Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 67

Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu. Orin.

67 Kí Ọlọ́run kí ó ṣàánú fún wa kí ó sì bùkún fún wa,
    kí ó sì jẹ́ kí ojú rẹ̀ tàn yí wa ká,
kí ọ̀nà rẹ le di mí mọ̀ ní ayé,
    ìgbàlà rẹ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.

Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run;
    kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́!
Kí orílẹ̀-èdè kí ó yọ̀, kí ó sì kọrin fún ayọ̀,
    nítorí ìwọ fi òdodo darí àwọn ènìyàn,
    ìwọ sì jẹ ọba àwọn orílẹ̀-èdè ní ayé.
Kí àwọn ènìyàn kí ó yìn ọ́, Ọlọ́run;
    kí gbogbo ènìyàn kí ó yìn ọ́. Sela.

Nígbà náà ní ilẹ̀ yóò mú ìkórè rẹ̀ wá, Ọlọ́run,
    Ọlọ́run wa, yóò bùkún fún wa.
Ọlọ́run yóò bùkún fún wa,
    àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò sì máa bẹ̀rù rẹ̀.

Isaiah 56:1-5

Ìgbàlà fún àwọn mìíràn

56 Èyí ni ohun ti Olúwa sọ:

“Ẹ pa ìdájọ́ mọ́
    ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ̀nà,
nítorí ìgbàlà mi súnmọ́ tòsí
    àti òdodo mi ni a ó fihàn láìpẹ́ jọjọ.
Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣe èyí,
    àti fún ọmọ ènìyàn tí ó dìímú ṣinṣin,
tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́,
    tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi ṣíṣe.”

Má ṣe jẹ́ kí àjèjì kan tí ó ti di ara rẹ̀
    mọ́ Olúwa sọ wí pé,
Olúwa yóò yà mí sọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.”
Àti kí ìwẹ̀fà kan ṣe àròyé pé,
    “Igi gbígbẹ lásán ni mí.”

Nítorí pé báyìí ni Olúwa wí:

“Sí àwọn ìwẹ̀fà yìí tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́,
    tí wọ́n yan ohun tí ó dùn mọ́ mi
    tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin
fún wọn ni Èmi yóò fún nínú tẹmpili àti àgbàlá rẹ̀
    ìrántí kan àti orúkọ kan
tí ó sàn ju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin
    Èmi yóò fún wọn ní orúkọ ayérayé
    tí a kì yóò ké kúrò.

Matiu 14:34-36

34 (A)Nígbà tí wọn rékọjá sí apá kejì wọ́n gúnlẹ̀ sí Genesareti. 35 Nígbà tiwọn mọ̀ pé Jesu ni, wọn sì ránṣẹ́ sí gbogbo ìlú náà yíká. Wọ́n sì gbé gbogbo àwọn aláìsàn tọ̀ ọ́ wá. 36 (B)Àwọn aláìsàn bẹ̀ ẹ́ pé kí ó gba àwọn láyè láti fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, gbogbo àwọn tí ó ṣe bẹ́ẹ̀ sì rí ìwòsàn.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.