Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
2 Ọba 21

Manase ọba Juda

21 (A)Manase jẹ́ ẹni ọdún méjìlá nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ìjọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún márùn-dínlọ́gọ́ta (55). Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Hẹfisiba. Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, ó sì tẹ̀lé iṣẹ́ ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa lé jáde níwájú àwọn ọmọ Israẹli. Ó sì tún ibi gíga tí baba rẹ̀ Hesekiah tí ó parun kọ́. Ó sì tún gbé pẹpẹ Baali dìde, ó sì ṣe ère òrìṣà Aṣerah, gẹ́gẹ́ bí Ahabu ọba Israẹli ti ṣe. Ó sì tẹríba sí gbogbo ogun ọ̀run, ó sì ń sìn wọ́n. Ó sì kọ́ pẹpẹ nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa, èyí tí Olúwa ti sọ pé, “Ní Jerusalẹmu ni èmi yóò kọ orúkọ mi sí.” Ní àgbàlá méjèèjì ilé Olúwa, ó sì kọ́ pẹpẹ fún gbogbo àwọn ìrúbọ nínú ilé, ṣe iṣẹ́ àkíyèsí àfọ̀ṣẹ, ó sì béèrè lọ́wọ́ àwọn òkú àti àwọn oṣó. Ó sì ṣe ọ̀pọ̀ búburú ní ojú Olúwa, ó sì mú un bínú. Ó fi àwọn ọmọ ara rẹ̀ rú ẹbọ nínú iná, ó ń ṣe àkíyèsí àfọ̀ṣẹ, ó sì ń lo àlúpàyídà, ó sì ń bá àwọn òku àti oṣó lò. Ó ṣe ọ̀pọ̀ ohun búburú ní ojú Olúwa láti mú un bínú.

Ó sì gbé ère fínfín òrìṣà Aṣerah tí ó ti ṣe, ó sì gbé e sínú ilé Olúwa, èyí tí Olúwa ti sọ fún Dafidi àti sí ọmọ rẹ̀ Solomoni, “Nínú ilé Olúwa yìí àti ní Jerusalẹmu, tí èmi ti yàn jáde lára gbogbo ẹ̀yà Israẹli, èmi yóò kọ orúkọ mi títí láéláé. Èmi kò ní jẹ́ kí ẹsẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli yẹ̀ kúrò láti ilẹ̀ tí èmi fi fún àwọn baba ńlá wọn tí ó bá jẹ́ wí pé wọn yóò ṣe àkíyèsí láti ṣe gbogbo ohun tí èmi ti paláṣẹ fún wọn kí wọn sì pa gbogbo òfin tí ìránṣẹ́ mi Mose fi fún wọn mọ́.” Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò tẹ́tí. Manase tàn wọ́n síwájú, bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n lè ṣe búburú ju gbogbo orílẹ̀-èdè tí Olúwa tí parun níwájú àwọn ọmọ Israẹli lọ.

10 Olúwa sì wí nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì pé: 11 “Manase ọba Juda ti ṣe ẹ̀ṣẹ̀ ohun ìríra. Ó ti ṣe ohun búburú jùlọ ju àwọn ará Amori lọ ẹni tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀ tí ó sì ti ṣáájú Juda sínú ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú àwọn ère rẹ̀. 12 Nítorí náà èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli, wí: Èmi le è lọ mú irú ibi báyìí wá sórí Jerusalẹmu àti Juda kí gbogbo etí olúkúlùkù tí ó gbọ́ nípa rẹ̀ le è hó. 13 Èmi yóò sì nà okùn ìwọ̀n kan tí a lò lórí Jerusalẹmu àti lórí Samaria àti òjé ìdiwọ̀n ti a lò lórí ilé Ahabu. Èmi yóò sì nu Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ọkàn tí ń nu àwokòtò nù tí o ń nù un tí o sì ń dorí rẹ̀ kodò. 14 Èmi yóò sì kọ ìyókù àwọn ìní mi sílẹ̀ èmi yóò sì kó wọn lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́. Wọn yóò sì di ìkógun àti ìjẹ fún gbogbo àwọn ọ̀tá wọn, 15 nítorí pé wọ́n ti ṣe búburú ní ojú mi, wọ́n sì ti mú mi bínú láti ọjọ́ tí baba ńlá wọn ti jáde wá láti Ejibiti títí di òní yìí.”

16 Pẹ̀lúpẹ̀lú, Manase pẹ̀lú ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ púpọ̀ tí ó kún Jerusalẹmu láti ìkangun dé ìkangun ní ẹ̀gbẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti mú Juda ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni, kí wọ́n lè ṣe ohun búburú ní ojú Olúwa.

17 Ní ti iṣẹ́ ìyókù ti ìjọba Manase, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, àti fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, ṣé wọ́n kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn àwọn ọba Juda? 18 (B)Manase sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ wọ́n sì sin ín nínú ọgbà ààfin rẹ̀, ọgbà Ussa. Amoni ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

Amoni ọba Juda

19 (C)Amoni jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó jẹ ọba. Orúkọ màmá rẹ̀ a sì máa jẹ́ Meṣulemeti ọmọbìnrin Harusi: ó wá láti Jotba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún méjì. 20 Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa àti gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Manase ti ṣe. 21 Ó rìn ní gbogbo ọ̀nà baba rẹ̀: Ó sì ń sin àwọn ère tí baba rẹ̀ ń sìn, ó sì ń tẹrí rẹ̀ ba fún wọn. 22 Ó sì kọ Olúwa Ọlọ́run baba rẹ̀ sílẹ̀ kò sì rìn ní ọ̀nà ti Olúwa.

23 Àwọn ìránṣẹ́ Amoni dìtẹ̀ lórí rẹ̀ wọ́n sì lu ọba pa ní àárín ilé rẹ̀. 24 Nígbà náà àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pa gbogbo àwọn tí ó dìtẹ̀ sí ọba Amoni, wọ́n sì fi Josiah ọmọ rẹ̀ jẹ ọba ní ààyè rẹ̀.

25 Àti gẹ́gẹ́ bí ìyókù iṣẹ́ ti ìjọba Amoni àti ohun tí ó ṣe, ṣé wọn kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn àwọn ọba Juda? 26 Wọ́n sì sin ín sínú isà òkú nínú ọgbà Ussa. Josiah ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

Heberu 3

Jesu pọ̀ ju Mose lọ

Nítorí náà ẹ̀yin ará mímọ́, alábápín ìpè ọ̀run, ẹ gba ti aposteli àti olórí àlùfáà ìjẹ́wọ́ wa rò, àní Jesu; (A)Ẹni tí o ṣe olóòtítọ́ si ẹni tí ó yàn án, bí Mose pẹ̀lú tí ṣe olóòtítọ́ nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo nínú ilé Ọlọ́run. Nítorí a ka ọkùnrin yìí ni yíyẹ sí ògo ju Mose lọ níwọ̀n bí ẹni tí ó kọ́ ilé ti lọ́lá ju ilé lọ. Láti ọwọ́ ènìyàn kan ni a sá à ti kọ́ olúkúlùkù ilé; ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ́ ohun gbogbo ni Ọlọ́run. (B)Mose nítòótọ́ sì ṣe olóòtítọ́ nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run, bí ìránṣẹ́, fún ẹ̀rí ohun tí a ó sọ̀rọ̀ wọ́n ní ìgbà ìkẹyìn. Ṣùgbọ́n Kristi jẹ́ olóòtítọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ lórí ilé Ọlọ́run; ilé ẹni tí àwa jẹ́, bí àwa bá gbẹ́kẹ̀lé e, tí a sì di ìṣògo ìrètí wa mu ṣinṣin títí dé òpin.

Ìkìlọ̀ fún aláìgbàgbọ́

(C)Nítorí náà gẹ́gẹ́ bi Ẹ̀mí Mímọ́ tí wí:

“Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
    Ẹ má ṣe sé ọkàn yín le,
bí ìgbà ìṣọ̀tẹ̀,
    bí i ní ọjọ́ ìdánwò ní aginjù:
Níbi tí àwọn baba yín ti dán mi wò,
    tí wọ́n sì rí iṣẹ́ mi ní ogójì ọdún.
10 Nítorí náà a mú inú bí mi si ìran náà,
    mo sì wí pé, ‘Nígbà gbogbo ni wọn ṣìnà ní ọkàn wọn;
    wọn kò sì mọ ọ̀nà mi.’
11 Bí mo tí búra nínú ìbínú mi,
    ‘wọn kí yóò wọ inú ìsinmi mi.’ ”

12 Ẹ kíyèsára, ará, kí ọkàn búburú ti àìgbàgbọ́ má ṣe wà nínú ẹnikẹ́ni yín, ní lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè. 13 Ṣùgbọ́n ẹ máa gba ara yín ní ìyànjú ní ojoojúmọ́, níwọ̀n ìgbà tí a bá ń pè ní “Òní,” kí a má ba à sé ọkàn ẹnikẹ́ni nínú yín le nípa ẹ̀tàn ẹ̀ṣẹ̀. 14 Nítorí àwa di alábápín pẹ̀lú Kristi, bí àwa bá di ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé wa mú ṣinṣin títí dé òpin; 15 (D)Nígbà tí a ń wí pé:

“Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
    ẹ má sé ọkàn yin le,
bí ìgbà ìṣọ̀tẹ̀.”

16 (E)Àwọn ta ni ó gbọ́ tí ó sì tún ṣọ̀tẹ̀? Kì í ha ṣe gbogbo àwọn tí o jáde kúrò ní Ejibiti ní abẹ́ àkóso Mose? 17 (F)Àwọn ta ni ó sì bínú sí fún ogójì ọdún? Kì í ha ṣe sí àwọn tí ó dẹ́ṣẹ̀, òkú àwọn tí ó sùn ní aginjù? 18 Àwọn wo ni ó búra fún pé wọn kì yóò wọ inú ìsinmi òun, bí kò ṣe fún àwọn tí ó ṣe àìgbọ́ràn? 19 Àwa sì rí i pé wọn kò lè wọ inú rẹ̀ nítorí àìgbàgbọ́.

Hosea 14

Ìwòsàn ń bẹ fún àwọn tó ronúpìwàdà

14 Yípadà ìwọ Israẹli sí Olúwa Ọlọ́run rẹ.
    Ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ló fa ìparun rẹ!
(A)Ẹ gba ọ̀rọ̀ Olúwa gbọ́,
    kí ẹ sì yípadà sí Olúwa.
Ẹ sọ fún un pé:
    “Darí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá
kí o sì fi oore-ọ̀fẹ́ gbà wá,
    kí àwa kí ó lè fi ètè wa sán an fún ọ
Asiria kò le gbà wá là;
    A kò ní í gorí ẹṣin ogun
A kò sì ní tún sọ ọ́ mọ́ láé
    ‘Àwọn ni òrìṣà wa
sí àwọn ohun tí ó fi ọwọ́ wa ṣe;
    nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni àwọn
    aláìní baba tí ń rí àánú.’

“Èmi wo àgàbàgebè wọn sàn,
    Èmi ó sì fẹ́ràn wọn, lọ́fẹ̀ẹ́,
    nítorí ìbínú mi ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn.
Èmi o dàbí ìrì sí Israẹli
    wọn o sì yọ ìtànná bi ewéko lílì
Bi kedari ti Lebanoni yóò si ta gbòǹgbò
    Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ẹ̀ka rẹ̀ yóò dàgbà,
Dídán ẹwà yóò rẹ̀ dànù bí igi olifi
    Òórùn rẹ yóò sì dàbí igi kedari ti Lebanoni.
Àwọn ènìyàn yóò tún padà gbé lábẹ́ òjijì rẹ̀.
    Yóò rúwé bi ọkà.
Yóò sì yọ ìtànná bi àjàrà,
    òórùn rẹ yóò dàbí ti wáìnì Lebanoni.
Ìwọ Efraimu; Kín ló tún kù tí mo ní ṣe pẹ̀lú ère òrìṣà?
    Èmi ó dá a lóhùn, èmi ó sì ṣe ìtọ́jú rẹ.
Mo dàbí igi junifa tó ń fi gbogbo ìgbà tutù,
    èso tí ìwọ ń so si ń wá láti ọ̀dọ̀ mi.”

(B)Ta ni ọlọ́gbọ́n? Òun yóò mòye àwọn nǹkan wọ̀nyí
    Ta a ní ó mọ̀? Òun yóò ní ìmọ̀ wọn.
Títọ́ ni ọ̀nà Olúwa
    àwọn olódodo si ń rìn nínú wọn
    Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ni yóò kọsẹ̀ nínú wọn.

Saamu 139

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.

139 Olúwa, ìwọ tí wádìí mi,
    ìwọ sì ti mọ̀ mí.
Ìwọ mọ̀ ìjókòó mi àti ìdìde mi,
    ìwọ mọ̀ èrò mi ní ọ̀nà jíjìn réré.
Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi ká àti ìdùbúlẹ̀ mi,
    gbogbo ọ̀nà mi sì di mí mọ̀ fún ọ.
Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi,
    kíyèsi i, Olúwa, ìwọ mọ̀ ọ́n pátápátá.
Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú,
    ìwọ sì fi ọwọ́ rẹ lé mi.
Irú ìmọ̀ yìí jẹ ohun ìyanu fún mi jù;
    ó ga, èmi kò le mọ̀ ọ́n.

Níbo ní èmi yóò gbé lọ kúrò ni ọwọ́ ẹ̀mí rẹ?
    Tàbí níbo ni èmi yóò sáré kúrò níwájú rẹ?
Bí èmi bá gòkè lọ sí ọ̀run, ìwọ wà níbẹ̀;
    bí èmí ba sì tẹ́ ẹní mi ní ipò òkú,
    kíyèsi i, ìwọ wà níbẹ̀ pẹ̀lú.
Èmi ìbá mú ìyẹ́ apá òwúrọ̀,
    kí èmi sì lọ jókòó ní ìhà òpin Òkun;
10 Àní, níbẹ̀ náà ni ọwọ́ rẹ̀ yóò fà mí
    ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì dì mímú.
11 Bí mo bá wí pé, “Ǹjẹ́ kí òkùnkùn kí ó bò mí mọ́lẹ̀;
    kí ìmọ́lẹ̀ kí ó di òru yí mi ká.”
12 Nítòótọ́ òkùnkùn kì í ṣú lọ́dọ̀ rẹ;
    ṣùgbọ́n òru tan ìmọ́lẹ̀ bí ọ̀sán;
    àti òkùnkùn àti ọ̀sán, méjèèjì bákan náà ní fún ọ.

13 Nítorí ìwọ ni ó dá ọkàn mi;
    ìwọ ni ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi.
14 Èmi yóò yìn ọ, nítorí tẹ̀rù tẹ̀rù àti tìyanu tìyanu ní a dá mi;
    ìyanu ní iṣẹ́ rẹ;
    èyí nì ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú
15 Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ,
    nígbà tí a dá mi ní ìkọ̀kọ̀.
    Tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà ní ìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé,
16 ojú rẹ ti rí ohun ara mi
    nígbà tí a kò tí ì ṣe mí pé:
    àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí,
ní ọjọ́ tí a dá wọn,
    nígbà tí wọn kò tilẹ̀ tí ì sí.
17 Ọlọ́run, èrò inú rẹ tí ṣe iyebíye tó fún mi,
    iye wọn ti pọ̀ tó!
18 Èmi ìbá kà wọ́n,
    wọ́n ju iyanrìn lọ ní iye:
nígbà tí mo bá jí,
    èmi yóò wà lọ́dọ̀ rẹ síbẹ̀.

19 Ọlọ́run ìbá jẹ́ pa àwọn ènìyàn búburú nítòótọ́;
    nítorí náà kúrò lọ́dọ̀ mi ẹ̀yin ọkùnrin ẹlẹ́jẹ̀.
20 Ẹni tí ń fi inú búburú sọ̀rọ̀ sí ọ,
    àwọn ọ̀tá rẹ ń pe orúkọ rẹ ní asán!
21 Olúwa, ǹjẹ́ èmi kò kórìíra àwọn tó kórìíra rẹ?
    Ǹjẹ́ inú mi kò a sì bàjẹ́ sí àwọn tí ó dìde sí ọ?
22 Èmi kórìíra wọn ní àkótán;
    èmi kà wọ́n sí ọ̀tá mi.
23 Ọlọ́run, wádìí mi, kí o sì mọ ọkàn mí;
    dán mi wò, kí o sì mọ ìrò inú mi
24 Kí ó sì wò ó bí ipa ọ̀nà búburú
    kan bá wà nínú mi kí ó sì
    fi ẹsẹ̀ mi lé ọ̀nà àìnípẹ̀kun.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.