Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
1 Samuẹli 18

Saulu ń jowú Dafidi

18 Lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ti parí ọ̀rọ̀ tí ó ń bá Saulu sọ, ọkàn Jonatani di ọ̀kan pẹ̀lú ti Dafidi, ó sì fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀. Láti ọjọ́ náà Saulu pa Dafidi mọ́ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ kò sì jẹ́ kí ó padà sí ilé baba rẹ̀ mọ́. Jonatani bá Dafidi dá májẹ̀mú nítorí tí ó fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀. Jonatani sì bọ́ aṣọ ìgúnwà, ó sì fi fun Dafidi pẹ̀lú aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ àti pẹ̀lú idà rẹ̀, ọrun rẹ̀ àti àmùrè rẹ̀.

Ohunkóhun tí Saulu bá rán an láti ṣe, Dafidi máa ṣe ní àṣeyọrí, Saulu náà sì fun un ní ipò tí ó ga jù láàrín àwọn ológun. Eléyìí sì tẹ́ gbogbo ènìyàn lọ́rùn, àti pẹ̀lú ó sì tẹ́ àwọn ìjòyè Saulu lọ́rùn pẹ̀lú.

Nígbà tí àwọn ènìyàn padà sí ilé lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ti pa Filistini, gbogbo àwọn obìnrin tú jáde láti inú ìlú Israẹli wá láti pàdé ọba Saulu pẹ̀lú orin àti ijó, pẹ̀lú orin ayọ̀ àti tambori àti ohun èlò orin olókùn. Bí wọ́n ṣe ń jó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń kọrin pé:

“Saulu pa ẹgbẹ̀rún tirẹ̀
    Dafidi sì pa ẹgbẹẹgbàárún ní tirẹ̀.”

Saulu sì bínú gidigidi, ọ̀rọ̀ náà sì korò létí rẹ̀ pé, “Wọ́n ti gbé ògo fún Dafidi pẹ̀lú ẹgbẹẹgbàárún” ó sì wí pé, “Ṣùgbọ́n èmi pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún kan. Kí ni ó kù kí ó gbà bí kò ṣe ìjọba?” Láti ìgbà náà lọ ni Saulu ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ojú ìlara wo Dafidi.

10 Ní ọjọ́ kejì ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá pẹ̀lú agbára sórí Saulu, ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ilé rẹ̀ nígbà tí Dafidi sì ń fọn ohun èlò orin olókùn, gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń ṣe láti ẹ̀yìn wá, Saulu sì ní ọ̀kọ̀ kan ní ọwọ́ rẹ̀. 11 Ó sì gbé e sókè, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, “Èmi yóò gún Dafidi pọ̀ mọ́ ògiri.” Ṣùgbọ́n, Dafidi yẹ̀ fún un lẹ́ẹ̀méjì.

12 Saulu sì ń bẹ̀rù Dafidi nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú Dafidi, ṣùgbọ́n ó ti fi Saulu sílẹ̀. 13 Ó sì lé Dafidi jáde ní ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì fi jẹ olórí ogun ẹgbẹ̀rún kan, Dafidi ń kó wọn lọ, ó ń kó wọn bọ̀ nínú ìgbòkègbodò ogun. 14 Dafidi sì ṣe ọlọ́gbọ́n ní gbogbo ìṣe rẹ̀, nítorí tí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀. 15 Nígbà tí Saulu rí bi àṣeyọrí rẹ̀ ti tó, ó sì bẹ̀rù rẹ̀. 16 Ṣùgbọ́n gbogbo Israẹli àti Juda ni wọ́n fẹ́ràn Dafidi, nítorí ó darí wọn lọ ní ìgbòkègbodò ogun wọn.

17 Saulu wí fún Dafidi pé, “Èyí ni àgbà nínú àwọn ọmọbìnrin mi Merabu. Èmi yóò fi òun fún ọ ní aya. Kí ìwọ sìn mí bí akọni, kí o sì máa ja ogun Olúwa.” Nítorí tí Saulu wí fún ara rẹ̀ pé, “Èmi kì yóò gbé ọwọ́ mi sókè sí i. Jẹ́ kí àwọn Filistini ṣe èyí.”

18 Ṣùgbọ́n Dafidi wí fún Saulu pé, “Ta ni mí, kí sì ni ìdílé mi tàbí ìdílé baba mi ní Israẹli, tí èmi yóò di àna ọba?” 19 Nígbà tí àkókò tó fún Merabu, ọmọbìnrin Saulu, láti fi fún Dafidi, ni a sì fi fún Adrieli ará Mehola ní aya.

20 Nísinsin yìí ọmọbìnrin Saulu Mikali sì fẹ́ràn Dafidi, nígbà tí wọ́n sọ fún Saulu nípa rẹ̀, ó sì dùn mọ́ ọn. 21 Ó sọ nínú ara rẹ̀ pé, “Èmi yóò fi fún un kí òun ba à le jẹ́ ìkẹ́kùn fún un, kí ọwọ́ àwọn ará Filistini lè wà lára rẹ̀.” Nígbà náà ni Saulu wí fún Dafidi pé, “Nísinsin yìí ìwọ ní àǹfààní eléyìí láti jẹ́ àna án mi.”

22 Saulu pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ sọ fún Dafidi ní ìkọ̀kọ̀, kí ẹ sì wí pé, ‘Wò ó, inú ọba dùn sí ọ, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni ó fẹ́ràn rẹ, nísinsin yìí jẹ́ àna ọba.’ ”

23 Wọ́n tún ọ̀rọ̀ náà sọ fún Dafidi. Ṣùgbọ́n Dafidi wí pé, “Ṣé ẹ rò pé ohun kékeré ni láti jẹ́ àna ọba? Mo jẹ́ tálákà ènìyàn àti onímọ̀ kékeré.”

24 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ Saulu sọ fún un ohun tí Dafidi sọ, 25 Saulu dáhùn pé, “Sọ fún Dafidi pé, ‘ọba kò fẹ́ owó orí láti ọ̀dọ̀ àna rẹ̀ ju awọ iwájú orí ọgọ́rùn-ún Filistini lọ láti fi gba ẹ̀san lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.’ ” Èrò Saulu ni wí pé kí Dafidi ṣubú sí ọwọ́ àwọn ará Filistini.

26 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ sọ àwọn nǹkan yìí fún Dafidi, inú rẹ̀ dùn láti di àna ọba kí àkókò tí ó dá tó kọjá, 27 Dafidi àti àwọn arákùnrin rẹ̀ jáde lọ wọ́n sì pa igba lára àwọn Filistini. Ó kó awọ iwájú orí wọn wá, ó sì pé iye tí ọba fẹ́ kí ó ba à lè jẹ́ àna ọba. Saulu sì fi ọmọ obìnrin Mikali fún un ní aya.

28 Nígbà tí Saulu sì wá mọ̀ pé Olúwa wà pẹ̀lú Dafidi tí ọmọbìnrin rẹ̀ Mikali sì fẹ́ràn Dafidi, 29 Saulu sì tún wá bẹ̀rù Dafidi síwájú àti síwájú, Saulu sì wá di ọ̀tá Dafidi fún gbogbo ọjọ́ rẹ̀ tókù.

30 Àwọn ọmọ-aládé Filistini tún tẹ̀síwájú láti lọ sí ogun, ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n lọ, Dafidi ṣe àṣeyọrí ju gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Saulu lọ, orúkọ rẹ̀ sì gbilẹ̀.

Romu 16

Ìkíni

16 Mo fi Febe arábìnrin wa le yin lọ́wọ́, ẹni tí ó jẹ́ díákónì nínú ìjọ tí ó wà ní Kenkerea. Mo rọ̀ yín kí ẹ gbà á ní orúkọ Olúwa, bí ó ti yẹ fún àwọn ènìyàn mímọ́, kí ẹ̀yin kí ó sì ràn án lọ́wọ́ ní gbogbo ọ̀nà, nítorí pé òun jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àti fún èmi náà pẹ̀lú.

(A)Ẹ kí Priskilla àti Akuila, àwọn tí ó ti jẹ́ alábáṣiṣẹ́pọ̀ mi nínú Kristi Jesu. Àwọn tí wọ́n ti fi ẹ̀mí wọn wéwu nítorí mi. Kì í ṣe èmi nìkan àti gbogbo àwọn ìjọ àwọn aláìkọlà ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn.

(B)Kí ẹ sì kí ìjọ tí ń péjọpọ̀ ní ilé wọn.

Ẹ kí Epenetu ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, òun ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó di ti Kristi ní orílẹ̀-èdè Asia.

Ẹ kí Maria, ẹni tí ó ṣe làálàá púpọ̀ lórí wa.

Ẹ kí Androniku àti Junia, àwọn ìbátan mi tí wọ́n wà ní ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú mi. Àwọn wọ̀nyí ní ìtayọ láàrín àwọn aposteli, wọ́n sì ti wà nínú Kristi ṣáájú mi.

Ẹ kí Ampliatu, ẹni tí ó jẹ́ olùfẹ́ mi nínú Olúwa.

Ẹ kí Urbani, alábáṣiṣẹ́pọ̀ wa nínú Kristi àti olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n Staki.

10 Ẹ kí Apelle, ẹni tí a mọ̀ dájú nínú Kristi.

Ẹ kí gbogbo àwọn ará nílé Aristobulu.

11 Ẹ kí Herodioni, ìbátan mi.

Ẹ kí gbogbo àwọn ará nílé Narkissu tí wọ́n wá nínú Olúwa.

12 Ẹ kí Trifena àti Trifosa, àwọn obìnrin tí wọ́n ṣe iṣẹ́ takuntakun nínú Olúwa.

Ẹ kí Persi ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, obìnrin mìíràn tí ó ṣe iṣẹ́ takuntakun nínú Olúwa.

13 Ẹ kí Rufusi, ẹni tí a yàn nínú Olúwa, àti ìyá rẹ̀ àti ẹni tí ó ti jẹ́ ìyá fún èmi náà pẹ̀lú.

14 Ẹ kí Asinkritu, Flegoni, Herma, Patroba, Hermesi àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí ó wà pẹ̀lú wọn.

15 Ẹ kí Filologu, àti Julia, Nereu, àti arábìnrin rẹ̀, àti Olimpa, àti gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà pẹ̀lú wọn.

16 (C)Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín.

Gbogbo ìjọ Kristi kí yín.

17 (D)Èmí rọ̀ yín, ara, kí ẹ máa sọ àwọn tí ń fa ìyapa, àti àwọn tí ń mú ohun ìkọ̀sẹ̀ wá sí ọ̀nà yín, èyí tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ẹ̀yin kọ́. Ẹ yà kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn. 18 Nítorí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò sin Kristi Olúwa wa, bí kò ṣe ikùn ara wọn. Nípa ọ̀rọ̀ rere àti ọ̀rọ̀ dídùndídùn ni wọ́n fi ń yí àwọn aláìmọ̀kan ní ọkàn padà. 19 (E)Nítorí ìgbọ́ràn yín tànkálẹ̀ dé ibi gbogbo, nítorí náà mo ní ayọ̀ lórí yín; ṣùgbọ́n èmi fẹ́ kí ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n sí ohun tí ó ṣe rere, kí ẹ sì ṣe òpè sí ohun tí í ṣe búburú.

20 (F)Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì tẹ Satani mọ́lẹ̀ ní àtẹ́lẹsẹ̀ yín ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí.

Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa kí ó wà pẹ̀lú yín.

21 (G)Timotiu alábáṣiṣẹ́ mi, àti Lukiu, àti Jasoni, àti Sosipateru, àwọn ìbátan mi, kí yín.

22 Èmi Tertiu tí ń kọ lẹ́tà yìí, kí yín nínú Olúwa.

23 (H)Gaiu, ẹni tí èmi àti gbogbo ìjọ gbádùn ìtọ́jú wa tí ó ṣe náà fi ìkíni ránṣẹ́.

Erastu, ẹni tí ó jẹ́ olùtọ́jú ìṣúra ìlú, àti arákùnrin wa Kuartu fi ìkíni wọn ránṣẹ́.

24 Ǹjẹ́ kí oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa, kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín. Àmín.

25 Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó ní agbára láti fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀ nípa ìhìnrere mi àti ìpolongo Jesu Kristi, gẹ́gẹ́ bí ìṣípayá ohun ìjìnlẹ̀ tí a ti pamọ́ láti ìgbà ayérayé, 26 ṣùgbọ́n, nísinsin yìí, a ti fihàn nípa ìwé mímọ́ àwọn wòlíì, àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run ayérayé pa, kí gbogbo orílẹ̀-èdè le ní ìgbọ́ràn tí ó wá láti inú ìgbàgbọ́; 27 kí ògo wà fún Ọlọ́run, Ẹnìkan ṣoṣo tí ọgbọ́n í ṣe tirẹ̀ nípa Jesu Kristi títí láé! Àmín.

Ẹkun Jeremiah 3

Èmi ni ọkùnrin tí ó rí ìpọ́njú
    pẹ̀lú ọ̀pá ìbínú rẹ.
Ó ti lé mi jáde ó sì mú mi rìn
    nínú òkùnkùn ju ti ìmọ́lẹ̀;
Nítòótọ́, ó ti yí ọwọ́ padà sí mi
    síwájú àti síwájú sí i ní gbogbo ọjọ́.

Ó jẹ́ kí àwọ̀ mi àti ẹran-ara mi gbó
    ó sì tún ṣẹ́ egungun mi.
Ó ti fi mí sí ìgbèkùn, ó sì ti yí mi ká
    pẹ̀lú ìkorò àti làálàá.
Ó mú mi gbé nínú òkùnkùn,
    bí ti àwọn tó ti kú fún ìgbà pípẹ́.

Ó ti tì mí mọ́ ilé, nítorí náà n kò le è sálọ;
    ó ti fi ẹ̀wọ̀n mú mi mọ́lẹ̀.
Pàápàá nígbà tí mo ké fún ìrànlọ́wọ́,
    ó kọ àdúrà mi.
Ó fi ògiri òkúta dí ọ̀nà mi;
    ó sì mú ọ̀nà mi wọ́.

10 Bí i beari tí ó dùbúlẹ̀,
    bí i kìnnìún tí ó sápamọ́.
11 Ó wọ́ mi kúrò ní ọ̀nà, ó tẹ̀ mí mọ́lẹ̀
    ó fi mi sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́.
12 Ó fa ọfà rẹ̀ yọ
    ó sì fi mí ṣe ohun ìtafàsí.

13 Ó fa ọkàn mí ya
    pẹ̀lú ọfà nínú àkọ̀ rẹ̀.
14 Mo di ẹni yẹ̀yẹ́ láàrín àwọn ènìyàn mi;
    wọn yẹ̀yẹ́ mi pẹ̀lú orin ní gbogbo ọjọ́.
15 Ó ti kún mi pẹ̀lú ewé kíkorò
    àti ìdààmú bí omi.

16 Ó ti fi òkúta kán eyín mi;
    ó ti tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ nínú eruku.
17 Mo ti jìnnà sí àlàáfíà;
    mo ti gbàgbé ohun tí àṣeyege ń ṣe.
18 Nítorí náà mo wí pé, “Ògo mi ti lọ
    àti ìrètí mi nínú Olúwa.”

19 Mo ṣe ìrántí ìpọ́njú àti ìdààmú mi,
    ìkorò àti ìbànújẹ́.
20 Mo ṣèrántí wọn,
    ọkàn mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.
21 Síbẹ̀, èyí ni mo ní ní ọkàn
    àti nítorí náà ní mo nírètí.

22 Nítorí ìfẹ́ Olúwa tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé,
    nítorí ti àánú rẹ kì í kùnà.
23 Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀;
    títóbi ni òdodo rẹ̀.
24 Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni Olúwa;
    nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́.

25 Dídára ni Olúwa fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀,
    sí àwọn tí ó ń wá a.
26 Ó dára kí a ní sùúrù
    fún ìgbàlà Olúwa.
27 Ó dára fún ènìyàn láti gbé àjàgà
    nígbà tí ó wà ní èwe.

28 Jẹ́ kí ó jókòó ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́,
    nítorí Olúwa ti fi fún un.
29 Jẹ́ kí ó bo ojú rẹ̀ sínú eruku—
    ìrètí sì lè wà.
30 Jẹ́ kí ó fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ fún àwọn tí yóò gbá a,
    sì jẹ́ kí ó wà ní ìdójútì.

31 Ènìyàn kò di ìtanù
    lọ́dọ̀ Olúwa títí láé.
32 Lóòtítọ́ ó mú ìbànújẹ́ wá, yóò fi àánú hàn,
    nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ̀.
33 Nítorí kò mọ̀ ọ́n mọ̀ mú ìpọ́njú wá
    tàbí ìrora wá fún ọmọ ènìyàn.

34 Láti tẹ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀
    gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní ilẹ̀ náà.
35 Láti ṣẹ́ ọmọ ènìyàn fún ẹ̀tọ́ rẹ̀
    níwájú Ọ̀gá-ògo jùlọ.
36 Láti yí ìdájọ́ ènìyàn padà,
    Ǹjẹ́ Olúwa kò rí ohun bẹ́ẹ̀.

37 Ta ni yóò sọ̀rọ̀ tí yóò rí bẹ́ẹ̀
    tí Olúwa kò bá fi àṣẹ sí i.
38 Ǹjẹ́ kì í ṣe láti ẹnu Ọ̀gá-ògo jùlọ
    ni rere àti búburú tí ń wá?
39 Kí ló dé tí ẹ̀dá alààyè ṣe ń kùn
    nígbà tí ó bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀?

40 Ẹ jẹ́ kí a yẹ ọ̀nà wa, kí a sì dán an wò,
    kí a sì tọ Olúwa lọ.
41 Ẹ jẹ́ kí a gbé ọkàn àti ọwọ́ wa sókè
    sí Ọlọ́run ní ọ̀run, kí a wí pé:
42 “Àwa ti ṣẹ̀ a sì ti ṣọ̀tẹ̀
    ìwọ kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá.

43 “Ìwọ fi ìbínú bo ara rẹ ìwọ sì ń lépa wa;
    ìwọ ń parun láìsí àánú.
44 Ìwọ ti fi àwọsánmọ̀ bo ara rẹ
    pé kí àdúrà wa má ba à dé ọ̀dọ̀ rẹ.
45 Ó ti sọ wá di èérí àti ààtàn
    láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo.

46 “Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ti la ẹnu wọn
    gbòòrò sí wa.
47 Àwa ti jìyà àti ìparun,
    nínú ìbẹ̀rù àti ewu.”
48 Omijé ń sàn ní ojú mi bí odò
    nítorí a pa àwọn ènìyàn mi run.

49 Ojú mi kò dá fún omijé,
    láì sinmi,
50 títí ìgbà tí Olúwa yóò ṣíjú wolẹ̀
    láti òkè ọ̀run tí yóò sì rí i.
51 Ohun tí mo rí mú ìbẹ̀rù wá ọkàn mi
    nítorí gbogbo àwọn obìnrin ìlú mi.

52 Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí
    dẹ mí bí ẹyẹ.
53 Wọ́n gbìyànjú láti mú òpin dé bá ayé mi nínú ihò
    wọ́n sì ju òkúta lù mí.
54 Orí mi kún fún omi,
    mo sì rò pé ìgbẹ̀yìn dé.

55 Mo pe orúkọ rẹ, Olúwa,
    láti ọ̀gbun ìsàlẹ̀ ihò.
56 Ìwọ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi: “Má ṣe di etí rẹ
    sí igbe ẹ̀bẹ̀ mi fún ìtura.”
57 O wá tòsí nígbà tí mo ké pè ọ́,
    o sì wí pé, “Má ṣe bẹ̀rù.”

58 Olúwa, ìwọ gba ẹjọ́ mi rò,
    o ra ẹ̀mí mi padà.
59 O ti rí i, Olúwa, búburú tí a ṣe sí mi
    Gbé ẹjọ́ mi ró!
60 Ìwọ ti rí ọ̀gbun ẹ̀san wọn,
    gbogbo ìmọ̀ wọn sí mi.

61 Olúwa ìwọ ti gbọ́ ẹ̀gàn wọn
    àti ìmọ̀ búburú wọn sí mi—
62 Ohun tí àwọn ọ̀tá mi ń sọ
    sí mi ní gbogbo ọjọ́.
63 Wò wọ́n! Ní jíjòkòó tàbí ní dídìde,
    wọ́n ń ṣẹlẹ́yà mi nínú orin wọn.

64 Olúwa san wọ́n lẹ́san ohun tí ó tọ́ sí wọn
    fún ohun tí ọwọ́ wọn ti ṣe.
65 Fi ìbòjú bò wọ́n ní ọkàn,
    kí o sì fi wọ́n ré.
66 Ni wọ́n lára kí o sì pa wọ́n run pẹ̀lú ìbínú,
    lábẹ́ ọ̀run Olúwa.

Saamu 34

Tí Dafidi. Nígbà tí ó díbọ́n bí ẹni tí ń ṣe wèrè níwájú Abimeleki, ẹni tí ó lé e lọ, ó sì jáde lọ.

34 Èmi yóò máa fi ìbùkún fún Olúwa nígbà gbogbo;
    ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi títí láé.
Ọkàn mí yóò máa ṣògo nínú Olúwa;
    jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ gbọ́ kí inú wọn kí ó sì máa dùn.
Gbé Olúwa ga pẹ̀lú mi;
    kí ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ rẹ̀ lékè.

Èmi wá Olúwa, ó sì dá mi lóhùn;
    Ó sì gbà mí kúrò nínú ìbẹ̀rù mi gbogbo.
Wọ́n wò ó, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ wọn;
    ojú kò sì tì wọ́n.
Ọkùnrin olùpọ́njú yí kígbe, Olúwa sì gbóhùn rẹ̀;
    ó sì gbà á là kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.
Angẹli Olúwa yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká
    ó sì gbà wọ́n.

Tọ́ ọ wò kí o sì rí i wí pé Olúwa dára;
    ẹni ayọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ààbò nínú rẹ̀.
Ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́,
    nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
10 Àwọn ọmọ kìnnìún a máa ṣe aláìní ebi a sì máa pa wọ́n;
    ṣùgbọ́n àwọn tí ó wá Olúwa kì yóò ṣe aláìní ohun tí ó dára.
11 Wá, ẹ̀yin ọmọ mi, fi etí sí mi;
    èmi yóò kọ́ ọ yín ní ẹ̀rù Olúwa.
12 (A)Ta ni nínú yín tí ń fẹ́ ìyè, tí ó sì ń fẹ́ ọjọ́ púpọ̀;
    kí ó lè gbádùn ọjọ́ rere?
13 Pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi
    àti ètè rẹ̀ kúrò ní ẹ̀tàn sísọ.
14 Yà kúrò nínú ibi kí o sì ṣe rere;
    wá àlàáfíà, kí o sì lépa rẹ̀.

15 Ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo;
    etí i rẹ̀ sì ṣí sí ẹkún wọn.
16 Ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú;
    láti ké ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.

17 Nígbà tí olódodo bá ké fún ìrànlọ́wọ́,
    Olúwa a máa gbọ́, a sì yọ wọ́n jáde láti inú gbogbo wàhálà wọn.
18 Olúwa súnmọ́ etí ọ̀dọ̀ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn;
    ó sì gba irú àwọn tí í ṣe oníròra ọkàn là.

19 Ìpọ́njú àwọn olódodo pọ̀,
    ṣùgbọ́n Olúwa gbà wọ́n kúrò nínú gbogbo rẹ̀.
20 Ó pa gbogbo egungun wọn mọ́;
    kò sí ọ̀kan tí ó dá nínú wọn.

21 Ibi ni ó mú ikú ìkà wá,
    àti àwọn tí ó kórìíra olódodo ni yóò jẹ̀bi.
22 Olúwa ra ọkàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ padà;
    kò sí ọ̀kan nínú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé tí yóò jẹ̀bi.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.