Revised Common Lectionary (Complementary)
Ìgbàlà ayérayé fún Sioni
51 “Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin tí ó ń lépa òdodo
àti ẹ̀yin tí ń wá Olúwa:
Wo àpáta, nínú èyí tí a ti gé yín jáde
àti ihò òkúta níbi tí a ti gbẹ́ yín jáde;
2 ẹ wo Abrahamu baba yín,
àti Sara, ẹni tó bí i yín.
Nígbà tí mo pè é, òun nìkan ni,
Èmi sì bùkún un, mo sì ṣọ́ ọ di ọ̀pọ̀lọpọ̀.
3 Dájúdájú, Olúwa yóò tu Sioni nínú
yóò sì bojú àánú wo gbogbo ahoro rẹ̀;
Òun yóò sọ gbogbo aṣálẹ̀ rẹ̀ di Edeni,
àti aṣálẹ̀ rẹ̀ yóò rí bí ọgbà Olúwa.
Ayọ̀ àti inú dídùn ni a ó rí nínú rẹ̀,
ọpẹ́ àti ariwo orín kíkọ.
4 “Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin ènìyàn mi;
gbọ́ tèmi, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè mi:
Òfin yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde wá;
ìdájọ́ mi yóò di ìmọ́lẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè.
5 Òdodo mi ń bọ̀ wá kíkankíkan,
ìgbàlà mi ń bọ̀ lójú ọ̀nà,
àti apá mi yóò sì mú ìdájọ́ wá
sí àwọn orílẹ̀-èdè.
Àwọn erékùṣù yóò wò mí
wọn yóò sì dúró ní ìrètí fún apá mi.
6 (A)Gbé ojú rẹ sókè sí àwọn ọ̀run,
wo ilẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀;
Àwọn ọ̀run yóò pòórá bí èéfín,
ilẹ̀ yóò sì gbó bí ẹ̀wù
àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò kú gẹ́gẹ́ bí àwọn eṣinṣin.
Ṣùgbọ́n ìgbàlà mi yóò wà títí láé,
òdodo mi kì yóò yẹ̀ láé.
Ti Dafidi
138 Èmi yóò yìn ọ́ tinútinú mi gbogbo;
níwájú àwọn òrìṣà ni èmi ó kọrin ìyìn sí ọ.
2 Èmi ó máa gbàdúrà sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀
èmi ó sì máa yin orúkọ rẹ
nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ;
nítorí ìwọ gbé ọ̀rọ̀ rẹ ga ju orúkọ rẹ lọ.
3 Ní ọjọ́ tí mo ké pè é ọ́, ìwọ dá mi lóhùn,
ìwọ sì fi ipa mú mi lára le ní ọkàn mi.
4 Gbogbo àwọn ọba ayé yóò yìn ọ́,
Olúwa, ní ìgbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ
5 Nítòótọ́, wọn ó máa kọrin ní ipa ọ̀nà Olúwa;
nítorí pé ńlá ni ògo Olúwa.
6 Bí Olúwa tilẹ̀ ga, síbẹ̀ ó júbà àwọn onírẹ̀lẹ̀;
ṣùgbọ́n agbéraga ni ó mọ̀ ní òkèrè réré.
7 Bí èmi tilẹ̀ ń rìn nínú ìpọ́njú ìwọ ni yóò sọ mi di ààyè;
ìwọ ó na ọwọ́ rẹ sí àwọn ọ̀tá mi,
ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbà mí.
8 Olúwa yóò ṣe ohun tí ń ṣe tèmi láṣepé;
Olúwa, àánú rẹ dúró láéláé;
Má ṣe kọ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ sílẹ̀.
Ẹbọ ààyè mímọ́
12 (A)Nítorí náà mo fi ìyọ́nú Ọlọ́run bẹ̀ yín ará, kí ẹ̀yin kí ó fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè mímọ́, ìtẹ́wọ́gbà, èyí ni iṣẹ́ ìsìn yín tí ó tọ̀nà. 2 (B)Kí ẹ má sì da ara yín pọ̀ mọ́ ayé yìí; ṣùgbọ́n kí ẹ paradà láti di tuntun ní èrò inú yín, kí ẹ̀yin kí ó lè rí ìdí ìfẹ́ Ọlọ́run, tí ó dára, tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ti ó sì pé.
Ìsìn ìrẹ̀lẹ̀ nínú Kristi
3 Ǹjẹ́ mo wí fún olúkúlùkù ènìyàn tí ó wà nínú yín, nípa oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún mi, kí ó má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣùgbọ́n kí ó le rò níwọ́ntún-wọ́nsì, bí Ọlọ́run ti fi ìwọ̀n ìgbàgbọ́ fún olúkúlùkù. 4 (C)Nítorí gẹ́gẹ́ bí àwa ti ní ẹ̀yà púpọ̀ nínú ara kan, tí gbogbo ẹ̀yà kò sì ní iṣẹ́ kan náà: 5 (D)Bẹ́ẹ̀ ni àwa, tí a jẹ́ púpọ̀, a jẹ́ ara kan nínú Kristi, àti olúkúlùkù ẹ̀yà ara ọmọnìkejì rẹ̀. 6 (E)Ǹjẹ́ bí àwa sì ti ń rí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹ̀bùn gbà gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún wa, bí ó ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, kí a máa sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ìgbàgbọ́; 7 Tàbí iṣẹ́ ìránṣẹ́, kí a kọjú sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa tàbí ẹni tí ń kọ́ni, kí ó kọjú sí kíkọ́. 8 Tàbí ẹni tí ó ń gbani níyànjú, sí ìgbìyànjú; ẹni tí ń fi fún ni kí ó máa fi inú kan ṣe é; ẹni tí ń ṣe olórí, kí ó máa ṣe é ní ojú méjèèjì; ẹni tí ń ṣàánú, kí ó máa fi inú dídùn ṣe é.
Peteru jẹ́wọ́ Kristi
13 (A)Nígbà tí Jesu sì dé Kesarea-Filipi, ó bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ta ni àwọn ènìyàn ń fi Ọmọ ènìyàn pè?”
14 (B)Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn kan ni Johanu onítẹ̀bọmi ni, àwọn mìíràn wí pé, Elijah ni, àwọn mìíràn wí pé, Jeremiah ni, tàbí ọ̀kan nínú àwọn wòlíì.”
15 “Ṣùgbọ́n ẹyin ń kọ?” Ó bi í léèrè pé, “Ta ni ẹ̀yin ń fi mi pè?”
16 (C)Simoni Peteru dáhùn pé, “Ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.”
17 (D)Jesu sì wí fún un pé, “Alábùkún fún ni ìwọ Simoni ọmọ Jona, nítorí ẹran-ara àti ẹ̀jẹ̀ kọ́ ló fi èyí hàn bí kò ṣe Baba mi tí ó ń bẹ ní ọ̀run. 18 Èmi wí fún ọ, ìwọ ni Peteru àti pé orí àpáta yìí ni èmi yóò kọ́ ìjọ mi lé, àti ẹnu-ọ̀nà ipò òkú kì yóò lè borí rẹ̀. 19 Èmi yóò fún ní àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba Ọ̀run; Ohun tí ìwọ bá dè ní ayé, òun ni a ó dè ní ọ̀run. Ohunkóhun tí ìwọ bá sì tú ní ayé yìí, a ó sì tú ní ọ̀run.” 20 (E)Nígbà náà ó kìlọ̀ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni pé Òun ni Kristi náà.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.