Revised Common Lectionary (Complementary)
Saamu ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú aginjù Juda.
63 Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi,
nígbà gbogbo ni mo ń ṣàfẹ́rí rẹ,
òǹgbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi,
ara mi fà sí ọ,
ní ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tí ń ṣàárẹ̀
níbi tí kò sí omi.
2 Èmi ti rí ọ ní ibi mímọ́,
mo rí agbára àti ògo rẹ.
3 Nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ayé lọ,
ètè mi yóò fògo fún ọ.
4 Èmi ó yìn ọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè,
èmi ó gbé ọwọ́ sókè, èmi ó sì pe orúkọ rẹ.
5 A ó tẹ́ ọkàn mi lọ́rùn bí ọlọ́ràá oúnjẹ;
pẹ̀lú ètè ìyìn, ẹnu mi yóò yìn ọ́.
6 Nígbà tí mo rántí rẹ lórí ibùsùn mi;
èmi ń ronú rẹ títí ìṣọ́ òru.
7 Nítorí ìwọ ni ìrànlọ́wọ́ mi,
mo kọrin níbi òjìji ìyẹ́ apá rẹ.
8 Ọkàn mí fà sí ọ:
ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbé mi ró.
9 Àwọn tí ó ń wá ọkàn mí ni a ó parun;
wọn ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé.
10 Wọn ó ti ọwọ́ idà ṣubú
wọn ó sì di jíjẹ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀.
11 Ṣùgbọ́n ọba yóò yọ̀ nínú Ọlọ́run
ẹni tí ó fi orúkọ Ọlọ́run búra yóò ṣògo
ṣùgbọ́n ẹnu àwọn òpùrọ́ la ó pamọ́.
1 Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Joẹli ọmọ Petueli wá.
Ìṣígun Eṣú
2 Ẹ gbọ́ èyí ẹ̀yin àgbàgbà;
ẹ fi etí sílẹ̀ gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ará ilẹ̀ náà.
Ǹjẹ́ irú èyí ha wà ní ọjọ́ yín,
tàbí ní ọjọ́ àwọn baba yín?
3 Ẹ sọ ọ́ fún àwọn ọmọ yín,
ki àwọn ọmọ yín sọ fún àwọn ọmọ wọn,
ki àwọn ọmọ wọn sọ fún àwọn ìran mìíràn.
4 Èyí tí eṣú tí agénijẹ jẹ kù
ní ọ̀wọ́ eṣú ńláńlá ti jẹ,
èyí tí ọ̀wọ́ eṣú ńláńlá jẹ kù
ní eṣú kéékèèkéé jẹ
Èyí tí eṣú kéékèèkéé jẹ kù
ni eṣú apanirun mìíràn jẹ.
5 Ẹ jí gbogbo ẹ̀yin ọ̀mùtí kí ẹ sì sọkún
ẹ hu gbogbo ẹ̀yin ọ̀mu-wáìnì;
ẹ hu nítorí wáìnì tuntun
nítorí a gbà á kúrò lẹ́nu yín.
6 (A)Nítorí orílẹ̀-èdè kan ti ṣígun sí ilẹ̀ mìíràn
ó ní agbára púpọ̀, kò sì ní òǹkà;
ó ní eyín kìnnìún
ó sì ní èrìgì abo kìnnìún.
7 Ó ti pa àjàrà mi run,
ó sì ti ya ẹ̀ka igi ọ̀pọ̀tọ́ mi kúrò,
ó ti bò èèpo rẹ̀ jálẹ̀, ó sì sọ ọ́ nù;
àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ni a sì sọ di funfun.
8 Ẹ pohùnréré ẹkún bí wúńdíá
tí a fi aṣọ ọ̀fọ̀ dí ni àmùrè, nítorí ọkọ ìgbà èwe rẹ̀.
9 A ké ọrẹ jíjẹ́ àti ọrẹ mímu kúrò
ní ilé Olúwa;
àwọn àlùfáà ń ṣọ̀fọ̀, àwọn
ìránṣẹ́ Olúwa,
10 Oko di ìgboro, ilẹ̀ ń ṣọ̀fọ̀,
nítorí a fi ọkà ṣòfò:
ọtí wáìnì tuntun gbẹ, òróró ń bùṣe.
11 Kí ojú kí ó tì yín, ẹ̀yin àgbẹ̀;
ẹ pohùnréré ẹkún ẹ̀yin olùtọ́jú àjàrà,
nítorí alikama àti nítorí ọkà barle;
nítorí ìkórè oko ṣègbé.
12 Àjàrà gbẹ, igi ọ̀pọ̀tọ́ sì rọ̀ dànù;
igi pomegiranate, igi ọ̀pẹ pẹ̀lú,
àti igi apiili, gbogbo igi igbó ni o rọ:
Nítorí náà ayọ̀ ọmọ ènìyàn gbẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn.
Ìpè fún ìrònúpìwàdà
13 Ẹ di ara yín ni àmùrè,
sí pohùnréré ẹkún ẹ̀yin àlùfáà:
ẹ pohùnréré ẹkún, ẹ̀yin ìránṣẹ́ pẹpẹ:
ẹ wá, fi gbogbo òru dùbúlẹ̀ nínú aṣọ ọ̀fọ̀,
ẹ̀yin ìránṣẹ́ Ọlọ́run mi: nítorí tí a dá ọrẹ-jíjẹ àti ọrẹ
mímu dúró ní ilé Ọlọ́run yín.
14 Ẹ yà àwẹ̀ kan sí mímọ́,
ẹ pe àjọ kan tí o ní ìrònú,
ẹ pe àwọn àgbàgbà,
àti gbogbo àwọn ará ilẹ̀ náà
jọ sí ilé Olúwa Ọlọ́run yín,
kí ẹ sí ké pe Olúwa.
Ọ̀rọ̀ ìyànjú Timotiu nínú ìròyìn
6 (A)Nísinsin yìí, Timotiu ti dé pẹ̀lú ìròyìn ayọ̀ wí pé, ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ yín ṣì lágbára bí i ti àtẹ̀yìnwá. Inú wa dùn láti gbọ́ wí pé ẹ ṣì ń rántí ìbágbé wa láàrín yín pẹ̀lú ayọ̀. Timotiu tún fi yé wa pé bí ó ti mú wa lọ́kàn tó láti rí i yín, ni ó ṣe ẹ̀yin pàápàá. 7 Nítorí náà, ẹ̀yin ará, inú wá dùn jọjọ nínú gbogbo ìyọnu àti ìjìyà wa níbí nítorí pé àwa mọ̀ nísinsin yìí pé, ẹ̀yin dúró gbọningbọnin fún Olúwa. 8 Nítorí àwa yè nísinsin yìí, bí ẹ̀yin bá dúró ṣinṣin nínú Olúwa. 9 Kò ṣe é ṣe fún wa láti dá ọpẹ́ tán lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí ayọ̀ àti ìfẹ́ tí ó máa ń kún ọkàn wa nípa àdúrà wa fún un yín. 10 Nítorí pé àwa ń gbàdúrà fún un yín lọ̀sán-án àti lóru. Èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àtúnṣe ibi tí ìgbàgbọ́ yín bá kù sí.
11 À ń gbàdúrà wí pé, kí ó wu Ọlọ́run pàápàá àti Olúwa wa Jesu Kristi láti rán wa padà sí ọ̀dọ̀ yín lẹ́ẹ̀kan sí í. 12 A sì béèrè pé, kí Ọlọ́run ràn yín lọ́wọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí ìfẹ́ yín yóò fi gbòòrò tí yóò sì sàn kan olúkúlùkù yín. Èyí yóò jẹ́ àpẹẹrẹ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ àwa náà ṣe sàn kan ẹ̀yin náà. 13 (B)Kí ó lè fi ọkàn yín balẹ̀ ní àìlábùkù nínú ìwà mímọ́ níwájú Ọlọ́run àti Baba wa. Nígbà náà, ẹ ó ní ìgboyà láti dúró níwájú rẹ̀ láìṣẹ̀, ní ọjọ́ tí Olúwa wa Jesu Kristi yóò padà wá pẹ̀lú àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.