Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 18:1-3

Fún adarí orin. Ti Dafidi ìránṣẹ́ Olúwa tí ó kọ sí Olúwa, ọ̀rọ̀ orin tí ó kọ sí Olúwa fún ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ Saulu ọ̀tá rẹ̀. Ó wí pé

18 (A)Mo fẹ́ ọ, Olúwa, agbára mi.

Olúwa ni àpáta àti odi mi, àti olùgbàlà mi;
    Ọlọ́run mi ni àpáta mi, ẹni tí mo fi ṣe ibi ìsádi mi.
    Òun ni àpáta ààbò àti ìwo ìgbàlà mi àti ibi ìsádi mi.

Mo ké pe Olúwa, ẹni tí ìyìn yẹ fún,
    a ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi.

Saamu 18:20-32

20 Olúwa ti hùwà sí mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;
    gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi, ó ti fi èrè fún mi
21 Nítorí mo ti pa ọ̀nà Olúwa mọ́;
    èmi kò ṣe búburú nípa yíyí padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi
22 Gbogbo òfin rẹ̀ ni ó wà níwájú mi;
    èmi kò sì yípadà kúrò nínú ìlànà rẹ̀.
23 Mo ti jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú rẹ̀;
    mo sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.
24 Olúwa san ẹ̀san fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;
    gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi níwájú rẹ̀.

25 Fún olóòtítọ́ ni ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní olóòtítọ́,
    sí aláìlẹ́bi, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní aláìlẹ́bi,
26 Sí ọlọ́kàn mímọ́, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní ọlọ́kàn mímọ́,
    ṣùgbọ́n sí ọlọ́kàn-wíwọ́, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní òǹrorò.
27 O pa onírẹ̀lẹ̀ mọ́,
    ṣùgbọ́n ó rẹ àwọn ti ń gbéraga sílẹ̀.
28 Ìwọ, Olúwa, jẹ́ kí fìtílà mi
    kí ó máa tàn; Ọlọ́run mi, yí òkùnkùn mi padà sí ìmọ́lẹ̀.
29 Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, èmi sáré tọ ogun lọ;
    pẹ̀lú Ọlọ́run mi mo lè fo odi kan.

30 Bí ó ṣe ti Ọlọ́run mi, ọ̀nà rẹ̀ pé,
    a ti rídìí ọ̀rọ̀ Olúwa
    òun ni àpáta ààbò fún gbogbo àwọn tí ó fi ṣe ààbò.
31 Nítorí ta ni ṣe Ọlọ́run bí kò ṣe Olúwa?
    Ta ní àpáta bí kò ṣe Olúwa wa?
32 Ọlọ́run ni ẹni tí ó fi agbára dì mí ní àmùrè
    ó sì mú ọ̀nà mi pé.

Deuteronomi 32:18-20

18 Ìwọ kò rántí àpáta, tí ó bí ọ;
    o sì gbàgbé Ọlọ́run tí ó dá ọ.

19 Olúwa sì rí èyí ó sì kọ̀ wọ́n,
    nítorí tí ó ti bínú nítorí ìwà ìmúnibínú àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ.
20 Ó sì wí pé, “Èmi yóò pa ojú mi mọ́ kúrò lára wọn,
    èmi yóò sì wò ó bí ìgbẹ̀yìn in wọn yóò ti rí;
nítorí wọ́n jẹ́ ìran alágídí,
    àwọn ọmọ tí kò sí ìgbàgbọ́ nínú wọn.

Deuteronomi 32:28-39

28 Wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tí kò ní ìmọ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni kò sí òye nínú wọn.
29 Bí ó ṣe pé wọ́n gbọ́n, kí òye yìí sì yé wọn
    kí wọn ro bí ìgbẹ̀yìn wọn yóò ti rí!
30 Báwo ni ẹnìkan ṣe lè lé ẹgbẹ̀rún,
    tàbí tí ẹni méjì sì lè lé ẹgbàárùn-ún sá,
bí kò ṣe pé àpáta wọn ti tà wọ́n,
    bí kò ṣe pé Olúwa wọn ti fi wọ́n tọrẹ?
31 Nítorí pé àpáta wọn kò dàbí àpáta wa,
    àní àwọn ọ̀tá wa tìkára wọn ń ṣe onídàájọ́.
32 Igi àjàrà a wọn wá láti igi àjàrà Sodomu
    àti ti ìgbẹ́ ẹ Gomorra.
Èso àjàrà wọn kún fún oró,
    Ìdì wọn korò.
33 Ọtí wáìnì wọn ìwọ ti dragoni ni,
    àti oró mímú ti ejò paramọ́lẹ̀.

34 “Èmi kò to èyí jọ ní ìpamọ́
    èmi kò sì fi èdìdì dì í ní ìṣúra mi?
35 Ti èmi ni láti gbẹ̀san; Èmi yóò san án fún wọn
    ní àkókò tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn yóò yọ;
ọjọ́ ìdààmú wọn súnmọ́ etílé
    ohun tí ó sì ń bọ̀ wá bá wọn yára bọ̀.”

36 Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn an rẹ̀
    yóò sì ṣàánú fún àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀
nígbà tí ó bá rí i pé agbára wọn lọ tán
    tí kò sì sí ẹnìkan tí ó kù, ẹrú tàbí ọmọ.
37 Yóò wí pé: “Òrìṣà wọn dà báyìí,
    àpáta tí wọ́n fi ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé e wọn,
38 ọlọ́run tí ó jẹ ọ̀rá ẹran ẹbọ wọn
    tí ó ti mu ọtí i wáìnì ẹbọ ohun mímu wọn?
Jẹ́ kí wọn dìde láti gbà wọ́n!
    Jẹ́ kí wọn ṣe ààbò fún un yín!

39 “Wò ó báyìí pé: èmi fúnra à mi, èmi ni!
    Kò sí ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi.
Mo sọ di kíkú mo sì tún sọ di ààyè,
    Mo ti ṣá lọ́gbẹ́ Èmi yóò sì mu jiná,
    kò sí ẹni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ ọ̀ mi.

Romu 11:33-36

Ìyìn fún Ọlọ́run

33 (A)A! Ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run!
    Àwámárídìí ìdájọ́ rẹ̀ ti rí,
    ọ̀nà rẹ̀ sì jù àwárí lọ!
34 (B)“Nítorí ta ni ó mọ ọkàn Olúwa?
    Tàbí ta ni í ṣe ìgbìmọ̀ rẹ̀?”
35 (C)“Tàbí ta ni ó kọ́ fi fún un,
    tí a kò sì san padà fún un?”
36 (D)Nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti nípa rẹ̀, àti fún un ni ohun gbogbo;
    ẹni tí ògo wà fún láéláé! Àmín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.