Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
1 Samuẹli 5-6

Àpótí ẹ̀rí Olúwa ní Aṣdodu àti Ekroni

Lẹ́yìn ìgbà tí àwọn Filistini ti gba àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run lọ, wọ́n gbé e láti Ebeneseri sí Aṣdodu. Nígbà tí àwọn Filistini gbé àpótí Ọlọ́run náà lọ sí tẹmpili Dagoni, wọ́n gbé e kalẹ̀ sí ẹ̀bá Dagoni. Nígbà tí àwọn ará Aṣdodu jí ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ní ọjọ́ kejì, Dagoni ṣubú, ó dojúbolẹ̀ níwájú àpótí Olúwa, wọ́n sì gbé Dagoni, wọ́n tún fi sí ààyè rẹ̀. Ṣùgbọ́n ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì nígbà tí wọ́n dìde, Dagoni ṣì wá, ó ṣubú ó dojúbolẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí Olúwa. Orí àti ọwọ́ rẹ̀ sì ti gé kúrò, ó sì dùbúlẹ̀ ní orí ìloro ẹnu-ọ̀nà, ara rẹ̀ nìkan ni ó kù. Ìdí nìyìí títí di òní tí ó fi jẹ́ pé àlùfáà Dagoni tàbí àwọn mìíràn tí ó wọ inú tẹmpili Dagoni ní Aṣdodu fi ń tẹ orí ìloro ẹnu-ọ̀nà.

Ọwọ́ Olúwa wúwo lára àwọn ènìyàn Aṣdodu àti gbogbo agbègbè rẹ̀: ó mú ìparun wá sórí wọn, ó sì pọ́n wọn lójú pẹ̀lú ààrùn oníkókó. Nígbà tí àwọn ọkùnrin Aṣdodu rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n wí pé, “Àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ti Israẹli kò gbọdọ̀ dúró níbí yìí pẹ̀lú wa, nítorí ọwọ́ rẹ̀ wúwo lára wa àti lára Dagoni ọlọ́run wá.” Nígbà náà ni wọ́n pè gbogbo àwọn olórí Filistini jọ wọ́n sì bi wọ́n pé, “Kí ni a ó ṣe pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àwọn Israẹli?”

Wọ́n dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí á gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àwọn Israẹli lọ sí Gati.” Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Israẹli.

Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti gbé e, ọwọ́ Olúwa sì wá sí ìlú náà, ó mú jìnnìjìnnì bá wọn. Ó sì pọ́n àwọn ènìyàn ìlú náà lójú, ọmọdé àti àgbà, pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn oníkókó. 10 Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run lọ sí Ekroni.

Bí àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ṣe wọ Ekroni, àwọn ará Ekroni fi igbe ta pé, “Wọ́n ti gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run Israẹli tọ̀ wá wá láti pa wá àti àwọn ènìyàn wa.” 11 Nígbà náà ni wọ́n pe gbogbo àwọn olórí àwọn Filistini jọ wọ́n sì wí pé, “Ẹ gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àwọn Israẹli lọ: ẹ jẹ́ kí ó padà sí ààyè rẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò pa wá àti àwọn ènìyàn wa.” Ikú ti mú jìnnìjìnnì bá àwọn ará ìlú: ọwọ́ Ọlọ́run sì wúwo lára wọn. 12 Àwọn tí kò kú wọ́n pọ́n wọn lójú pẹ̀lú ààrùn oníkókó, ẹkún ìlú náà sì gòkè lọ sí ọ̀run.

Àpótí ẹ̀rí Olúwa padà sí Israẹli

Nígbà tí àpótí ẹ̀rí Olúwa sì ti wà ní agbègbè Filistini fún oṣù méje, àwọn ará Filistini pe àwọn àlùfáà, àti àwọn alásọtẹ́lẹ̀, wọ́n sì sọ pé, “Kí ni kí a ṣe pẹ̀lú àpótí ẹ̀rí Olúwa? Sọ fún wa bí àwa yóò ti dá a padà sí ààyè rẹ̀.”

Wọ́n dáhùn wí pé, “Tí ẹ bá dá àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ti àwọn ọmọ Israẹli padà, ẹ má ṣe dá a padà ní òfìfo, ṣùgbọ́n bí ó ti wù kí ó rí, ẹ fún un ní ẹbọ ẹ̀bi. Nígbà náà ni a ó mú un yín láradá, ẹ̀yin yóò sì mọ ìdí tí ọwọ́ rẹ̀ kò fi tí ì kúrò lára yín.”

Àwọn ará Filistini béèrè pé, “Irú ẹbọ ẹ̀bi wo ni kí a fi fún un?”

Wọ́n dáhùn, “Wúrà oníkókó márùn-ún àti eku ẹ̀lírí wúrà márùn-ún, gẹ́gẹ́ bí iye àwọn aláṣẹ Filistini, nítorí àjàkálẹ̀-ààrùn kan náà ni ó kọlù yín àti olórí yín. Mọ àwòrán ààrùn oníkókó àti ti eku ẹ̀lírí yin tí ó ń ba orílẹ̀-èdè náà jẹ́ kí o sì bu ọlá fún Ọlọ́run Israẹli, Bóyá yóò gbé ọwọ́ rẹ̀ kúrò lára yín, lára ọlọ́run yín àti lára ilẹ̀ yín. Kí ni ó dé tí ẹ fi ń sé ọkàn yín le gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Ejibiti àti Farao ti ṣe? Nígbà tí ó fi ọwọ́ líle mú wọn, ṣé wọn kò rán àwọn ọmọ Israẹli jáde kí wọn kí ó lè lọ ní ọ̀nà wọn?

“Nísinsin yìí ẹ pèsè kẹ̀kẹ́ ẹrù tuntun sílẹ̀, pẹ̀lú màlúù méjì tí ó ti fi ọmú fún ọmọ, èyí tí a kò tí ì gba àjàgà sí ọrùn rí, kí ẹ sì so ó mọ́ kẹ̀kẹ́ náà, kí ẹ sì mú ọmọ wọn kúrò lọ́dọ̀ wọn wá sí ilé láti so. Kí ẹ sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa sí orí kẹ̀kẹ́ ẹrù àti kí ẹ̀yin sì kó àwọn ohun èlò wúrà tí ẹ̀yin fi fún un gẹ́gẹ́ bí ti ẹbọ ẹ̀bi sí inú àpótí ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó sì rán an lọ, ṣùgbọ́n kí ẹ sì máa ṣọ́ ọ. Tí ó bá ń lọ sí ilẹ̀ rẹ̀, ìlú rẹ̀, níhà Beti-Ṣemeṣi. Nígbà náà ni Olúwa mú àjálù ńlá yìí bá wa. Ṣùgbọ́n bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà náà ni a mọ̀ pé kì í ṣe ọwọ́ rẹ̀ ni ó kọlù wá, ṣùgbọ́n ó wá bẹ́ẹ̀ ni.”

10 Nígbà náà ni wọ́n ṣe èyí. Wọ́n mú abo màlúù méjì, tí ń fi ọmú fún ọmọ, wọn mọ́ ara, wọ́n sì dè é ni ilé kẹ̀kẹ́ ẹrù, wọn sì so àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀ ni ilé. 11 Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa lé orí kẹ̀kẹ́ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni àpótí tí eku ẹ̀lírí wúrà àti àwòrán ààrùn oníkókó wà níbẹ̀. 12 Nígbà náà; àwọn màlúù lọ tààrà sí ìhà Beti-Ṣemeṣi, wọ́n ń lọ tààrà, wọ́n sì ń dún bí wọ́n ti ń lọ. Wọn kò yà sí ọ̀tún tàbí yà sí òsì. Àwọn aláṣẹ Filistini tẹ̀lé wọn títí dé ibodè Beti-Ṣemeṣi.

13 Nísinsin yìí, àwọn ará Beti-Ṣemeṣi ń kórè jéró wọn ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, nígbà tí wọ́n wo òkè tí wọ́n sì rí àpótí ẹ̀rí Olúwa, wọ́n yọ̀ níwájú rẹ̀. 14 Kẹ̀kẹ́ ẹrù wá sí pápá Joṣua ti Beti-Ṣemeṣi, níbẹ̀ ni ó ti dúró ní ẹ̀bá àpáta ńlá kan. Àwọn ènìyàn gé igi ara kẹ̀kẹ́ ẹrù sí wẹ́wẹ́ wọ́n sì fi àwọn màlúù náà rú ẹbọ sísun sí Olúwa. 15 Àwọn ará Lefi gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa wá sí ìsàlẹ̀ pẹ̀lú àpótí tí ohun èlò wúrà wà níbẹ̀, wọ́n sì gbé wọn ka orí àpáta ńlá náà. Ní ọjọ́ náà, àwọn ará Beti-Ṣemeṣi rú ẹbọ sísun, wọ́n sì ṣe ìrúbọ sí Olúwa. 16 Àwọn aláṣẹ Filistini márààrún rí gbogbo èyí, wọ́n sì padà ní ọjọ́ náà sí Ekroni.

17 Èyí ni kókó wúrà tí àwọn Filistini fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀bi ọ̀kọ̀ọ̀kan fún Aṣdodu, ọ̀kan ti Gasa, ọ̀kan ti Aṣkeloni, ọ̀kan ti Gati, ọ̀kan ti Ekroni. 18 Wúrà eku ẹ̀lírí jẹ́ iye ìlú tí àwọn aláṣẹ Filistini márààrún ti wá, ìlú olódi pẹ̀lú ìletò wọn. Àpáta ńlá náà, lórí èyí tí a gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa lé jẹ́ ẹ̀rí títí di òní ní oko Joṣua ará Beti-Ṣemeṣi.

19 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kọlu díẹ̀ lára àwọn ọkùnrin Beti-Ṣemeṣi, ó pa àádọ́rin wọn, nítorí wọ́n ti wo inú àpótí ẹ̀rí Olúwa. Àwọn ènìyàn ṣọ̀fọ̀ nítorí àjálù ńlá tí Olúwa fi bá ọ̀pọ̀ wọn jà. 20 Àwọn ọkùnrin ará Beti-Ṣemeṣi béèrè pé, “Ta ni ó le è dúró ní iwájú Olúwa Ọlọ́run mímọ́ yìí? Ọ̀dọ̀ ta ni àpótí ẹ̀rí Olúwa yóò gbà gòkè lọ láti ibí yìí?”

21 Nígbà náà, wọ́n rán àwọn ìránṣẹ́ sí àwọn ènìyàn tí Kiriati-Jearimu wí pé, “àwọn Filistini ti dá àpótí ẹ̀rí Olúwa padà. Ẹ sọ̀kalẹ̀ wá, kí ẹ gbé e gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ yín.”

Romu 5

Àlàáfíà àti ayọ̀

(A)Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí a ti dá wa láre nípa ìgbàgbọ́, àwa ní àlàáfíà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ Olúwa wa Jesu Kristi. (B)Nípasẹ̀ ẹni tí àwa sì ti rí ọ̀nà gbà nípa ìgbàgbọ́ sí inú oore-ọ̀fẹ́ yìí nínú èyí tí àwa gbé dúró. Àwa sì ń yọ̀ nínú ìrètí ògo Ọlọ́run. (C)Kì í sì ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa tún ń ṣògo nínú ìjìyà pẹ̀lú: bí a ti mọ̀ pé ìjìyà ń ṣiṣẹ́ sùúrù; àti pé sùúrù ń ṣiṣẹ́ ìwà rere; àti pé ìwà rere ń ṣiṣẹ́ ìrètí: (D)Ìrètí kì í sì í dójúti ni nítorí a ti dá ìfẹ́ Ọlọ́run sí wa lọ́kàn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a fi fún wa.

Nítorí ìgbà tí àwa jẹ́ aláìlera, ní àkókò tí ó yẹ, Kristi kú fún àwa aláìwà-bí-Ọlọ́run. Nítorí ó ṣọ̀wọ́n kí ẹnìkan tó kú fún olódodo: ṣùgbọ́n fún ènìyàn rere bóyá ẹlòmíràn tilẹ̀ lè dábàá láti kú. (E)Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìfẹ́ òun pàápàá sí wa hàn nínú èyí pé, nígbà tí àwa jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.

(F)Mélòó mélòó sì ni tí a dá wa láre nísinsin yìí nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ni a ó gbà wá là kúrò nínú ìbínú nípasẹ̀ rẹ̀. 10 (G)Ǹjẹ́, nígbà tí àwa wà ní ọ̀tá, a mú wa, ba Ọlọ́run làjà nípa ikú Ọmọ rẹ̀, mélòó mélòó, nígbà tí a là wá ní ìjà tan, ni a ó gbà wá là nípa ìyè rẹ̀. 11 (H)Kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa ń ṣògo nínú Ọlọ́run nípa Olúwa wa Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí àwa ti rí ìlàjà gbà nísinsin yìí.

Ikú nípasẹ̀ Adamu, iyè nípasẹ̀ Jesu

12 (I)Nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti tipa ọ̀dọ̀ ènìyàn kan wọ ayé, àti ikú nípa ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ikú sì kọjá sórí ènìyàn gbogbo, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí gbogbo ènìyàn ti dẹ́ṣẹ̀:

13 Nítorí kí òfin tó dé, ẹ̀ṣẹ̀ ti wà láyé; ṣùgbọ́n a kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí ni lọ́rùn nígbà tí òfin kò sí. 14 (J)Ṣùgbọ́n ikú jẹ ọba láti ìgbà Adamu wá títí fi di ìgbà ti Mose, àti lórí àwọn tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò dàbí irú ìrékọjá Adamu, ẹni tí í ṣe àpẹẹrẹ ẹni tí ń bọ̀.

15 (K)Ṣùgbọ́n ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ kò dàbí ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí bí nípa ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí bí o bá jẹ pé ẹnìkan ẹni púpọ̀ kú, mélòó mélòó ni oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, àti ẹ̀bùn nínú oore-ọ̀fẹ́ ọkùnrin kan, Jesu Kristi, di púpọ̀ fún ẹni púpọ̀. 16 (L)Kì í ṣe nípa ẹnìkan tí ó sẹ̀ ni ẹ̀bùn náà: Nítorí ìdájọ́ ti ipasẹ̀ ẹnìkan wá fún ìdálẹ́bi, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ti inú ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ wá fún ìdáláre, 17 Ǹjẹ́ bí o bá jẹ pé nípa ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin kan, ikú jẹ ọba nípasẹ̀ ẹnìkan náà; mélòó mélòó ni àwọn tí ń gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore-ọ̀fẹ́ àti ẹ̀bùn òdodo yóò jẹ ọba nínú ìyè nípasẹ̀ ẹnìkan, Jesu Kristi.

18 Ǹjẹ́ bí o bá jẹ pé nípa ẹ̀ṣẹ̀ ẹnìkan ìdájọ́ dé bá gbogbo ènìyàn sí ìdálẹ́bi; gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni nípa ìwà òdodo ẹnìkan, ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ dé sórí gbogbo ènìyàn fún ìdáláre sí ìyè. 19 (M)Nítorí gẹ́gẹ́ bí nípa àìgbọ́ràn ọkùnrin kan, ènìyàn púpọ̀ di ẹlẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni nípa ìgbọ́ràn ẹnìkan, a ó sọ ènìyàn púpọ̀ di olódodo.

20 (N)Ṣùgbọ́n òfin bọ́ sí inú rẹ̀, kí ẹ̀ṣẹ̀ lè di púpọ̀, ṣùgbọ́n ni ibi ti ẹ̀ṣẹ̀ di púpọ̀, oore-ọ̀fẹ́ di púpọ̀ rékọjá. 21 (O)Pé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti jẹ ọba nípa ikú bẹ́ẹ̀ ni kí oore-ọ̀fẹ́ sì lè jẹ ọba nípa òdodo títí ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa.

Jeremiah 43

43 Nígbà tí Jeremiah parí sísọ ọ̀rọ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rán an sí wọn tan. Asariah ọmọ Hoṣaiah àti Johanani ọmọ Karea, àti gbogbo àwọn agbéraga ọkùnrin sọ fún Jeremiah pé, “Ìwọ ń pa irọ́! Olúwa Ọlọ́run wa kò rán ọ láti sọ pé, ‘Ẹ má lọ sí Ejibiti láti ṣàtìpó níbẹ̀.’ Ṣùgbọ́n Baruku, ọmọ Neriah, ni ó fi ọ̀rọ̀ sí ọ lẹ́nu sí wa, láti fà wá lé àwọn ará Babeli lọ́wọ́, láti pa wá àti láti kó wa ní ìgbèkùn lọ sí Babeli.”

Nítorí náà, Johanani ti Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun, àti gbogbo àwọn ènìyàn tàpá sí àṣẹ Olúwa nípa dídúró sí Juda. Dípò bẹ́ẹ̀, Johanani ọmọ Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun sì ko àwọn àjẹkù Juda tí wọ́n wá láti gbé ilẹ̀ Juda láti orílẹ̀-èdè gbogbo tí wọ́n ti tú wọn ká. Wọ́n tún kó àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé, àti àwọn ọmọ ọba tí ó jẹ́ obìnrin èyí tí Nebusaradani balógun ẹ̀ṣọ́ ti fi sílẹ̀ pẹ̀lú Gedaliah ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, àti Jeremiah wòlíì náà àti Baruku ọmọ Neriah. Nítorí náà, wọn wọ Ejibiti pẹ̀lú àìgbọ́ràn sí àṣẹ Olúwa, wọ́n sì lọ títí dé Tafanesi.

Ní Tafanesi ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá: “Nígbà tí àwọn Júù ń wòye mú àwọn òkúta pẹ̀lú rẹ, kí o sì rì wọ́n mọ́ inú amọ̀ tí ó wà nínú bíríkì tí ó wà níbi pèpéle ẹnu-ọ̀nà ààfin Farao ní Tafanesi. 10 Báyìí kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run alágbára, Ọlọ́run Israẹli wí: Èmi yóò ránṣẹ́ sí ìránṣẹ́ mi Nebukadnessari ọba Babeli Èmi yóò gbé ìjọba rẹ̀ ka orí àwọn òkúta; èyí tí mo ti rì sí ibí yìí, yóò tan ìjọba rẹ̀ jù wọ́n lọ. 11 Yóò gbé ogun sí Ejibiti; yóò mú ikú bá àwọn tí ó yan ikú; ìgbèkùn fún àwọn tí ó ti yan ìgbèkùn, àti idà fún àwọn tí ó yan idà. 12 Yóò dá, iná sun tẹmpili àwọn òrìṣà Ejibiti, yóò sun tẹmpili àwọn òrìṣà Ejibiti, yóò sì mú wọn lọ ìgbèkùn. Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn, yóò ró aṣọ rẹ̀ mọ́ra, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò ró Ejibiti òun yóò sì lọ kúrò níbẹ̀ ní àlàáfíà 13 Ní tẹmpili ni yóò ti fọ́ ère ilé oòrùn tí ó wà ní ilẹ̀ Ejibiti túútúú, yóò sì sun àwọn tẹmpili àwọn òrìṣà Ejibiti.’ ”

Saamu 19

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

19 Àwọn ọ̀run ń sọ nípa ti ògo Ọlọ́run;
    Àwọsánmọ̀ ń sọ nípa ti iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
Wọ́n ń fọhùn ní ọjọ́ dé ọjọ́;
    wọ́n ń fi ìmọ̀ hàn ní alẹ́ dé alẹ́.
Kò sí ohùn tàbí èdè
    níbi tí a kò gbé gbọ́ ìró wọn
(A)Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo orílẹ̀ ayé,
    ọ̀rọ̀ wọn títí dé òpin ilẹ̀ ayé.
Ó ti kọ́ àgọ́ fún oòrùn nínú àwọn ọ̀run.
    Tí ó dàbí ọkọ ìyàwó tí ó ń jáde ti yàrá rẹ̀ wá,
    òun yọ bí alágbára ọkùnrin tí ó ń sáré ìje.
Ìjáde lọ rẹ̀ ni láti òpin ọ̀run wá
    àti àyíká rẹ̀ sì dé ìpínlẹ̀ rẹ̀;
    kò sì sí ohun tí ó pamọ́ kúrò nínú oore rẹ̀.

Pípé ni òfin Olúwa,
    ó ń yí ọkàn padà.
Ẹ̀rí Olúwa dánilójú,
    ó sọ òpè di ọlọ́gbọ́n.
Ìlànà Olúwa tọ̀nà,
    ó ń fi ayọ̀ fún ọkàn.
Àṣẹ Olúwa ni mímọ́,
    ó ń fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú.
Ìbẹ̀rù Olúwa mọ́,
    ó ń faradà títí láéláé.
Ìdájọ́ Olúwa dájú
    òdodo ni gbogbo wọn.

10 Wọn ṣọ̀wọ́n ju wúrà lọ,
    ju wúrà tí o dára jùlọ,
wọ́n dùn ju oyin lọ,
    àti ju afárá oyin lọ.
11 Nípa wọn ni a ti ṣí ìránṣẹ́ rẹ̀ létí;
    nípa pípa wọ́n mọ́, èrè púpọ̀ ń bẹ.
12 Ta ni ó lè mọ àṣìṣe rẹ̀?
    Dáríjì mí nínú àṣìṣe mi tí ó pamọ́.
13 Wẹ ìránṣẹ́ rẹ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́n-mọ̀-dá;
    má ṣe jẹ kí wọn kí ó jẹ ọba lórí mi.
Nígbà náà ní èmi yóò dúró ṣinṣin,
    èmi yóò sì ṣe aláìlẹ́bi kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ńlá.

14 Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn mi
    kí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà ní ojú rẹ,
    Ìwọ Olúwa àpáta mi, àti Olùdáǹdè mi.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.