Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Numeri 9

Àsè ìrékọjá

(A)Olúwa sọ fún Mose nínú aginjù Sinai ní oṣù kìn-ín-ní ọdún kejì lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti wí pé; “Mú kí àwọn ọmọ Israẹli máa pa àjọ ìrékọjá mọ́ ní àsìkò rẹ̀. Ẹ ṣe é ní àsìkò rẹ̀ gan an ní ìdajì ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí ní ìbámu pẹ̀lú àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀.”

Mose sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n máa pa àjọ ìrékọjá mọ́. Wọ́n sì ṣe àjọ ìrékọjá ní aginjù Sinai ní ìdajì ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe gbogbo nǹkan gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Àwọn díẹ̀ nínú wọn kò lè ṣe àjọ Ìrékọjá lọ́jọ́ náà nítorí pé wọ́n di aláìmọ́ nítorí òkú ènìyàn. Nítorí èyí wọ́n wá sọ́dọ̀ Mose àti Aaroni lọ́jọ́ náà. Wọ́n sọ fún Mose pé, “A di aláìmọ́ nípa òkú ènìyàn, ṣùgbọ́n kí ló dé tí a kò fi ní í le è fi ọrẹ wa fún Olúwa pẹ̀lú àwọn ará Israẹli yòókù ní àsìkò tí a ti yàn.”

Mose sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ dúró kí n ba lè mọ ohun tí Olúwa yóò pàṣẹ nípa yín.”

Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, 10 “Sọ fún àwọn ará Israẹli: ‘Bí ẹnìkan nínú yín tàbí nínú ìran yín bá di aláìmọ́ nípa òkú ènìyàn tàbí bí ó bá lọ sí ìrìnàjò síbẹ̀ yóò pa àjọ Ìrékọjá Olúwa mọ́. 11 Wọn yóò ṣe tiwọn ní ìdajì ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejì. Wọn yóò jẹ ẹran náà, pẹ̀lú àkàrà aláìwú àti ewúro. 12 (B)Wọn kò gbọdọ̀ ṣẹ́ ọ̀kankan kù di àárọ̀, wọn kò sì gbọdọ̀ ṣẹ́ eegun rẹ̀. Wọ́n gbọdọ̀ tẹ̀lé gbogbo ìlànà fún ṣíṣe àjọ Ìrékọjá. 13 Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan tó wà ní mímọ́ tí kò sì lọ sí ìrìnàjò bá kọ̀ láti pa àjọ Ìrékọjá mọ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀ nítorí pé kò mú ọrẹ Olúwa wá ní àsìkò tí ó yẹ. Ẹni náà yóò sì ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

14 “ ‘Bí àlejò tí ń gbé láàrín yín bá fẹ́ ṣe Àjọ Ìrékọjá Olúwa, ó gbọdọ̀ pa á mọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà àti òfin rẹ̀. Ìlànà kan náà ni kí ẹ ní fún àlejò àti àwọn ọmọ bíbí ilẹ̀ yín.’ ”

Ìkùùkuu lórí àgọ́

15 (C)Ní ọjọ́ tí wọ́n gbé àgọ́ ró, èyí tí í ṣe àgọ́ ẹ̀rí, dúró, ìkùùkuu àwọsánmọ̀ bò ó mọ́lẹ̀. Ìkùùkuu náà sì dàbí iná ní orí àgọ́ láti ìrọ̀lẹ́ títí di òwúrọ̀. 16 Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí nígbà gbogbo; ìkùùkuu bò ó, àti pé ní alẹ́ ìrísí rẹ̀ sì dàbí iná. 17 Nígbàkígbà tí ìkùùkuu yìí bá ká sókè kúrò lórí àgọ́ ni àwọn ọmọ Israẹli yóò dìde láti máa lọ; ibikíbi tí ìkùùkuu náà bá dúró sí ni àwọn ọmọ Israẹli yóò pa ibùdó wọn sí. 18 Nípa àṣẹ Olúwa ni àwọn ọmọ Israẹli ń jáde lọ, nípa àṣẹ Olúwa náà sì ni wọ́n ń pa ibùdó wọn. Nígbà tí ìkùùkuu bá dúró sórí àgọ́, àwọn náà yóò dúró sí ibùdó. 19 Nígbà tí ìkùùkuu bá dúró sórí àgọ́ fún ìgbà pípẹ́, síbẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli gbọ́rọ̀ sí àṣẹ Olúwa wọn kò sì ní gbéra láti lọ. 20 Ìgbà mìíràn ìkùùkuu lè wà lórí àgọ́ fún ọjọ́ díẹ̀; síbẹ̀ ní àṣẹ Olúwa, wọn yóò dúró ní ibùdó, bí ó sì tún yá, ní àṣẹ rẹ̀ náà ni wọn yóò gbéra. 21 Ìgbà mìíràn ìkùùkuu lè dúró láti ìrọ̀lẹ́ di àárọ̀, nígbà tó bá ṣí kúrò ní àárọ̀, wọn ó gbéra. Ìbá à ṣe ní ọ̀sán tàbí òru, ìgbàkígbà tí ìkùùkuu bá tó kúrò náà ni wọn ó tó gbéra. 22 Ìbá à ṣe fún ọjọ́ méjì, oṣù kan tàbí ọdún kan ni ìkùùkuu fi dúró sórí àgọ́, àwọn ọmọ Israẹli yóò dúró ní ibùdó wọn, wọn kò ní gbéra; ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá lọ sókè ni wọn ó tó o gbéra. 23 Nípa àṣẹ Olúwa ni wọ́n ń pa ibùdó wọn, nípa àṣẹ Olúwa náà sì ni wọ́n ń gbéra. Wọ́n gbọ́rọ̀ sí àṣẹ Olúwa ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mose.

Saamu 45

Fún adarí orin. Tí ohun orin “Lílì.” Ti orin àwọn ọmọ Kora. Maskili. Orin ìgbéyàwó.

45 Ọkàn mi mọ ọ̀rọ̀ rere
    gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń sọ ohun tí mo ti ṣe fún ọba
    ahọ́n mi ni kálámù ayára kọ̀wé.

Ìwọ yanjú ju àwọn ọmọ ènìyàn lọ:
    a da oore-ọ̀fẹ́ sí ọ ní ètè:
    nítorí náà ni Ọlọ́run ṣe bùkún fún ọ láéláé.

Gba idà rẹ mọ́ ìhà rẹ, ìwọ alágbára jùlọ
    wọ ara rẹ ní ògo àti ọláńlá.
Nínú ọláńlá rẹ, máa gẹṣin lọ ní àlàáfíà
    lórí òtítọ́, ìwà tútù àti òtítọ́
    jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ohun ẹ̀rù.
Jẹ́ kí ọfà mímú rẹ̀ dá ọkàn àwọn ọ̀tá ọba lu
    jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.
(A)Ọlọ́run láé, àti láéláé ni ìtẹ́ rẹ,
    ọ̀pá aládé ìjọba rẹ, ọ̀pá aládé òtítọ́ ni.
Ìwọ fẹ́ olódodo, ìwọ sì kórìíra ìwà búburú
    nígbà náà Ọlọ́run, Ọlọ́run rẹ ti yàn ọ́ ṣe olórí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ,
    nípa fífi ààmì òróró ayọ̀ kùn ọ́.
Gbogbo aṣọ rẹ̀ ni ó ń rùn pẹ̀lú òjìá àti aloe àti kasia;
    láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe
    orin olókùn tẹ́ẹ́rẹ́ mú inú rẹ̀ dùn.
Àwọn ọmọbìnrin àwọn ọba
    wà nínú àwọn àyànfẹ́ rẹ̀,
ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni ayaba náà gbé dúró
    nínú wúrà ofiri.

10 Gbọ́ ìwọ ọmọbìnrin, ronú kí o sì dẹtí rẹ sí mi
    gbàgbé àwọn ènìyàn rẹ àti ilé baba rẹ
11 Bẹ́ẹ̀ ni ọba yóò fẹ́ ẹwà rẹ gidigidi
    nítorí òun ni olúwa rẹ
kí ìwọ sì máa tẹríba fún un.
12 Ọmọbìnrin ọba Tire yóò wá pẹ̀lú ẹ̀bùn
    àwọn ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yóò máa wá ojúrere rẹ̀.
13 Gbogbo ògo ni ti ọmọbìnrin ọba ní àárín ilé rẹ̀,
    iṣẹ́ wúrà ọnà abẹ́rẹ́ ní aṣọ rẹ̀.
14 Nínú aṣọ olówó iyebíye ni a mú un tọ́ ọba wá,
    àwọn wúńdíá ẹgbẹ́ rẹ̀ tẹ̀lé e, wọ́n sí mú un tọ̀ ọ́ wá.
15 Wọ́n sì mú un wá pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùn
    wọ́n sì wọ ààfin ọba.

16 Ọmọ rẹ̀ ni yóò gba ipò baba rẹ̀
    ìwọ yóò sì fi wọ́n joyè lórí ilẹ̀ gbogbo.

17 Èmí yóò máa rántí orúkọ rẹ̀ ní ìran gbogbo,
    nígbà náà ni orílẹ̀-èdè yóò yìn ọ́ láé àti láéláé.

Orin Solomoni 7

Báwo ni ẹsẹ̀ rẹ ti ní ẹwà tó nínú bàtà,
    Ìwọ ọmọbìnrin ọba!
Oríkèé itan rẹ rí bí ohun ọ̀ṣọ́
    iṣẹ́ ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà
Ìdodo rẹ rí bí àwo
    tí kì í ṣe aláìní ọtí,
ìbàdí rẹ bí òkìtì alikama
    tí a fi lílì yíká.
Ọmú rẹ rí bí abo egbin méjì
    tí wọ́n jẹ́ ìbejì àgbọ̀nrín.
Ọrùn rẹ rí bí ilé ìṣọ́ eyín erin.
Ojú rẹ rí bí adágún ní Heṣboni
    ní ẹ̀bá ẹnu ibodè Bati-Rabbimu.
Imú rẹ rí bí ilé ìṣọ́ Lebanoni
    tí ó kọ ojú sí Damasku.
Bí òkè Karmeli ṣe ṣe adé yí àwọn òkè ká
    Bẹ́ẹ̀ ni irun orí rẹ ṣe adé yí orí rẹ ká
    a fi àìdi irun rẹ mú ọba ní ìgbèkùn.
Báwo ni ẹwà rẹ ti pọ̀ tó
    báwo ni o sì ti dára tó ìwọ olùfẹ́ mi nínú ìfẹ́?
Ìdúró rẹ rí bí igi ọ̀pẹ,
    àti ọmú rẹ bí ìdì èso àjàrà.
Mo ní, “Èmi yóò gun igi ọ̀pẹ lọ;
    Èmi yóò di ẹ̀ka rẹ̀ mú”
Kí ọmú rẹ rí bí ìdì èso àjàrà,
    àti èémí imú rẹ bí i ápù.
    Àti ìfẹnukonu rẹ rí bí ọtí wáìnì tí ó dára jùlọ.
Tí ó kúnná tí ó sì dùn,
    tí ń mú kí ètè àwọn tí ó sùn kí ó sọ̀rọ̀.
10 Ti olùfẹ́ mi ni èmi í ṣe,
    èmi sì ni ẹni tí ó wù ú.
11 Wá, olùfẹ́ mi, jẹ́ kí a lọ sí ibi pápá,
    jẹ́ kí a lo àṣálẹ́ ní àwọn ìletò
12 Jẹ́ kí a lọ sínú ọgbà àjàrà ní kùtùkùtù
    láti wo bí àjàrà rúwé
bí ìtànná àjàrà bá là.
    Àti bí pomegiranate bá ti rudi,
    níbẹ̀ ni èmi yóò ti fi ìfẹ́ mi fún ọ.
13 Àwọn èso mándrákì mú òórùn wọn jáde
    ní ẹnu-ọ̀nà wa ni onírúurú àṣàyàn èso,
èso tuntun àti ọjọ́ pípẹ́
    tí mo ti kó pamọ́ fún ọ, olùfẹ́ mi.

Heberu 7

Melkisedeki jẹ́ àlùfáà

(A)Nítorí Melkisedeki yìí, ọba Salẹmu, àlùfáà Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, ẹni tí ó pàdé Abrahamu bí ó ti ń padà bọ̀ láti ibi pípa àwọn ọba, tí ó sì súre fún un, ẹni tí Abrahamu sì pín ìdámẹ́wàá ohun gbogbo fún. Ní ọ̀nà èkínní orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí “ọba òdodo,” àti lẹ́yìn náà pẹ̀lú, “ọba Salẹmu,” tí í ṣe “ọba àlàáfíà.” Láìní baba, láìní ìyá, láìní ìtàn ìran, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ tàbí òpin ọjọ́ ayé; ṣùgbọ́n a ṣe é bí ọmọ Ọlọ́run; ó wà ní àlùfáà títí.

Ǹjẹ́ ẹ gbà á rò bí ọkùnrin yìí ti pọ̀ tó, ẹni tí Abrahamu baba ńlá fi ìdámẹ́wàá nínú àwọn àṣàyàn ìkógun fún. Àti nítòótọ́ àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Lefi, tí o gba oyè àlùfáà, wọ́n ní àṣẹ láti máa gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí òfin, èyí yìí, lọ́wọ́ àwọn arákùnrin wọn, bí ó tilẹ̀ ti jẹ́ pé, wọn ti inú Abrahamu jáde. Ṣùgbọ́n òun ẹni tí a kò tilẹ̀ pìtàn ìran rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ wọn wá, gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ Abrahamu, ó sì súre fún ẹni tí ó gba ìlérí, láìsí ìjiyàn rárá ẹni kò tó ẹni tí à ń súre fún láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ju ni. Ni apá kan, àwọn ẹni kíkú gba ìdámẹ́wàá; ṣùgbọ́n níbẹ̀, ẹni tí a jẹ́rìí rẹ̀ pé o ń bẹ láààyè nì. Àti bí a ti lè wí, Lefi pàápàá tí ń gba ìdámẹ́wàá, ti san ìdámẹ́wàá nípasẹ̀ Abrahamu. 10 Nítorí o sá à sì ń bẹ ní inú baba rẹ̀, nígbà ti Melkisedeki pàdé rẹ̀.

Jesu fẹ́ràn Melkisedeki

11 (B)Ǹjẹ́ ìbá ṣe pé pípé ń bẹ nípa oyè àlùfáà Lefi, (nítorí pé lábẹ́ rẹ̀ ni àwọn ènìyàn gba òfin), kín ni ó sì tún kù mọ́ tí àlùfáà mìíràn ìbá fi dìde ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ tí Melkisedeki, tí a kò si wí pé ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ tí Aaroni? 12 Nítorí pé bí a ti ń pààrọ̀ iṣẹ́ àlùfáà, a kò sì lè ṣàì máa pààrọ̀ òfin. 13 Nítorí ẹni tí à ń sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀nyí nípa rẹ̀ jẹ́ ẹ̀yà mìíràn, láti inú èyí tí ẹnikẹ́ni kò tì jọ́sìn rí níbi pẹpẹ. 14 Nítorí ó hàn gbangba pé láti inú ẹ̀yà Juda ni Olúwa wa ti dìde; nípa ẹ̀yà yìí Mose kò sọ ohunkóhun ní ti àwọn àlùfáà. 15 Ó sì tún hàn gbangba ju bẹ́ẹ̀ lọ bí ó ti jẹ pé àlùfáà mìíràn dìde ní àpẹẹrẹ ti Melkisedeki. 16 Èyí tí a fi jẹ́, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin nípa ti ara, bí kò ṣe nípa agbára ti ìyè àìlópin. 17 Nítorí a jẹ́rìí pé:

“Ìwọ ni àlùfáà títí láé
    ní ipasẹ̀ ti Melkisedeki.”

18 Nítorí a mú òfin ìṣáájú kúrò nítorí àìlera àti àìlérè rẹ̀. 19 (Nítorí òfin kò mú ohunkóhun pé), a sì mú ìrètí tí ó dára jù wá nípa èyí tí àwa ń súnmọ́ Ọlọ́run.

20 Níwọ́n bí ó sì ti ṣe pé kì í ṣe ní àìbúra ni. Nítorí àwọn àlùfáà tẹ́lẹ̀ jẹ oyè láìsí ìbúra, 21 ṣùgbọ́n ti òun jẹ́ pẹ̀lú ìbúra nígbà tí Ọlọ́run wí fún un pé,

“Olúwa búra,
    kí yóò sì yí padà:
‘Ìwọ ni àlùfáà kan títí láé ni ipasẹ̀ ti Mekisédékì.’ ”

22 Níwọ́n bẹ́ẹ̀ ni Jesu ti di onígbọ̀wọ́ májẹ̀mú tí ó dára jù.

23 Àti nítòótọ́ àwọn púpọ̀ ní a ti fi jẹ àlùfáà, nítorí wọn kò lè wà títí nítorí ikú. 24 Ṣùgbọ́n òun, nítorí tí o wà títí láé, ó ní oyè àlùfáà tí a kò lè rọ̀ ní ipò. 25 Nítorí náà ó sì le gbà wọ́n là pẹ̀lú títí dé òpin, ẹni tí ó bá tọ Ọlọ́run wá nípasẹ̀ rẹ̀, nítorí tí o ń bẹ láààyè títí láé láti máa bẹ̀bẹ̀ fún wọn.

26 Nítorí pé irú olórí àlùfáà bẹ́ẹ̀ ni o yẹ wá, mímọ́, àìlẹ́gàn, àìléèérí, tí a yà sọ́tọ̀ kúrò láàrín àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tí a sì gbéga ju àwọn ọ̀run lọ; 27 Ẹni tí kò ní láti máa rú ẹbọ lójoojúmọ́, bí àwọn olórí àlùfáà, fún ẹ̀ṣẹ̀ ti ara rẹ̀ náà, àti lẹ́yìn náà fún tí àwọn ènìyàn; nítorí èyí ni tí ó ṣe lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ. 28 Nítorí pé òfin a máa fi àwọn ènìyàn tí ó ní àìlera jẹ olórí àlùfáà; ṣùgbọ́n nípa ọ̀rọ̀ ti ìbúra, tí ó ṣe lẹ́yìn òfin, ó fi ọmọ jẹ; ẹni tí a sọ di pípé títí láé.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.