Revised Common Lectionary (Complementary)
Fún adarí orin. Ti Dafidi ìránṣẹ́ Olúwa tí ó kọ sí Olúwa, ọ̀rọ̀ orin tí ó kọ sí Olúwa fún ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ Saulu ọ̀tá rẹ̀. Ó wí pé
18 (A)Mo fẹ́ ọ, Olúwa, agbára mi.
2 Olúwa ni àpáta àti odi mi, àti olùgbàlà mi;
Ọlọ́run mi ni àpáta mi, ẹni tí mo fi ṣe ibi ìsádi mi.
Òun ni àpáta ààbò àti ìwo ìgbàlà mi àti ibi ìsádi mi.
3 Mo ké pe Olúwa, ẹni tí ìyìn yẹ fún,
a ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi.
4 Ìrora ikú yí mi kà,
àti ìṣàn omi àwọn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí.
5 Okùn isà òkú yí mi ká,
ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí.
6 Nínú ìpọ́njú mo ké pe Olúwa;
Mo sọkún sí Olúwa mi fún ìrànlọ́wọ́.
Láti inú tẹmpili rẹ̀, ó gbọ́ igbe mi;
ẹkún mi wá sí iwájú rẹ̀, sí inú etí rẹ̀.
7 Ayé wárìrì, ó sì mì tìtì,
ìpìlẹ̀ àwọn òkè gíga sì ṣídìí;
wọ́n wárìrì nítorí tí ó ń bínú.
8 Èéfín ti ihò imú rẹ̀ jáde wá;
Iná ajónirun ti ẹnu rẹ̀ jáde wá,
ẹ̀yin iná bú jáde láti inú rẹ̀.
9 Ó pín àwọn ọ̀run, Ó sì jáde wá;
àwọsánmọ̀ dúdú sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.
10 Ó gun orí kérúbù, ó sì fò;
ó ń rábàbà lórí ìyẹ́ apá afẹ́fẹ́.
11 Ó fi òkùnkùn ṣe ibojì rẹ̀, ó fi ṣe ìbòrí yí ara rẹ̀ ká
kurukuru òjò dúdú ní ojú ọ̀run.
12 Nípa ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀, àwọsánmọ̀ ṣíṣú dudu rẹ kọjá lọ
pẹ̀lú yìnyín àti ẹ̀yín iná
13 Olúwa sán àrá láti ọ̀run wá;
Ọ̀gá-ògo sì fọ ohun rẹ̀; yìnyín àti ẹ̀yin iná.
14 Ó ta àwọn ọfà rẹ̀, ó sì tú àwọn ọ̀tá náà ká,
ọfà mọ̀nàmọ́ná ńlá sì dà wọ́n rú.
15 A sì fi ìsàlẹ̀ àwọn Òkun hàn,
a sì rí àwọn ìpìlẹ̀ ayé
nípa ìbáwí rẹ, Olúwa,
nípa fífún èémí ihò imú rẹ.
16 Ó sọ̀kalẹ̀ láti ibi gíga, ó sì dì mímú;
Ó fà mí jáde láti inú omi jíjìn.
17 Ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára,
láti ọwọ́ àwọn ọ̀tá, ti ó lágbára jù fún mi.
18 Wọ́n dojúkọ mí ní ọjọ́ ìpọ́njú mi;
ṣùgbọ́n Olúwa ni alátìlẹ́yìn mi.
19 Ó mú mi jáde wá sínú ibi ńlá;
Ó gbà mí nítorí tí ó ní inú dídùn sí mi.
24 Rántí kí ìwọ kí ó gbé iṣẹ́ rẹ̀ ga,
ti ènìyàn ni yín nínú orin.
25 Olúkúlùkù ènìyàn a máa rí i;
ẹni ikú a máa wò ó ní òkèrè,
26 Kíyèsi i, Ọlọ́run tóbi, àwa kò sì mọ̀ bí ó ti ní òye tó,
bẹ́ẹ̀ ni a kò lè wádìí iye ọdún rẹ̀ rí.
27 “Nítorí pé òun ni ó fa ìkán omi òjò sílẹ̀,
kí wọn kí ó kán bí òjò ní ìkùùkuu rẹ̀,
28 tí àwọsánmọ̀ ń rọ̀ ìrì rẹ̀ sílẹ̀,
tí ó sì fi ń sẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ lórí ènìyàn.
29 Pẹ̀lúpẹ̀lú ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè ní ìmọ̀ ìtànká àwọsánmọ̀,
tàbí ariwo àrá láti àgọ́ rẹ̀?
30 Kíyèsi i, ó tan ìmọ́lẹ̀ yí ara rẹ̀ ká
ó sì bo ìsàlẹ̀ Òkun mọ́lẹ̀.
31 Nítorí pé nípa wọn ní ń ṣe dájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ènìyàn;
ó sí ń pèsè oúnjẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
32 Ó fi ìmọ́lẹ̀ bo ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì
ó sì rán an sí ẹni olódì.
33 Ariwo àrá rẹ̀ fi ìjì hàn ní;
ọ̀wọ́ ẹran pẹ̀lú wí pé, ó súnmọ́ etílé!
14 “Jobu, dẹtí sílẹ̀ sí èyí;
dúró jẹ́ẹ́ kí o sì ro iṣẹ́ ìyanu Ọlọ́run.
15 Ṣe ìwọ mọ àkókò ìgbà tí Ọlọ́run ṣe wọ́n lọ́jọ̀,
tí ó sì mú ìmọ́lẹ̀ àwọsánmọ̀ rẹ̀ dán?
16 Ṣé ìwọ mọ ìgbà tí àwọsánmọ̀ í fò lọ,
iṣẹ́ ìyanu ẹni tí ó pé ní ìmọ̀?
17 Ìwọ ẹni ti aṣọ rẹ̀ ti máa n gbóná,
nígbà tí ó fi atẹ́gùn ìhà gúúsù mú ayé dákẹ́.
18 Ìwọ ha ba tẹ́ pẹpẹ ojú ọ̀run, tí ó dúró ṣinṣin,
tí ó sì dàbí dígí tí ó yọ̀ dà?
19 “Kọ́ wa ní èyí tí a lè wí fún un;
nítorí pé àwa kò le wádìí ọ̀rọ̀ náà nítorí òkùnkùn wa.
20 A ó ha wí fún un pé, èmi fẹ́ sọ̀rọ̀?
Tàbí ẹnìkan lè wí pé, ìfẹ́ mi ni pé kí a gbé mi mì?
21 Síbẹ̀ nísinsin yìí ènìyàn kò rí
oòrùn tí ń dán nínú àwọsánmọ̀,
ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ń kọjá, a sì gbá wọn mọ́.
22 Wúrà dídán ti inú ìhà àríwá jáde wá;
lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ọláńlá ẹ̀rù ńlá wa.
23 Nípa ti Olódùmarè àwa kò le wádìí rẹ̀, ó rékọjá ní ipá;
nínú ìdájọ́ àti títí bi òun kì í ba ẹ̀tọ́ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òtítọ́ jẹ́.
24 Nítorí náà ènìyàn ha máa bẹ̀rù rẹ̀,
òun kì í ṣe ojú sájú ẹnikẹ́ni tí ó gbọ́n ní ayé?”
Jesu dá ìjì líle dúró
23 (A)Nígbà náà ni ó bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀lé e. 24 Ní àìròtẹ́lẹ̀, ìjì líle dìde lórí Òkun tó bẹ́ẹ̀ tí rírú omi fi bò ọkọ̀ náà mọ́lẹ̀; ṣùgbọ́n Jesu ń sùn. 25 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn jí i, wọ́n wí pe, “Olúwa, gbà wá! Àwa yóò rì!”
26 (B)Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré. Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń bẹ̀rù?” Nígbà náà ní ó dìde dúró, ó sì bá ìjì àti rírú Òkun náà wí, gbogbo rẹ̀ sì parọ́rọ́.
27 Ṣùgbọ́n ẹnu yà àwọn ọkùnrin náà, wọ́n sì béèrè pé, “Irú ènìyàn wo ni èyí? Kódà ìjì líle àti rírú omi Òkun gbọ́ tirẹ̀?”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.