M’Cheyne Bible Reading Plan
7 1 Nígbà náà àwọn ará Kiriati-Jearimu wá, wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa. Wọ́n gbé e lọ sí ilé Abinadabu lórí òkè, wọ́n sì ya Eleasari ọmọ rẹ̀ sí mímọ́ láti ṣọ́ àpótí ẹ̀rí Olúwa.
Samuẹli ṣẹ́gun àwọn ará Filistini ní Mispa
2 Ó sì jẹ́ ní ìgbà pípẹ́, ogún ọdún ni àpótí ẹ̀rí Olúwa fi wà ní Kiriati-Jearimu. Gbogbo ilé Israẹli ṣọ̀fọ̀ wọ́n sì pohùnréré ẹkún sí Olúwa. 3 Samuẹli sọ fún gbogbo ilé Israẹli pé, “Tí ẹ bá ń padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn yín, Ẹ yẹra kúrò lọ́dọ̀ ọlọ́run àjèjì àti Aṣtoreti kí ẹ sì fi ara yín jì fún Olúwa kí ẹ sì sin òun nìkan ṣoṣo, òun yóò sì gbà yín kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Filistini” 4 Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli yẹra fún Baali àti Aṣtoreti, wọ́n sì sin Olúwa nìkan ṣoṣo.
5 Nígbà náà ni, Samuẹli wí pé, “Ẹ kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ sí Mispa, èmi yóò bẹ̀bẹ̀ fún un yín lọ́dọ̀ Olúwa.” 6 Nígbà tí wọ́n sì ti péjọpọ̀ ní Mispa, wọ́n pọn omi, wọ́n sì dà á sílẹ̀ níwájú Olúwa. Ní ọjọ́ náà, wọ́n gbààwẹ̀, wọ́n sì jẹ́wọ́ pé, “Àwa ti ṣẹ̀ sí Olúwa.” Samuẹli sì jẹ́ olórí àwọn ọmọ Israẹli ní Mispa.
7 Nígbà tí àwọn Filistini gbọ́ pé àwọn Israẹli ti péjọ ní Mispa, àwọn aláṣẹ Filistini gòkè wá láti kọlù wọ́n. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ èyí, Ẹ̀rù bà wọ́n nítorí àwọn Filistini. 8 Wọ́n sọ fún Samuẹli pé, “Má ṣe dákẹ́ kíké pe Olúwa Ọlọ́run wa fún wa, ké pè é kí ó lè gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn Filistini.” 9 Nígbà náà ni Samuẹli mú ọ̀dọ́-àgùntàn tí ó jẹ́ ọmọ ọmú, ó sì fi rú ẹbọ sísun sí Olúwa. Ó sí ké pe Olúwa nítorí ilé Israẹli, Olúwa sì dá a lóhùn.
10 Nígbà tí Samuẹli ń ṣe ìrúbọ ẹbọ sísun, àwọn Filistini súnmọ́ tòsí láti bá Israẹli ja ogun. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ náà, Olúwa sán àrá ńlá lu àwọn Filistini, ó sì mú jìnnìjìnnì bá wọn, a sì lé wọn níwájú àwọn ọmọ Israẹli. 11 Àwọn ọkùnrin Israẹli tú jáde láti Mispa. Wọ́n sì ń lépa àwọn Filistini, wọ́n sì pa wọ́n ní àpá rìn títí dé abẹ́ Beti-Kari.
12 Samuẹli mú òkúta kan ó sì fi lélẹ̀ láàrín Mispa àti Ṣeni, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ebeneseri, wí pé, “Ibí ni Olúwa ràn wá lọ́wọ́ dé.” 13 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣẹ́gun Filistini, wọn kò sì wá sí agbègbè àwọn ọmọ Israẹli mọ́.
Ní gbogbo ìgbésí ayé Samuẹli, ọwọ́ Olúwa lòdì sí àwọn Filistini. 14 Àwọn ìlú láti Ekroni dé Gati tí àwọn Filistini ti gbà lọ́wọ́ Israẹli ni ó ti gbà padà fún Israẹli, ó sì gba gbogbo ilẹ̀ agbègbè rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìṣàkóso àwọn Filistini. Ìrẹ́pọ̀ sì wà láàrín Israẹli àti àwọn Amori.
15 Samuẹli tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́ bí adájọ́ lórí Israẹli. Ní ọjọ́ ayé e rẹ̀. 16 Láti ọdún dé ọdún, ó lọ yíká láti Beteli dé Gilgali dé Mispa, ó sì ń ṣe ìdájọ́ Israẹli ní gbogbo ibi wọ̀nyí. 17 Ṣùgbọ́n ó máa ń padà sí ilé rẹ̀ ní Rama, níbí tí ilé rẹ̀ wà, ó sì túnṣe ìdájọ́ Israẹli níbẹ̀, ó sì kọ́ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Olúwa.
Israẹli béèrè fún ọba
8 Nígbà tí Samuẹli di arúgbó, ó yan àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí adájọ́ fún Israẹli. 2 Orúkọ àkọ́bí rẹ̀ a máa jẹ́ Joeli àti orúkọ èkejì a máa jẹ́ Abijah, wọ́n ṣe ìdájọ́ ní Beerṣeba. 3 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ rẹ̀, kò rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Wọ́n yípadà sí èrè àìṣòótọ́, wọ́n gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ń yí ìdájọ́ po.
4 Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo àwọn àgbàgbà ti Israẹli péjọpọ̀, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ Samuẹli ní Rama. 5 Wọ́n wí fún un pé, “Ìwọ ti di arúgbó, àwọn ọmọ rẹ kò sì rìn ní ọ̀nà rẹ: Nísinsin yìí, yan ọba fún wa kí ó lè máa darí wa gẹ́gẹ́ bí i tí gbogbo orílẹ̀-èdè.”
6 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n wí pé, “Fún wa ní ọba tí yóò darí wa” Èyí kò tẹ́ Samuẹli lọ́rùn, ó sì gbàdúrà sí Olúwa. 7 Olúwa sì sọ fún Samuẹli pé: “Gbọ́ ohùn àwọn ènìyàn náà, ní gbogbo èyí tí wọ́n sọ fún ọ; nítorí kì í ṣe ìwọ ni wọ́n kọ̀, ṣùgbọ́n Èmi ni wọ́n kọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba lórí wọn. 8 Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní ọjọ́ tí mo mú wọn jáde wá láti Ejibiti títí di ọjọ́ òní, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì ń sin ọlọ́run mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe sí ọ. 9 Nísinsin yìí, gbọ́ tiwọn; ṣùgbọ́n kìlọ̀ fún wọn dáradára, kí o sì jẹ́ kí wọ́n mọ irú ohun tí ọba tí yóò jẹ́ lórí wọn yóò ṣe.”
10 Samuẹli sọ gbogbo ọ̀rọ̀ Olúwa sí àwọn ọmọ ènìyàn tí ó ń béèrè fún ọba lọ́wọ́ rẹ̀. 11 Ó wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba tí yóò jẹ lórí yín yóò ṣe. Yóò kó àwọn ọmọkùnrin yín, yóò sì mú wọn ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti fún ẹlẹ́ṣin rẹ, wọn yóò sì máa sáré níwájú kẹ̀kẹ́ rẹ̀. 12 Yóò yan díẹ̀ láti jẹ́ olórí ẹgbẹ̀rún àti olórí àádọ́ta àti àwọn mìíràn. Yóò yan wọ́n láti máa tulẹ̀ oko rẹ̀ àti láti máa kórè rẹ̀ àti àwọn mìíràn láti máa ṣe ohun èlò ogun àti ohun èlò kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀. 13 Yóò mú àwọn ọmọbìnrin yín láti máa ṣe olùṣe ìkunra olóòórùn dídùn àti láti máa ṣe àsè àti láti máa ṣe àkàrà. 14 Yóò mú èyí tí ó dára jù nínú oko yín, àti nínú ọgbà àjàrà yín àti nínú igi olifi yín, yóò sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. 15 Yóò mú ìdásímẹ́wàá hóró ọkà yín àti àká èso àjàrà yín, yóò sì fi fún àwọn oníṣẹ́ àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. 16 Àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin yín àti èyí tí ó dára jù nínú ẹran ọ̀sìn àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín ni yóò mú fún ìlò ti ara rẹ̀. 17 Yóò sì mú ìdámẹ́wàá nínú àwọn agbo ẹran yín, yóò sì máa ṣe ẹrú u rẹ̀. 18 Tí ọjọ́ náà bá dé, ẹ̀yin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ ọba tí ẹ̀yin ti yàn. Olúwa kò sì ní dá a yín lóhùn ní ọjọ́ náà.”
19 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kọ̀ láti tẹ́tí sí Samuẹli wọ́n wí pé, “Rárá! A bí ìwọ fẹ́ jẹ́ ọba lórí i wa? 20 Nígbà náà àwa yóò dàbí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, pẹ̀lú ọba láti darí i wa àti láti jáde lọ níwájú wa láti ja ogun wa.”
21 Nígbà tí Samuẹli gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn sọ, ó tún tún un sọ níwájú Olúwa. 22 Olúwa dáhùn pé, “Tẹ́tí sí wọn, kí o sì yan ọba fún wọn.”
Nígbà náà, Samuẹli sọ fún àwọn ọkùnrin Israẹli pé, “Kí olúkúlùkù padà sí ìlú u rẹ̀.”
Ikú sí ẹsẹ̀, iyè nínú Kristi
6 (A)Ǹjẹ́ àwa ó ha ti wí? Ṣé kí àwa ó jókòó nínú ẹ̀ṣẹ̀, kí oore-ọ̀fẹ́ ba à lè máa pọ̀ sí i? 2 (B)Kí a má ri! Àwa ẹni tí ó ti kú sí ẹ̀ṣẹ̀, àwa ó ha ṣe wà láààyè nínú rẹ̀ mọ́? 3 (C)Tàbí ẹyin kò mọ pé gbogbo wa ti a ti bamitiisi wa sínú Jesu Kristi ni a ti bamitiisi sínú ikú rẹ. 4 (D)Nítorí náà, a sin wa pẹ̀lú Kristi nípa ìtẹ̀bọmi si ikú, kí ó bá le jẹ́ pe bí a ti jí Kristi dìde pẹ̀lú ògo Baba, àwa pẹ̀lú gbé ìgbé ayé tuntun.
5 (E)Nítorí pé ẹ̀yin ti di ọ̀kan ṣoṣo pẹ̀lú rẹ̀, àti pé ẹ kú pẹ̀lú rẹ̀, nígbà tí òun kú. Nísinsin yìí, ẹ ń pín ìyè tuntun rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì jí dìde gẹ́gẹ́ bí òun náà ti jí dìde. 6 (F)Gbogbo èrò búburú ọkàn yín ni a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀. Ẹ̀mí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sì ń fẹ́ láti máa dẹ́ṣẹ̀ nínú yín ni a ti sọ di aláìlera. Nítorí náà, ara yín tí ó ń fẹ́ láti máa dẹ́ṣẹ̀ kò sí lábẹ́ àkóso ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, kò sì ní láti jẹ́ ẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. 7 (G)Nítorí pé nígbà tí ẹ ti di òkú fún ẹ̀ṣẹ̀, a ti gbà yín sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ gbogbo agbára ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ kò ní agbára lórí yín mọ́.
8 (H)Nísinsin yìí, bí àwa bá kú pẹ̀lú Kristi àwa gbàgbọ́ pé àwa yóò wà láààyè pẹ̀lú rẹ̀. 9 (I)Nítorí àwa mọ̀ pé Kristi ti jí dìde kúrò nínú òkú. Òun kò sì ní kú mọ́. Ikú kò sì lè ní agbára lórí rẹ̀ mọ́. 10 Kristi kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, láti ṣẹ́gun agbára ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó wà láààyè títí ayé àìnípẹ̀kun ní ìdàpọ̀ mímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.
11 (J)Nítorí náà, ẹ ka ara yín bí òkú sí ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n bí alààyè sí Ọlọ́run nínú Kristi Jesu. 12 Nítorí náà kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ jẹ ọba lórí ara kíkú yín kí ó lè ba à máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀. 13 (K)Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀yà ara yín kan di ohun èlò ohun búburú, nípa ẹ̀ṣẹ̀ dídá. Ṣùgbọ́n ẹ fi wọn fún Ọlọ́run pátápátá. Wọ́n ti di ààyè, ẹ jẹ́ kí wọn di ohun èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run, kí ó lè lò wọ́n fún àwọn ìlànà rẹ̀ tí ó dára. 14 (L)Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ kì yóò tún ní ipá lórí yín mọ́, nítorí ẹ̀yin kò sí lábẹ́ ìdè òfin, bí kò ṣe lábẹ́ oore-ọ̀fẹ́.
Ẹrú sí ìṣòdodo
15 (M)Ǹjẹ́ èyí túmọ̀ sí pé, nísinsin yìí, a lè tẹ̀síwájú láti máa dẹ́ṣẹ̀ láìbìkítà, nítorí ìgbàlà wa kò dúró nípa òfin mọ́, bí kò ṣe nípa gbígba oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run! 16 (N)Àbí ẹ̀yin kò mọ̀ pé, ẹnikẹ́ni lè yan ọ̀gá tí ó bá fẹ́? Ẹ lè yan ẹ̀ṣẹ̀ ti o yọrí si ikú tàbí ìgbọ́ràn ti o yọrí sí ìdáláre. Ẹnikẹ́ni tí ẹ bá fi ara yín fún, òun náà ni yóò jẹ́ ọ̀gá yín, ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ẹrú rẹ̀. 17 Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run pé, bí ẹ̀yin ti jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ rí, ẹ̀yin jẹ́ olùgbọ́ran láti ọkàn wá sí àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ èyí tí Ọlọ́run fi lé yín lọ́wọ́. 18 (O)Nísinsin yìí, ẹ ti dòmìnira kúrò lọ́wọ́ ọ̀gá yín àtijọ́, èyí tí í ṣe ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti di ẹrú ọ̀gá tuntun èyí ni òdodo.
19 (P)Èmi ń sọ̀rọ̀ bí ènìyàn nítorí àìlera yín. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yín ti jọ̀wọ́ àwọn ẹ̀yà ara yín lọ́wọ́ bí ẹrú fún ìwà èérí àti ẹ̀ṣẹ̀ dé inú ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí ẹ̀yin kí ó jọ̀wọ́ àwọn ẹ̀yà ara yín lọ́wọ́ nísinsin yìí bí ẹrú fún òdodo sí ìwà mímọ́. 20 (Q)Nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin wà ní òmìnira sí òdodo. 21 (R)Àti pé, kín ni ìyọrísí rẹ̀? Dájúdájú àbájáde rẹ̀ kò dára. Níwọ́n ìgbà tí ojú ń tì ọ́ nísinsin yìí láti ronú nípa àwọn wọ̀n-ọn-nì tí o ti máa ń ṣe nítorí gbogbo wọn yọrí sí ìparun ayérayé. 22 Ṣùgbọ́n báyìí, ẹ ti bọ́ kúrò lọ́wọ́ agbára ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti di ẹrú Ọlọ́run àwọn ìbùkún rẹ̀ sí yin ni ìwà mímọ́ àti ìyè tí kò nípẹ̀kun. 23 (S)Nítorí ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn Ọlọ́run ni ìyè àìnípẹ̀kun nínú Kristi Jesu Olúwa wa.
Àjálù nítorí ṣinṣin òrìṣà
44 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá nípa àwọn Júù tí ń gbé ní ìsàlẹ̀ Ejibiti ní Migdoli, Tafanesi àti Memfisi àti ní apá òkè Ejibiti: 2 “Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: Wo ibi tí mo mú bá Jerusalẹmu àti gbogbo ìlú Juda. Lónìí, wọ́n wà ní ìyapa àti ìparun. 3 Nítorí pé ibi tí wọ́n ti ṣe. Wọ́n mú mi bínú nípa tùràrí fínfín àti nípa bíbọ àwọn òrìṣà, yálà èyí tí ìwọ tàbí àwọn baba rẹ kò mọ̀. 4 Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ní mo rán wòlíì mi, èyí tí ó wí báyìí pé, ‘Má ṣe àwọn ohun ìríra yìí tí èmi kórìíra.’ 5 Ṣùgbọ́n wọn kò fetísílẹ̀ láti fi ọkàn si. Wọn kò sì yípadà kúrò nínú búburú wọn tàbí dáwọ́ ẹbọ sísun sí àwọn òrìṣà dúró. 6 Fún ìdí èyí, ìbínú gbígbóná mi ni èmi yóò yọ sí àwọn ìlú Juda àti òpópó Jerusalẹmu àti sísọ wọ́n di ìparun bí ó ṣe wà lónìí yìí.
7 “Báyìí tún ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Israẹli wí: Kí ló dé tí ẹ fi ń mu ibi ńlá yìí wá sí orí ara yín nípa yíyapa kúrò lára Juda ọkùnrin àti obìnrin, ọmọdé àti èwe, tí ẹ kò sì ku ọ̀kankan? 8 Èéṣe tí ẹ fi mú mi bínú pẹ̀lú ohun tí ọwọ́ yín ṣe pẹ̀lú ẹbọ sísun sí àwọn òrìṣà Ejibiti, níbi tí ẹ wá láti máa gbé? Ẹ̀ ò pa ara yín run, ẹ̀ ó sì sọ ara yín di ẹni ìfiré àti ẹ̀gàn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè ayé gbogbo. 9 Ṣé ẹ̀yin ti gbàgbé ibi tí àwọn baba ńlá yín àti àwọn ọba; àwọn ayaba Juda, àti àwọn ibi tí ẹ ti ṣe àti àwọn ìyàwó yín ní ilẹ̀ Juda àti ní òpópó Jerusalẹmu? 10 Láti ìgbà náà sí àkókò yìí, wọn kò rẹ ara wọn sílẹ̀ tàbí fi ìtẹríba hàn tàbí kí wọn ó tẹ̀lé òfin àti àṣẹ tí mo pa fún un yín àti àwọn baba yín.
11 “Fún ìdí èyí, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn Israẹli wí: Mo ti pinnu láti mú ibi wá sí orí yín àti láti pa Juda run. 12 Èmi yóò sì mú àwọn èérún tí ó kù ní Juda, tí wọ́n ṣetán láti lọ Ejibiti. Wọn yóò ṣubú pẹ̀lú idà tàbí kí wọn kú pẹ̀lú ìyàn láti orí ọmọdé títí dé àgbà ni wọn yóò kú láti ọwọ́ ìyàn tàbí idà. Wọn yóò di ẹni ìfiré àti ìparun, ẹni ẹ̀kọ̀ àti ẹni ẹ̀gàn. 13 Èmi yóò fi ìyà jẹ ẹni tí ó bá ń gbé ní Ejibiti pẹ̀lú idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn bí mo ṣe fi ìyà jẹ Jerusalẹmu. 14 Kò sí èyí tí ó kéré jù nínú Juda tí ó kù, tí ó ń gbé ilẹ̀ Ejibiti tí yóò sá àsálà padà sórí ilẹ̀ Juda, èyí tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ láti padà sí, àti láti máa gbé; àyàfi àwọn aṣàtìpó mélòó kan.”
15 Lẹ́yìn èyí, gbogbo àwọn ọkùnrin tí ẹ bá mọ̀ pé, ìyàwó wọn sun tùràrí sí àwọn òrìṣà pẹ̀lú àwọn obìnrin tí ó bá wá àwọn ènìyàn púpọ̀, pàápàá àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé ní òkè àti ìsàlẹ̀ Ejibiti, bẹ́ẹ̀ ni a wí fún Jeremiah. 16 “Wọn sì wí pé: Àwa kò ní fetísílẹ̀ ọ̀rọ̀ tí o bá bá wa sọ ní orúkọ Olúwa. 17 Dájúdájú; à ó ṣe gbogbo nǹkan tí a sọ pé à ò ṣe: A ó sun tùràrí sí ayaba ọ̀run; à ó sì da ohun mímu sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sí àwa àti àwọn baba wa, àwọn ọba àti àwọn aláṣẹ ti ṣe ní àwọn ìlú Juda àti ni àwọn ìgboro Jerusalẹmu. Nígbà naà àwa ní oúnjẹ púpọ̀ a sì ṣe rere a kò sì rí ibi 18 Ṣùgbọ́n láti ìgbà tí a ti dáwọ́ tùràrí sísun sí Ayaba Ọ̀run àti láti da ẹbọ ohun mímu fún un, àwa ti ṣaláìní ohun gbogbo, a sì run nípa idà àti nípa ìyàn.”
19 Àwọn obìnrin náà fi kún un pé, “Nígbà tí à ń jó tùràrí sí ayaba ọ̀run, tí a sì ń fi ohun mímu rú ẹbọ si; ǹjẹ́ àwọn ọkọ wa kò mọ pé àwa ń ṣe àkàrà bí i, àwòrán rẹ, àti wí pé à ń da ọtí si gẹ́gẹ́ bi ohun ìrúbọ?”
20 Wàyí o, Jeremiah sọ fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, ọkùnrin àti obìnrin, tí wọn sì ń dáhùn pé, 21 “Ṣe Ọlọ́run kò rántí ẹbọ sísun ní ìlú Juda àti àwọn ìgboro Jerusalẹmu láti ọ̀dọ̀ rẹ àti ọ̀dọ̀ àwọn baba rẹ, àwọn ọba àti àwọn aláṣẹ àti àwọn ènìyàn ìlú. 22 Nígbà tí Ọlọ́run kò lè fi ara da ìwà búburú yín àti àwọn nǹkan ìríra gbogbo tí ẹ ṣe, ilẹ̀ yín sì di ohun ìfiré àti ìkọ̀sílẹ̀, láìsí olùgbé gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe wà lónìí. 23 Nítorí pé ẹ ti sun ẹbọ, tí ẹ sì ti ṣẹ̀ sí Olúwa àti pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu, àti pé ẹ kò sì tẹ̀lé òfin rẹ̀ àti àwọn àṣẹ. Ibi náà yóò wá sórí rẹ àti bí o ṣe rí i.”
24 Nígbà náà ni Jeremiah dáhùn pẹ̀lú obìnrin náà pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ọmọ Juda tí ó wà ní Ejibiti. 25 Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: Ìwọ àti àwọn Ìyàwó rẹ fihàn pẹ̀lú àwọn ìhùwà rẹ àti àwọn ohun tí ó ṣèlérí nígbà tí o wí pé, ‘Àwa yóò mú ẹ̀jẹ́ tí a jẹ́ ṣẹ lórí sísun tùràrí àti dída ẹbọ ohun mímu sí orí ère Ayaba Ọ̀run.’
“Tẹ̀síwájú nígbà náà, ṣe ohun tí o sọ, kí o sì mú ẹ̀jẹ́ rẹ ṣẹ. 26 Ṣùgbọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Olódùmarè, gbogbo ẹ̀yin Júù tí ń gbé ilẹ̀ Ejibiti, mo gégùn ún: ‘Mo búra pẹ̀lú títóbi orúkọ mi,’ bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, ‘wí pé, kò sí ẹnikẹ́ni láti Juda tí ń gbé ibikíbi ní Ejibiti ni tí ó gbọdọ̀ ké pe orúkọ mi tàbí búra. “Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó dá wa ti wà láààyè.” 27 Nítorí náà, èmi ó ṣọ wọ́n fún ibi, kì í ṣe fún rere. Àti gbogbo àwọn ọkùnrin Juda tí ó wà ní ilẹ̀ Ejibiti ni a ó parun pẹ̀lú idà àti ìyàn títí tí gbogbo wọn yóò fi tán. 28 Àwọn tí ó bá sá àsálà kúrò lọ́wọ́ ìparun idà àti pípadà sí ilẹ̀ Juda láti Ejibiti yóò kéré níye. Gbogbo àwọn tí ó bá kú ní ilẹ̀ Juda, tí ó wá gbé ilẹ̀ Ejibiti yóò mọ ọ̀rọ̀ ẹni tí yóò dúró yálà tèmi tàbí tiyín.
29 “ ‘Èyí ni yóò jẹ́ ààmì fún un yín pé èmi yóò fi ìyà jẹ yín níbi tí Olúwa ti sọ láti lè jẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ìjìyà mi tí mo sọ pé ẹ̀ ó jẹ yóò ṣẹ.’ 30 Báyìí ni Olúwa wí: ‘Èmi yóò fi Farao Hofira ọba Ejibiti lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́, èyí tí ó lè pa ayé rẹ́; gẹ́gẹ́ bí mo ti fi Sedekiah ọba Juda lé Nebukadnessari ọba Babeli lọ́wọ́ ọ̀tá tó ń lépa ẹ̀mí rẹ̀.’ ”
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
20 Kí Olúwa kí ó gbóhùn rẹ ní ọjọ́ ìpọ́njú;
kí orúkọ Ọlọ́run Jakọbu kí ó dáàbò bò ọ́.
2 Kí ó rán ìrànlọ́wọ́ sí ọ, láti ibi mímọ́
kí ó sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Sioni wá.
3 Kí ó sì rántí gbogbo ẹbọ rẹ
kí ó sì gba ẹbọ sísun rẹ. Sela
4 Kí ó fi fún ọ gẹ́gẹ́ bi ti èrò ọkàn rẹ
kí ó sì mú gbogbo ìmọ̀ rẹ ṣẹ.
5 Àwa yóò hó fún ayọ̀ nígbà tí o bá di aṣẹ́gun
àwa yóò gbé àsíá wa sókè ní orúkọ Ọlọ́run wa.
Kí Ọlọ́run kí ó mú gbogbo ìbéèrè rẹ̀ ṣẹ.
6 Nísinsin yìí, èmi mọ̀ wí pé:
Olúwa pa ẹni ààmì òróró rẹ̀ mọ́.
Yóò gbọ́ láti ọ̀run mímọ́ rẹ̀ wá
pẹ̀lú agbára ìgbàlà ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.
7 Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé kẹ̀kẹ́, àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé ẹṣin,
ṣùgbọ́n àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa Ọlọ́run wa.
8 Wọ́n wólẹ̀, ní eékún, wọ́n sì ṣubú,
ṣùgbọ́n àwa dìde, a sì dúró ṣinṣin.
9 Olúwa, fi ìṣẹ́gun fún ọba!
Dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń kígbe pè!
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
21 Háà! Olúwa, ọba yóò yọ̀ nínú agbára rẹ,
àti ní ìgbàlà rẹ, yóò ti yọ̀ pẹ́ tó!
2 Nítorí pé ìwọ ti fi ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ fún un,
bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò sì dùn ún ní ìbéèrè ẹnu rẹ̀. Sela.
3 Ìwọ ti fi àwọn ìbùkún oore kò ó ni ọ̀nà
ìwọ fi adé wúrà dé e ní orí.
4 Ó béèrè fún ìyè, ìwọ sì fi fún un,
àní ọjọ́ gígùn títí ayérayé.
5 Ògo rẹ̀ pọ̀ nípasẹ̀ ìṣẹ́gun tí o fi fún un;
ìwọ sì jẹ́ kí iyì ọláńlá rẹ̀ wà lára rẹ.
6 Dájúdájú, ìwọ ti fi ìbùkún ayérayé fún un:
ìwọ sì mú inú rẹ̀ dùn pẹ̀lú ayọ̀ ojú u rẹ̀.
7 Ọba ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa;
nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọ̀gá-ògo tí kì í kùnà
kì yóò sípò padà.
8 Ọwọ́ rẹ yóò wá gbogbo àwọn ọ̀tá a rẹ rí;
ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò wá àwọn tí o kórìíra rẹ rí.
9 Nígbà tí ìwọ bá yọ
ìwọ yóò mú wọn dàbí iná ìléru.
Olúwa yóò gbé wọn mì nínú ìbínú rẹ̀,
àti pé iná rẹ̀ yóò jó wọn run.
10 Ìwọ yóò pa ìrandíran wọn run kúrò lórí ilẹ̀,
àti irú-ọmọ wọn kúrò láàrín àwọn ọmọ ènìyàn.
11 Bí o tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n ro èrò ibi sí ọ
wọ́n sì ń pète ìwà ìkà, wọn kì yóò ṣe àṣeyọrí.
12 Nítorí pé ìwọ yóò mú wọn yí ẹ̀yìn wọn padà
nígbà tí o bá pinnu láti ta wọ́n ní ọfà.
13 Gbígbéga ni ọ́ Olúwa, nínú agbára rẹ;
a ó kọrin, a ó yín agbára a rẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.