Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 43

43 Dá mi láre, Ọlọ́run mi,
    kí o sì gba ọ̀rọ̀ mi rò lọ́dọ̀ àwọn aláìláàánú orílẹ̀-èdè:
yọ mí kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́tàn àti àwọn ènìyàn búburú.
Ìwọ ni Ọlọ́run ibi agbára mi.
    Èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mi sílẹ̀?
Èéṣe tí èmi yóò máa rìn nínú ìbìnújẹ́,
    nítorí ìnilára lọ́dọ̀ àwọn ọ̀tá?
Rán ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ rẹ jáde,
    jẹ́ kí wọn ó máa dáàbò bò mí;
jẹ́ kí wọn mú mi wá sí òkè mímọ́ rẹ,
    sí ibi tí ìwọ ń gbé.
Nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi pẹpẹ Ọlọ́run,
    sí Ọlọ́run ayọ̀ mi àti ìdùnnú mi,
èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú dùùrù,
    ìwọ Ọlọ́run, Ọlọ́run mi.

Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mí?
    Èéṣe tí ó fi ń ru sókè nínú mi?
Fi ìrètí rẹ sínú Ọlọ́run,
    nítorí èmi yóò máa yìn ín, Òun ni
    Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.

Malaki 1:6-2:9

Ẹbọ àìmọ́

“Ọmọ a máa bu ọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀, ọmọ ọ̀dọ̀ a sì máa bu ọlá fún olúwa rẹ̀. Ǹjẹ́ bí èmí bá jẹ́ baba, ọlá tí ó tọ́ sí mi ha dà? Bí èmi bá sì jẹ́ olúwa, ẹ̀rù tí ó tọ́ sí mi dà?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

“Ẹ̀yin ni, ẹ̀yin àlùfáà, ni ẹ ń gan orúkọ mi.

“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe gan orúkọ rẹ?’

“Ẹ̀yin gbé oúnjẹ àìmọ́ sí orí pẹpẹ mi.

“Ẹ̀yin sì tún béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe ṣe àìmọ́ sí ọ?’

“Nípa sísọ pé tábìlì Olúwa di ẹ̀gàn. Nígbà tí ẹ̀yin mú afọ́jú ẹran wá fún ìrúbọ, ṣé èyí kò ha burú bí? Nígbà tí ẹ̀yin fi amúnkùn ún àti aláìsàn ẹran rú ẹbọ, ṣé èyí kò ha burú gidigidi bí? Ẹ dán an wò, ẹ fi wọ́n rú ẹbọ sí àwọn baálẹ̀ yín! Ṣé inú rẹ̀ yóò dùn sí yín? Ṣé yóò gbà yín?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

“Ní ìsinsin yìí, ẹ bẹ Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa. Ṣùgbọ́n pẹ̀lú irú àwọn ẹbọ wọ̀nyí láti ọwọ́ yín wá, ṣé yóò gbà yín?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

10 “Hó ò! Ẹnìkan ìbá jẹ́ wà láàrín yín ti yóò sé ìlẹ̀kùn tẹmpili, pé kí ẹ má ba à ṣe dá iná asán lórí pẹpẹ mi mọ́! Èmi kò ní inú dídùn sí i yín,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò gba ọrẹ kan lọ́wọ́ yín. 11 Orúkọ mi yóò tóbi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, láti ìlà-oòrùn títí ó sì fi dé ìwọ̀-oòrùn. Ní ibi gbogbo ni a ó ti mú tùràrí àti ọrẹ mímọ́ wá fún orúkọ mi, nítorí orúkọ mi tóbi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

12 “Nítorí ẹ̀yin ti sọ ọ́ di àìmọ́, nínú èyí tí ẹ wí pé, ‘Tábìlì Olúwa di àìmọ́ àti èso rẹ̀,’ àní oúnjẹ rẹ̀ ni ohun ẹ̀gàn. 13 Ẹ̀yin wí pẹ̀lú pé, ‘Wò ó, irú àjàgà kín ni èyí!’ Ẹ̀yin sì yínmú sí i,” ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

“Nígbà tí ẹ̀yin sì mú èyí tí ó fi ara pa, arọ àti ọlọkùnrùn ẹran tí ẹ sì fi rú ẹbọ, Èmi o ha gba èyí lọ́wọ́ yín?” ni Olúwa wí. 14 “Ṣùgbọ́n ègún ni fún ẹlẹ́tàn náà, tí ó ni akọ nínú ọ̀wọ́ ẹran rẹ̀, tí ó sì ṣe ìlérí láti fi lélẹ̀ tí ó sì fi ẹran tó lábùkù rú ẹbọ sí Olúwa; nítorí ọba ńlá ni Èmi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “ẹ̀rù sì ni orúkọ mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.

Ìkìlọ̀ fún àwọn àlùfáà

“Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ̀yin àlùfáà, òfin yìí ní fún yín. Bí ẹ̀yin kò bá ni gbọ́, bí ẹ̀yin kò bá ní fi í sí àyà láti fi ọ̀wọ̀ fún orúkọ mi,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí; èmi yóò sì ran ègún sí orí yín, èmi yóò sì fi ìbùkún yín ré. Nítòótọ́ mó ti fi ré ná, nítorí pé, ẹ̀yin kò fi sí ọkàn yín láti bu ọlá fún mi.

“Nítorí tiyín èmí yóò ba àwọn ọmọ yín wí, èmi ó sì fi ìgbẹ́ rẹ́ yín lójú, àní àwọn ìgbẹ́ ọrẹ ọwọ́ yín wọ̀nyí, a ó sì kó yín lọ pẹ̀lú rẹ̀. Ẹ̀yin ó sì mọ̀ pé, èmi ni ó ti rán òfin yìí sí yín, kí májẹ̀mú mi pẹ̀lú Lefi lè tẹ̀síwájú” ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Májẹ̀mú mi wà pẹ̀lú rẹ̀, májẹ̀mú ti ìyè àti àlàáfíà wà pẹ̀lú rẹ̀; mo sì fi wọn fún un, nítorí bíbẹ̀rù tí ó bẹ̀rù mi, tí ẹ̀rù orúkọ mi sì bà á. Òfin òtítọ́ wà ni ẹnu rẹ̀, a kò sì rí irọ́ ni ètè rẹ̀: ó ba mi rìn ní àlàáfíà àti ni ìdúró ṣinṣin, ó sì yí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.

“Nítorí ètè àlùfáà ní òye láti máa pa ìmọ̀ mọ́, kí àwọn ènìyàn lè máa wá ìtọ́ni ni ẹnu rẹ̀: nítorí òun ni ìránṣẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yapa kúrò ní ọ̀nà náà; ẹ̀yin sì ti fi ìkọ́ni yín mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ kọsẹ̀; ẹ̀yin ti ba májẹ̀mú tí mo da pẹ̀lú Lefi jẹ́,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Nítorí náà ni èmi pẹ̀lú ṣe sọ yín di ẹ̀gàn, àti ẹni àìkàsí níwájú gbogbo ènìyàn, nítorí ẹ̀yin kò tẹ̀lé ọ̀nà mi, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń ṣe ojúsàájú nínú òfin.”

Matiu 23:13-28

13 (A)“Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè! Ẹ̀yin sé ìjọba ọ̀run mọ́ àwọn ènìyàn nítorí ẹ̀yin tìkára yín kò wọlé, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ wọlé ó wọlé.

14 “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè! Nítorí ẹ̀yin jẹ ilé àwọn opó run, àti nítorí àṣehàn, ẹ̀ ń gbàdúrà gígùn, nítorí náà ni ẹ̀yin yóò ṣe jẹ̀bi púpọ̀.

15 (B)“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè! Nítorí ẹ̀yin rin yí ilẹ̀ àti Òkun ká láti yí ẹnìkan lọ́kàn padà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń sọ ọ́ di ọmọ ọ̀run àpáàdì ní ìlọ́po méjì ju ẹ̀yin pàápàá.

16 (C)“Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin afọ́jú ti ń fi ọ̀nà han afọ́jú! Tí ó wí pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó ba fi tẹmpili búra kò sí nǹkan kan, ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá fi wúrà inú tẹmpili búra, ó di ajigbèsè.’ 17 Ẹ̀yin aláìmòye afọ́jú: èwo ni ó ga jù, wúrà tàbí tẹmpili tí ó ń sọ wúrà di mímọ́? 18 Àti pé, Ẹnikẹ́ni tó bá fi pẹpẹ búra, kò jámọ́ nǹkan, ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni tí ó ba fi ẹ̀bùn tí ó wà lórí rẹ̀ búra, ó di ajigbèsè. 19 Ẹ̀yin aláìmòye afọ́jú wọ̀nyí! Èwo ni ó pọ̀jù: ẹ̀bùn tí ó wà lórí pẹpẹ ni tàbí pẹpẹ fúnrarẹ̀ tí ó sọ ẹ̀bùn náà di mímọ́? 20 Nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá ń fi pẹpẹ búra, ó fi í búra àti gbogbo ohun tí ó wà lórí rẹ̀. 21 Àti pé, ẹni tí ó bá fi tẹmpili búra, ó fi í búra àti ẹni tí ń gbé inú rẹ̀. 22 Àti pé, ẹni tí ó bá sì fi ọ̀run búra, ó fi ìtẹ́ Ọlọ́run àti ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ búra.

23 (D)“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè! Nítorí ẹ̀yin ń gba ìdámẹ́wàá minti, dili àti kumini, ẹ̀yin sì ti fi ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ nínú òfin sílẹ̀ láìṣe, ìdájọ́, àánú àti ìgbàgbọ́: Wọ̀nyí ni ó tọ́ tí ẹ̀yin ìbá ṣe, ẹ̀yin kò bá fi wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀ láìṣe. 24 Ẹ̀yin afọ́jú tó ń fi afọ́jú mọ̀nà! Ẹ tu kòkòrò-kantíkantí tó bọ́ sì yín lẹ́nu nù, ẹ gbé ìbákasẹ mì.

25 (E)“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin Farisi àti ẹ̀yin olùkọ́ òfin, ẹ̀yin àgàbàgebè. Ẹ̀yin ń fọ òde ago àti àwo ṣùgbọ́n inú rẹ̀ kún fún ìrẹ́jẹ àti ẹ̀gbin gbogbo. 26 Ìwọ afọ́jú Farisi, tètè kọ́ fọ inú ago àti àwo, gbogbo ago náà yóò sì di mímọ́.

27 (F)“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin Farisi àti ẹ̀yin olùkọ́ òfin, ẹ̀yin àgàbàgebè. Ẹ dàbí ibojì funfun tí ó dára ní wíwò, ṣùgbọ́n tí ó kún fún egungun ènìyàn àti fún ẹ̀gbin àti ìbàjẹ́. 28 Ẹ̀yin gbìyànjú láti farahàn bí ènìyàn mímọ́, olódodo, lábẹ́ aṣọ mímọ́ yín ni ọkàn tí ó kún fún ìbàjẹ́ pẹ̀lú oríṣìíríṣìí àgàbàgebè àti ẹ̀ṣẹ̀ wà.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.