Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
1 Kronika 22

22 Nígbà náà Dafidi wí pé, “Ilé Olúwa Ọlọ́run ni ó gbọdọ̀ wà níbí, àti pẹ̀lú pẹpẹ ẹbọ sísun fún Israẹli.”

Ìmúrasílẹ̀ fún ilé tí a kọ́ fún ìsìn Ọlọ́run

Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi pàṣẹ láti kó àwọn àjèjì tí ń gbé ní Israẹli jọ, àti wí pé lára wọn ni ó ti yan àwọn agbẹ́-òkúta láti gbé òkúta dáradára láti fi kọ́lé Ọlọ́run. Dafidi sì pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye irin láti fi ṣe ìṣó fún àwọn ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà àti fún idẹ; àti fún òpó idẹ ni àìní ìwọ̀n. Ó sì tún pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi Kedari tí ó jẹ́ àìníye, nítorí pé àwọn ará Sidoni àti àwọn ará Tire mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi kedari wá fún Dafidi.

Dafidi wí pé, “Ọmọ mi Solomoni ọ̀dọ́mọdé ni ó sì jẹ́ aláìní ìrírí, ilé tí a ó kọ́ fún Olúwa gbọdọ̀ jẹ́ títóbi jọjọ, kí ó sì ní òkìkí àti ògo jákèjádò gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè. Nítorí náà ni èmi yóò ṣe pèsè sílẹ̀ fún un”. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì ṣe ìpèsè sílẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ kí ó tó di wí pé ó kú.

Nígbà náà ó pe Solomoni ọmọ rẹ̀ ó sì sọ fun pé kí ó kọ́ ilé fún un Olúwa, Ọlọ́run Israẹli. (A)Dafidi sì wí fún Solomoni pé, “Ọmọ mi, mo sì ní-in ní ọkàn mi láti kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run mi. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: ‘Ìwọ ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, o sì ti ja ọ̀pọ̀ ogun ńláńlá, kì í ṣe ìwọ ni yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi, nítorí ìwọ ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ púpọ̀ lórí ilẹ̀ ní ojú mi. Ṣùgbọ́n ìwọ yóò ní ọmọ tí yóò sì jẹ́ ọkùnrin onírẹ̀lẹ̀ àti onísinmi, Èmi yóò sì fún un ní ìsinmi láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀ yíká. Orúkọ rẹ̀ yóò sì máa jẹ́ Solomoni, Èmi yóò sì fi àlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ fún Israẹli lásìkò ìjọba rẹ̀. 10 Òun ni ẹni náà tí yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi. Yóò sì jẹ́ ọmọ mi, èmi yóò sì jẹ́ baba rẹ̀ èmi yóò sì fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lórí Israẹli láéláé.’

11 “Nísinsin yìí, ọmọ mi, kí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, kí ìwọ kí ó sì ní àṣeyọrí kí o sì kọ́ ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ nípa rẹ. 12 Olúwa kí ó fún ọ ni ọgbọ́n àti òye nígbà tí ó bá fi ọ́ ṣe aláṣẹ lórí Israẹli, Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó lè pa òfin Olúwa Ọlọ́run mọ́. 13 Nígbà náà ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí tí ìwọ bá ṣe àkíyèsí láti mú àṣẹ àti ìdájọ́ àti òfin ti Olúwa ti fi fún Mose fun Israẹli ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni ki ìwọ jẹ́ alágbára àti onígboyà. Má ṣè bẹ̀rù tàbí kí àyà má sì ṣe fò ọ́.

14 “Èmi ti gba ìpọ́njú ńlá láti ṣe fún ilé Olúwa ọ̀kẹ́ márùn-ún tálẹ́ǹtì wúrà, àti ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún tálẹ́ǹtì fàdákà, ìwọ̀n idẹ àti irin tí ó tóbi àìní ìwọ̀n, àti ìtì igi àti òkúta. Ìwọ sì tún le fi kún wọn. 15 Ìwọ sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oníṣẹ́ ènìyàn: àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àti àwọn oníṣọ̀nà òkúta àti àwọn agbẹ́-òkúta, àti gẹ́gẹ́ bí onírúurú ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní gbogbo onírúurú iṣẹ́. 16 Nínú wúrà, fàdákà àti idẹ àti irin oníṣọ̀nà tí kò ní ìwọ̀n. Nísinsin yìí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, kí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.”

17 Nígbà náà Dafidi pa á láṣẹ fún gbogbo àwọn àgbàgbà ní Israẹli láti ran Solomoni ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. 18 Ó sì wí pé, “Ṣé kò sí Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú rẹ? Òun kò ha ti fi ìsinmi fún ọ lórí gbogbo ilẹ̀? Nítorí ó sì ti fi àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ náà lé mi lọ́wọ́ ó sì ti fi ìṣẹ́gun fún ilẹ̀ náà níwájú Olúwa àti níwájú àwọn ènìyàn. 19 Nísinsin yìí, ẹ ṣí ọkàn yin páyà àti àyà yín sí àti wá Olúwa Ọlọ́run yín. Bẹ́ẹ̀ sì ni kọ́ ibi mímọ́ fún Olúwa Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó le gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa àti ohun èlò mímọ́ tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run, sínú ilé Olúwa tí a o kọ́ fún orúkọ Olúwa.”

1 Peteru 3

Àwọn aya àti àwọn ọkọ

Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín; pé, bí ẹnikẹ́ni ba tilẹ̀ ń ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láì sọ̀rọ̀ nípa ìwà àwọn aya wọn. Nígbà tí wọ́n bá ń wo ìwà rere pẹ̀lú ẹ̀rù yín: Kí ọ̀ṣọ́ yín má ṣe jẹ́ ọ̀ṣọ́ òde, tí irun dídì, àti wúrà lílò, tàbí ti aṣọ wíwọ̀; Ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni tí ó fi ara sin ní ọkàn, nínú ọ̀ṣọ́ àìdíbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ẹ̀mí tútù, èyí tí i ṣe iyebíye níwájú Ọlọ́run. Nítorí báyìí ni àwọn obìnrin mímọ́ ìgbàanì pẹ̀lú, tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, fi ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, wọn a máa tẹríba fún àwọn ọkọ wọn. (A)Gẹ́gẹ́ bí Sara ti gbọ́ ti Abrahamu, tí ó ń pè é ní olúwa rẹ̀. Ọmọbìnrin ẹni tí ẹ̀yin jẹ́, bí ẹ̀yin bá ń ṣe rere, tí ohunkóhun kò sí dẹ́rùbà yín.

Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa fi òye ba àwọn aya yín gbé, ẹ máa fi ọlá fún aya, bi ohun èlò ti kò lágbára, àti pẹ̀lú bí àjùmọ̀jogún oore-ọ̀fẹ́ ìyè; kí àdúrà yín má bà á ní ìdènà.

Jíjìyà fún ṣíṣe iṣẹ́ rere

Lákòótan, kí gbogbo yín jẹ́ onínú kan, ẹ máa bá ara yín kẹ́dùn, ẹ ní ìfẹ́ ará, ẹ máa ṣe ìyọ́nú, ẹ ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ Ẹ má ṣe fi búburú san búburú, tàbí fi èébú san èébú: ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa súre; nítorí èyí ni a pè yín sí, kí ẹ̀yin lè jogún ìbùkún. 10 (B)Nítorí,

“Ẹni tí yóò bá fẹ́ ìyè,
    ti yóò sì rí ọjọ́ rere,
kí o pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi,
    àti ètè rẹ̀ mọ́ kúrò nínú sísọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn:
11 Kí ó yà kúrò nínú ibi, kí ó sì máa ṣe rere;
    kí ó máa wá àlàáfíà, kí ó sì máa lépa rẹ̀.
12 Nítorí ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo,
    etí rẹ̀ sì ṣí sí ẹ̀bẹ̀ wọn:
ṣùgbọ́n ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú.”

13 Tá nì yóò sì ṣe yín ní ibi, bí ẹ̀yin bá jẹ́ onítara sí ohun rere? 14 (C)Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá jìyà nítorí òdodo, a ti bùkún yín. “Ẹ má ṣe bẹ̀rù ìhàlẹ̀ wọn, kí ẹ má sì ṣe kọminú.” 15 Ṣùgbọ́n ẹ bọ̀wọ̀ fún Kristi bí Olúwa ní ọkàn yín: kí ẹ sì múra tan nígbà gbogbo láti dá olúkúlùkù lóhùn tí ń béèrè ìrètí tí o ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn tútù àti ìbẹ̀rù. 16 Kí ẹ máa ni ẹ̀rí ọkàn rere bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ yín ní ibi, kí ojú lè ti àwọn tí ń kẹ́gàn ìwà rere yín nínú Kristi. 17 Nítorí ó sàn, bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ẹ jìyà fún ṣíṣe rere ju fún ṣíṣe búburú lọ. 18 Nítorí tí Kristi pẹ̀lú jìyà lẹ́ẹ̀kan nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòótọ́ fún àwọn aláìṣòótọ́, kí a lè mú wa dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí a pa nínú ara, ṣùgbọ́n tí a sọ di ààyè nínú ẹ̀mí: 19 Nínú èyí tí ó lọ pẹ̀lú tí ó sì wàásù fún àwọn ẹ̀mí nínú túbú: 20 (D)àwọn tí ó ṣe aláìgbọ́ràn nígbà kan, nígbà tí sùúrù Ọlọ́run dúró pẹ́ ní sá à kan ní ọjọ́ Noa, nígbà tí wọ́n fi kan ọkọ̀ nínú èyí tí a gba ọkàn díẹ̀ là nípa omi, èyí ni ẹni mẹ́jọ. 21 Àpẹẹrẹ èyí ti ń gbà yín là nísinsin yìí pẹ̀lú, àní ìtẹ̀bọmi, kì í ṣe wíwẹ́ èérí ti ara nù, bí kò ṣe ìdáhùn ẹ̀rí ọkàn rere si Ọlọ́run, nípa àjíǹde Jesu Kristi. 22 Ẹni tí ó lọ sí ọ̀run, tí ó sì ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run: pẹ̀lú àwọn angẹli, àwọn aláṣẹ, àti àwọn alágbára sì tẹríba lábẹ́ rẹ̀.

Mika 1

Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Mika ará Moreṣeti wá ní àkókò ìjọba Jotamu, Ahasi, àti Hesekiah, àwọn ọba Juda nìwọ̀nyí, ìran tí ó rí nípa Samaria àti Jerusalẹmu.

Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn,
    fetísílẹ̀, ìwọ ayé àti gbogbo ohun tó wà níbẹ̀,
Olúwa Olódùmarè lè ṣe ẹlẹ́rìí sí yín,
    (A)Olúwa láti inú tẹmpili mímọ́ rẹ̀ wá.

Ìdájọ́ tí o lòdì sí Samaria àti Jerusalẹmu

Wò ó! Olúwa ń bọ̀ wá láti ibùgbé rẹ̀;
    yóò sọ̀kalẹ̀, yóò sì tẹ ibi gíga ayé mọ́lẹ̀.
Àwọn òkè ńlá yóò sí yọ́ lábẹ́ rẹ̀,
    àwọn Àfonífojì yóò sì pínyà,
bí idà níwájú iná,
    bí omi tí ó ń sàn lọ ni ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́.
Nítorí ìré-òfin-kọjá Jakọbu ni gbogbo èyí,
    àti nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli.
Kí ni ìré-òfin-kọjá Jakọbu?
    Ǹjẹ́ Samaria ha kọ?
Kí ni àwọn ibi gíga Juda?
    Ǹjẹ́ Jerusalẹmu ha kọ?

“Nítorí náà, èmi yóò ṣe Samaria bí òkìtì lórí pápá,
    bí ibi ti à ń lò fún gbígbin ọgbà àjàrà.
Èmi yóò gbá àwọn òkúta rẹ̀ dànù sínú àfonífojì.
    Èmi yóò sí tú ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ palẹ̀.
Gbogbo àwọn ère fínfín rẹ̀ ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́
    gbogbo àwọn ẹ̀bùn tẹmpili rẹ̀ ni a ó fi iná sun:
    Èmi yóò sì pa gbogbo àwọn òrìṣà rẹ̀ run.
Nítorí tí ó ti kó àwọn ẹ̀bùn rẹ̀ jọ láti inú owó èrè panṣágà,
    gẹ́gẹ́ bí owó èrè panṣágà, wọn yóò sì tún padà sí owó iṣẹ́ panṣágà.”

Ẹkún òun ọfọ̀

Nítorí èyí, èmi yóò sì sọkún,
    èmi yóò sì pohùnréré ẹkún:
èmi yóò máa lọ ní ẹsẹ̀ lásán àti ní ìhòhò
    Èmi yóò ké bí akátá,
    èmi yóò sì máa dárò bí àwọn ọmọ ògòǹgò.
Nítorí tí ọgbẹ́ rẹ̀ jẹ́ aláìlèwòtán;
    ó sì ti wá sí Juda.
Ó sì ti dé ẹnu-bodè àwọn ènìyàn mi,
    àní sí Jerusalẹmu.
10 Ẹ má ṣe sọ ní Gati
    ẹ má ṣe sọkún rárá.
Ní ilẹ̀ Beti-Ofra
    mo yí ara mi nínú eruku.
11 Ẹ kọjá lọ ni ìhòhò àti ni ìtìjú,
    ìwọ tí ó ń gbé ni Ṣafiri.
Àwọn tí ó ń gbé ni Ṣaanani
    kì yóò sì jáde wá.
Beti-Eseli wà nínú ọ̀fọ̀;
    A ó sì gba ààbò rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ yin.
12 Nítorí àwọn tí ó ń gbé ni Marati ń retí ìre,
    Ṣùgbọ́n ibi sọ̀kalẹ̀ ti ọ̀dọ̀ Olúwa wá sí ẹnu-bodè Jerusalẹmu.
13 Ìwọ olùgbé Lakiṣi,
    dì kẹ̀kẹ́ mọ́ ẹranko tí ó yára.
Òun sì ni ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀
    sí àwọn ọmọbìnrin Sioni,
    nítorí a rí àìṣedéédéé Israẹli nínú rẹ̀.
14 Nítorí náà ni ìwọ ó ṣe fi ìwé ìkọ̀sílẹ̀
    fún Moreṣeti Gati.
Àwọn ilé Aksibu yóò jẹ́ ẹlẹ́tàn sí àwọn ọba Israẹli.
15 Èmi yóò sì mú àrólé kan wá sórí rẹ ìwọ olùgbé Meraṣa.
    Ẹni tí ó jẹ́ ògo Israẹli
    yóò sì wá sí Adullamu.
16 Fá irun orí rẹ nínú ọ̀fọ̀
    nítorí àwọn ọmọ rẹ aláìlágbára,
sọ ra rẹ̀ di apárí bí ẹyẹ igún,
    nítorí wọn yóò kúrò lọ́dọ̀ rẹ lọ sí ìgbèkùn.

Luku 10

Jesu rán àádọ́rin ọmọ-ẹ̀yìn jáde

10 (A)Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Olúwa sì yan àádọ́rin ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn pẹ̀lú, ó sì rán wọn ní méjì méjì lọ ṣáájú rẹ̀, sí gbogbo ìlú àti ibi tí òun tìkára rẹ̀ yóò sì dé. (B)Ó sì wí fún wọn pé, “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kò tó nǹkan, nítorí náà ẹ bẹ Olúwa ìkórè, kí ó lè rán àwọn alágbàṣe sínú ìkórè rẹ̀. (C)Ẹ mú ọ̀nà yín pọ̀n: sá wò ó, èmi rán yín lọ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sáàrín ìkookò. Ẹ má ṣe mú àpò, ẹ má ṣe mú àpamọ́wọ́, tàbí bàtà: ẹ má sì ṣe kí ẹnikẹ́ni lọ́nà.

(D)“Ní ilékílé tí ẹ̀yin bá wọ̀, kí ẹ kọ́ wí pé, ‘Àlàáfíà fún ilé yìí!’ Bí ọmọ àlàáfíà bá sì wà níbẹ̀, àlàáfíà yín yóò bà lé e: ṣùgbọ́n bí kò bá sí, yóò tún padà sọ́dọ̀ yín. (E)Ẹ dúró sínú ilé náà, kí ẹ máa jẹ, kí ẹ sì máa mu ohunkóhun tí wọ́n bá fi fún yín; nítorí ọ̀yà alágbàṣe tọ́ sí i, Ẹ má ṣe lọ láti ilé dé ilé.

“Ìlúkílùú tí ẹ̀yin bá wọ̀, tí wọ́n bá sì gbà yín, ẹ jẹ ohunkóhun tí a bá gbé ka iwájú yín: Ẹ sì mú àwọn aláìsàn tí ń bẹ nínú rẹ̀ láradá, kí ẹ sì wí fún wọn pé, ‘Ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀ sí yín!’ 10 Ṣùgbọ́n ní ìlúkílùú tí ẹ̀yin bá sì wọ̀, tí wọn kò bá sì gbà yín, nígbà tí ẹ̀yin bá sì jáde ní ìgboro ìlú náà, kí ẹ̀yin sì wí pé, 11 (F)‘Eruku ìlú yín tí ó kù sí wa lẹ́sẹ̀, a gbọ̀n ọ́n sílẹ̀ fún yín! Ṣùgbọ́n ẹ mọ èyí pé, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀.’ 12 (G)Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, yóò sàn fún Sodomu ní ọjọ́ náà, ju fún ìlú náà lọ.

13 (H)“Ègbé ni fún ìwọ, Koraṣini! Ègbé ni fún ìwọ Betisaida! Nítorí ìbá ṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ agbára tí a ṣe nínú yín, ní Tire àti Sidoni, wọn ìbá ti ronúpìwàdà lọ́jọ́ pípẹ́ sẹ́yìn, wọn ìbá sì jókòó nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti nínú eérú. 14 Ṣùgbọ́n yóò sàn fún Tire àti Sidoni nígbà ìdájọ́ jù fún yín lọ. 15 Àti ìwọ, Kapernaumu, a ó ha gbé ọ ga dé òkè ọ̀run? A ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ dé isà òkú.

16 (I)“Ẹni tí ó bá gbọ́ tiyín, ó gbọ́ tèmi. Ẹni tí ó bá sì kọ̀ yín, ó kọ̀ mi. Ẹni tí ó bá sì kọ̀ mi, ó kọ ẹni tí ó rán mi.”

17 Àwọn àádọ́rin náà sì fi ayọ̀ padà, wí pé, “Olúwa, àwọn ẹ̀mí èṣù tilẹ̀ foríbalẹ̀ fún wa ní orúkọ rẹ.”

18 (J)Ó sì wí fún wọn pé, “Èmí rí Satani ṣubú bí mọ̀nàmọ́ná láti ọ̀run wá. 19 Kíyèsi i, èmí fún yín ní àṣẹ láti tẹ ejò àti àkéekèe mọ́lẹ̀, àti lórí gbogbo agbára ọ̀tá: kò sì ṣí ohun kan bí ó ti wù tí ó ṣe, tí yóò pa yín lára. 20 (K)Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe yọ̀ nítorí èyí pé, àwọn ẹ̀mí ń foríbalẹ̀ fún yín; ṣùgbọ́n ẹ kúkú yọ̀, pé; a kọ̀wé orúkọ yín ní ọ̀run!”

21 (L)(M) Ní wákàtí kan náà Jesu yọ̀ nínú Ẹ̀mí mímọ́ ó sì wí pé, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Olúwa ọ̀run àti ayé, pé, ìwọ pa nǹkan wọ̀nyí mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye, ìwọ sì fi wọ́n hàn fún àwọn ọmọ ọwọ́: bẹ́ẹ̀ ni, Baba, bẹ́ẹ̀ ni ó sá à yẹ ní ojú rẹ.

22 (N)“Ohun gbogbo ni a ti fi fún mi láti ọ̀dọ̀ Baba mi; kò sì ṣí ẹni tí ó mọ ẹni tí ọmọ jẹ́, bí kò ṣe Baba; àti ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wu ọmọ láti fi í hàn fún.”

23 (O)Ó sì yípadà sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní apá kan. Ó ní, “Ìbùkún ni fún ojú tí ń rí ohun tí ẹ̀yin ń rí. 24 Nítorí mo wí fún yín, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti àwọn ọba ni ó ń fẹ́ láti rí ohun tí ẹ̀yin ń rí, wọn kò sì rí wọn, àti láti gbọ́ ohun tí ẹ̀yin ń gbọ́, wọn kò sì gbọ́ wọn.”

Òwe aláàánú ará Samaria

25 (P)(Q) Sì kíyèsi i amòfin kan dìde, ó ń dán an wò, ó ní, “Olùkọ́, kín ni èmi ó ṣe kí èmi lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”

26 Ó sì bi í pé, “Kí ni a kọ sínú ìwé òfin? Báwo ni ìwọ sì ti kà á?”

27 (R)Ó sì dáhùn wí pé, “ ‘Kí ìwọ fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ, àti gbogbo inú rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ’; àti, ‘ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ.’ ”

28 (S)Ó sì wí fún un pé, “Ìwọ́ dáhùn rere. Ṣe èyí, ìwọ ó sì yè.”

29 Ṣùgbọ́n ó ń fẹ́ láti da ara rẹ̀ láre, ó wí fún Jesu wí pé, “Ta ha sì ni ẹnìkejì mi?”

30 Jesu sì dáhùn ó wí pé, “Ọkùnrin kan ń ti Jerusalẹmu sọ̀kalẹ̀ lọ sí Jeriko, ó sì bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà; wọ́n gbà á ní aṣọ, wọ́n sá a lọ́gbẹ́, wọ́n sì fi sílẹ̀ lọ ní àìpatán. 31 Ní kòńgẹ́ àkókò yìí ni àlùfáà kan sì ń sọ̀kalẹ̀ lọ lọ́nà náà. Nígbà tí ó sì rí i ó kọjá lọ níhà kejì. 32 Bẹ́ẹ̀ náà sì ni ọmọ Lefi kan pẹ̀lú, nígbà tí ó dé ibẹ̀, tí ó sì rí i, ó kọjá lọ níhà kejì. 33 (T)Ṣùgbọ́n ará Samaria kan, bí ó ti ń re àjò, ó dé ibi tí ó gbé wà; nígbà tí ó sì rí i, àánú ṣe é. 34 Ó sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì di ọgbẹ́ rẹ̀, ó da òróró àti ọtí wáìnì sí i, ó sì gbé e lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ti òun tìkára rẹ̀, ó sì mú un wá sí ilé èrò, a sì ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀. 35 Nígbà tí ó sì lọ ní ọjọ́ kejì, ó fi owó idẹ méjì fún olórí ilé èrò ó sì wí fún un pé, ‘Máa tọ́jú rẹ̀; ohunkóhun tí ìwọ bá sì ná kún un, nígbà tí mo bá padà dé, èmi ó san án fún ọ.’

36 “Nínú àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí, ta ni ìwọ rò pé ó jẹ́ ẹnìkejì ẹni tí ó bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà?”

37 Ó sì dáhùn wí pé, “Ẹni tí ó ṣàánú fún un ni.”

Jesu sì wí fún un pé, “Lọ, kí o ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́!”

Ní ilé Marta àti Maria

38 (U)Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń lọ, o wọ ìletò kan, obìnrin kan tí a ń pè ní Marta sì gbà á sí ilé rẹ̀. 39 Ó sì ní arábìnrin kan tí a ń pè ní Maria tí ó sì jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Olúwa, tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. 40 Ṣùgbọ́n Marta ń ṣe ìyọnu ohun púpọ̀, ó sì tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, “Olúwa, ìwọ kò sì bìkítà sí ti arábìnrin mi pé ó fi mí sílẹ̀ láti máa nìkan ṣe ìránṣẹ́? Wí fún un kí ó ràn mí lọ́wọ́.”

41 (V)Ṣùgbọ́n Olúwa sì dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Marta, Marta, ìwọ ń ṣe àníyàn àti làálàá nítorí ohun púpọ̀. 42 Ṣùgbọ́n ohun kan ni a kò lè ṣe aláìní, Maria sì ti yan ipa rere náà tí a kò lè gbà lọ́wọ́ rẹ̀.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.