M’Cheyne Bible Reading Plan
Ọ̀rọ̀ ìdágbére Samuẹli
12 Samuẹli sì wí fún gbogbo Israẹli pé, “Èmi tí gbọ́ gbogbo ohun tí ẹ sọ fún mi, èmi sì ti yan ọba fún un yín. 2 Nísinsin yìí ẹ ti ní ọba bí olórí yín. Bí ó ṣe tèmi, èmi ti di arúgbó, mo sì ti hewú, àwọn ọmọ mi sì ń bẹ níhìn-ín yìí pẹ̀lú yín. Èmi ti ń ṣe olórí yín láti ìgbà èwe mi wá títí di òní yìí. 3 Èmi dúró níhìn-ín yìí, ẹ jẹ́rìí sí mi níwájú Olúwa àti níwájú ẹni ààmì òróró rẹ̀. Màlúù ta ni mo gbà rí? Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ta ni mo gbà rí? Ta ni mo rẹ́ jẹ rí? Ọwọ́ ta ni mo ti gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kan rí láti fi bo ara mi lójú? Bí mo bá ti ṣe nǹkan kan nínú ohun wọ̀nyí, èmi yóò sì san án padà fún yín.”
4 Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Ìwọ kò rẹ́ wa jẹ tàbí pọ́n wa lójú rí, ìwọ kò sì gba ohunkóhun lọ́wọ́ ẹnìkankan.”
5 Samuẹli sì wí fún wọn pé, “Olúwa ni ẹlẹ́rìí sí i yín, àti ẹni ààmì òróró rẹ̀ ni ẹlẹ́rìí lónìí pé, ẹ̀yin kò rí ohunkóhun lọ́wọ́ mi.”
Wọ́n sì sọ wí pé, “Òun ni ẹlẹ́rìí.”
6 Nígbà náà ni Samuẹli wí fún àwọn ènìyàn náà pé, “Olúwa ni ó yan Mose àti Aaroni àti ti ó mú àwọn baba ńlá yín gòkè wá láti Ejibiti. 7 Nísinsin yìí, ẹ dúró níbi, nítorí èmi ń lọ láti bá a yín sọ̀rọ̀ níwájú Olúwa ní ti gbogbo ìṣe òdodo rẹ̀ tí ó ti ṣe fún un yín àti fún àwọn baba yín.
8 “Lẹ́yìn ìgbà tí Jakọbu wọ Ejibiti, wọ́n ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa sì rán Mose àti Aaroni, tí wọ́n mú àwọn baba ńlá yín jáde láti Ejibiti láti mú wọn jókòó níbí yìí.
9 “Ṣùgbọ́n wọ́n gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tà wọ́n sí ọwọ́ àwọn Sisera, olórí ogun Hasori, àti sí ọwọ́ àwọn Filistini àti sí ọwọ́ ọba Moabu, tí ó bá wọn jà. 10 Wọ́n kégbe pe Olúwa, wọ́n sì wí pé, ‘Àwa ti ṣẹ̀; a ti kọ Olúwa sílẹ̀, a sì ti sin Baali, àti Aṣtoreti. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, àwa yóò sì sìn ọ́.’ 11 Nígbà náà ni Olúwa rán Jerubbaali, Bedani, Jefta àti Samuẹli, ó sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá a yín gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ń gbé ní àlàáfíà.
12 “Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin sì rí i pé Nahaṣi ọba àwọn Ammoni dìde sí i yín, ẹ sọ fún mi pé, ‘Rárá, àwa ń fẹ́ ọba tí yóò jẹ́ lórí wa,’ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa Ọlọ́run yín jẹ́ ọba yín. 13 Nísinsin yìí èyí ni ọba tí ẹ̀yin ti yàn, tí ẹ̀yin béèrè fún; wò ó, Olúwa ti fi ọba jẹ lórí yín. 14 Bí ẹ̀yin bá bẹ̀rù Olúwa àti bí ẹ̀yin bá ń sìn ín, tí ẹ sì gbọ́ tirẹ̀, tí ẹ̀yin kò sì ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀, àti tí ẹ̀yin àti ọba tí ó jẹ lórí yín bá ń tẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run yín: ó dára 15 ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá gbọ́ tí Olúwa, tí ẹ sì ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ yóò wà lára yín sí ibi, bí ó ti wà lára baba yín.
16 “Nítorí náà, ẹ dúró jẹ́ẹ́ kí ẹ sì wo ohun ńlá yìí tí Olúwa fẹ́ ṣe ní ojú u yín! 17 Òní kì í ha á ṣe ọjọ́ ìkórè ọkà alikama bí? Èmi yóò ké pe Olúwa kí ó rán àrá àti òjò. Ẹ̀yin yóò sì mọ irú ohun búburú tí ẹ ti ṣe níwájú Olúwa nígbà tí ẹ̀ ń béèrè fún ọba.”
18 Nígbà náà ni Samuẹli ké pe Olúwa, Olúwa sì rán àrá àti òjò ní ọjọ́ náà. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ènìyàn sì bẹ̀rù Olúwa àti Samuẹli púpọ̀.
19 Gbogbo àwọn ènìyàn sì wí fún Samuẹli pé, “Gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ kí a má ba à kú, nítorí tí àwa ti fi búburú yìí kún ẹ̀ṣẹ̀ wa ní bíbéèrè fún ọba.”
20 Samuẹli sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ ti ṣe gbogbo búburú yìí; síbẹ̀ ẹ má ṣe yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n ẹ fi gbogbo àyà yín sin Olúwa. 21 Ẹ má ṣe yípadà sọ́dọ̀ àwọn òrìṣà. Wọn kò le ṣe ohun rere kan fún un yín, tàbí kí wọ́n gbà yín là, nítorí asán ni wọ́n. 22 Nítorí orúkọ ńlá rẹ̀ Olúwa kì yóò kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀, nítorí tí inú Olúwa dùn láti fi yín ṣe ènìyàn rẹ̀. 23 Bí ó ṣe ti èmi ni, kí á má rí i pé èmi dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa nípa dídẹ́kun àti gbàdúrà fún un yín. Èmi yóò sì kọ́ ọ yín ní ọ̀nà rere àti ọ̀nà òtítọ́. 24 Ṣùgbọ́n ẹ rí i dájú pé, ẹ bẹ̀rù Olúwa, kí ẹ sì sìn ín nínú òtítọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn an yín; Ẹ kíyèsi ohun ńlá tí ó ti ṣe fún un yín. 25 Síbẹ̀ bí ẹ̀yin bá ń ṣe búburú, ẹ̀yin àti ọba yín ni a ó gbá kúrò.”
10 Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ìfẹ́ ọkàn àti àdúrà mi sí Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn Israẹli ni kí wọ́n le ní ìgbàlà. 2 (A)Nítorí mo gba ẹ̀rí wọn jẹ́ wí pé, wọ́n ní ìtara fún Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀. 3 (B)Nítorí bí wọn kò tí mọ òdodo Ọlọ́run, tí wọ́n si ń wá ọ̀nà láti gbé òdodo ara wọn kalẹ̀, wọn kò tẹríba fún òdodo Ọlọ́run. 4 (C)Nítorí Kristi ni òpin òfin sí òdodo fún olúkúlùkù ẹni tí ó gbà á gbọ́.
5 (D)Mose ṣá kọ èyí nípa òdodo tí í ṣe ti òfin pé, “Ẹni tí ó ba ṣe, yóò yè nípa wọn.” 6 (E)Ṣùgbọ́n òdodo tí í ṣe ìgbàgbọ́ wí pé, “Má ṣe wí ni ọkàn rẹ̀ pé, ta ni yóò gòkè lọ si ọ̀run?” (èyí i ni ni, láti mú Kristi sọ̀kalẹ̀) 7 “tàbí, ta ni yóò sọ̀kalẹ̀ lọ si ọ̀gbun?” (èyí i ni ni, láti mú Kristi gòkè ti inú òkú wá). 8 (F)Ṣùgbọ́n kí ni ó wí? “Ọ̀rọ̀ náà wà létí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ní ẹnu rẹ̀, àti ní ọkàn rẹ̀,” èyí nì ni ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́, tí àwa ń wàásù; 9 (G)Pé, bí ìwọ bá fi ẹnu rẹ̀ jẹ́wọ́ “Jesu ní Olúwa,” tí ìwọ si gbàgbọ́ ní ọkàn rẹ pé, Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òku, a ó gbà ọ́ là. 10 Nítorí ọkàn ni a fi ìgbàgbọ́ sí òdodo; ẹnu ni a sì ń fi ìjẹ́wọ́ sí ìgbàlà. 11 (H)Nítorí ìwé Mímọ́ wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà a gbọ́ ojú kò yóò tì í.” 12 (I)Nítorí kò si ìyàtọ̀ nínú Júù àti Helleni: nítorí Olúwa kan náà ni Olúwa gbogbo wọn, o si pọ̀ ni ọrọ̀ fún gbogbo àwọn ti ń ké pe e. 13 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá à ti pe orúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.”
14 Ǹjẹ́ wọn ó ha ti ṣe ké pe ẹni tí wọn kò gbàgbọ́? Wọn ó ha sì ti ṣe gba ẹni tí wọn kò gbúròó rẹ̀ rí gbọ́? Wọn o ha sì ti ṣe gbọ́ láìsí oníwàásù? 15 (J)Wọ́n ó ha sì ti ṣe wàásù, bí kò ṣe pé a rán wọn? Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹsẹ̀ àwọn tí ń wàásù ìhìnrere àlàáfíà ti dára tó, àwọn tí ń wàásù ìròyìn ayọ̀ ohun rere!”
16 (K)Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo wọn ni ó gbọ́ ti ìhìnrere. Nítorí Isaiah wí pé, “Olúwa, ta ni ó gba ìyìn wa gbọ́?” 17 Ǹjẹ́ nípa gbígbọ́ ni ìgbàgbọ́ ti í wá, àti gbígbọ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 18 (L)Ṣùgbọ́n mo ní, wọn kò ha gbọ́ bí? Bẹ́ẹ̀ ni nítòótọ́:
“Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀,
àti ọ̀rọ̀ wọn sí òpin ilẹ̀ ayé.”
19 (M)Ṣùgbọ́n mo wí pé, Israẹli kò ha mọ̀ bí? Mose ni ó kọ́ wí pé,
“Èmi ó fi àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mú yín jowú.
Àti àwọn aláìmòye ènìyàn ni èmi ó fi bí yín nínú.”
20 (N)Ṣùgbọ́n Isaiah tilẹ̀ láyà, ó wí pé,
“Àwọn tí kò wá mi rí mi;
Àwọn tí kò béèrè mi ni a fi mí hàn fún.”
21 (O)Ṣùgbọ́n nípa ti Israẹli ni ó wí pé,
“Ní gbogbo ọjọ́ ni mo na ọwọ́ mi
sí àwọn aláìgbọ́ràn àti aláríwísí ènìyàn.”
Àṣọtẹ́lẹ̀ ní tí Ammoni
49 (A)Ní ti Ammoni:
Báyìí ni Olúwa wí:
“Israẹli kò ha ní ọmọkùnrin?
Israẹli kò ha ní àrólé bí?
Nítorí kí ni Malkomu ṣe jogún Gadi?
Kí ló dé tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ń gbé ìlú rẹ̀?
2 Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà ń bọ̀,”
ni Olúwa wí;
“nígbà tí èmi yóò mú kí a gbọ́ ìdágìrì ogun ní Rabba
tí Ammoni yóò sì di òkìtì ahoro,
gbogbo ìlú tí ó yí i ká ni a ó jó níná.
Nígbà náà ni Israẹli yóò
lé wọn, àwọn tí ó ti lé e jáde,”
ni Olúwa wí.
3 “Hu, ìwọ Heṣboni
nítorí Ai tí rún,
kígbe ẹ̀yin olùgbé Rabba!
Ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀ kí ẹ sì ṣọ̀fọ̀.
Ẹ sáré sókè sódò nínú ọgbà,
nítorí Malkomu yóò lọ sí ìgbèkùn
pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti ìjòyè rẹ̀.
4 Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣògo nínú Àfonífojì rẹ,
ṣògo nínú Àfonífojì rẹ fún èso?
Ẹ̀yin ọmọbìnrin Ammoni aláìṣòótọ́,
ẹ gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ yín, ẹ sì wí pé,
‘ta ni yóò kò mí lójú?’
5 Èmi yóò mu ẹ̀rù wá lórí rẹ
láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tó yí ọ ká,”
ni Olúwa, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
6 “Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
Gbogbo yín ni ó lé jáde, kò sì ṣí ẹnìkan
tí yóò dá ìkólọ Ammoni padà,”
ni Olúwa wí.
Àsọtẹ́lẹ̀ Ní ti Edomu
7 (B)Nípa Edomu:
Èyí ní ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:
“Ṣe kò ha sí ọgbọ́n mọ́ ni Temani?
Ṣé a ti ké ìmọ̀ràn kúrò ní ọ̀dọ̀ olóyè?
Ṣé ọgbọ́n wọn ti bàjẹ́ bí?
8 Yípadà kí o sálọ, sápamọ́ sínú ihò,
ìwọ tí ó ń gbé ní Dedani,
nítorí èmi yóò mú ibi wá sórí Esau,
ní àkókò tí èmi ó bẹ̀ ẹ́ wò.
9 Tí àwọn tí ń ṣa èso bá tọ̀ ọ́ wá;
ǹjẹ́ wọn kò ní fi èso díẹ̀ sílẹ̀?
Tí olè bá wá ní òru; ǹjẹ́ wọn kò ní
kó gbogbo ohun tí wọ́n bá fẹ́?
10 Ṣùgbọ́n èmi yóò tu Esau sí ìhòhò,
èmi ti fi ibi ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ hàn,
nítorí kí o máa ba à fi ara rẹ pamọ́.
Àwọn ọmọ rẹ, ẹbí rẹ àti
àwọn ará ilé rẹ yóò parun.
Wọn kò sì ní sí mọ́.
11 Fi àwọn ọmọ aláìní baba sílẹ̀
èmi yóò dáàbò bo ẹ̀mí wọn.
Àwọn opó rẹ gan an lè gbẹ́kẹ̀lé mi.”
12 Èyí ni ohun tí Olúwa wí bí ẹnikẹ́ni tí kò bá yẹ kí ó mu ago náà bá mú un, kí ló dé tí ìwọ yóò fi lọ láìjìyà? Ìwọ kò ní lọ láìjìyà; ṣùgbọ́n ìwọ yóò mú un. 13 Èmi fi ara mi búra ni Olúwa wí, wí pé, “Bosra yóò ba ayé ara rẹ̀ jẹ́. Yóò di ẹni ẹ̀gàn, ẹni èpè àti ẹni ègún, àti gbogbo ìlú rẹ̀ yóò di ìbàjẹ́ títí láé.”
14 Ní gbígbọ́, èmi ti gbọ́ ìró kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa:
A rán ikọ̀ kan sí orílẹ̀-èdè pé,
Ẹ kó ara yín jọ, ẹ wá sórí rẹ̀, ẹ sì dìde láti jagun.
15 “Ní báyìí, èmi yóò sọ ọ́ di
kékeré láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo;
ẹni ẹ̀gàn láàrín àwọn ènìyàn.
16 Ìpayà tí ìwọ ti fà sínú
ìgbéraga ọkàn rẹ sì ti tàn ọ́ jẹ;
ìwọ tí ń gbé ní pàlàpálá àpáta,
tí o jókòó lórí ìtẹ́ gíga
síbẹ̀ o kọ́ ìtẹ́ rẹ ga gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ idì;
láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá,”
ni Olúwa wí.
17 “Edomu yóò di ahoro
gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò jáyà, wọn ó sì
fi rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà nítorí gbogbo ìpalára rẹ
18 Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe gba Sodomu
àti Gomorra pẹ̀lú àwọn ìlú
tí ó wà ní àyíká rẹ,”
ní Olúwa wí.
“Bẹ́ẹ̀ ni, kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbé níbẹ̀;
kò sì ní sí ènìyàn tí yóò tẹ̀dó síbẹ̀ mọ́.
19 “Bí i kìnnìún ni òun ó gòkè wá láti igbó Jordani sí orí ilẹ̀ ọlọ́ràá,
Èmi ó lé Edomu kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ ní kíákíá.
Ta ni àyànfẹ́ náà tí èmi ó yàn sórí rẹ̀?
Ta ló dàbí mi, ta ni ó sì pé mi ṣe ẹlẹ́rìí?
Ta ni olùṣọ́-àgùntàn náà tí yóò le dúró níwájú mi?”
20 Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí
Olúwa ní fún Edomu, ohun tí
ó ní ní pàtàkì fún àwọn tí ń gbé ní Temani.
Àwọn ọ̀dọ́ àgbò ni à ó lé jáde.
Pápá oko wọn ni yóò run nítorí wọn.
21 Ilẹ̀ yóò mì tìtì nípa ariwo ìṣubú wọn,
a ó gbọ́ igbe wọn
ní Òkun pupa.
22 Wò ó! Ẹyẹ idì yóò gòkè fò wálẹ̀,
yóò tẹ ìyẹ́ rẹ̀ lórí Bosra.
Ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn ajagun
Edomu yóò dàbí ọkàn obìnrin tí ń rọbí.
Àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa Damasku
23 Nípa Damasku,
“Inú Hamati àti Arpadi bàjẹ́ nítorí wọ́n gbọ́ ìròyìn búburú, ìjayà dé bá wọn,
wọ́n sì dààmú bí omi Òkun.
24 Damasku di aláìlera, ó pẹ̀yìndà
láti sálọ, ìwárìrì sì dé bá a,
ìbẹ̀rù àti ìrora dìímú, ìrora
bí ti obìnrin tí ó wà ní ipò ìrọbí.
25 Kí ló dé tí ìlú olókìkí di ohun ìkọ̀sílẹ̀;
ìlú tí mo dunnú sí.
26 Lóòtítọ́, àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ
yóò ṣubú lójú pópó, gbogbo
àwọn ọmọ-ogun rẹ yóò pa
ẹnu mọ́ ní ọjọ́ náà,”
ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
27 “Èmi yóò fi iná sí odi Damasku,
yóò sì jó gbọ̀ngàn Beni-Hadadi run.”
Ọ̀rọ̀ nípa Kedari àti Hasori
28 Nípa Kedari àti ìjọba Hasori èyí ti Nebukadnessari ọba Babeli dojú ìjà kọ:
Èyí ni ohun tí Olúwa sọ:
“Dìde kí o sì dojú ìjà kọ Kedari,
kí o sì pa àwọn ènìyàn ìlà-oòrùn run.
29 (C)Àgọ́ wọn àti agbo àgùntàn wọn ni wọn ó kó lọ;
àgọ́ wọn yóò di ìṣínípò padà
pẹ̀lú gbogbo ẹrù àti ìbákasẹ wọn.
Àwọn ènìyàn yóò ké sórí wọ́n pé;
‘Ẹ̀rù yí káàkiri!’
30 “Sálọ kíákíá!
Fi ara pamọ́ sí ibi jíjìn, ẹ̀yin olùgbé Hasori,”
ni Olúwa wí.
“Nebukadnessari ọba Babeli ti dojú ìjà kọ ọ́.
31 “Dìde kí o sì dojú ìjà kọ orílẹ̀-èdè tí ó wà nínú ìrọ̀rùn,
èyí tí ó gbé ní àìléwu,”
ní Olúwa wí.
“Orílẹ̀-èdè tí kò ní odi tàbí irin,
àwọn ènìyàn rẹ̀ ń dágbé.
32 Àwọn ìbákasẹ á di ẹrù
àti àwọn ẹran ọ̀sìn, wọ́n á di ìkógun.
Èmi yóò tú àwọn tí ó wà ní òkèèrè sí inú afẹ́fẹ́.
Èmi yóò sì mú ibi wá sí àyíká gbogbo,”
báyìí ní Olúwa wí.
33 “Hasori yóò di ibi ìdọdẹ àwọn
akátá, ibi ìkọ̀sílẹ̀ ayérayé,
kò sí ẹni tí yóò gbé ní ibẹ̀.”
Àṣọtẹ́lẹ̀ ní ti Elamu
34 Èyí ní ọ̀rọ̀ Olúwa èyí tí ó tọ Jeremiah wòlíì wá nípa Elamu ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekiah ọba Juda:
35 Èyí ni ohun tí Ọlọ́run alágbára sọ:
“Wò ó, èmi yóò fọ́ ìtẹ̀gùn Elamu,
ẹni tí wọ́n sinmi lé nípa agbára.
36 Èmi yóò mú kí afẹ́fẹ́ orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin
àgbáyé lòdì sí Elamu.
Èmi yóò tú wọn ká sí ìpín afẹ́fẹ́ mẹ́rin
àti pé, kò sí orílẹ̀-èdè tí ilẹ̀ àjèjì Elamu kò ní lọ.
37 Èmi yóò kẹ́gàn Elamu níwájú àwọn ọ̀tá wọn,
àti níwájú àwọn tí wọ́n ń wá ẹ̀mí wọn;
Èmi yóò mú ibi wá sí orí wọn,
àní, ìbínú gbígbóná mi,”
bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí.
“Èmi yóò lé wọn pẹ̀lú idà, di ìgbà tí èmi yóò rẹ́yìn wọn.
38 Èmi yóò sì gbé ìtẹ́ mi kalẹ̀ ní Elamu,
èmí yóò sì pa ọba wọn àti ìjòyè wọn run,”
báyìí ni Olúwa wí.
39 “Síbẹ̀, èmi yóò dá ìkólọ
Elamu padà láìpẹ́ ọjọ́,”
báyìí ni Olúwa wí.
Ti Dafidi.
26 Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa,
nítorí tí mo ti ń rìn nínú ìwà òtítọ́ ọ̀ mi,
mo sì ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa
Ǹjẹ́ ẹsẹ̀ mi kì yóò yẹ̀.
2 Wádìí mi wò, Ìwọ Olúwa, kí o sì dán mi wò,
dán àyà àti ọkàn mi wò;
3 Nítorí ìfẹ́ ẹ̀ rẹ tí ó dúró ṣinṣin ń bẹ níwájú mi,
èmí sì ti rìn nínú òtítọ́ rẹ.
4 Èmi kò jókòó pẹ̀lú aláìṣòótọ́,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá àwọn àgàbàgebè wọlé;
5 Èmi ti kórìíra àwùjọ àwọn ènìyàn búburú
èmi kì yóò sì bá àwọn ènìyàn ìkà jókòó.
6 Èmí ó wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì yí pẹpẹ rẹ ká Olúwa.
7 Èmi yóò kọrin sókè àní orin ọpẹ́,
èmi yóò sì máa sọ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.
8 Háà Olúwa, èmí ń fẹ́ ilé rẹ níbi tí ìwọ ń gbé,
àní níbi tí ògo rẹ̀ wà.
9 Má ṣe gbá mi dànù pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
tàbí ẹ̀mí mi pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ,
10 Àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún ìwà ibi,
tí ọwọ́ ọ̀tún wọn kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
11 Ṣùgbọ́n èmi ó máa rìn nínú ìwà títọ́;
rà mí padà, kí o sì ṣàánú fún mi.
12 Ẹsẹ̀ mi dúró lórí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú;
nínú ìjọ ńlá èmi yóò fi ìbùkún fún Olúwa.
Ti Dafidi.
27 Olúwa ni ìmọ́lẹ̀ mi àti ìgbàlà mi;
ta ni èmi yóò bẹ̀rù?
Olúwa ni ibi ìsádi ẹ̀mí mi,
ẹ̀rù ta ni yóò bà mí?
2 Nígbà tí àwọn ènìyàn búburú kọjú ìjà sí mi
láti jẹ ẹran-ara mi,
àní àwọn ọ̀tá mi àti àwọn abínúkú mi,
wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.
3 Bí ọmọ-ogun tilẹ̀ yí mi ká tí wọ́n sì dìde sí mi,
ọkàn mi kì yóò bẹ̀rù;
bí ogun tilẹ̀ dìde sí mi,
nínú èyí ni ọkàn mi yóò le.
4 Ohun kan ni mo béèrè lọ́dọ̀ Olúwa,
òhun ni èmi yóò máa wá kiri:
kí èmi kí ó le wà ní ilé Olúwa
ní ọjọ́ ayé mi gbogbo,
kí èmi: kí ó le kíyèsi ẹwà Olúwa,
kí èmi kí ó sì máa wà ní tẹmpili rẹ̀.
5 Nítorí pé ní ìgbà ìpọ́njú
òun yóò pa mí mọ́ nínú àgọ́ rẹ̀;
níbi ìkọ̀kọ̀ àgọ́ rẹ̀ ni òun yóò pa mí mọ́;
yóò sì gbé mi sókè lórí àpáta.
6 Ní ìsinsin yìí, a ti gbé orí mi sókè
ga ju ti àwọn ọ̀tá mi lọ tí ó yí mí ká;
èmi yóò rú ẹbọ nínú àgọ́ rẹ, ẹbọ ariwo àti ti ayọ̀;
èmi yóò kọrin àní orin dídùn sí Olúwa.
7 Gbọ́ ohùn mi nígbà tí ẹ̀mí bá à ń pè, Háà! Olúwa,
ṣe àánú fún mi kí o sì dá mi lóhùn;
8 “Wá,” ọkàn mi wí pé, “wá ojú u rẹ̀.”
Ojú rẹ, Olúwa, ni èmí ń wá.
9 Má ṣe fi ojú rẹ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi,
má ṣe fi ìbínú sá ìránṣẹ́ rẹ tì;
ìwọ tí o ti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi,
Má ṣe fi mí sílẹ̀, má sì ṣe kọ̀ mí,
háà! Ọlọ́run ìgbàlà mi.
10 Bí ìyá àti baba bá kọ̀ mí sílẹ̀,
Olúwa yóò tẹ́wọ́ gbà mí.
11 Kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, Olúwa,
kí o sì sìn mi lọ sí ọ̀nà tí ó tẹ́jú
nítorí àwọn ọ̀tá mi.
12 Má ṣe fi mí lé ìfẹ́ àwọn ọ̀tá mi lọ́wọ́,
nítorí àwọn ẹlẹ́rìí èké ti dìde sí mi,
wọ́n sì mí ìmí ìkà.
13 Èmi ní ìgbàgbọ́ pé,
èmi yóò rí ìre Olúwa
ní ilẹ̀ alààyè.
14 Dúró de Olúwa;
kí ó jẹ alágbára, kí o sì mú ọkàn le
àní dúró de Olúwa.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.