Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Numeri 27

Ọmọbìnrin Ṣelofehadi

27 (A)Ọmọbìnrin Ṣelofehadi ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri ọmọ Manase tó jẹ́ ìdílé Manase, ọmọ Josẹfu wá. Orúkọ àwọn ọmọbìnrin náà ni Mahila, Noa, Hogla, Milka àti Tirsa. Wọ́n súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé wọ́n sì dúró níwájú Mose, àti Eleasari àlùfáà, àti níwájú àwọn olórí àti ìjọ, wọ́n sì wí pé, “Baba wa kú sí aginjù. Kò sí lára àwọn ẹgbẹ́ Kora tí wọ́n kó ara wọn pọ̀ lòdì sí Olúwa, Ṣùgbọ́n ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kò sì fi ọmọkùnrin sílẹ̀. Kín ni ó dé tí orúkọ baba wa yóò parẹ́ nínú ìdílé rẹ̀ nítorí pé kò ní ọmọkùnrin? Fún wa ní ilẹ̀ ìní láàrín àwọn arákùnrin baba wa.”

Nígbà náà Mose mú ọ̀rọ̀ wọn wá síwájú Olúwa. Olúwa sì wí fún un pé, “Ohun tí àwọn ọmọbìnrin Ṣelofehadi ń sọ tọ̀nà. Ogbọdọ̀ fún wọn ní ogún ìní ti baba wọn.

“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, ‘Tí ọkùnrin kan bá kú tí kò sì fi ọmọkùnrin sáyé, ẹ fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ní ogún ìní rẹ̀. Tí kò bá ní ọmọbìnrin, fi ohun ìní rẹ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀. 10 Tí kò bá ní arákùnrin, fi ogún ìní rẹ̀ fún arákùnrin baba rẹ̀. 11 Tí baba rẹ̀ kò bá ní arákùnrin, fún ará ilé rẹ̀ tí ó bá súnmọ́ jù ní ìdílé rẹ̀ ní ogún ìní rẹ̀, kí ó lè jogún rẹ̀. Èyí gbọdọ̀ jẹ́ ìlànà ìdájọ́ fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.’ ”

Joṣua láti rọ́pò Mose

12 (B)Nígbà náà Olúwa sọ fún Mose pé, “Lọ sì orí òkè Abarimu yìí, kí o sì lọ wo ilẹ̀ tí mo fún àwọn ọmọ Israẹli. 13 Lẹ́yìn ìgbà tí o bá sì ti rí i, ìwọ náà yóò darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn rẹ gẹ́gẹ́ bí Aaroni arákùnrin rẹ ṣe ṣe, 14 nítorí nígbà tí ìlú ṣọ̀tẹ̀ níbi omi ní Aginjù Sini, tí gbogbo yín ṣe àìgbọ́ràn sí mi láti yà mí sí mímọ́ níwájú wọn.” (Èyí ni omi Meriba ní Kadeṣi ní aginjù Sini.)

15 Mose sọ fún Olúwa wí pé, 16 “Jẹ́ kí Olúwa, Ọlọ́run ẹ̀mí gbogbo ènìyàn, kí ó yan ọkùnrin kan sí orí ìjọ ènìyàn yìí 17 Láti máa darí wọn, ẹni tí yóò mú wọn jáde, tí yóò sì mú wọn wọlé, gbogbo ènìyàn Olúwa kí yóò dàbí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́.”

18 (C)Nígbà náà ní Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú Joṣua ọmọ Nuni, ọkùnrin nínú ẹni tí èmi wà, kí o sì gbé ọwọ́ rẹ lé e. 19 Jẹ́ kí ó dúró níwájú Eleasari àlùfáà àti ojú gbogbo àwọn ìjọ ènìyàn Israẹli kí o sì fi àṣẹ fún un ní ojú wọn. 20 Kí ìwọ kí ó sì fi nínú ọláńlá rẹ sí i lára, kí gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli kí ó lè gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu. 21 Kí ó dúró níwájú Eleasari àlùfáà, tí yóò gba ìpinnu fún láti béèrè Urimu níwájú Olúwa. Gẹ́gẹ́ bí òfin yìí ni òun pẹ̀lú gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli yóò jáde lọ, pẹ̀lú òfin rẹ̀ sì ni wọn ó wọlé.”

22 Mose sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún un. Ó mú Joṣua ó sì mú kí ó dúró níwájú Eleasari àlùfáà àti níwájú gbogbo ìjọ. 23 (D)Nígbà náà ni ó gbé ọwọ́ rẹ̀ le e, ó sì fi àṣẹ fún un gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Saamu 70-71

Fún adarí orin. Ti Dafidi. Ẹ̀bẹ̀.

70 (A)Yára, Ọlọ́run, láti gbà mí là,
    Olúwa, wá kánkán láti ràn mí lọ́wọ́.

Kí àwọn tí ń wá ọkàn mi
    kí a dójútì wọ́n, kí wọn sì dààmú;
kí àwọn tó ń wá ìparun mi
    yí ẹ̀yìn padà nínú ìtìjú.
Kí a pa wọ́n ní ẹ̀yìn dà fún èrè
    ìtìjú àwọn tí ń wí pé, “Háà! Háà!”
Ṣùgbọ́n kí àwọn tí ó ń wá ọ ó máa yọ̀
    kí inú wọn kí ó sì máa dùn nípa rẹ,
kí àwọn tí ó ń fẹ́ ìgbàlà rẹ máa wí pé,
    “Jẹ́ kí a gbé Ọlọ́run ga!”

Ṣùgbọ́n mo jẹ́ òtòṣì àti aláìní;
    wa kánkán sí ọ̀dọ̀ mi, Ọlọ́run.
Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àti olùdáǹdè mi;
    Olúwa, má ṣe dúró pẹ́.
71 Nínú rẹ, Olúwa, ni mo ní ààbò;
    Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.
Gbà mí kí o sì tú mi sílẹ̀ nínú òdodo rẹ;
    dẹ etí rẹ sí mi, kí o sì gbà mí.
Jẹ́ àpáta ààbò mi,
    níbi tí èmi lè máa lọ,
pa àṣẹ láti gbà mí,
    nítorí ìwọ ni àpáta àti odi agbára mi.
Gbà mí, Ọlọ́run mi, lọ́wọ́ àwọn olùṣe búburú,
    ní ọwọ́ aláìṣòdodo àti ìkà ọkùnrin.

Nítorí ìwọ jẹ́ ìrètí mi, Olúwa Olódùmarè,
    ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi láti ìgbà èwe.
Mo gbẹ́kẹ̀lé ọ láti ìgbà ìbí mi;
    Ìwọ mú mi jáde láti inú ìyá mi wá
èmi ó máa yìn ọ́ títí láé.
Mo di ààmì fún ọ̀pọ̀ ènìyàn,
    ṣùgbọ́n ìwọ ni ààbò mi tí ó lágbára.
Ìyìn rẹ̀ kún ẹnu mi,
    ó ń sọ ti ọlá rẹ ní ọjọ́ gbogbo.

Má ṣe ta mí nù ní ọjọ́ ogbó mi
    Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ nígbà tí kò sí okun mọ́
10 Nítorí àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀-òdì sí mi,
    àwọn tí wọn dúró láti pa mí gbìmọ̀ pọ̀.
11 Wọ́n wí pé, “Ọlọ́run ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀;
    lépa rẹ̀ kí ẹ sì mu,
    nítorí kò sí ẹni tí yóò gbà á.”
12 Má ṣe jìnnà sí mi, Ọlọ́run;
    wa kánkán, Ọlọ́run mi, láti ràn mí lọ́wọ́.
13 Jẹ́ kí wọn kí ó dààmú,
    kí a sì run àwọn tí ń ṣe ọ̀tá ọkàn mi
kí a sì fi ẹ̀gàn àti àbùkù
    bo àwọn tí ń wá ìpalára mi.

14 Ṣùgbọ́n ní tèmi, ìgbà gbogbo ní ìrètí mi;
    èmi ó yìn ọ́ síwájú àti síwájú sí i.

15 Ẹnu mi yóò sọ nípa ti òdodo rẹ,
ti ìgbàlà rẹ, ni gbogbo ọjọ́,
lóòtítọ́, èmi kò mọ iye rẹ̀.
16 Èmi ó wá láti wá kéde agbára,
    Olúwa Olódùmarè;
    èmi ó kéde òdodo rẹ̀ nìkan.
17 Láti ìgbà èwe, Ọlọ́run ni ìwọ ti kọ́ mi
    títí di òní ni mo ń sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ.
18 Pẹ̀lúpẹ̀lú, nígbà tí èmi di arúgbó tán tí mo sì hewú,
    Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, Ọlọ́run mi,
títí èmi ó fi ipá rẹ han ìran tí ń bọ̀,
    àti agbára rẹ fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn.

19 Ọlọ́run, òdodo rẹ dé ọ̀run,
    ìwọ tí o ti ṣe ohun ńlá
    Ta ni ó dàbí rẹ, Ọlọ́run?
20 Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ ti mú mi rí ìdààmú, tí ó pọ̀ tí ó sì korò,
    ìwọ yóò tún sọ ayé mi jí
ìwọ yóò sì tún mú mi sọ sókè
    láti ọ̀gbun ilẹ̀ wá.
Ìwọ yóò sọ ọlá mi di púpọ̀
21 Ìwọ yóò fi kún ọwọ́ mi
    ìwọ yóò tù mí nínú ní ha gbogbo.

22 Èmi yóò fi dùùrù mi yìn
    fún òtítọ́ rẹ, Ọlọ́run mi;
èmi ó kọrin ìyìn sí ọ pẹ̀lú dùùrù
    ìwọ ẹni mímọ́ Israẹli.
23 Ètè mi yóò kígbe fún ìyìn
    nígbà tí mo bá kọrin ìyìn sí ọ:
    èmi, ẹni tí o rà padà.
24 Ahọ́n mi yóò sọ ti òdodo rẹ ní gbogbo ọjọ́,
    fún àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára,
    a sì dójúti àwọn tí ń wá ìdààmú mi.

Isaiah 17-18

Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ ní ti Damasku

17 (A)Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Damasku:

    “Kíyèsi i, Damasku kò ní jẹ́ ìlú mọ́
    ṣùgbọ́n yóò padà di ààtàn.
Àwọn ìlú Aroeri ni a ó kọ̀sílẹ̀
    fún àwọn agbo ẹran tí yóò máa sùn síbẹ̀,
    láìsí ẹni tí yóò dẹ́rùbà wọ́n.
Ìlú olódi ni yóò pòórá kúrò ní Efraimu,
    àti agbára ọba kúrò ní Damasku;
àwọn àṣẹ́kù Aramu yóò dá
    gẹ́gẹ́ bí ògo ti àwọn Israẹli,”
    ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

“Ní ọjọ́ náà ni ògo Jakọbu yóò sá;
    ọ̀rá ara rẹ̀ yóò ṣòfò dànù.
Yóò sì dàbí ìgbà tí olùkórè kó àwọn
    irúgbìn tí ó dúró jọ
tí ó sì ń kórè irúgbìn pẹ̀lú apá rẹ̀—
    àti gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ènìyàn pa ọkà ní Àfonífojì ti Refaimu.
Síbẹ̀síbẹ̀ irúgbìn díẹ̀ yóò ṣẹ́kù,
    gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a gbọn igi olifi,
tí èso olifi méjì tàbí mẹ́ta ṣẹ́kù
    sórí ẹ̀ka tí ó ga jùlọ,
mẹ́rin tàbí márùn-ún lórí ẹ̀ka tí ó so jù,”
    ni Olúwa wí, àní Ọlọ́run Israẹli.

Ní ọjọ́ náà, àwọn ènìyàn yóò gbójú sókè sí Ẹlẹ́dàá wọn
    wọn yóò sì ṣíjú wo Ẹni Mímọ́ Israẹli.
Wọn kò ní wo àwọn pẹpẹ mọ́,
    èyí tí í ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wọn,
wọn kò sì ní kọbi ara sí ère Aṣerah mọ́
    tàbí pẹpẹ tùràrí tí ìka ọwọ́ wọn ti ṣe.

Ní ọjọ́ náà àwọn ìlú alágbára rẹ̀, yóò dàbí ẹ̀ka ìkọ̀sílẹ̀, àti ẹ̀ka téńté òkè tí wọ́n fi sílẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Gbogbo wọn yóò sì di ahoro.

10 Nítorí ìwọ ti gbàgbé Ọlọ́run ìgbàlà rẹ;
    tí ìwọ kò sì náání àpáta ìgbàlà rẹ̀,
    nítorí náà ni ìwọ ti gbin ọ̀gbìn dáradára
    ìwọ sì tọ́ àjèjì ẹ̀ka sínú rẹ̀.
11 Nítorí náà, bí ẹ tilẹ̀ mú àṣàyàn igi tí ẹ sì gbin àjàrà tí ó ti òkèrè wá,
    bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ tí ẹ kó wọn jáde ẹ mú wọn hù jáde,
àti ní òwúrọ̀ tí ẹ gbìn wọ́n
    ẹ mú kí wọ́n rúdí,
síbẹ̀síbẹ̀ ìkórè kò ní mú nǹkan wá
    ní ọjọ́ ààrùn àti ìrora tí kò gbóògùn.

12 Kíyèsi i, ìrunú àwọn orílẹ̀-èdè—
    wọ́n ń runú bí ìgbì Òkun!
Kíyèsi i, rògbòdìyàn tí ogunlọ́gọ̀ ènìyàn
    wọ́n bú ramúramù gẹ́gẹ́ bí ariwo odò ńlá!
13 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń bú
    ramúramù gẹ́gẹ́ bí ìrúmi odò,
nígbà tí ó bá wọn wí wọ́n sálọ jìnnà réré,
    a tì wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò ní orí òkè,
    àti gẹ́gẹ́ bí ewéko níwájú ìjì líle.
14 Ní aginjù, ìpayà òjijì!
    Kí ó tó di òwúrọ̀, a ò rí wọn mọ́!
Èyí ni ìpín àwọn tí ó jí wa lẹ́rù,
    àti ìpín àwọn tí ó fi ogun kó wa.

Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Kuṣi

18 (B)Ègbé ni fún ilẹ̀ tí ó kún fún ariwo ìyẹ́ eṣú,
    ní àwọn ipadò Kuṣi,
tí ó rán àwọn ikọ̀ lórí Òkun
    lórí omi nínú ọkọ̀-ọpọ́n tí a fi eèsún papirusi ṣe.

Ẹ lọ, ẹ̀yin ikọ̀ tí ó yára,
    sí àwọn ènìyàn gíga tí àwọ̀ ara wọn jọ̀lọ̀,
sí àwọn ènìyàn tí a ń bẹ̀rù káàkiri,
    orílẹ̀-èdè aláfojúdi alájèjì èdè,
    tí odò pín ilẹ̀ rẹ̀ yẹ́lẹyẹ̀lẹ.

Gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ayé,
    tí ó ń gbé orílẹ̀ ayé,
nígbà tí a bá gbé àsíá kan sókè lórí òkè,
    ẹ ó rí i,
nígbà tí a bá fun fèrè kan
    ẹ ó gbọ́ ọ.
Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi:
    “Èmi yóò dákẹ́ jẹ́ẹ́, èmi yóò sì máa wo òréré
láti ibùgbé e mi wá,
    gẹ́gẹ́ bí ooru gbígbóná nínú ìtànṣán oòrùn,
    gẹ́gẹ́ bí òjò-dídì ní àárín gbùngbùn ìkórè.”
Nítorí, kí ìkórè tó bẹ̀rẹ̀,
    nígbà tí ìrudí bá kún,
nígbà tí ìtànná bá di èso àjàrà pípọ́n.
    Òun yóò sì fi dòjé rẹ́ ẹ̀ka tuntun,
yóò sì mu kúrò,
    yóò sì gé ẹ̀ka lulẹ̀.
A ó fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn ẹyẹ òkè ńlá
    àti fún àwọn ẹranko búburú;
àwọn ẹyẹ yóò fi wọ́n ṣe oúnjẹ nínú ẹ̀ẹ̀rùn
    àti àwọn ẹranko búburú nígbà òjò.

Ní àkókò náà ni a ó mú ẹ̀bùn wá fún Olúwa àwọn ọmọ-ogun

láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn gíga tí ẹran-ara wọn jọ̀lọ̀,
    láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí a bẹ̀rù níbi gbogbo,
orílẹ̀-èdè aláfojúdi àti alájèjì èdè,
    ilẹ̀ ẹni tí omi pín sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ—

a ó mú àwọn ẹ̀bùn náà wá sí òkè Sioni, ibi tí orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbé wà.

1 Peteru 5

Sí àwọn alàgbà àti àwọn ọ̀dọ́kùnrin

Àwọn alàgbà tí ń bẹ láàrín yín ni mo gbànímọ̀ràn, èmi ẹni tí ń ṣe alàgbà bí ẹ̀yin, àti ẹlẹ́rìí ìyà Kristi, àti alábápín nínú ògo tí a ó fihàn: Ẹ máa tọ́jú agbo Ọlọ́run tí ń bẹ láàrín yín, ẹ máa bojútó o, kì í ṣe àfipáṣe, bí kò ṣe tìfẹ́tìfẹ́; kó má sì jẹ́ fún èrè ìjẹkújẹ, bí kò ṣe pẹ̀lú ìpinnu tí ó múra tan. Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe bí ẹni tí ń lo agbára lórí ìjọ, ṣùgbọ́n kí ẹ ṣe ara yín ní àpẹẹrẹ fún agbo. Nígbà tí olórí Olùṣọ́-àgùntàn bá sì fi ara hàn, ẹ̀yin ó gba adé ògo ti kì í sá.

(A)Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ tẹríba fún àwọn alàgbà. Àní, gbogbo yín ẹ máa tẹríba fún ara yín kí ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ wọ ara yín ní aṣọ: nítorí,

“Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn agbéraga,
    ṣùgbọ́n ó ń fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.”

Nítorí náà, ẹ rẹ ara yin sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára Ọlọ́run, kí òun lè gbe yín ga lákokò. (B)Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lé e; nítorí tí òun ń ṣe ìtọ́jú yín.

Ẹ máa wà ni àìrékọjá, ẹ máa ṣọ́ra; nítorí èṣù ọ̀tá yín, bí i kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń rìn káàkiri, ó ń wa ẹni tí yóò pajẹ. Ẹ kọ ojú ìjà sí i pẹ̀lú ìdúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́, bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé ìyà kan náà ni àwọn ará yín tí ń bẹ nínú ayé ń jẹ.

10 Ọlọ́run oore-ọ̀fẹ́ gbogbo, tí ó ti pè yín sínú ògo rẹ̀ tí kò nípẹ̀kun nínú Kristi Jesu, nígbà tí ẹ̀yin bá ti jìyà díẹ̀, òun tìkára rẹ̀, yóò sì ṣe yín ní àṣepé, yóò fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, yóò fún yín lágbára, yóò fi ìdí yín kalẹ̀. 11 Tìrẹ ni ògo àti agbára títí láé. Àmín.

Àwọn ìkíni ìkẹyìn

12 Nítorí Sila, arákùnrin wa olóòtítọ́ gẹ́gẹ́ bí mo ti kà á sí, ni mo kọ̀wé kúkúrú sí i yín, tí mo ń gbà yín níyànjú, tí mo sì ń jẹ́rìí pé, èyí ni òtítọ́ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run: ẹ dúró ṣinṣin nínú rẹ̀.

13 Ìjọ tí ń bẹ ní Babeli, tí a yàn, pẹ̀lú kí yín, bẹ́ẹ̀ sì ni Marku ọmọ mi pẹ̀lú.

14 Ẹ fi ìfẹ́nukonu ìfẹ́ kí ara, yín.

Àlàáfíà fún gbogbo yín tí ẹ wà nínú Kristi.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.