Revised Common Lectionary (Complementary)
Ti Dafidi.
144 Ìyìn sí Olúwa àpáta mi,
ẹni tí ó kọ́ ọwọ́ mi fún ogun,
àti ìka mi fún ìjà.
2 Òun ni Ọlọ́run ìfẹ́ mi àti odi alágbára mi,
ibi gíga mi àti olùgbàlà mi, asà mi,
ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé,
ẹni tí ó tẹrí àwọn ènìyàn ba lábẹ́ mi.
3 Olúwa, kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣàníyàn fún un,
tàbí ọmọ ènìyàn tí ìwọ fi ń ronú nípa rẹ̀?
4 Ènìyàn rí bí èmi;
ọjọ́ rẹ̀ rí bí òjìji tí ń kọjá lọ.
5 Tẹ ọ̀run rẹ ba, Olúwa, kí o sì sọ̀kalẹ̀;
tọ́ àwọn òkè ńlá wọn yóò sí rú èéfín.
6 Rán mọ̀nàmọ́ná kí ó sì fọ́n àwọn ọ̀tá ká;
ta ọfà rẹ kí ó sì dà wọ́n rú.
7 Na ọwọ́ rẹ sílẹ̀ láti ibi gíga;
gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewu
kúrò nínú omi ńlá:
kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì.
8 Ẹnu ẹni tí ó kún fún èké
ẹni tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ jẹ́ ìrẹ́jẹ.
9 Èmi yóò kọ orin tuntun sí ọ
Ọlọ́run; lára ohun èlò orin
olókùn mẹ́wàá èmi yóò
kọ orin sí ọ
10 Òun ni ó fi ìgbàlà fún àwọn ọba,
ẹni tí ó gba Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ idà ìpanilára.
Lọ́wọ́ pípanirun. 11 Gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewu
kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì
tí ẹnu wọn kún fún èké,
tí ọwọ́ ọ̀tún wọn jẹ́ ọwọ́ ọ̀tún èké.
12 Kí àwọn ọmọkùnrin wa
kí ó dàbí igi gbígbìn tí ó dàgbà ni ìgbà èwe wọn,
àti ọmọbìnrin wa yóò dàbí òpó ilé
tí a ṣe ọ̀nà sí bí àfarawé ààfin.
13 Àká wa yóò kún
pẹ̀lú gbogbo onírúurú oúnjẹ
àgùntàn wa yóò pọ̀ si ní ẹgbẹ̀rún,
ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní oko wa:
14 Àwọn màlúù wa yóò ru ẹrù wúwo
kí ó má sí ìkọlù,
kí ó má sí ìkólọ sí ìgbèkùn,
kí ó má sí i igbe ìpọ́njú ní ìgboro wa.
15 Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà tí ó wà ní irú ipò bẹ́ẹ̀,
Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà,
tí ẹni tí Ọlọ́run Olúwa ń ṣe.
10 “ ‘Ìyá rẹ dàbí àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ̀;
tí á gbìn sí etí odò ó, kún fún èso,
ó sì kún fún ẹ̀ka nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi,
11 Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lágbára tó láti fi ṣe ọ̀pá àṣẹ ìjòyè,
ó ga sókè láàrín ewé rẹ̀,
gíga rẹ̀ hàn jáde láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ka rẹ̀.
12 Ṣùgbọ́n ó fà á tu ní ìrunú,
á sì wọ́ ọ lulẹ̀,
afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn sì gbé èso rẹ̀,
ọ̀pá líle rẹ̀ ti ṣẹ́, ó sì rọ
iná sì jó wọn run.
13 Báyìí, a tún ún gbìn sínú aṣálẹ̀
ni ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tó ń pòǹgbẹ omi.
14 Iná sì jáde láti ọ̀kan lára ẹ̀ka rẹ̀
ó sì pa ẹ̀ka àti èso rẹ̀ run,
dé bi pé kò sí ẹ̀ka tó lágbára lórí rẹ̀ mọ́;
èyí to ṣe fi ṣe ọ̀pá fún olórí mọ́.’
Èyí ni orin ọ̀fọ̀ a o sì máa lo bí orin ọ̀fọ̀.”
Àpáta iyè àti ènìyàn tí a yàn
4 (A)Ẹni tí ẹ̀yin ń tọ̀ bọ̀, sí bi òkúta ààyè náà, èyí ti a ti ọwọ́ ènìyàn kọ̀ sílẹ̀ nítòótọ́, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àṣàyàn òkúta iyebíye. 5 Ẹ̀yin pẹ̀lú, bí òkúta ààyè, ni a kọ́ ní ilé ẹ̀mí, àlùfáà mímọ́, láti máa rú ẹbọ ẹ̀mí, tí i ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípa Jesu Kristi. 6 (B)Nítorí nínú Ìwé Mímọ́, ó wí pe:
“Kíyèsi i, mo fi pàtàkì òkúta igun ilé àṣàyàn,
iyebíye, lélẹ̀ ni Sioni:
ẹni tí ó bá sì gbà á gbọ́
ojú kì yóò tì í.”
7 (C)Báyìí fún ẹ̀yin ti ẹ gbà á gbọ́, ó ṣe iyebíye; ṣùgbọ́n fún àwọn tí kò gbà á gbọ́,
“Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,
òun ni ó di pàtàkì igun ilé,”
8 (D)àti pẹ̀lú,
“Òkúta ìdìgbòlù,
àti àpáta ìkọ̀sẹ̀.”
Nítorí wọ́n kọsẹ̀ nípa ṣíṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, sínú èyí tí a gbé yàn wọ́n sí pẹ̀lú.
9 (E)Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni ìran tí a yàn olú àlùfáà, Orílẹ̀-èdè mímọ́, Ènìyàn ọ̀tọ̀ ki ẹ̀yin lè fi ọláńlá ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn sínú ìmọ́lẹ̀ ìyanu rẹ̀ hàn: 10 (F)Ẹ̀yin tí kì í ṣe ènìyàn nígbà kan rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin ti di ènìyàn Ọlọ́run, ẹ̀yin tí kò rí àánú gbà rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ ti rí àánú gbà.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.