Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
1 Kronika 5-6

Rubeni

(A)Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Reubeni, àkọ́bí Israẹli. (Nítorí òun ni àkọ́bí; ṣùgbọ́n, bí ó ti ṣe pé ó ba ibùsùn baba rẹ̀ jẹ́, a fi ogún ìbí rẹ̀ fún àwọn ọmọ Josẹfu ọmọ Israẹli: a kì yóò sì ka ìtàn ìdílé náà gẹ́gẹ́ bí ipò ìbí. Nítorí Juda borí àwọn arákùnrin rẹ̀, àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni aláṣẹ ti ń jáde wá; ṣùgbọ́n ogún ìbí jẹ́ ti Josẹfu), àwọn ọmọ Reubeni àkọ́bí Israẹli ni:

Hanoku àti Pallu, Hesroni àti Karmi.

Àwọn ọmọ Joeli:

Ṣemaiah ọmọ rẹ̀, Gogu ọmọ rẹ̀,

Ṣimei ọmọ rẹ̀. Mika ọmọ rẹ̀,

Reaiah ọmọ rẹ̀, Baali ọmọ rẹ̀.

Beera ọmọ rẹ̀, tí Tiglat-Pileseri ọba Asiria kó ní ìgbèkùn lọ. Ìjòyè àwọn ọmọ Reubeni ni Beera jẹ́.

Àti àwọn arákùnrin rẹ̀ nípa ìdílé wọn, nígbà tí a ń ka ìtàn ìdílé ìran wọn:

Jeieli àti Sekariah ni olórí, àti Bela ọmọ Asasi ọmọ Ṣema, ọmọ Joeli.

Wọ́n tí ń gbé Aroeri àní títí dé Nebo àti Baali-Meoni. Àti níhà àríwá, o tẹ̀dó lọ títí dé àtiwọ aginjù láti odò Eufurate; nítorí tí ẹran ọ̀sìn wọn pọ̀ sí i ní ilẹ̀ Gileadi.

10 Àti ní ọjọ́ Saulu, wọ́n bá àwọn ọmọ Hagari jagun, ẹni tí ó ṣubú nípa ọwọ́ wọn; wọ́n sì ń gbé inú àgọ́ wọn ní gbogbo ilẹ̀ àríwá Gileadi.

Ìdílé Gadi

11 Àti àwọn ọmọ Gadi ń gbé lékè wọn, ní ilẹ̀ Baṣani títí dé Saleka:

12 Joeli jẹ́ olórí, Ṣafamu ìran ọmọ, Janai, àti Ṣafati ni Baṣani,

13 Àti àwọn arákùnrin wọn ti ilẹ̀ àwọn baba wọn ní:

Mikaeli, Meṣullamu Ṣeba, Jorai, Jaka, Sia àti Eberi méje.

14 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Abihaili, ọmọ Huri, ọmọ Jeroa, ọmọ Gileadi, ọmọ Mikaeli, ọmọ Jeṣiṣai, ọmọ Jado ọmọ Busi.

15 Ahi, ọmọ Adbeeli, ọmọ Guni, olórí ilé àwọn baba wọn.

16 Wọ́n sì ń gbé Gileadi ní Baṣani àti nínú àwọn ìlú rẹ̀, àti nínú gbogbo ìgbèríko Ṣaroni, ní agbègbè wọn.

17 Gbogbo wọ̀nyí ni a kà nípa ìtàn ìdílé, ní ọjọ́ Jotamu ọba Juda, àti ní ọjọ́ Jeroboamu ọba Israẹli.

18 Àwọn ọmọ Reubeni, àti àwọn ọmọ Gadi, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase, nínú àwọn ọkùnrin alágbára tí wọ́n ń gbé asà àti idà, tí wọ́n sì ń fi ọrun tafà, tí wọ́n sì mòye ogun, jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ènìyàn ó lé ẹgbẹ̀rìnlélógún dín ogójì, tí ó jáde lọ sí ogún náà. 19 Wọ́n sì bá àwọn ọmọ Hagari jagun, pẹ̀lú Jeturi, àti Nafiṣi àti Nadabu. 20 Nígbà tí wọ́n sì rí ìrànlọ́wọ́ gbà si, a sì fi àwọn ọmọ Hagari lé wọn lọ́wọ́, àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú wọn; nítorí tiwọn ké pe Ọlọ́run ní ogun náà, òun sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn; nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé e. 21 Wọ́n sì kó ẹran ọ̀sìn wọn lọ; ìbákasẹ ẹgbàá-mẹ́dọ́gbọ̀n àti àgùntàn ọ̀kẹ́ méjìlá ó lé ẹgbàárùn-ún, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbàá, àti ènìyàn ọ̀kẹ́ márùn-ún. 22 Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ṣubú tí a pa, nítorí láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ogun náà, wọ́n sì jókòó ní ipò wọn títí di ìgbà ìkólọ sí ìgbèkùn.

Ààbọ̀ Ẹ̀yà Manase

23 Àwọn ọmọkùnrin ààbọ̀ ẹ̀yà Manase ń gbé ní ilẹ̀ náà: wọ́n bí sí i láti Baṣani títí dé Baali-Hermoni, àti Seniri àti títí dé òkè Hermoni.

24 Wọ̀nyí sì ni àwọn olórí ilé àwọn baba wọn. Eferi, Iṣi, Elieli, Asrieli, Jeremiah, Hodafiah àti Jahdieli àwọn alágbára akọni ọkùnrin, ọkùnrin olókìkí, àti olórí ilé àwọn baba wọn. 25 Wọ́n sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run àwọn baba wọn, wọ́n sì ṣe àgbèrè tọ àwọn ọlọ́run ènìyàn ilẹ̀ náà lẹ́yìn, tí Ọlọ́run ti parun ní iwájú wọn. 26 Nítorí náà Ọlọ́run Israẹli ru ẹ̀mí Pulu ọba Asiria sókè (ẹ̀mí Tiglat-Pileseri ọba Asiria), ó si kó wọn lọ, àní àwọn ọmọ Reubeni àti àwọn ọmọ Gadi, àti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase lọ sí ìgbèkùn. Ó sì kó wọn wá sí Hala, àti Habori, àti Harani, àti sí etí odò Gosani; títí dí òní yìí.

Lefi

(B)Àwọn ọmọ Lefi:

Gerṣoni, Kohati àti Merari.

Àwọn ọmọ Kohati:

Amramu, Isari, Hebroni, àti Usieli.

Àwọn ọmọ Amramu:

Aaroni, Mose àti Miriamu.

Àwọn ọmọkùnrin Aaroni:

Nadabu, Abihu, Eleasari àti Itamari.

Eleasari jẹ́ baba Finehasi,

Finehasi baba Abiṣua

Abiṣua baba Bukki,

Bukki baba Ussi,

Ussi baba Serahiah,

Serahiah baba Meraioti,

Meraioti baba Amariah,

Amariah baba Ahitubu

Ahitubu baba Sadoku,

Sadoku baba Ahimasi,

Ahimasi baba Asariah,

Asariah baba Johanani,

10 Johanani baba Asariah.

(Òhun ni ó sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà nínú ilé Olúwa tí Solomoni kọ́ sí Jerusalẹmu).

11 Asariah baba Amariah

Amariah baba Ahitubu

12 Ahitubu baba Sadoku.

Sadoku baba Ṣallumu,

13 Ṣallumu baba Hilkiah,

Hilkiah baba Asariah,

14 Asariah baba Seraiah,

pẹ̀lú Seraiah baba Josadaki

15 A kó Josadaki lẹ́rú nígbà tí Olúwa lé Juda àti Jerusalẹmu kúrò ní ìlú nípasẹ̀ Nebukadnessari.

16 Àwọn ọmọ Lefi:

Gerṣoni, Kohati àti Merari.

17 Wọ̀nyí ni àwọn orúkọ àwọn ọmọ Gerṣoni:

Libni àti Ṣimei.

18 Àwọn ọmọ Kohati:

Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli.

19 Àwọn ọmọ Merari:

Mahili àti Muṣi.

Wọ̀nyí ni àwọn ìdílé ará Lefi tí a kọ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí baba wọn:

20 Ti Gerṣoni:

Libni ọmọkùnrin rẹ̀, Jahati

Ọmọkùnrin rẹ̀, Simma ọmọkùnrin rẹ̀, 21 Joah ọmọkùnrin rẹ̀,

Iddo ọmọkùnrin rẹ̀, Sera ọmọkùnrin rẹ̀

àti Jeaterai ọmọkùnrin rẹ̀.

22 Àwọn ìran ọmọ Kohati:

Amminadabu ọmọkùnrin rẹ̀, Kora ọmọkùnrin rẹ̀,

Asiri ọmọkùnrin rẹ̀. 23 Elkana ọmọkùnrin rẹ̀,

Ebiasafi ọmọkùnrin rẹ̀, Asiri ọmọkùnrin rẹ̀.

24 Tahati ọmọkùnrin rẹ̀, Urieli ọmọkùnrin rẹ̀,

Ussiah ọmọkùnrin rẹ̀ àti Saulu ọmọkùnrin rẹ̀.

25 Àwọn ìran ọmọ Elkana:

Amasai, Ahimoti

26 Elkana ọmọ rẹ̀, Sofai ọmọ rẹ̀

Nahati ọmọ rẹ̀, 27 Eliabu ọmọ rẹ̀,

Jerohamu ọmọ rẹ̀, Elkana ọmọ rẹ̀

àti Samuẹli ọmọ rẹ̀.

28 Àwọn ọmọ Samuẹli:

Joeli àkọ́bí

àti Abijah ọmọ ẹlẹ́ẹ̀kejì.

29 Àwọn ìran ọmọ Merari:

Mahili, Libni ọmọ rẹ̀.

Ṣimei ọmọ rẹ̀, Ussa ọmọ rẹ̀.

30 Ṣimea ọmọ rẹ̀, Haggiah ọmọ rẹ̀

àti Asaiah ọmọ rẹ̀.

Ilé ti a kọ́ fún àwọn Olórin

31 Èyí ní àwọn ọkùnrin Dafidi tí a fi sí ìdí orin nínú ilé Olúwa lẹ́yìn tí àpótí ẹ̀rí ti wá láti sinmi níbẹ̀. 32 Wọ́n jíṣẹ́ pẹ̀lú orin níwájú àgọ́ ìpàdé títí tí Solomoni fi kọ́ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu. Wọ́n ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ fún wọn.

33 Wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ó sìn pẹ̀lú ọmọ wọn:

Láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Kohati:

Hemani olùkọrin,

ọmọ Joeli, ọmọ Samuẹli,

34 Ọmọ Elkana ọmọ Jerohamu,

ọmọ Elieli, ọmọ Toha

35 Ọmọ Sufu, ọmọ Elkana,

ọmọ Mahati, ọmọ Amasai,

36 Ọmọ Elkana, ọmọ Joeli,

ọmọ Asariah, ọmọ Sefaniah

37 Ọmọ Tahati, ọmọ Asiri,

ọmọ Ebiasafi ọmọ Kora,

38 ọmọ Isari, ọmọ Kohati

ọmọ Lefi, ọmọ Israẹli;

39 Hemani sì darapọ̀ mọ́ Asafu, ẹni tí o sìn ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀:

Asafu ọmọ Bẹrẹkiah, ọmọ Ṣimea,

40 Ọmọ Mikaeli, ọmọ Baaseiah,

ọmọ Malkiah 41 Ọmọ Etini,

ọmọ Sera, ọmọ Adaiah,

42 Ọmọ Etani, ọmọ Simma,

ọmọ Ṣimei, 43 Ọmọ Jahati,

ọmọ Gerṣoni, ọmọ Lefi;

44 láti ìbákẹ́gbẹ́ wọn, àwọn ará Merari wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀:

Etani ọmọ Kiṣi, ọmọ Abdi,

ọmọ Malluki, 45 Ọmọ Haṣabiah

ọmọ Amasiah, ọmọ Hilkiah,

46 Ọmọ Amisi ọmọ Bani,

ọmọ Ṣemeri, 47 Ọmọ Mahili,

ọmọ Muṣi, ọmọ Merari,

ọmọ Lefi.

48 Àwọn Lefi ẹgbẹ́ wọn ni wọn yan àwọn iṣẹ́ yòókù ti àgọ́ fún, èyí tí í ṣe ilé Ọlọ́run. 49 Ṣùgbọ́n Aaroni àti àwọn ìran ọmọ rẹ̀ jẹ́ àwọn tí ó gbé ọrẹ kalẹ̀ lórí pẹpẹ ẹbọ sísun àti lórí pẹpẹ tùràrí ní ìbátan pẹ̀lú gbogbo ohun tí a ṣe ní ibi mímọ́ jùlọ. Ṣíṣe ètùtù fún Israẹli, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Mose ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti pàṣẹ.

50 Wọ̀nyí ni àwọn ìránṣẹ́ Aaroni:

Eleasari ọmọ rẹ̀. Finehasi ọmọ rẹ̀,

Abiṣua ọmọ rẹ̀, 51 Bukki ọmọ rẹ̀,

Ussi ọmọ rẹ̀. Serahiah ọmọ rẹ̀,

52 Meraioti ọmọ rẹ̀, Amariah ọmọ rẹ̀,

Ahitubu ọmọ rẹ̀, 53 Sadoku ọmọ rẹ̀

àti Ahimasi ọmọ rẹ̀.

54 (C)Wọ̀nyí ni ibùgbé wọn tí a pín fún wọn gẹ́gẹ́ bí agbègbè wọn (tí a fi lé àwọn ìran ọmọ Aaroni lọ́wọ́ tí ó wá láti ẹ̀yà Kohati, nítorí kèké alákọ́kọ́ jẹ́ tiwọn):

55 A fún wọn ní Hebroni ní Juda pẹ̀lú àyíká pápá oko tútù ilẹ̀ rẹ̀. 56 Ṣùgbọ́n àwọn pápá àti ìletò tí ó yí ìlú ńlá náà ká ni a fi fún Kalebu ọmọ Jefunne. 57 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìran ọmọ Aaroni ni a fún ní Hebroni (ìlú ti ààbò), àti Libina, Jattiri, Eṣitemoa, 58 Hileni, Debiri, 59 Aṣani, Jutta àti Beti-Ṣemeṣi lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ rẹ̀.

60 Àti láti inú ẹ̀yà Benjamini, a fún wọn ní Gibeoni, Geba, Alemeti àti Anatoti lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.

Àwọn ìlú wọ̀nyí, tí a pín láàrín àwọn ẹ̀yà Kohati jẹ́ mẹ́tàlá ní gbogbo rẹ̀.

61 Ìyókù àwọn ìran ọmọ Kohati ní a pín ìlú mẹ́wàá fún láti àwọn ìdílé ní ti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase.

62 Àwọn ìran ọmọ Gerṣoni, sí ìdílé ni a pín ìlú mẹ́tàlá fún láti ẹ̀yà àwọn ẹ̀yà Isakari, Aṣeri àti Naftali, àti láti apá ẹ̀yà Manase tí ó wà ní Baṣani.

63 Sebuluni Àwọn ìran ọmọ Merari, ìdílé sí ìdílé, ní a pín ìlú méjìlá fún láti ẹ̀yà Reubeni, Gadi àti Sebuluni.

64 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli fún àwọn ará Lefi ní ìlú wọ̀nyí pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.

65 Láti ẹ̀yà Juda, Simeoni àti Benjamini ni a pín ìlú tí a ti dárúkọ wọn sẹ́yìn fún.

66 Lára àwọn ìdílé Kohati ni a fún ní ìlú láti ẹ̀yà Efraimu gẹ́gẹ́ bí ìlú agbègbè wọn.

67 Ní òkè orílẹ̀-èdè Efraimu, a fún wọn ní Ṣekemu (Ìlú ńlá ti ààbò), àti Geseri 68 Jokimeamu, Beti-Horoni. 69 Aijaloni àti Gati-Rimoni lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.

70 Pẹ̀lú láti apá ààbọ̀ ẹ̀yà Manase àwọn ọmọ Israẹli fún Aneri àti Bileamu lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn, fún ìyókù àwọn ìdílé Kohati.

71 Àwọn ará Gerṣoni gbà nǹkan wọ̀nyí:

Láti ààbọ̀ ẹ̀yà ti Manase wọ́n gba Golani ní Baṣani àti pẹ̀lú Aṣtarotu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù wọn;

72 Láti ẹ̀yà Isakari wọ́n gba Kedeṣi, Daberati 73 Ramoti àti Anenu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn;

74 Láti ẹ̀yà Aṣeri wọ́n gba Maṣali, Abdoni, 75 Hukoki àti Rehobu lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn;

76 Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Naftali wọ́n gba Kedeṣi ní Galili, Hammoni àti Kiriataimu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.

77 Àwọn ará Merari (ìyókù àwọn ará Lefi) gbà nǹkan wọ̀nyí:

Láti ẹ̀yà Sebuluni wọ́n gba Jokneamu, Karta, Rimoni àti Tabori, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn;

78 Láti ẹ̀yà Reubeni rékọjá Jordani ìlà-oòrùn Jeriko wọ́n gba Beseri nínú aginjù Jahisa, 79 Kedemoti àti Mefaati, lápapọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko tútù wọn;

80 Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Gadi wọ́n gba Ramoti ní Gileadi Mahanaimu, 81 Heṣboni àti Jaseri lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ pápá oko tútù wọn.

Heberu 10

Ìrúbọ Kristi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo fún gbogbo ènìyàn

10 Nítorí tí òfin jẹ́ òjìji àwọn ohun rere ti ń bọ̀ tí kì í ṣe àwòrán tòótọ́ fún àwọn òtítọ́ náà, wọn kò lè fi ẹbọ kan náà tí wọn ń rú nígbà gbogbo lọ́dọọdún mu àwọn tí ń wá jọ́sìn di pípé. Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, a kì ìbá tí dẹ́kun àti máa rú wọn, nítorí àwọn ti ń sìn ki ìbá tí ní ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀, nígbà tí a bá ti wẹ̀ wọ́n mọ́ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Ṣùgbọ́n nínú ẹbọ wọ̀nyí ni a ń ṣe ìrántí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́dọọdún. Nítorí ko ṣe é ṣe fún ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù àti ti ewúrẹ́ láti mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò.

(A)Nítorí náà nígbà tí Kristi wá sí ayé, ó wí pé,

“Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọrẹ,
    ṣùgbọ́n ara ni ìwọ ti pèsè fún mi;
Ẹbọ sísun àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ ni
    ìwọ kò ní inú dídùn sí.
Nígbà náà ni mo wí pé, ‘Kíyèsi i (nínú ìwé kíká ni a gbé kọ ọ́ nípa ti èmi)
    mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run.’ ”

Nígbà tí o wí ni ìṣáájú pé, “Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọrẹ àti ẹbọ sísun, àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò ni inú dídùn si wọn” (àwọn èyí tí a ń rú gẹ́gẹ́ bí òfin). Nígbà náà ni ó wí pé, “Kíyèsi i, mo de láti ṣe ìfẹ́ rẹ Ọlọ́run.” Ó mú ti ìṣáájú kúrò, kí a lè fi ìdí èkejì múlẹ̀. 10 Nípa ìfẹ́ náà ni a ti sọ wá di mímọ́ nípa ẹbọ ti Jesu Kristi fi ara rẹ̀ rú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.

11 Àti olúkúlùkù àlùfáà sì ń dúró lójoojúmọ́ láti ṣiṣẹ́ ìsìn, ó sì ń ṣe ẹbọ kan náà nígbàkúgbà, tí kò lè mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò láé: 12 (B)Ṣùgbọ́n òun, lẹ́yìn ìgbà tí o ti rú ẹbọ kan fún ẹ̀ṣẹ̀ títí láé, o jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run; 13 Láti ìgbà náà, ó retí títí a o fi àwọn ọ̀tá rẹ̀ ṣe àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀. 14 Nítorí nípa ẹbọ kan a ti mú àwọn tí a sọ di mímọ́ pé títí láé.

15 Ẹ̀mí Mímọ́ sì ń jẹ́rìí fún wa pẹ̀lú: Nítorí lẹ́yìn tí ó wí pé,

16 (C)“Èyí ni májẹ̀mú ti èmi o ba wọn dá
    lẹ́hìn àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, ni Olúwa wí.
Èmi o fi òfin mi sí wọn ní ọkàn,
    inú wọn pẹ̀lú ni èmi o sì kọ wọn sí.”

17 Ó tún sọ wí pé:

“Ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àìṣedéédéé wọn
    lèmi kì yóò sì rántí mọ́.”

18 Ṣùgbọ́n níbi tí ìmúkúrò ìwọ̀nyí bá gbé wà, ìrúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ kò sí mọ́.

Ìpè sí ìforítì

19 Ará, ǹjẹ́ bí a ti ní ìgboyà láti wọ inú ibi mímọ́ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Jesu, 20 nípa ọ̀nà títún àti ààyè, tí o yà sí mímọ́ fún wa, àti láti kọjá aṣọ ìkélé èyí yìí ní, ara rẹ̀; 21 àti bí a ti ni àlùfáà gíga lórí ilé Ọlọ́run; 22 ẹ jẹ́ kí a fi òtítọ́ ọkàn súnmọ́ tòsí ni ẹ̀kún ìgbàgbọ́, kí a sì wẹ ọkàn wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀rí ọkàn búburú, kí a sì fi omi mímọ́ wẹ ara wa nù. 23 Ẹ jẹ́ kí a di ìjẹ́wọ́ ìrètí wa mu ṣinṣin ni àìṣiyèméjì; (nítorí pé olóòtítọ́ ní ẹni tí o ṣe ìlérí). 24 Ẹ jẹ́ kí a yẹ ara wa wò láti ru ara wa sí ìfẹ́ àti sí iṣẹ́ rere: 25 kí a ma máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bi àṣà àwọn ẹlòmíràn; ṣùgbọ́n kí a máa gba ara ẹni níyànjú pẹ̀lúpẹ̀lú bí ẹ̀yin ti rí i pé ọjọ́ náà ń súnmọ́ etílé.

26 Nítorí bí àwa ba mọ̀ ọ́n mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí àwa bá ti gba ìmọ̀ òtítọ́ kò tún sí ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. 27 (D)Bí kò ṣe ìrètí ìdájọ́ tí ó ba ni lẹ́rù, àti ti ìbínú ti o múná, tí yóò pa àwọn ọ̀tá run. 28 (E)Ẹnikẹ́ni tí ó ba gan òfin Mose, ó kú láìsí àánú nípa ẹ̀rí ẹni méjì tàbí mẹ́ta: 29 (F)Mélòó mélòó ni ẹ rò pé a o jẹ ẹni náà ní ìyà kíkan, ẹni tí o tẹ ọmọ Ọlọ́run mọ́lẹ̀ tí ó sì ti ka ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú ti a fi sọ ọ́ di mímọ́ si ohun àìmọ́, tí ó sì ti kẹ́gàn ẹ̀mí oore-ọ̀fẹ́. 30 (G)Nítorí àwa mọ ẹni tí o wí pé: Ẹ̀san ni ti èmi, Olúwa wí pé, “Èmi ó gbẹ̀san.” Àti pẹ̀lú, “Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀.” 31 Ohun ẹ̀rù ni láti ṣubú sí ọwọ́ Ọlọ́run alààyè.

32 Ṣùgbọ́n ẹ rántí ọjọ́ ìṣáájú nínú èyí tí, nígbà tí a ti sí yin lójú, ẹ fi ara da wàhálà ńlá ti ìjìyà; 33 lápákan, nígbà tí a sọ yín di ìran wíwò nípa ẹ̀gàn àti ìpọ́njú; àti lápákan, nígbà tí ẹ̀yin di ẹgbẹ́ àwọn tí a ṣe bẹ́ẹ̀ si. 34 Nítorí ẹ̀yin bá àwọn tí ó wà nínú ìdè kẹ́dùn, ẹ sì fi ayọ̀ gba ìkólọ ẹrù yin, nítorí ẹ̀yin mọ nínú ara yin pé, ẹ ni ọrọ̀ tí ó wà títí, tí ó sì dára jù bẹ́ẹ̀ lọ. 35 Nítorí náà ẹ má ṣe gbé ìgboyà yín sọnù, èyí ti o ni èrè ńlá.

36 Nítorí ẹ̀yin kò le ṣe aláìní sùúrù, nítorí ìgbà tí ẹ̀yin bá ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tan kí ẹ̀yin le gba ìlérí náà. 37 (H)Nítorí,

“Ni ìwọ̀n ìgbà díẹ̀ sí i,
    ẹni náà ti ń bọ̀ yóò dé,
    kí yóò sì jáfara.

38 Ṣùgbọ́n,

“Olódodo ni yóò yè nípa ìgbàgbọ́.
    Ṣùgbọ́n bí o ba fàsẹ́yìn,
    ọkàn mi kò ní inú dídùn sí i.”

39 Ṣùgbọ́n àwa kò sí nínú àwọn tí ń fàsẹ́yìn sínú ègbé; bí kò ṣe nínú àwọn tí o gbàgbọ́ sí ìgbàlà ọkàn.

Amosi 4

Israẹli kò yípadà sí Ọlọ́run

Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin màlúù Baṣani lórí òkè Samaria,
    ẹ̀yin obìnrin tí ó ń ni tálákà lára,
    tí ó ń tẹ aláìní mọ́lẹ̀, tí ó wí fún ọkọ rẹ̀, “Gbé wá kí a sì mu!”
Olúwa Olódùmarè ti fi ìwà mímọ́ rẹ̀ búra:
    “Àkókò náà yóò dé nítòótọ́
nígbà tí a ó fi ìwọ̀ mú un yín lọ,
    ẹni tí ó kẹ́yìn pẹ̀lú ìwọ̀ ẹja.
Ẹni kọ̀ọ̀kan yín yóò jáde lọ
    gba àárín odi yíya
    a ó sì lé e yín sí Harmoni,”
    ni Olúwa wí.
“Ẹ lọ sí Beteli láti dẹ́ṣẹ̀;
    ẹ lọ sí Gilgali kí ẹ sì dẹ́ṣẹ̀ sí i.
Ẹ mú ẹbọ sísun yín láràárọ̀ wá,
    ìdámẹ́wàá yín ní ọdọọdún mẹ́ta.
Kí ẹ mú ọ̀rẹ́ ìdúpẹ́ ìyẹ̀fun ìwúkàrà ti a sun
    kí ẹ sì mú ọrẹ àtinúwá
lọ fi wọ́n yangàn, ẹ̀yin ènìyàn Israẹli,
    nítorí èyí ni ẹ fẹ́ láti ṣe,”
    ni Olúwa Olódùmarè wí.

“Èmi fún un yín ní mímọ́ eyín ní gbogbo ìlú yín,
    àti àìní oúnjẹ ní gbogbo ibùgbé yín,
    síbẹ̀, ẹ̀yin kò yípadà sọ́dọ̀ mi,”
    ni Olúwa wí.

“Àti pẹ̀lú mo mú òjò dúró
    nígbà tí ìkórè ku oṣù mẹ́ta.
Mo rán òjò sí ibùgbé kan
    ṣùgbọ́n kò rọ̀ sí ìlú mìíràn.
Oko kan ní òjò;
    àwọn mìíràn kò ní ó sì gbẹ.
Àwọn ènìyàn ń rìn láti ìlú kan sí ìlú mìíràn fún omi
    wọn kò rí mu tẹ́ wọn lọ́rùn,
    síbẹ̀ ẹ̀yin kò padà sí ọ̀dọ̀ mi,”
    ni Olúwa wí.

“Lọ́pọ̀ ìgbà ni mo kọlu ọgbà àti ọgbà àjàrà yín
    mo fi ìrẹ̀dànù àti ìmúwòdù lù wọ́n.
Eṣú sì jẹ igi ọ̀pọ̀tọ́ àti igi olifi yín,
    síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,”
    ni Olúwa wí.

10 “Mo rán àjàkálẹ̀-ààrùn sí i yín
    bí mo ti ṣe sí Ejibiti.
Mo fi idà pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín.
    Pẹ̀lú àwọn ẹṣin tí a kó ní ìgbèkùn.
Mo kún imú yín fún òórùn ibùdó yín,
    síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,”
    ni Olúwa wí.

11 “Mo ti bì ṣubú nínú yín,
    bí Ọlọ́run ti bi Sodomu àti Gomorra ṣubú
ẹ̀yin sì dàbí ògúnná tí a fa yọ kúrò nínú iná,
    síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,”
    ni Olúwa wí.

12 “Nítorí náà, èyí ni ohun tí èmi yóò ṣe sí i yín, Israẹli,
    àti nítorí tí èmi ó ṣe èyí sí i yín,
    ẹ múra láti pàdé Ọlọ́run yín, ẹ̀yin Israẹli.”

13 Ẹni tí ó dá àwọn òkè
    tí ó dá afẹ́fẹ́
    tí ó sì fi èrò rẹ̀ hàn sí ènìyàn,
ẹni tí ó yípadà sí òkùnkùn
    tí ó sì tẹ ibi gíga ayé.
    Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.

Saamu 148-150

148 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa láti ọ̀run wá,
    Ẹ fi ìyìn fún un níbi gíga.
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin ọmọ-ogun rẹ̀
Ẹ fi ìyìn fún un,
    oòrùn àti òṣùpá
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.
Ẹ fi ìyìn fún un,
    ẹ̀yin ọ̀run àti àwọn ọ̀run gíga
    àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run.

Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa
    nítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn
Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláé
    ó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já.

Ẹ yin Olúwa láti ilẹ̀ ayé wá
    ẹ̀yin ẹ̀dá inú Òkun títóbi
    àti ẹ̀yin ibú Òkun
Mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyín
    ìdí omi àti àwọn ìkùùkuu,
    ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ;
Òkè ńlá àti gbogbo òkè kéékèèkéé,
    igi eléso àti gbogbo igi kedari,
10 Àwọn ẹranko ńlá àti ẹran ọ̀sìn
    gbogbo ohun afàyàfà àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́:
11 Àwọn ọba ayé àti ènìyàn ayé gbogbo
    àwọn ọmọ-aládé àti gbogbo àwọn onídàájọ́ ayé,
12 Ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin
    àwọn arúgbó àti àwọn ọmọdé.

13 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa
    nítorí orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ní ọlá
    ògo rẹ̀ kọjá ayé àti ọ̀run
14 Ó sì gbé ìwo kan sókè fún àwọn ènìyàn rẹ̀,
    ìyìn fún gbogbo ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àní fún àwọn ọmọ Israẹli,
    àwọn ènìyàn tí ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
149 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa.
    Ẹ yìn ín ní àwùjọ àwọn ènìyàn mímọ́.

Jẹ́ kí Israẹli kí ó ní inú dídùn sí ẹni tí ó dá a
    jẹ́ kí àwọn ọmọ Sioni kí ó ní
    ayọ̀ nínú ọba wọn.
Jẹ́ kí wọn kí ó fi ijó yin orúkọ rẹ̀
    jẹ́ kí wọn kí ó fi ohun èlò orin kọrin ìyìn sí i.
Nítorí Olúwa ní inú dídùn sí àwọn ènìyàn rẹ̀
    ó fi ìgbàlà dé àwọn onírẹ̀lẹ̀ ládé
Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mímọ́ kí ó yọ̀ nínú ọlá rẹ̀
    kí wọn kí ó máa kọrin fún ayọ̀ ní orí ibùsùn wọn.

Kí ìyìn Ọlọ́run kí ó wà ní ẹnu wọn
    àti idà olójú méjì ní ọwọ́ wọn.
Láti gba ẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè,
    àti ìjìyà lára àwọn ènìyàn,
Láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba wọn
    àti láti fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀
irin de àwọn ọlọ́lá wọn.
Láti ṣe ìdájọ́ tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ sí wọn
    èyí ni ògo àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
150 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ẹ fi ìyìn fún Ọlọ́run ní ibi mímọ́ rẹ̀
    Ẹ yìn ín nínú agbára ọ̀run rẹ̀.
Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ agbára rẹ̀.
    Ẹ yìn ín fún títóbi rẹ̀ tí ó tayọ̀.
Ẹ fi ohùn ìpè yìn ín.
    Ẹ fi ohun èlò orin yìn ín.
Ẹ fi ohun èlò orin àti ijó yìn ín
    fi ohun èlò orin olókùn àti ìpè yìn ín
Ẹ yìn ín pẹ̀lú aro olóhùn òkè,
    Ẹ yìn ín lára aro olóhùn gooro.

Jẹ́ kí gbogbo ohun tí ó ní ẹ̀mí yin Olúwa.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.