Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 1

ÌWÉ KÌN-ÍN-NÍ

Saamu 1–41

(A)Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà,
    tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú,
ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
    tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn.
Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin Olúwa
    àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.
Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn,
    tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀
tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀.
    Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.

Kò le rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú!
    Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkà
    tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù.
Nítorí náà àwọn ènìyàn búburú kì yóò le è dìde dúró ní ìdájọ́,
    bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò le è dúró ní àwùjọ àwọn olódodo.

Nítorí Olúwa ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn olódodo,
    ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.

Òwe 24:23-34

Àwọn ọrọ̀ ọlọ́gbọ́n mìíràn

23 Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú tún jẹ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n:

    láti ṣe ojúsàájú níbi ìdájọ́ kò dára rárá:
24 Ẹnikẹ́ni tí ó wí fún ẹlẹ́bi pé, “Ìwọ lo jàre”
    àwọn ènìyàn yóò ṣẹ́ èpè fún un àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì kọ̀ ọ́.
25 Ṣùgbọ́n yóò dára fún àwọn tí ń dá ẹlẹ́bi lẹ́bi,
    ọ̀pọ̀ ìbùkún yóò sì wá sórí wọn.

26 Ìdáhùn òtítọ́
    dàbí ìfẹnu-koni-ní-ẹnu.

27 Parí gbogbo iṣẹ́ ajé rẹ
    sì rí i pé oko rẹ ti ṣe dáradára;
    lẹ́yìn náà kọ́ ilé rẹ.

28 Má ṣe rojọ́ èké mọ́ aládùúgbò rẹ láìnídìí,
    tàbí kí o fi ètè rẹ tannijẹ.
29 Má ṣe wí pé, “Èmi yóò ṣe é fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún mi;
    Èmi yóò san ohun tí ó ṣe fún mi padà fún un.”

30 Mo kọjá níbi oko ọ̀lẹ,
    mo kọjá níbi ọgbà àjàrà aláìgbọ́n ènìyàn;
31 ẹ̀gún ti hù ní ibi gbogbo,
    koríko ti gba gbogbo oko náà
32 Mo fi ọkàn mi sí nǹkan tí mo kíyèsi
    mo sì kẹ́kọ̀ọ́ lára ohun tí mo rí;
33 oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀,
    ìkáwọ́gbera díẹ̀ láti sinmi
34 Òsì yóò sì dé bá ọ bí adigunjalè
    àti àìní bí olè.

Johanu 5:39-47

39 (A)Ẹ̀yin ń wá ìwé mímọ́ nítorí ẹ̀yin rò pé nínú wọn ni ẹ̀yin ní ìyè tí kò nípẹ̀kun. Wọ̀nyí sì ni àwọn tí ó ń jẹ́rìí mi. 40 Ẹ̀yin kò sì fẹ́ láti wá sọ́dọ̀ mi, kí ẹ̀yin ba à lè ní ìyè.

41 “Èmi kò gba ògo lọ́dọ̀ ènìyàn. 42 Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé, ẹ̀yin fúnrayín kò ní ìfẹ́ Ọlọ́run nínú yín. 43 (B)Èmi wá ní orúkọ Baba mi, ẹ̀yin kò sì gbà mí; bí ẹlòmíràn bá wá ní orúkọ ara rẹ̀, òun ni ẹ̀yin yóò gbà. 44 Ẹ̀yin ó ti ṣe lè gbàgbọ́, ẹ̀yin tí ń gba ògo lọ́dọ̀ ara yín tí kò wá ògo tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nìkan wá?

45 (C)“Ẹ má ṣe rò pé, èmi ó fi yín sùn lọ́dọ̀ Baba: ẹni tí ń fi yín sùn wà, àní Mose, ẹni tí ẹ̀yin gbẹ́kẹ̀lé. 46 Nítorí pé ẹ̀yin ìbá gba Mose gbọ́, ẹ̀yin ìbá gbà mí gbọ́: nítorí ó kọ ìwé nípa tèmi. 47 (D)Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá gba ìwé rẹ̀ gbọ́, ẹ̀yin ó ti ṣe gbà ọ̀rọ̀ mi gbọ́?”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.