Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
1 Kronika 17

Ìlérí Ọlọ́run sí Dafidi

17 (A)Lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ti fi ìdí kalẹ̀ sínú ààfin rẹ̀, ó sọ fún Natani wòlíì pé, “Èmi nìyí, tí ń gbé inú òpépé (igi) ààfin kedari nígbà tí àpótí ẹ̀rí Olúwa wà lábẹ́ àgọ́.”

Natani dá Dafidi lóhùn pé, “Ohunkóhun tí o bá ní lọ́kàn, ṣe é nítorí tí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.”

Ní àṣálẹ́ ọjọ́ náà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Natani wá, wí pé:

“Lọ sọ fún ìránṣẹ́ mi Dafidi, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí: Ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ ilé fún mi láti máa gbé. Èmi kò tí ì gbé nínú ilé láti ọjọ́ tí mo ti mú Israẹli jáde wá láti Ejibiti títí di òní yìí. Èmi ń lọ láti àgọ́ dé àgọ́ àti láti ibùgbé dé ibùgbé. Ni ibi gbogbo tí mo ti bá gbogbo Israẹli rìn dé, ǹjẹ́ mo wí nǹkan kan sí ọ̀kan nínú àwọn adarí Israẹli, tí èmí pàṣẹ fún láti máa jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn mi, wí pé, “Kí ní ṣe tí ẹ̀yin kò fi kọ́ ilé tí a fi igi kedari kọ́ fún mi?” ’

“Nígbà náà, sọ fún ìránṣẹ́ mi Dafidi pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi mú ọ kúrò ní pápá oko tútù wá, àní kúrò lẹ́yìn agbo àgùntàn, kí ìwọ kí ó lè máa ṣe olórí àwọn ènìyàn mi Israẹli. Èmi ti wà pẹ̀lú rẹ ní, ibikíbi tí ìwọ bá lọ, èmí sì ti gé gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ kúrò níwájú rẹ. Nísinsin yìí Èmi yóò mú kí orúkọ rẹ kí ó dàbí orúkọ àwọn ènìyàn ńlá jùlọ tí ó wà ní ayé. Èmi yóò sì pèsè ààyè kan fún àwọn ènìyàn mi Israẹli, kí wọn kí ó lè ní ilé tiwọn, kí a má sì ṣe dààmú wọn mọ́. Àwọn ènìyàn búburú kì yóò ni wọ́n lára mọ́, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀. 10 Bí wọ́n sì ti ṣe láti ìgbà tí mo ti yan àwọn aṣáájú lórí àwọn ènìyàn mi Israẹli. Èmi pẹ̀lú yóò ṣẹ́gun gbogbo àwọn ọ̀tá yín.

“ ‘Èmi sọ fún yín pé Olúwa yóò kọ́ ilé kan fún yín: 11 Nígbà ti ọjọ́ rẹ bá kọjá, tí ìwọ bá lọ láti lọ bá àwọn baba à rẹ, Èmi yóò gbé àwọn ọmọ rẹ sókè láti rọ́pò rẹ, ọ̀kan lára àwọn ọmọ tìrẹ, Èmi yóò sì fìdí ìjọba rẹ̀ kalẹ̀. 12 Òun ni ẹni tí yóò kọ́ ilé fún mi, èmi yóò sí fi ìdí ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ títí láé. 13 Èmi yóò jẹ́ baba rẹ̀, Òun yóò sì jẹ́ ọmọ mi. Èmi kì yóò mú ìfẹ́ mi kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ láéláé gẹ́gẹ́ bí mo ṣe mú un kúrò lọ́dọ̀ àwọn aṣáájú rẹ̀. 14 Èmi yóò gbé e ka orí ilé mi àti ìjọba mi títí láé; ìtẹ́ rẹ̀ ni a ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.’ ”

15 Natani ròyìn fún Dafidi gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ ti ìfihàn yí.

Àdúrà Dafidi

16 Nígbà náà, ọba Dafidi wọlé lọ, ó sì jókòó níwájú Olúwa ó sì wí pé:

“Ta ni èmi, Olúwa Ọlọ́run, àti ki ni ìdílé mi, tí ìwọ mú mi dé ibí? 17 Pẹ̀lú bí ẹni pé èyí kò tó lójú rẹ, Ọlọ́run. Ìwọ ti sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ iwájú ilé ìránṣẹ́ rẹ. Ìwọ ti wò mí bí ẹni pé èmi ni ẹni gbígbéga jù láàrín àwọn ọkùnrin Olúwa Ọlọ́run.

18 “Kí ni ohun tí Dafidi tún lè sọ nítorí ọlá tí o bù fún ìránṣẹ́ rẹ? Nítorí tí ìwọ mọ ìránṣẹ́ rẹ, 19 Olúwa. Nítorí ti ìránṣẹ́ rẹ àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ rẹ, ìwọ ti ṣe ohun ńlá yìí àti láti fi gbogbo ìlérí ńlá yìí hàn.

20 “Kò sí ẹnìkan bí rẹ, kò sì sí Ọlọ́run kan àfi ìwọ, gẹ́gẹ́ bí à ti gbọ́ pẹ̀lú etí ara wa. 21 Pẹ̀lú ta ni ó dàbí àwọn ènìyàn rẹ Israẹli—orílẹ̀-èdè kan ní ayé, tí Ọlọ́run jáde lọ láti ra àwọn ènìyàn kan padà fún ara rẹ̀, àti láti lè ṣe orúkọ fún ara à rẹ, àti láti ṣe ohun ńlá àti ọwọ́ ìyanu nípa lílé àwọn orílẹ̀-èdè kúrò níwájú àwọn ènìyàn rẹ̀, ẹni tí ó gbàlà láti Ejibiti? 22 Ìwọ ṣe àwọn ènìyàn rẹ Israẹli ní tìrẹ láéláé ìwọ Olúwa sì ti di Ọlọ́run wọn.

23 “Nísinsin yìí, Olúwa, Jẹ́ kí ìlérí tí ìwọ ti ṣe fún ìránṣẹ́ rẹ àti ilé rẹ̀ di fífi ìdí múlẹ̀ títí láé. Ṣe gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe ìlérí. 24 Kí ó lè di fífi ìdí múlẹ̀ àti kí orúkọ rẹ di gbígbéga títí láé. Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin yóò wí pé, ‘Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ni Ọlọ́run Israẹli.’ Ilé ìránṣẹ́ rẹ Dafidi sì ni a ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ níwájú rẹ.

25 “Ìwọ, Ọlọ́run mi, ti fihan ìránṣẹ́ rẹ pé, ìwọ yóò kọ́ ilé fún un. Bẹ́ẹ̀ ni ìránṣẹ́ rẹ ti ní ìgboyà láti gbàdúrà sí ọ. 26 Olúwa, ìwọ ni Ọlọ́run. Ìwọ ti fi ìlérí dídára yìí fún ìránṣẹ́ rẹ. 27 Nísinsin yìí ó ti tẹ́ ọ lọ́rùn láti bùkún ilé ìránṣẹ́ rẹ kí ó lè tẹ̀síwájú ní ojú rẹ; nítorí ìwọ, Olúwa, ti bùkún un, a ó sì bùkún un títí láéláé.”

Jakọbu 4

Ìyọ̀ǹda ara ẹni fún Ọlọ́run

Níbo ni ogun ti wá, níbo ni ìjà sì ti wá láàrín yín? Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara yín ha kọ́ ni tí ó ń jagun nínú àwọn ẹ̀yà ara yín bí? Ẹ̀yin ń fẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ẹ kò sì ní: ẹ̀yin ń pànìyàn, ẹ sì ń ṣe ìlara, ẹ kò sì le ní: ẹ̀yin ń jà, ẹ̀yin sì ń jagun; ẹ kò ní, nítorí tí ẹ̀yin kò béèrè. Ẹ̀yin béèrè, ẹ kò sì rí gbà, nítorí tí ẹ̀yin ṣì béèrè, kí ẹ̀yin kí ó lè lò ó fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara yín.

Ẹ̀yin panṣágà ọkùnrin, àti panṣágà obìnrin, ẹ kò mọ̀ pé ìbárẹ́ ayé ìṣọ̀tá Ọlọ́run ni? Nítorí náà ẹni tí ó bá fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé di ọ̀tá Ọlọ́run. Ẹ̀yin ṣe bí Ìwé mímọ́ sọ lásán pé, Ẹ̀mí tí ó fi sínú wa ń jowú gidigidi lórí wa? (A)Ṣùgbọ́n ó fún ni ní oore-ọ̀fẹ́ sí i. Nítorí náà ni ìwé mímọ́ ṣe wí pé,

“Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn agbéraga,
    ṣùgbọ́n ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀ ọkàn.”

Nítorí náà, ẹ tẹríba fún Ọlọ́run. Ẹ kọ ojú ìjà sí èṣù, òun ó sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín. Ẹ súnmọ́ Ọlọ́run, òun ó sì súnmọ́ yín. Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀; ẹ sì ṣe ọkàn yín ní mímọ́, ẹ̀yin oníyèméjì. Ẹ banújẹ́, ẹ ṣọ̀fọ̀, kí ẹ sì hu fún ẹkún. Ẹ jẹ́ kí ẹ̀rín yín kí ó di ọ̀fọ̀, àti ayọ̀ yín kí ó di ìbànújẹ́. 10 Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú Olúwa, òun ó sì gbé yín ga.

11 Ará, ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ ibi sí ara yín. Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ibi sí arákùnrin rẹ̀, tí ó ń dá arákùnrin rẹ̀ lẹ́jọ́, ó ń sọ̀rọ̀ ibi sí òfin, ó sì ń dá òfin lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń dá òfin lẹ́jọ́, ìwọ kì í ṣe olùfẹ́ òfin, bí kò ṣe onídàájọ́. 12 Aṣòfin àti onídàájọ́ kan ṣoṣo ní ó ń bẹ, àní ẹni tí ó lè gbàlà tí ó sì le parun, ṣùgbọ́n ta ni ìwọ tí ó ń dá ẹnìkejì rẹ lẹ́jọ́?

Má ṣe ìlérí nípa ọjọ́ ọ̀la

13 Ẹ wá nísinsin yìí, ẹ̀yin tí ó ń wí pé, “Lónìí tàbí lọ́la àwa ó lọ sí ìlú báyìí, a ó sì ṣe ọdún kan níbẹ̀, a ó sì ṣòwò, a ó sì jèrè.” 14 Nígbà tí ẹ̀yin kò mọ ohun tí yóò hù lọ́la. Kí ni ẹ̀mí yín? Ìkùùkuu sá à ni yín, tí ó hàn nígbà díẹ̀, lẹ́yìn náà a sì túká lọ. 15 Èyí tí ẹ̀ bá fi wí pé, “Bí Olúwa bá fẹ́, àwa yóò wà láààyè, àwa ó sì ṣe èyí tàbí èyí i nì.” 16 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin ń gbéraga nínú ìfọ́nnu yín, gbogbo irú ìfọ́nnu bẹ́ẹ̀, ibi ni. 17 Nítorí náà ẹni tí ó bá mọ rere í ṣe tí kò sì ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni fún un.

Jona 1

Jona sá ní iwájú Olúwa

Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jona ọmọ Amittai wá, wí pé: “Dìde lọ sí ìlú ńlá Ninefe kí o sì wàásù sí i, nítorí ìwà búburú rẹ̀ gòkè wá iwájú mi.”

Ṣùgbọ́n Jona dìde kúrò láti sálọ sí Tarṣiṣi kúrò níwájú Olúwa, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Joppa, ìbí ti ó tí rí ọkọ̀ kan tí ń lọ sí Tarṣiṣi: lẹ́yìn ti ó sanwó ọkọ̀, ó wọlé sínú rẹ̀, láti bá wọn lọ sí Tarṣiṣi kúrò níwájú Olúwa.

Nígbà náà ni Olúwa rán ìjì ńlá jáde sí ojú Òkun, ìjì líle sì wà nínú Òkun tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ náà dàbí ẹni pé yóò fọ́. Nígbà náà ni àwọn atukọ̀ bẹ̀rù, olúkúlùkù sì ń kígbe sí ọlọ́run rẹ̀, wọ́n kó ẹrù tí ó wà nínú ọkọ̀ dà sínú Òkun, kí ó bá à lè fúyẹ́.

Ṣùgbọ́n Jona sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ ọkọ̀ ó sì dùbúlẹ̀, ó sùn wọra. Bẹ́ẹ̀ ni olórí ọkọ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi sùn, ìwọ olóòórùn? Dìde kí o ké pe Ọlọ́run rẹ! Bóyá yóò ro tiwa, kí àwa má ba à ṣègbé.”

Nígbà náà ni àwọn atukọ̀ sọ fún ara wọn pé, “Wá, ẹ jẹ́ kí a sẹ́ kèké, kí àwa kí o le mọ̀ nítorí ta ni búburú yìí ṣe wá sórí wa.” Wọ́n ṣẹ́ kèké, kèké sì mú Jona. Nígbà náà ni wọn wí fún un pé, “Sọ fún wa, àwa bẹ̀ ọ́, nítorí ta ni búburú yìí ṣe wá sórí wa? Kí ni iṣẹ́ rẹ? Níbo ni ìwọ ti wá? Kí ni orúkọ ìlú rẹ? Ẹ̀yà orílẹ̀-èdè wo sì ni ìwọ sì í ṣe?”

Òun sì dá wọn lóhùn pé, “Heberu ni èmi, mo sì bẹ̀rù Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run ẹni tí ó dá Òkun àti ìyàngbẹ ilẹ̀.”

10 Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin náà bẹ̀rù gidigidi, wọn sì wí fún un pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ṣe èyí?” (Nítorí àwọn ọkùnrin náà mọ̀ pé ó ń sá kúrò ní iwájú Olúwa ni, nítorí òun ti sọ fun wọn bẹ́ẹ̀.)

11 Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Kí ni kí àwa ó ṣe sí ọ kí Òkun lè dákẹ́ fún wa?” Nítorí Òkun ru, ó sì ja ẹ̀fúùfù líle.

12 Òun sì wí fún wọn pé, “Ẹ gbé mi, kí ẹ sì sọ mi sínú Òkun, bẹ́ẹ̀ ni okun yóò sì dákẹ́ fún un yin. Nítorí èmi mọ̀ pé, nítorí mi ni ẹ̀fúùfù líle yìí ṣe dé bá a yín.”

13 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà gbìyànjú gidigidi láti mú ọkọ̀ wà sí ilẹ̀: ṣùgbọ́n wọn kò lè ṣe é: nítorí tí Òkun túbọ̀ ru sí i, ó sì ja ẹ̀fúùfù líle sí wọn. 14 Nítorí náà wọ́n kígbe sí Olúwa, wọ́n sì wí pé, “Olúwa àwa bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí àwa ṣègbé nítorí ẹ̀mí ọkùnrin yìí. Má sì ka ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sí wa ní ọrùn, nítorí ìwọ, Olúwa, ti ṣe bí ó ti wù ọ́.” 15 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé Jona, tí wọ́n sì sọ ọ́ sínú Òkun, Òkun sì dẹ́kun ríru rẹ̀. 16 Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin náà bẹ̀rù Olúwa gidigidi, wọn si rú ẹbọ sí Olúwa, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀jẹ́.

17 Ṣùgbọ́n Olúwa ti pèsè ẹja ńlá kan láti gbé Jona mì. Jona sì wà nínú ẹja náà ni ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta.

Luku 6

Olúwa ọjọ́ ìsinmi

(A)(B) Ní ọjọ́ ìsinmi kejì, Jesu ń kọjá láàrín oko ọkà; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì ń ya ìpẹ́ ọkà, wọ́n sì ń jẹ ẹ́. (C)Àwọn kan nínú àwọn Farisi sì wí fún wọn pé, “ki lo de tí ẹ̀yin fi ń ṣe èyí tí kò yẹ láti ṣe ní ọjọ́ ìsinmi?”

(D)Jesu sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin kò kà nípa ohun tí Dafidi ṣe, nígbà tí ebi ń pa òun tìkára rẹ̀ àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀; (E)bi ó ti wọ ilé Ọlọ́run lọ, tí ó sì mú àkàrà ìfihàn tí ó sì jẹ ẹ́, tí ó sì fi fún àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú; tí kò yẹ fún un láti jẹ, bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà nìkan ṣoṣo?” Ó sì wí fún wọn pé, “Ọmọ ènìyàn ni Olúwa ọjọ́ ìsinmi.”

(F)Ní ọjọ́ ìsinmi mìíràn, ó wọ inú Sinagọgu lọ, ó sì ń kọ́ni, ọkùnrin kan sì ń bẹ níbẹ̀ tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ rọ. Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi ń ṣọ́ ọ, bóyá yóò mú un láradá ní ọjọ́ ìsinmi; kí wọn lè rí ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kàn án. Ṣùgbọ́n ó mọ èrò inú wọn, ó sì wí fún ọkùnrin náà tí ọwọ́ rẹ̀ rọ pé, “Dìde, kí o sì dúró láàrín.” Ó sì dìde dúró.

Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Èmi bi yín léèrè, Ó ha tọ́ láti máa ṣe rere ni ọjọ́ ìsinmi, tàbí láti máa ṣe búburú? Láti gba ọkàn là, tàbí láti pa á run?”

10 Nígbà tí ó sì wo gbogbo wọn yíká, ó wí fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀: ọwọ́ rẹ̀ sì padà bọ̀ sípò gẹ́gẹ́ bí èkejì. 11 Wọ́n sì kún fún ìbínú gbígbóná; wọ́n sì bá ara wọn rò ohun tí àwọn ìbá ṣe sí Jesu.

Àwọn aposteli méjìlá

12 (G)(H) Ni ọ̀kan nínú àwọn ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Jesu lọ sí orí òkè láti gbàdúrà, ó sì fi gbogbo òru náà gbàdúrà sí Ọlọ́run. 13 Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀; nínú wọn ni ó sì yan méjìlá, tí ó sì sọ ní aposteli:

14 Simoni (ẹni tí a pè ní Peteru) àti Anderu arákùnrin rẹ̀,

Jakọbu,

Johanu,

Filipi,

Bartolomeu,

15 Matiu,

Tomasi,

Jakọbu ọmọ Alfeu,

Simoni tí a ń pè ní Sealoti,

16 Judea arákùnrin Jakọbu,

àti Judasi Iskariotu tí ó di ọ̀dàlẹ̀.

Ìbùkún àti ègún

17 (I)Ó sì bá wọn sọ̀kalẹ̀, ó sì dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àti ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn, láti gbogbo Judea, àti Jerusalẹmu, àti agbègbè Tire àti Sidoni, tí wọ́n wá láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti láti gba ìmúláradá kúrò nínú ààrùn wọn; 18 Àti àwọn tí ara wọn kún fún ẹ̀mí àìmọ́; ni ó sì mú láradá. 19 (J)Gbogbo ìjọ ènìyàn sì ń fẹ́ láti fọwọ́ kàn án, nítorí tí àṣẹ ń jáde lára rẹ̀, ó sì mú gbogbo wọn láradá.

20 (K)Nígbà tí ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní:

“Alábùkún fún ni ẹ̀yin òtòṣì,
    nítorí tiyín ni ìjọba Ọlọ́run.
21 Alábùkún fún ni ẹ̀yin tí ebi ń pa
    nísinsin yìí; nítorí tí ẹ ó yóò.
Alábùkún fún ni ẹ̀yin tí ń
    sọkún nísinsin yìí: nítorí tí ẹ̀yin ó rẹ́rìn-ín.
22 (L)Alábùkún fún ni ẹ̀yin, nígbà tí àwọn ènìyàn bá kórìíra yín,
    tí wọ́n bá yà yín kúrò nínú ẹgbẹ́ wọn, tí wọ́n bá gàn yín,
    tí wọ́n bá ta orúkọ yín nù bí ohun búburú,
        nítorí ọmọ ènìyàn.

23 “Ẹ jẹ́ kí inú yín dùn, kí ẹ sì fò fún ayọ̀, nítorí púpọ̀ ní èrè yín ni ọ̀run. Báyìí ni àwọn baba yín ṣe ṣe sí àwọn wòlíì.

24 (M)(N) “Ègbé ni fún ẹ̀yin ọlọ́rọ̀
    nítorí ẹ ti gba ìtùnú yín.
25 Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ó yó,
    nítorí ebi yóò pa yín,
Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ń rẹ́rìn-ín nísinsin yìí,
    nítorí tí ẹ̀yin ó ṣọ̀fọ̀, ẹ̀yin ó sì sọkún.
26 Ègbé ni fún yín, nígbà tí gbogbo ènìyàn bá ń sọ̀rọ̀ yín ní rere,
    nítorí bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn baba wọn ṣe sí àwọn wòlíì èké.

Ìfẹ́ fún àwọn ọ̀tá

27 (O)“Ṣùgbọ́n mo wí fún ẹ̀yin tí ń gbọ́ mi: Ẹ fẹ́ àwọn ọ̀tá yín, ṣoore fún àwọn tí ó kórìíra yín; 28 Súre fún àwọn tí ń fi yín ré, sì gbàdúrà fún àwọn tí ń kẹ́gàn yín. 29 Ẹni tí ó bá sì lù ọ́ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ kan, yí kejì sí i pẹ̀lú; àti ẹni tí ó gba agbádá rẹ, má ṣe dá a dúró láti gba ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ pẹ̀lú. 30 Sì fi fún gbogbo ẹni tí ó tọrọ lọ́dọ̀ rẹ; lọ́dọ̀ ẹni tí ó sì kó ọ ní ẹrù, má sì ṣe padà béèrè. 31 (P)Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin sì ti fẹ́ kí ènìyàn ṣe sí yín, kí ẹ̀yin sì ṣe bẹ́ẹ̀ sí wọn pẹ̀lú.

32 (Q)“Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin bá fẹ́ àwọn tí ó fẹ́ yín, ọpẹ́ kí ni ẹ̀yin ní? Àwọn ‘ẹlẹ́ṣẹ̀’ pẹ̀lú ń fẹ́ àwọn tí ó fẹ́ wọn. 33 Bí ẹ̀yin sì ṣoore fún àwọn tí ó ṣoore fún yín, ọpẹ́ kín ni ẹ̀yin ní? Àwọn ‘ẹlẹ́ṣẹ̀’ pẹ̀lú ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. 34 Bí ẹ̀yin bá fi fún ẹni tí ẹ̀yin ń retí láti rí gbà padà, ọpẹ́ kín ni ẹ̀yin ní? Àwọn ‘ẹlẹ́ṣẹ̀’ pẹ̀lú ń yá ‘ẹlẹ́ṣẹ̀,’ kí wọn lè gba ìwọ̀n bẹ́ẹ̀ padà. 35 (R)Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin fẹ́ àwọn ọ̀tá yín kí ẹ sì ṣoore, kí ẹ̀yin sì yá ẹlòmíràn, kí ẹ̀yin má ṣe retí láti rí nǹkan gbà padà; èrè yín yóò sì pọ̀, àwọn ọmọ Ọ̀gá-ògo ni a ó sì máa pè yín: nítorí tí ó ṣe rere fún aláìmoore àti fún ẹni búburú. 36 Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin ní àánú, gẹ́gẹ́ bí Baba yín sì ti ní àánú.

Dídá ni lẹ́jọ́

37 (S)“Ẹ má ṣe dá ni lẹ́jọ́, a kì yóò sì dá yín lẹ́jọ́: ẹ má ṣe dá ni lẹ́bi, a kì yóò sì dá yín lẹ́bi: ẹ dáríjì, a ó sì dáríjì yín. 38 (T)Ẹ fi fún ni, a ó sì fi fún yín; òṣùwọ̀n dáradára, àkìmọ́lẹ̀, àti àmìpọ̀, àkúnwọ́sílẹ̀, ni a ó wọ́n si àyà yín: nítorí òṣùwọ̀n náà tí ẹ̀yin fi wọ́n, òun ni a ó padà fi wọ́n fún yín.”

39 (U)Ó sì pa òwe kan fún wọn wí pé, “Afọ́jú ha lè ṣe amọ̀nà afọ́jú bí? Àwọn méjèèjì kọ́ ni yóò ṣubú sínú ihò bí? 40 (V)Ẹni tí a ń kọ́ kì í ju olùkọ́ rẹ̀ lọ: ṣùgbọ́n olúkúlùkù ẹni tí a bá kọ dáradára, yóò dàbí olùkọ́ rẹ̀.

41 (W)“Èétiṣe tí ìwọ fi ń wo ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi ìtì igi tí ń bẹ ní ojú ara rẹ? 42 Tàbí ìwọ ó ti ṣe lè wí fún arákùnrin rẹ pé, ‘Arákùnrin, jẹ́ kí èmi yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ lójú rẹ,’ nígbà tí ìwọ tìkára rẹ kò kíyèsi ìtì igi tí ń bẹ lójú rẹ? Ìwọ àgàbàgebè, kọ́kọ́ yọ ìtí igi jáde kúrò lójú ara rẹ ná, nígbà náà ni ìwọ ó sì tó ríran gbangba láti yọ èérún igi tí ń bẹ lójú arákùnrin rẹ kúrò.

Igi àti èso rẹ̀

43 (X)“Nítorí igi rere kì í so èso búburú; bẹ́ẹ̀ ni igi búburú kì í so èso rere. 44 Olúkúlùkù igi ni a ń fi èso rẹ̀ mọ̀ ọn; nítorí lórí ẹ̀gún òṣùṣú, ènìyàn kì í ká èso ọ̀pọ̀tọ́ bẹ́ẹ̀ ni lórí ẹ̀gún ọ̀gàn a kì í ká èso àjàrà. 45 (Y)Ènìyàn rere láti inú yàrá ìṣúra rere ọkàn rẹ̀ ní mú ohun rere jáde wá; àti ènìyàn búburú láti inú ìṣúra búburú ọkàn rẹ̀ ní í mú ohun búburú jáde wá: nítorí láti inú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọkàn ní ẹnu ti máa sọ jáde.

Ọlọ́gbọ́n àti òmùgọ̀ ọ̀mọ̀lé

46 (Z)“Nítorí náà, èéṣe tí ẹ̀yin ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ tí ẹ̀yin kò sì ṣe ohun tí mo wí? 47 (AA)Ẹnikẹ́ni tí ó tọ̀ mí wá, tí ó sì ń gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó sì ń ṣe é, èmi yóò fi ẹni tí ó jọ hàn yín; 48 Ó jọ Ọkùnrin kan, tí ó kọ́ ilé, tí ó sì wa ilẹ̀ jìn, tí ó sì fi ìpìlẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta, nígbà tí kíkún omi sì dé, ìgbì omi kọlu ilé náà, kò sì lè mì ín nítorí tí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta. 49 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́, tí kò sì ṣe é, ó dàbí ọkùnrin tí ó kọ́ ilé sí orí ilẹ̀ láìní ìpìlẹ̀; nígbà tí ìgbì omi kọlù ú, lọ́gán, ó sì wó; wíwó ilé náà sì pọ̀ púpọ̀.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.