Revised Common Lectionary (Complementary)
Ti Dafidi
138 Èmi yóò yìn ọ́ tinútinú mi gbogbo;
níwájú àwọn òrìṣà ni èmi ó kọrin ìyìn sí ọ.
2 Èmi ó máa gbàdúrà sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀
èmi ó sì máa yin orúkọ rẹ
nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ;
nítorí ìwọ gbé ọ̀rọ̀ rẹ ga ju orúkọ rẹ lọ.
3 Ní ọjọ́ tí mo ké pè é ọ́, ìwọ dá mi lóhùn,
ìwọ sì fi ipa mú mi lára le ní ọkàn mi.
4 Gbogbo àwọn ọba ayé yóò yìn ọ́,
Olúwa, ní ìgbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ
5 Nítòótọ́, wọn ó máa kọrin ní ipa ọ̀nà Olúwa;
nítorí pé ńlá ni ògo Olúwa.
6 Bí Olúwa tilẹ̀ ga, síbẹ̀ ó júbà àwọn onírẹ̀lẹ̀;
ṣùgbọ́n agbéraga ni ó mọ̀ ní òkèrè réré.
7 Bí èmi tilẹ̀ ń rìn nínú ìpọ́njú ìwọ ni yóò sọ mi di ààyè;
ìwọ ó na ọwọ́ rẹ sí àwọn ọ̀tá mi,
ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbà mí.
8 Olúwa yóò ṣe ohun tí ń ṣe tèmi láṣepé;
Olúwa, àánú rẹ dúró láéláé;
Má ṣe kọ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ sílẹ̀.
11 Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: 12 “Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún sórí ọba Tire kí ó sì sọ fún un pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ ìjẹ́pípé náà,
o kún fún ọgbọ́n,
o sì pé ní ẹwà.
13 Ìwọ ti wà ní Edeni, ọgbà Ọlọ́run;
onírúurú òkúta oníyebíye ni ìbora rẹ;
sardiu, topasi àti diamọndi, berili, óníkìsì,
àti jasperi, safire, emeradi,
turikuoṣe, àti karbunkili, àti wúrà,
ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti àwọn òkè rẹ ní a dà,
láti ara wúrà,
ní ọjọ́ tí á dá ọ ní a pèsè wọn.
14 A fi ààmì òróró yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí olùtọ́jú kérúbù,
torí èyí ni mo fi yàn ọ́.
Ìwọ wà lórí òkè mímọ́ Ọlọ́run;
ìwọ rìn ni àárín òkúta a mú bí iná,
15 Ìwọ pé ní ọ̀nà rẹ,
láti ọjọ́ tí a ti dá ọ,
títí a fi rí àìṣedéédéé ní inú rẹ.
16 Nípa ìtànkálẹ̀ òwò rẹ,
ìwọ kún fún ìwà ipá;
ìwọ sì dẹ́ṣẹ̀.
Nítorí náà ni mo ṣe sọ ọ nù,
bí ohun àìlọ́wọ̀ kúrò lórí òkè Ọlọ́run.
Èmi sì pa ọ run,
ìwọ kérúbù, tí ó bọ́ kúrò ní àárín òkúta a mú bí iná.
17 Ọkàn rẹ gbéraga,
nítorí ẹwà rẹ.
Ìwọ sì ba ọgbọ́n rẹ jẹ́,
nítorí dídára rẹ.
Nítorí náà mo le ọ sórí ayé;
mo sọ ọ di awòojú níwájú àwọn ọba.
18 Nípa ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ rẹ àti òwò àìṣòótọ́ rẹ,
ìwọ ti ba àwọn ibi mímọ́ rẹ jẹ́.
Nítorí náà mo mú kí iná jáde wá,
láti inú rẹ, yóò sì jó ọ run,
èmi yóò sì sọ ọ́ di eérú lórí ilẹ̀,
lójú gbogbo àwọn tí ó ń wò ọ́.
19 Gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó mọ̀ ọ́n,
ní ẹnu ń yà sí ọ;
ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rù,
ìwọ kì yóò sì ṣí mọ́ láéláé.’ ”
Ìyànjú èdè-àìyedè àwọn onígbàgbọ́
6 (A)Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ni èdè-àìyedè sí ẹnìkejì rẹ̀, ó ha gbọdọ̀ lọ pè é lẹ́jọ́ níwájú àwọn aláìṣòótọ́ bí, bí kò ṣe níwájú àwọn ènìyàn mímọ́? 2 Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwọn ẹni mímọ́ ni yóò ṣe ìdájọ́ ayé? Ǹjẹ́ bí ó ba ṣe ìpàṣẹ yín ni a o ti ṣe ìdájọ́ ayé, kín ni ìdí tí ẹ kò fi yanjú àwọn ọ̀rọ̀ kéékèèkéé wọ̀nyí láàrín ara yín. 3 Ẹ kò mọ̀ pé àwa ni a ó ṣe ìdájọ́ àwọn angẹli ní? Mélòó mélòó àwọn nǹkan tó wà nínú ayé yìí. 4 Nítorí náà, bí ẹ̀yin bá ni aáwọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí, ǹjẹ́ ẹ ó yàn láti gba ìdájọ́ lọ́dọ̀ àwọn tí ìgbé ayé wọn ń di gígàn nínú ìjọ. 5 Mo sọ èyí kí ojú lè tì yín. Ṣé ó ṣe é ṣe kí a máa rín ẹnìkan láàrín yín tí ó gbọ́n níwọ̀n láti ṣe ìdájọ́ èdè-àìyedè láàrín àwọn onígbàgbọ́? 6 Ṣùgbọ́n dípò èyí, arákùnrin kan ń pe arákùnrin kejì lẹ́jọ́ sí ilé ẹjọ́ níwájú àwọn aláìgbàgbọ́.
7 (B)Ǹjẹ́ nísinsin yìí, àbùkù ni fún un yín pátápátá pé ẹ̀yin ń bá ara yín ṣe ẹjọ́. Kín ní ṣe tí ẹ kò kúkú gba ìyà? Kín ló dé tí ẹ kò kúkú gba ìrẹ́jẹ kí ẹ sì fi i sílẹ̀ bẹ́ẹ̀? 8 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń jẹ ni ní ìyà, ẹ sì ń rẹ́ ni jẹ. Ẹ̀yin si ń ṣe èyí sí àwọn arákùnrin yín. 9 (C)Ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwọn aláìṣòótọ́ kì í yóò jogún ìjọba Ọlọ́run? Kí a máa tàn yín jẹ; kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ṣe ìṣe obìnrin tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ba ara wọn lòpọ̀ 10 tàbí àwọn olè, tàbí àwọn wọ̀bìà, tàbí àwọn ọ̀mùtí, tàbí àwọn apẹ̀gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run. 11 (D)Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn nínú yín sì tí jẹ́ rí; ṣùgbọ́n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti dá yín láre ni orúkọ Jesu Kristi Olúwa, àti nípa Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run wa.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.