M’Cheyne Bible Reading Plan
Ahasi ọba Juda
16 Ní ọdún kẹtà-dínlógún Peka ọmọ Remaliah, Ahasi ọmọ Jotamu ọba Juda bẹ̀rẹ̀ sí i jẹ ọba. 2 (A)Ẹni ogún ọdún ni Ahasi nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ọba, ó sì jẹ ọba ọdún mẹ́rìn-dínlógún ní Jerusalẹmu, kò sì ṣe èyí tí ó tọ́ lójú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Dafidi baba rẹ̀. 3 Ṣùgbọ́n ó rìn ní ọ̀nà àwọn ọba Israẹli, nítòótọ́, ó sì sun ọmọ rẹ̀ nínú iná, gẹ́gẹ́ bí ohun ìríra àwọn orílẹ̀-èdè, tí Olúwa lé jáde níwájú àwọn ọmọ Israẹli. 4 Ó sì rú ẹbọ, ó sì sun tùràrí ní àwọn ibi gíga, àti lórí àwọn òkè kéékèèkéé àti lábẹ́ gbogbo igi tútù.
5 Nígbà náà ni Resini ọba Siria àti Peka ọmọ Remaliah ọba Israẹli gòkè wá sí Jerusalẹmu láti jagun: wọ́n dó ti Ahasi, ṣùgbọ́n wọn kò lè borí rẹ̀. 6 Ní àkókò náà, Resini ọba Siria gba Elati padà fún Siria, ó sì lé àwọn ènìyàn Juda kúrò ní Elati: àwọn ará Siria sì wá sí Elati, wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ títí di òní yìí.
7 Ahasi sì rán oníṣẹ́ sọ́dọ̀ Tiglat-Pileseri ọba Asiria wí pé, “ìránṣẹ́ rẹ ni èmi, àti ọmọ rẹ; gòkè wá, kí o sì gbà mi lọ́wọ́ ọba Siria, àti lọ́wọ́ ọba Israẹli tí ó dìde sí mi.” 8 Ahasi sì mú fàdákà àti wúrà tí a rí ní ilé Olúwa, àti nínú ìṣúra ilé ọba, ó sì rán an sí ọba Asiria ní ọrẹ. 9 Ọba Asiria sì gbọ́ tirẹ̀: nítorí ọba Asiria gòkè wá sí Damasku, ó sì kó o, ó sì mú un ní ìgbèkùn lọ sí Kiri, ó sì pa Resini.
10 Ọba sì lọ sí Damasku láti pàdé Tiglat-Pileseri, ọba Asiria, ó sì rí pẹpẹ kan tí ó wà ní Damasku: Ahasi ọba sì rán àwòrán pẹpẹ náà, àti àpẹẹrẹ rẹ̀ sí Uriah àlùfáà, gẹ́gẹ́ bí gbogbo iṣẹ́ ọ̀nà rẹ̀. 11 Uriah àlùfáà sì kọ́ pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bi gbogbo èyí tí Ahasi ọba fi ránṣẹ́ sí i láti Damasku; bẹ́ẹ̀ ni Uriah àlùfáà ṣe é dé ìpadàbọ̀ Ahasi ọba láti Damasku. 12 Nígbà tí ọba sì ti Damasku dé, ọba sì rí pẹpẹ náà: ọba sì súnmọ́ pẹpẹ náà, ó sì rú ẹbọ lórí rẹ̀. 13 Ó sì sun ẹbọ sísun rẹ̀ àti ọrẹ-jíjẹ rẹ̀, o si ta ohun mímu rẹ̀ sílẹ̀, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ ọrẹ àlàáfíà rẹ̀ sí ara pẹpẹ náà. 14 Ṣùgbọ́n ó mú pẹpẹ idẹ tí ó wà níwájú Olúwa kúrò láti iwájú ilé náà, láti àárín méjì pẹpẹ náà, àti ilé Olúwa, ó sì fi í sí apá àríwá pẹpẹ náà.
15 Ahasi ọba sì pàṣẹ fún Uriah àlùfáà, wí pé, “Lórí pẹpẹ ńlá náà ni kó o máa sun ẹbọ sísun òròwúrọ̀ àti ọrẹ-jíjẹ alaalẹ́, àti ẹbọ sísun ti ọba, àti ọrẹ-jíjẹ rẹ̀, pẹ̀lú ẹbọ sísun tí gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti ọrẹ-jíjẹ wọn, àti ọrẹ ohun mímu wọn; kí o sì wọ́n gbogbo ẹ̀jẹ̀ ẹbọ sísun náà lórí rẹ̀, àti gbogbo ẹ̀jẹ̀ ẹbọ mìíràn: ṣùgbọ́n ní ti pẹpẹ idẹ náà èmi ó máa gbèrò ohun tí èmi ó fi ṣe.” 16 Báyìí ni Uriah àlùfáà ṣe, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Ahasi ọba pàṣẹ.
17 Ahasi ọba sì gé igi-ìpílẹ̀ àwọn àgbédúró náà, ó ṣí agbada náà kúrò lára wọn; ó sì gbé agbada ńlá náà kalẹ̀ kúrò lára àwọn màlúù idẹ tí ń bẹ lábẹ́ rẹ̀, ó sì gbé e ka ilẹ̀ tí a fi òkúta tẹ́. 18 Ibi ààbò fún ọjọ́ ìsinmi tí a kọ́ nínú ilé náà, àti ọ̀nà ìjáde sí òde ọba, ni ó yípadà kúrò ní ilé Olúwa nítorí ọba Asiria.
19 Àti ìyókù ìṣe Ahasi tí ó ṣe, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Juda? 20 (B)Ahasi sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dafidi: Hesekiah ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
Àwọn ẹ̀kọ́ tí a gbọdọ̀ kọ́ ní onírúurú àkójọpọ̀
2 Ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ máa kọ́ni ní ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro lórí ìgbé ayé onígbàgbọ́ tòótọ́. 2 Kọ́ àwọn àgbà ọkùnrin lẹ́kọ̀ọ́ láti ní ìrònú àti láti jẹ́ ẹni àpọ́nlé àti ẹni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. Wọn gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí ó jinlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́, nínú ìfẹ́ àti nínú ìpamọ́ra.
3 Bákan náà, ni kí ó kọ́ àwọn àgbà obìnrin lẹ́kọ̀ọ́ láti kọ́ bí à a tí gbé ìgbé ayé ẹni ọ̀wọ̀, wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ afọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ tàbí olùfẹ́ ọtí mímu, ṣùgbọ́n wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ olùkọ́ni ní ohun rere. 4 Nípa èyí, wọ́n yóò lè máa kọ́ àwọn ọ̀dọ́bìnrin láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọkọ wọn àti àwọn ọmọ wọn, 5 láti jẹ́ ẹni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti ọlọ́kàn mímọ́, kí wọ́n máa ṣe ojúṣe wọn nínú ilé, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ onínúrere, kí wọ́n sì máa tẹríba fún àwọn ọkọ wọ́n, kí ẹnikẹ́ni máa ba à sọ̀rọ̀-òdì sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
6 Bákan náà, rọ àwọn ọ̀dọ́ ọkùnrin láti kó ara wọn ni ìjánu. 7 Nínú ohun gbogbo fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí alápẹẹrẹ ohun rere. Nínú ẹ̀kọ́ rẹ fi àpẹẹrẹ ìwà pípé hàn, ẹni tó kún ojú òṣùwọ̀n 8 ọ̀rọ̀ tí ó yè kooro, tí a kò lè dá lẹ́bi, kí ojú kí ó ti ẹni tí ó ń sòdì, ní àìní ohun búburú kan láti wí sí wa.
9 Kọ́ àwọn ẹrú láti ṣe ìgbọ́ràn sí àwọn olówó wọn nínú ohun gbogbo, láti máa gbìyànjú láti tẹ́ wọn lọ́rùn, wọn kò gbọdọ̀ gbó olówó wọn lẹ́nu, 10 wọn kò gbọdọ̀ jà wọ́n lólè ohunkóhun, ṣùgbọ́n kí wọ́n jẹ́ ẹni tó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, kí wọn ó làkàkà ní gbogbo ọ̀nà láti jẹ́ kí ìkọ́ni nípa Ọlọ́run àti Olùgbàlà ní ìtumọ̀ rere.
11 Nítorí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tó mú ìgbàlà wà ti fi ara hàn fún gbogbo ènìyàn. 12 Ó ń kọ́ wa láti sẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ayé, kí a sì máa wà ní àìrékọjá, ní òdodo àti ní ìwà-bí-Ọlọ́run ní ayé ìsinsin yìí, 13 bí a ti ń wọ́nà fún ìrètí tó ní bùkún, èyí ń ní ìfarahàn ògo Ọlọ́run wa tí ó tóbi àti Olùgbàlà wa Jesu Kristi. 14 (A)Ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún wa láti rà fún ìràpadà kúrò nínú ìwà búburú gbogbo àti kí ó sì le wẹ̀ àwọn ènìyàn kan mọ́ fún ara rẹ̀ fún ìní ohun tìkára rẹ̀, àwọn tó ń ní ìtara fún iṣẹ́ rere.
15 Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni kí ìwọ kí ó máa kọ wọn. Gbani níyànjú kí ó sì máa fi gbogbo àṣẹ bá ni wí. Máa jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó gàn ọ́.
Ìdájọ́ fún ẹsẹ̀ Israẹli
9 Má ṣe yọ̀, ìwọ Israẹli;
má ṣe hó ìhó ayọ̀ bí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.
Nítorí ẹ ti jẹ́ aláìṣòótọ́ si Ọlọ́run yín.
Ẹ fẹ́ràn láti gba owó iṣẹ́ àgbèrè
ní gbogbo ilẹ̀ ìpakà.
2 Àwọn ilẹ̀ ìpakà àti ilé ìfun wáìnì kò ní fún àwọn ènìyàn lóúnjẹ
wáìnì tuntun yóò tàn láìròtẹ́lẹ̀
3 Wọn kò ní ṣẹ́kù sí ilé Olúwa
Efraimu yóò padà sí Ejibiti
Yóò sì jẹ oúnjẹ àìmọ́ ní Asiria.
4 Wọn kò ní fi ọrẹ ohun mímu fún Olúwa.
Bẹ́ẹ̀ ni ìrúbọ wọn kò ní mú, inú rẹ̀ dùn.
Ìrú ẹbọ bẹ́ẹ̀ yóò dàbí oúnjẹ àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀.
Gbogbo àwọn tó bá sì jẹ ẹ́ yóò di aláìmọ́.
Oúnjẹ yìí yóò wà fún wọn fúnrawọn
kò ní wá sí orí tẹmpili Olúwa.
5 Kí ni ẹ̀yin ó ṣe ní ọjọ́ àjọ̀dún tí a yàn
ní àwọn ọjọ́ àjọ̀dún Olúwa?
6 Bí wọ́n tilẹ̀ yọ́ kúrò lọ́wọ́ ìparun
Ejibiti yóò kó wọn jọ,
Memfisi yóò sì sin wọ́n.
Ibi ìsọjọ̀ fàdákà wọn ni ẹ̀gún yóò jogún,
Ẹ̀gún yóò bo àpótí ìṣúra fàdákà wọn.
Ẹ̀gún yóò sì bo
gbogbo àgọ́ wọn.
7 (A)Àwọn ọjọ́ ìjìyà ń bọ̀;
àwọn ọjọ́ ìṣirò iṣẹ́ ti dé
Jẹ́ kí Israẹli mọ èyí
Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ yín pọ̀
ìkórìíra yín sì pọ̀ gan an ni.
A ka àwọn wòlíì sí òmùgọ̀
A ka ẹni ìmísí sí asínwín.
8 Wòlíì, papọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run,
ni olùṣọ́ ọ Efraimu.
Síbẹ̀ ìdẹ̀kùn dúró dè é ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀
àti ìkórìíra ní ilé Ọlọ́run rẹ̀
9 Wọ́n ti gbilẹ̀ nínú ìwà ìbàjẹ́
gẹ́gẹ́ bí i ọjọ́ Gibeah
Ọlọ́run yóò rántí ìwà búburú wọn
yóò sì jẹ wọ́n ní yà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
10 “Mo rí Israẹli bí èso àjàrà ní aginjù.
Mo rí àwọn baba yín,
bí àkọ́pọ́n nínú igi ọ̀pọ̀tọ́ ní àkọ́so rẹ̀.
Ṣùgbọ́n wọ́n tọ Baali-Peori lọ,
wọ́n yà wọn sọ́tọ̀ fún òrìṣà tó ń mú ìtìjú bá ni,
ohun ìríra wọn sì rí gẹ́gẹ́ bí wọn ti fẹ́. 11 Ògo Efraimu yóò fò lọ bí ẹyẹ
kò ní sí ìfẹ́rakù, ìlóyún àti ìbímọ.
12 Bí wọ́n tilẹ̀ tọ́ ọmọ dàgbà.
Èmi yóò mú wọn ṣọ̀fọ̀ lórí gbogbo wọn
Ègbé ni fún wọn,
nígbà tí mo yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn!
13 Mo rí Efraimu bí ìlú Tire
tí a tẹ̀dó sí ibi dáradára
ṣùgbọ́n Efraimu yóò kó àwọn
ọmọ rẹ̀ jáde fún àwọn apànìyàn.”
14 Fún wọn, Olúwa!
Kí ni ìwọ yóò fún wọn?
Fún wọn ní inú tí ń ba oyún jẹ́
àti ọyàn gbígbẹ.
15 “Nítorí gbogbo ìwà búburú tí wọ́n hù ní Gilgali
Mo kórìíra wọn níbẹ̀,
nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Èmi yóò lé wọn jáde ní ilé mi
Èmi kò ní ní ìfẹ́ wọn mọ́
ọlọ̀tẹ̀ ni gbogbo olórí wọn.
16 Efraimu ti rẹ̀ dànù
gbogbo rẹ̀ sì ti rọ,
kò sì so èso,
Bí wọ́n tilẹ̀ bímọ.
Èmi ó pa àwọn ọmọ wọn tí wọ́n fẹ́ràn jùlọ.”
17 Ọlọ́run mi yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀
nítorí pé wọn kò gbọ́rọ̀ sí i;
wọn yóò sì di alárìnkiri láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.
Orin fún ìgòkè.
126 Nígbà tí Olúwa mú ìkólọ Sioni padà,
àwa dàbí ẹni tí ó ń lá àlá.
2 Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín,
àti ahọ́n wa kọ orin;
nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn kèfèrí pé,
Olúwa ṣe ohun ńlá fún wọn.
3 Olúwa ṣe ohun ńlá fún wa;
nítorí náà àwa ń yọ̀.
4 Olúwa mú ìkólọ wa padà,
bí ìṣàn omi ní gúúsù.
5 Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn
yóò fi ayọ̀ ka.
6 Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ,
tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́,
lóòtítọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá,
yóò sì ru ìtí rẹ̀.
Orin fún ìgòkè. Ti Solomoni.
127 Bí kò ṣe pé Olúwa bá kọ́ ilé náà
àwọn tí ń kọ́ ọ ń ṣiṣẹ́ lásán ni;
bí kò ṣe pé Olúwa bá pa ìlú mọ́, olùṣọ́ jí lásán.
2 Asán ni fún ẹ̀yin ti ẹ dìde ní kùtùkùtù
láti pẹ́ dùbúlẹ̀, láti jẹ oúnjẹ làálàá;
bẹ́ẹ̀ ni ó ń fi ìre fún olùfẹ́ rẹ̀ lójú ọ̀run.
3 Kíyèsi i, àwọn ọmọ ni ìní Olúwa:
ọmọ inú sì ni èrè rẹ̀.
4 Bí ọfà ti rí ní ọwọ́ alágbára,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ èwe
5 Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí apó rẹ̀ kún fún wọn;
ojú kì yóò tì wọ́n,
ṣùgbọ́n wọn yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá ní ẹnu-ọ̀nà.
Orin fún ìgòkè.
Ìbẹ̀rù Olúwa dára
128 Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Olúwa:
tí ó sì ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀
2 Nítorí tí ìwọ yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ
ìbùkún ni fún ọ; yóò sì dára fún ọ
3 Obìnrin rẹ yóò dàbí àjàrà rere
eléso púpọ̀ ní àárín ilé rẹ;
àwọn ọmọ rẹ yóò dàbí igi olifi tí ó yí tábìlì rẹ ká.
4 Kíyèsi i pé, bẹ́ẹ̀ ni a ó bùsi i fún ọkùnrin náà,
tí ó bẹ̀rù Olúwa.
5 Kí Olúwa kí ó bùsi i fún ọ láti Sioni wá,
kí ìwọ kí ó sì máa rí ìre
Jerusalẹmu ní ọjọ́ ayé rẹ gbogbo.
6 Bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì máa rí àti ọmọdọ́mọ rẹ.
Láti àlàáfíà lára Israẹli.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.