náà àwọn Farisi dá wọn lóhùn pé, “A ha tan ẹ̀yin jẹ pẹ̀lú bí? 48 Ǹjẹ́ nínú àwọn ìjòyè, tàbí àwọn Farisi ti gbà á gbọ́ bí? 49 Ṣùgbọ́n ìjọ ènìyàn yìí, tí ko mọ òfin di ẹni ìfibú.”
50 (E)Nikodemu ẹni tí ó tọ Jesu wá lóru rí, tí ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú wọn sì sọ fún wọn pé, 51 “Òfin wa ha ń ṣe ìdájọ́ ènìyàn kí ó tó gbọ́ ti ẹnu rẹ̀ àti kí ó tó mọ ohun tí ó ṣe bí?”
52 (F)Wọ́n dáhùn wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ pẹ̀lú wá láti Galili bí? Wá kiri, kí o sì wò nítorí kò sí wòlíì kan tí ó ti Galili dìde.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.