M’Cheyne Bible Reading Plan
Ìran Adamu títí de Abrahamu
Títí dé ọmọkùnrin Noa
4 Àwọn ọmọ Noa: Ṣemu, Hamu àti Jafeti.
Àwọn Ọmọ Jafeti
5 Àwọn ọmọ Jafeti ni:
Gomeri, Magogu, Madai; Jafani, Tubali, Meṣeki àti Tirasi.
6 Àwọn ọmọ Gomeri ni:
Aṣkenasi, Rifàti àti Togarma.
7 Àwọn ọmọ Jafani ni:
Eliṣa, Tarṣiṣi, Kittimu, àti Dodanimu.
Àwọn ọmọ Hamu
8 Àwọn ọmọ Hamu ni:
Kuṣi, Misraimu, Puti, àti Kenaani.
9 Àwọn ọmọ Kuṣi ni:
Seba, Hafila, Sabta, Raama, àti Ṣabteka.
Àwọn ọmọ Raama:
Ṣeba àti Dedani.
10 Kuṣi sì bí Nimrodu:
Ẹni tí ó di alágbára jagunjagun ní ayé.
11 Misraimu sì bí
Ludimu, Anamimu, Lehabimu, Naftuhimu, 12 Patrusimu, Kasluhimu, (láti ọ̀dọ̀ ẹni tí àwọn ará Filistini ti wá) àti àwọn ará Kaftorimu.
13 Kenaani sì bí Sidoni àkọ́bí rẹ̀,
àti Heti, 14 Àti àwọn ará Jebusi, àti àwọn ará Amori, àti àwọn ará Girgaṣi, 15 àti àwọn ará Hifi, àti àwọn ará Arki, àti àwọn ará Sini, 16 àti àwọn ará Arfadi, àti àwọn ará Ṣemari, àti àwọn ará Hamati.
Àwọn ará Ṣemu.
17 Àwọn ọmọ Ṣemu ni:
Elamu, Aṣuri, Arfakṣadi, Ludi àti Aramu.
Àwọn ọmọ Aramu:
Usi, Huli, Geteri, àti Meṣeki.
18 Arfakṣadi sì bí Ṣela,
Ṣela sì bí Eberi.
19 Eberi sì bí ọmọ méjì:
ọ̀kan ń jẹ́ Pelegi, nítorí ní ìgbà ọjọ́ rẹ̀ ni ilẹ̀ ya; orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Joktani.
20 Joktani sì bí
Almodadi, Ṣelefi, Hasarmafeti, Jera. 21 Hadoramu, Usali, Dikla, 22 Ebali, Abimaeli, Ṣeba. 23 Ofiri, Hafila, àti Jobabu. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Joktani.
24 Ṣemu, Arfakṣadi, Ṣela,
25 Eberi, Pelegi. Reu,
26 Serugu, Nahori, Tẹra:
27 Àti Abramu (tí ń ṣe Abrahamu).
Ìdílé Abrahamu
28 Àwọn ọmọ Abrahamu: Isaaki àti Iṣmaeli.
Àwọn ọmọ Hagari
29 Èyí ni àwọn ọmọ náà:
Nebaioti àkọ́bí Iṣmaeli: Kedari, Adbeeli, Mibsamu, 30 Miṣima, Duma, Massa, Hadadi, Tema, 31 Jeturi, Nafiṣi, àti Kedema.
Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Iṣmaeli.
Àwọn ọmọ Ketura
32 Àwọn ọmọ Ketura, obìnrin Abrahamu:
Simrani, Jokṣani Medani, Midiani Iṣbaki àti Ṣua.
Àwọn ọmọ Jokṣani:
Ṣeba àti Dedani.
33 Àwọn ọmọ Midiani:
Efani, Eferi, Hanoku, Abida àti Eldaa.
Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ìran Ketura.
Àwọn Ìran Sara
34 Abrahamu sì jẹ́ baba Isaaki:
Àwọn ọmọ Isaaki:
Esau àti Israẹli.
Àwọn ọmọ Esau
35 Àwọn ọmọ Esau:
Elifasi, Reueli, Jeuṣi, Jalamu, àti Kora.
36 Àwọn ọmọ Elifasi:
Temani, Omari, Sefi, Gatamu àti Kenasi;
láti Timna: Amaleki.
37 Àwọn ọmọ Reueli:
Nahati, Sera, Ṣamma àti Missa.
Àwọn ènìyàn Seiri ní Edomu
38 Àwọn ọmọ Seiri:
Lotani, Ṣobali, Sibeoni, Ana, Diṣoni, Eseri àti Diṣani.
39 Àwọn ọmọ Lotani:
Hori àti Homamu: Timna sì ni arábìnrin Lotani.
40 Àwọn ọmọ Ṣobali:
Afiani, Manahati, Ebali, Ṣefo àti Onamu.
Àwọn ọmọ Sibeoni:
Aiah àti Ana.
41 Àwọn ọmọ Ana:
Diṣoni.
Àwọn ọmọ Diṣoni:
Hemdani, Eṣbani, Itrani, àti Kerani.
42 Àwọn ọmọ Eseri:
Bilhani, Saafani àti Akani.
Àwọn ọmọ Diṣani:
Usi àti Arani.
Àwọn alákòóso Edomu
43 Àwọn wọ̀nyí ni ọba tí ó jẹ ní Edomu, kí ó tó di pé ọba kankan jẹ lórí Israẹli:
Bela ọmọ Beori, orúkọ ìlú rẹ̀ ni Dinhaba.
44 Nígbà tí Bela kú, Jobabu ọmọ Sera ti Bosra sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
45 Nígbà tí Jobabu kú, Huṣamu láti ilẹ̀ Temani sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
46 Nígbà tí Huṣamu kú, Hadadi ọmọ Bedadi tí ó kọlu Midiani ní ìgbẹ́ Moabu, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Afiti.
47 Nígbà tí Hadadi sì kú, Samla láti Masreka, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
48 Samla sì kú, Saulu ti Rehoboti létí odò sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀
49 Nígbà tí Saulu kú, Baali-Hanani, ọmọ Akbori jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
50 Nígbà tí Baali-Hanani kú, Hadadi ni ó jẹ ọba ní ipò rẹ̀. Orúkọ ìlú rẹ̀ ni Pau; orúkọ ìyàwó sì ni Mehetabeeli ọmọbìnrin Matiredi, ọmọbìnrin Mesahabu. 51 Hadadi sì kú pẹ̀lú.
Àwọn baálẹ̀ Edomu ni:
baálẹ̀ Timna, baálẹ̀ Alfa, baálẹ̀ Jeteti 52 baálẹ̀ Oholibama, baálẹ̀ Ela, baálẹ̀ Pinoni. 53 baálẹ̀ Kenasi, baálẹ̀ Temani, baálẹ̀ Mibsari, 54 Magdieli àti Iramu.
Àwọn wọ̀nyí ni baálẹ̀ Edomu.
Àwọn ọmọ Israẹli
2 (B)Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Israẹli. Reubeni, Simeoni, Lefi, Juda, Isakari, Sebuluni, 2 Dani, Josẹfu, Benjamini; Naftali, Gadi: àti Aṣeri.
Juda
Àwọn ọmọ Hesroni
3 (C)Àwọn ọmọ Juda:
Eri, Onani àti Ṣela, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí ni wọ́n bí fún un láti ọ̀dọ̀ arábìnrin Kenaani, ọmọbìnrin Ṣua.
Eri àkọ́bí Juda, ó sì burú ní ojú Olúwa; Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì pa á.
4 Tamari, aya ọmọbìnrin Juda, ó sì bí Peresi àti Sera sì ní ọmọ márùn-ún ní àpapọ̀.
5 (D)Àwọn ọmọ Peresi:
Hesroni àti Hamulu.
6 Àwọn ọmọ Sera:
Simri, Etani, Hemani, Kalkoli àti Dara, gbogbo wọn jẹ́ márùn-ún.
7 Àwọn ọmọ Karmi:
Akani, ẹni tí ó mú ìyọnu wá sórí Israẹli nípa ẹ̀ṣẹ̀ ìfibú lórí mímú ohun ìyàsọ́tọ̀.
8 Àwọn ọmọ Etani:
Asariah.
9 Àwọn ọmọ tí a bí fún Hesroni ni:
Jerahmeeli, Ramu àti Kalebu.
Láti ọ̀dọ̀ Ramu ọmọ Hesroni
10 Ramu sì ni baba Amminadabu,
àti Amminadabu baba Nahiṣoni olórí àwọn ènìyàn Juda.
11 Nahiṣoni sì ni baba Salmoni,
Salmoni ni baba Boasi,
12 Boasi baba Obedi
àti Obedi baba Jese.
13 Jese sì ni baba
Eliabu àkọ́bí rẹ̀; ọmọ ẹlẹ́kejì sì ni Abinadabu,
ẹlẹ́kẹta ni Ṣimea, 14 Ẹlẹ́kẹrin Netaneli,
ẹlẹ́karùnún Raddai, 15 ẹlẹ́kẹfà Osemu
àti ẹlẹ́keje Dafidi.
16 Àwọn arábìnrin wọn ni Seruiah àti Abigaili.
Àwọn ọmọ mẹ́ta Seruiah ni Abiṣai, Joabu àti Asaheli.
17 Abigaili ni ìyá Amasa, ẹni tí baba rẹ̀ sì jẹ́ Jeteri ará Iṣmaeli.
Kalebu ọmọ Hesroni
18 Kalebu ọmọ Hesroni ní ọmọ láti ọ̀dọ̀ ìyàwó rẹ̀ Asuba (láti ọ̀dọ̀ Jerioti). Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ rẹ̀:
Jeṣeri, Ṣobabu àti Ardoni.
19 Nígbà tí Asuba sì kú, Kalebu sì fẹ́ Efrata ní aya, ẹni tí ó bí Huri fún un.
20 Huri ni baba Uri, Uri sì jẹ́ baba Besaleli.
21 Nígbà tí ó yá, Hesroni sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ọmọbìnrin Makiri baba Gileadi (ó sì ti fẹ́ ní aya láti ìgbà tí ó ti wà ní ẹni ọgọ́ta ọdún) ó sì bí Segubu.
22 Segubu sì jẹ́ baba Jairi, ẹni tí ó jẹ́ olùdarí ìlú mẹ́tàlélógún ní ilẹ̀ Gileadi.
23 (Ṣùgbọ́n Geṣuri àti Aramu sì fi agbára gba Hafoti-Jairi, àti Kenati pẹ̀lú gbogbo agbègbè rẹ̀ tí wọn tẹ̀dó sí jẹ́ ọgọ́ta ìlú.)
Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Makiri Baba Gileadi.
24 Lẹ́yìn tí Hesroni sì kú ni Kalebu Efrata, Abijah ìyàwó rẹ̀ ti Hesroni sì bí Aṣihuri baba Tekoa fún un.
Jerahmeeli ọmọ Hesroni
25 Ọmọ Jerahmeeli àkọ́bí Hesroni:
Ramu ọmọ àkọ́bí rẹ̀ Buna, Oreni, Osemu àti Ahijah. 26 Jerahmeeli ní ìyàwó mìíràn, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Atara; ó sì jẹ́ ìyá fún Onamu.
27 Àwọn ọmọ Ramu àkọ́bí Jerahmeeli:
Maasi, Jamini àti Ekeri.
28 Àwọn ọmọ Onamu:
Ṣammai àti Jada.
Àwọn ọmọ Ṣammai:
Nadabu àti Abiṣuri. 29 Orúkọ ìyàwó Abiṣuri ni Abihaili ẹni tí ó bí Ahbani àti Molidi.
30 Àwọn ọmọ Nadabu
Ṣeledi àti Appaimu. Ṣeledi sì kú láìsí ọmọ.
31 Àwọn ọmọ Appaimu:
Iṣi, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Ṣeṣani. Ṣeṣani sì jẹ́ baba fún Ahlai.
32 Àwọn ọmọ Jada, arákùnrin Ṣammai:
Jeteri àti Jonatani. Jeteri sì kú láìní ọmọ.
33 Àwọn ọmọ Jonatani:
Peleti àti Sasa.
Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Jerahmeeli.
34 Ṣeṣani kò sì ní ọmọkùnrin àwọn ọmọbìnrin nìkan ni ó ní.
Ó sì ní ìránṣẹ́ ará Ejibiti tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jariha. 35 Ṣeṣani sì fi ọmọ obìnrin rẹ̀ ní aya fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Jariha, ó sì bí ọmọ fún tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Attai.
36 Attai sì jẹ́ baba fún Natani,
Natani sì jẹ́ baba fún Sabadi,
37 Sabadi ni baba Eflali,
Eflali jẹ́ baba Obedi,
38 Obedi sì ni baba Jehu,
Jehu ni baba Asariah,
39 Asariah sì ni baba Helesi,
Helesi ni baba Eleasa,
40 Eleasa ni baba Sismai,
Sismai ni baba Ṣallumu,
41 Ṣallumu sì ni baba Jekamiah,
Jekamiah sì ni baba Eliṣama.
Ìdílé Kalebu
42 Àwọn ọmọ Kalebu arákùnrin Jerahmeeli:
Meṣa àkọ́bí rẹ̀, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Sifi,
àti àwọn ọmọ rẹ̀ Meraṣa, ẹni tí ó jẹ́ baba fún Hebroni.
43 Àwọn ọmọ Hebroni:
Kora, Tapua, Rekemu, àti Ṣema.
44 Ṣema ni baba Rahamu,
Rahamu sì jẹ́ baba fún Jorkeamu.
Rekemu sì ni baba Ṣammai.
45 Àwọn ọmọ Ṣammai ni Maoni,
Maoni sì ni baba Beti-Suri.
46 Efani obìnrin Kalebu sì ni ìyá
Harani, Mosa àti Gasesi,
Harani sì ni baba Gasesi.
47 Àwọn ọmọ Jahdai:
Regemu, Jotamu, Geṣani, Peleti, Efani àti Ṣaafa.
48 Maaka obìnrin Kalebu sì ni ìyá
Seberi àti Tirhana.
49 Ó sì bí Ṣaafa baba Madmana,
Ṣefa baba Makbena àti baba Gibeah.
ọmọbìnrin Kalebu sì ni Aksa.
50 Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Kalebu.
Àwọn ọmọ Huri, àkọ́bí Efrata:
Ṣobali baba Kiriati-Jearimu. 51 Salma baba Bẹtilẹhẹmu àti Harefu baba Beti-Gaderi.
52 Àwọn ọmọ Ṣobali baba Kiriati-Jearimu ni:
Haroe, ìdajì àwọn ará Manaheti. 53 Àti ìdílé Kiriati-Jearimu: àti àwọn ara Itri, àti àwọn ará Puti, àti àwọn ará Ṣumati àti àwọn ará Miṣraiti: láti ọ̀dọ̀ wọn ni àwọn ọmọ ará Sorati àti àwọn ará Eṣtaoli ti wá.
54 Àwọn ọmọ Salma:
Bẹtilẹhẹmu, àti àwọn ará Netofa, Atrotu Beti-Joabu, ìdajì àwọn ará Manahati, àti ará Sori, 55 Àti àwọn ìdílé àwọn akọ̀wé, ẹni tí ń gbé ní Jabesi: àti àwọn ọmọ Tirati àti àwọn ará Ṣimeati àti àwọn ará Sukati. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ará Keni, ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Hamati, baba ilé Rekabu.
Olórí àlùfáà ti májẹ̀mú tuntun
8 (A)Nísinsin yìí, kókó ohun tí à ń sọ nìyí: Àwa ní irú olórí àlùfáà bẹ́ẹ̀, tí ó jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọláńlá nínú àwọn ọ̀run: 2 ìránṣẹ́ ibi mímọ́, àti ti àgọ́ tòótọ́, tí Olúwa pa, kì í ṣe ènìyàn.
3 Nítorí a fi olórí àlùfáà kọ̀ọ̀kan jẹ láti máa mú ẹ̀bùn wá láti máa rú ẹbọ: Nítorí náà ó ṣe pàtàkì fún eléyìí náà láti ní nǹkan tí ó máa fi sílẹ̀. 4 Tí ó bá jẹ́ pé ó wà ní ayé ni, òun kì bá ti jẹ́ àlùfáà, nítorí pé àwọn ọkùnrin tí ó ń fi ẹ̀bùn sílẹ̀ ti wà bí òfin ṣe là á sílẹ̀. 5 (B)Àwọn ẹni tí ń jọ́sìn nínú pẹpẹ kan tí ó jẹ́ àpẹẹrẹ àti òjìji ohun tí ń bẹ ní ọ̀run. Ìdí abájọ nìyí tí a fi kìlọ̀ fún Mose nígbà tí ó fẹ́ kọ́ àgọ́: Nítorí ó wí pé, “Kíyèsí i, kí ìwọ kí ó ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ wọn, ti a fi hàn ọ́ ni orí òkè.” 6 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí o ti gba iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ó ni ọlá jù, níwọ̀n bí o ti jẹ pé alárinà májẹ̀mú tí o dára jù ní i ṣe, èyí tí a fi ṣe òfin lórí ìlérí tí o sàn jù bẹ́ẹ̀ lọ.
7 Nítorí ìbá ṣe pé májẹ̀mú ìṣáájú nì kò ní àbùkù, ǹjẹ́ a kì bá ti wá ààyè fún èkejì. 8 (C)Nítorí tí ó rí àbùkù lára wọn, ó wí pé,
“Ìgbà kan ń bọ̀, ni Olúwa wí,
tí Èmi yóò bá ilé Israẹli
àti ilé Juda dá májẹ̀mú tuntun.
9 Kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú
tí mo ti bá àwọn baba baba wọn dá,
nígbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ láti mú wọn jáde
kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, nítorí wọn kò jẹ́ olóòtítọ́ sí májẹ̀mú mi
èmi kò sì ta wọ́n nu, ni Olúwa wí
10 Nítorí èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Israẹli
dá lẹ́yìn àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, ni Olúwa wí.
Èmi ó fi òfin mi sí inú wọn,
èmi ó sì kọ wọ́n sí ọkàn wọn,
èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run fún wọn,
wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn fún mi.
11 Olúkúlùkù kò ní tún máa kọ́ ara ìlú rẹ̀,
tàbí olúkúlùkù arákùnrin rẹ̀, pé, ‘mọ Olúwa,’
Nítorí pé gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí,
láti kékeré dé àgbà.
12 Nítorí pé èmi ó ṣàánú fún àìṣòdodo wọn,
àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àìṣedéédéé wọn lèmi ki yóò sì rántí mọ́.”
13 Ní èyí tí ó wí pé, májẹ̀mú títún ó ti sọ ti ìṣáájú di ti láéláé. Ṣùgbọ́n èyí tí ó ń di i ti láéláé tí ó sì ń gbó, o múra àti di asán.
2 (A)Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Moabu,
àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà,
Nítorí ó ti sun ún, di eérú,
egungun ọba Edomu
2 Èmi yóò rán iná sí orí Moabu
èyí tí yóò jó àwọn ààfin Kerioti run.
Moabu yóò sì kú pẹ̀lú ariwo
pẹ̀lú igbe àti pẹ̀lú ìró ìpè
3 Èmi yóò ké onídàájọ́ rẹ̀ kúrò
Èmi yóò sì pa gbogbo àwọn ọmọ-aládé rẹ́ nínú rẹ̀,”
ni Olúwa wí.
4 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Juda,
àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà
Nítorí wọn ti kọ òfin Olúwa sílẹ̀
wọn kò sì pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́
Nítorí àwọn òrìṣà ti sì wọ́n lọ́nà
òrìṣà tí àwọn Baba ńlá wọn ń tẹ̀lé
5 Èmi yóò rán iná sí orí Juda
èyí tí yóò jó àwọn ààfin Jerusalẹmu run.”
Ìdájọ́ tí yóò wá sórí Israẹli
6 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta Israẹli
àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà.
Wọ́n ta olódodo fún fàdákà
àti aláìní fún bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì.
7 Wọ́n fi ẹsẹ̀ tẹ orí àwọn tálákà mọ́lẹ̀
bí wọ́n ti ń tẹ erùpẹ̀ ilẹ̀
tí wọ́n ko sì ṣe òtítọ́ si àwọn tí a ni lára
Baba àti ọmọ ń wọlé tọ wúńdíá kan náà
Láti ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́
8 Wọ́n dùbúlẹ̀ lẹ́bàá a pẹpẹ
Lórí aṣọ tí wọ́n ti jẹ́ ẹ̀jẹ́
ní ilé òrìṣà wọn
wọ́n sì mu ọtí tí wọ́n san fún ìtánràn.
9 “Mo pa àwọn ará Amori run níwájú wọn
gíga ẹni tí ó dàbí igi kedari.
Òun sì le koko bí igi óákù
mo pa èso rẹ̀ run láti òkè wá
àti egbò rẹ̀ láti ìsàlẹ̀ wá.
10 Èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá,
mo sì sìn yín la aginjù já ní ogójì ọdún
láti fi ilẹ̀ àwọn ará Amori fún un yín.
11 “Èmi sì tún gbé àwọn wòlíì dìde láàrín àwọn ọmọ yín
àti láàrín àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín láti jẹ Nasiri
èyí kò ha jẹ́ òtítọ́ bí ará Israẹli?”
ni Olúwa wí.
12 “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin fún àwọn Nasiri ní ọtí mu
e sì pàṣẹ fún àwọn wòlíì kí wọ́n má ṣe sọtẹ́lẹ̀.
13 “Ní báyìí, èmi yóò tẹ̀ yín mọ́lẹ̀
bí kẹ̀kẹ́ tí ó kún fún ìtí ti í tẹ̀.
14 Ẹni tí ó yára bí àṣá kò ní rí ọ̀nà àbáyọ
alágbára kò ní le è dúró lé agbára rẹ̀
jagunjagun kì yóò le gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là
15 Tafàtafà kì yóò dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀
bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó gún ẹṣin
kì yóò gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là
16 Àní jagunjagun tí ó gbóyà jùlọ
yóò sálọ ní ìhòhò ní ọjọ́ náà,”
ni Olúwa wí.
Saamu ìyìn. Ti Dafidi.
145 Èmi yóò gbé ọ ga, Ọlọ́run ọba mi;
Èmi yóò yin orúkọ rẹ̀ láé àti láéláé
2 Ní ojoojúmọ́ èmi yóò yìn ọ́
èmi yóò sì pòkìkí orúkọ rẹ láé àti láéláé.
3 Títóbi ni Olúwa. Òun sì ni ó yẹ láti fi ìyìn fún púpọ̀púpọ̀:
kò sí ẹni tí ó lè wọn títóbi rẹ̀.
4 Ìran kan yóò máa yin iṣẹ́ rẹ dé ìran mìíràn;
wọn yóò máa sọ iṣẹ́ agbára rẹ
5 Wọn yóò máa sọ ìyìn ọláńlá rẹ tí ó lógo,
èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú iṣẹ́ ìyanu rẹ.
6 Wọn yóò sọ iṣẹ́ agbára rẹ tí ó ní ẹ̀rù
èmi yóò kéde iṣẹ́ ńlá rẹ̀.
7 Wọn yóò ṣe ìrántí ọ̀pọ̀lọpọ̀
ìwà rere rẹ àti orin ayọ̀ òdodo rẹ.
8 Olóore-ọ̀fẹ́ ni Olúwa àti aláàánú
ó lọ́ra láti bínú ó sì ní ìfẹ́ púpọ̀.
9 Olúwa dára sí ẹni gbogbo;
ó ní àánú lórí ohun gbogbo tí ó dá.
10 Gbogbo ohun tí ìwọ ti dá ni
yóò máa yìn ọ́ Olúwa;
àwọn ẹni mímọ́ yóò máa pòkìkí rẹ.
11 Wọn yóò sọ ògo ìjọba rẹ
wọn yóò sì sọ̀rọ̀ agbára rẹ,
12 Kí gbogbo ènìyàn le mọ iṣẹ́ agbára rẹ̀
àti ọláńlá ìjọba rẹ tí ó lógo.
13 Ìjọba rẹ ìjọba ayérayé ni,
àti ìjọba rẹ wà ní gbogbo ìrandíran.
14 Olúwa mú gbogbo àwọn tí ó ṣubú ró
ó sì gbé gbogbo àwọn tí ó tẹríba dìde.
15 Ojú gbogbo ènìyàn ń wò ọ́,
ó sì fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó yẹ
16 Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ
ìwọ sì tẹ́ ìfẹ́ gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.
17 Olúwa jẹ́ olódodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀
àti ìfẹ́ rẹ̀ sí gbogbo ohun tí o dá.
18 Olúwa wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é,
sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́.
19 Ó mú ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ṣẹ;
ó gbọ́ igbe wọn, ó sì gbà wọ́n.
20 Olúwa dá gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́ sẹ sí
ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹni
búburú ní yóò parun.
21 Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ìyìn Olúwa.
Jẹ́ kí gbogbo ẹ̀dá yín orúkọ rẹ̀ mímọ́ láé àti láéláé.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.