Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Numeri 26

Ìkànìyàn ẹlẹ́ẹ̀kejì

26 (A)Lẹ́yìn àjàkálẹ̀-ààrùn Olúwa sọ fún Mose àti Eleasari ọmọ Aaroni, àlùfáà pé “Ka iye gbogbo àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọ́n; láti ẹni ogun (20) ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ó lè jà lójú ogun ní Israẹli.” Lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ ti Moabu pẹ̀lú Jordani tí ó kọjá Jeriko, Mose àti Eleasari àlùfáà sọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn ó wí pé, “Ka iye àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ọmọ-ogun (20) ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.”

Èyí ni àwọn ọmọ Israẹli tí ó jáde láti Ejibiti wá:

(B)Àwọn ọmọ Reubeni, àkọ́bí ọmọkùnrin Israẹli,

láti ẹni ti ìdílé Hanoku, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé Hanoku ti jáde wá;

Láti ìdílé Pallu, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé àwọn ọmọ Pallu ti jáde wá;

ti Hesroni, ìdílé àwọn ọmọ Hesroni;

ti Karmi, ìdílé àwọn ọmọ Karmi.

Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Reubeni; àwọn tí a sì kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá-mọ́kànlélógún ó-lé-ẹgbẹ̀sán ó-dínàádọ́rin (43,730).

Àwọn ọmọkùnrin Pallu ni Eliabu, àwọn ọmọkùnrin Elifelehu ni Nemueli àti Eliabu, Datani àti Abiramu. Èyí ni Datani àti Abiramu náà tí wọ́n ní òkìkí nínú ìjọ tí ó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí Mose àti Aaroni tí ó sì wà lára àwọn ẹgbẹ́ Kora nígbà tí wọ́n bá Olúwa jà. 10 Ilẹ̀ sì la ẹnu rẹ̀, ó sì gbé wọn mì pọ̀ pẹ̀lú Kora, nígbà tí ẹgbẹ́ rẹ̀ kú níbi tí iná ti run àwọn àádọ́tà-lé-nígba ọkùnrin (250). Tí wọ́n sì di ààmì ìkìlọ̀. 11 Àwọn ọmọ Kora, bí ó ti wù kí ó rí, wọn kò kú.

12 Àwọn ọmọ ìran Simeoni bí ìdílé wọn:

ti Nemueli, ìdílé Nemueli;

ti Jamini, ìdílé Jamini;

ti Jakini, ìdílé Jakini;

13 ti Sera, ìdílé Sera;

tí Saulu, ìdílé Saulu.

14 Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Simeoni, ẹgbàá-mọ́kànlá ó-lé-igba. (22,200) ọkùnrin.

15 Àwọn ọmọ Gadi bí ìdílé wọn:

ti Sefoni, ìdílé Sefoni;

ti Haggi, ìdílé Haggi;

ti Ṣuni, ìdílé Ṣuni;

16 ti Osni, ìdílé Osni;

ti Eri, ìdílé Eri;

17 ti Arodi, ìdílé Arodi;

ti Areli, ìdílé Areli.

18 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gadi tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500).

19 Àwọn ọmọ Juda ni Eri àti Onani, ṣùgbọ́n Eri àti Onani kú ní ilẹ̀ Kenaani.

20 Àti àwọn ọmọ Juda gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:

ti Ṣela, ìdílé Ṣela;

ti Peresi, ìdílé Peresi;

ti Sera, ìdílé Sera.

21 Àwọn ọmọ Peresi:

ti Hesroni, ìdílé Hesroni;

ti Hamulu, ìdílé Hamulu.

22 Wọ̀nyí ni ìdílé Juda; gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá-méjì-dínlógójì ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (76,500).

23 Àwọn ọmọ Isakari gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:

ti Tola, ìdílé Tola;

ti Pufa, ìdílé Pufa;

24 ti Jaṣubu, ìdílé Jaṣubu;

ti Ṣimroni, ìdílé Ṣimroni.

25 Wọ̀nyí ni ìdílé Isakari gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá-méjìlélọ́gbọ̀n ó-lé-ọ̀ọ́dúnrún (64,300).

26 Àwọn ọmọ Sebuluni gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:

ti Seredi, ìdílé Seredi;

ti Eloni, ìdílé Eloni;

ti Jaleeli, ìdílé Jaleeli.

27 Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Sebuluni gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (60,500).

28 Àwọn ọmọ Josẹfu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; Manase àti Efraimu:

29 Àwọn ọmọ Manase:

ti Makiri, ìdílé Makiri (Makiri sì bí Gileadi);

ti Gileadi, ìdílé àwọn ọmọ Gileadi.

30 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gileadi:

ti Ieseri, ìdílé Ieseri;

ti Heleki, ìdílé Heleki

31 àti ti Asrieli, ìdílé Asrieli;

àti ti Ṣekemu, ìdílé Ṣekemu;

32 àti Ṣemida, ìdílé àwọn ọmọ Ṣemida;

àti ti Heferi, ìdílé àwọn ọmọ Heferi.

33 (Ṣelofehadi ọmọ Heferi kò sì ni ọmọkùnrin, bí kò ṣe ọmọbìnrin; orúkọ àwọn ọmọbìnrin ni Mahila, Noa, àti Hogla, Milka àti Tirsa).

34 Wọ̀nyí ni ìdílé Manase tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (52,700).

35 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Efraimu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:

láti ọ̀dọ̀ Ṣutelahi, ìdílé àwọn ọmọ Ṣutelahi;

ti Bekeri, ìdílé àwọn ọmọ Bekeri;

ti Tahani, ìdílé àwọn ọmọ Tahani.

36 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ṣutelahi:

ti Erani, ìdílé àwọn ọmọ Erani;

37 Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Efraimu, àwọn tí a kà nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìn-dínlógún ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (32,500).

Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Josẹfu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.

38 Àwọn ọmọ Benjamini gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn nìyìí:

tí Bela, ìdílé àwọn ọmọ Bela;

ti Aṣbeli, ìdílé àwọn ọmọ Aṣbeli;

ti Ahiramu, ìdílé àwọn ọmọ Ahiramu;

39 ti Ṣufamu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣufamu;

ti Hufamu, ìdílé àwọn ọmọ Hufamu.

40 Àwọn ọmọ Bela ní ipasẹ̀ Ardi àti Naamani nìyìí:

ti Ardi, ìdílé àwọn ọmọ Ardi;

ti Naamani, ìdílé àwọn ọmọ Naamani.

41 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Benjamini; gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; àti àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá-méjìlélógún ó-lé-ẹgbẹ̀jọ (45,600).

42 Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dani gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:

ti Ṣuhamu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣuhamu

Wọ̀nyí ni ìdílé Dani gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: 43 Gbogbo ìdílé àwọn ọmọ Ṣuhamu, gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá-méjìlélọ́gbọ̀n ó-lé-irínwó (64,400).

44 Ti àwọn ọmọ Aṣeri gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:

ti Imina, ìdílé àwọn ọmọ Imina;

ti Iṣfi, ìdílé àwọn ọmọ Iṣfi;

ti Beriah, ìdílé àwọn ọmọ Berii;

45 Ti àwọn ọmọ Beriah:

ti Heberi, ìdílé àwọn ọmọ Heberi;

ti Malkieli, ìdílé àwọn ọmọ Malkieli.

46 (Orúkọ ọmọ Aṣeri obìnrin nì jẹ́ Sera.)

47 Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Aṣeri gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá-mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó-lé-egbèje (53,400).

48 Ti àwọn ọmọ Naftali gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:

ti Jasieli, ìdílé àwọn ọmọ Jaseeli:

ti Guni, ìdílé àwọn ọmọ Guni;

49 ti Jeseri, ìdílé àwọn ọmọ Jeṣeri;

ti Ṣillemu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣillemu.

50 Wọ̀nyí ni ìdílé ti Naftali gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá-méjìlélógún ó-lé-egbèje (45,400).

51 Àpapọ̀ iye tí a kà nínú àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó-lé-ẹgbẹ̀sán ó-dínàádọ́rin (601,730).

52 Olúwa sọ fún Mose pé, 53 “Ilẹ̀ náà gbọdọ̀ jẹ́ pínpín fún wọn gẹ́gẹ́ bí ogún wọn gẹ́gẹ́ bí iye orúkọ wọn 54 Fún àwọn ọ̀pọ̀ ni kí ìwọ ó fún ní ogún ìlú púpọ̀ àti fún àwọn tí ó kéré ni kí ìwọ ó fi kékeré fún, ẹnìkọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ gba ogún ìbí tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí a kọ. 55 Rí dájú pé ilẹ̀ yìí gbọdọ̀ jẹ́ fífi ìbò pín gẹ́gẹ́ bí wọn sì ti pọ̀ tó. Gẹ́gẹ́ bí orúkọ ẹ̀yà àwọn baba wọn ni kí wọn kí ó ni í. 56 Olúkúlùkù ogún ìní ni a gbọdọ̀ fi ìbò pín gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pọ̀ tó láàrín ńlá àti kékeré.”

57 (C)Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Lefi tí a kà nínú wọn gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn:

ti Gerṣoni, ìdílé àwọn ọmọ Gerṣoni;

ti Kohati, ìdílé àwọn ọmọ Kohati;

ti Merari, ìdílé àwọn ọmọ Merari.

58 Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Lefi;

ìdílé àwọn ọmọ Libni,

ìdílé àwọn ọmọ Hebroni,

ìdílé àwọn ọmọ Mahili,

ìdílé àwọn ọmọ Muṣi,

ìdílé àwọn ọmọ Kora.

(Kohati ni baba Amramu, 59 Orúkọ aya Amramu sì ń jẹ́ Jokebedi, ọmọbìnrin Lefi, tí ìyá rẹ̀ bí fún Lefi ní Ejibiti. Òun sì bí Aaroni, Mose, àti Miriamu arábìnrin wọn fún Amramu. 60 Aaroni ni baba Nadabu àti Abihu, Eleasari àti Itamari. 61 Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu kú, nígbà tí wọ́n rú ẹbọ níwájú Olúwa nígbà tí wọ́n mú iná àjèjì wá.)

62 Gbogbo àwọn ọmọkùnrin Lefi láti oṣù kan àti ju bẹ́ẹ̀ lọ ẹgbàá-mọ́kànlá ó-lé-lẹ́gbẹ̀rún (23,000). Wọn kò ka wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Israẹli tókù nítorí tí wọ́n kò gba ogún ìní lára wọn.

63 Àwọn wọ̀nyí ni Mose àti Eleasari àlùfáà kà nígbà tí wọ́n ka àwọn ọmọ Israẹli ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá odò Jordani létí Jeriko. 64 (D)Kò sí ẹnìkan nínú àwọn tí Mose àti Aaroni àlùfáà kà nígbà tí wọ́n ka àwọn ọmọ Israẹli ní aginjù Sinai. 65 Nítorí Olúwa ti sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kíkú ni wọn yóò kú sí aginjù, kò sì sí ẹnìkankan nínú wọn tí kò kú àfi Kalebu ọmọ Jefunne, àti Joṣua ọmọ Nuni.

Saamu 69

Fún adarí orin. Tí ohùn “Àwọn Lílì.” Ti Dafidi.

69 Gbà mí, Ọlọ́run,
    nítorí omi ti kún dé ọrùn mi.
Mo ń rì nínú irà jíjìn,
    níbi tí kò sí ibi ìfẹsẹ̀lé.
Mo ti wá sínú omi jíjìn;
    ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀.
Agara dá mi, mo ń pè fún ìrànlọ́wọ́;
    ọ̀fun mí gbẹ, ojú mi ṣú,
nígbà tí èmi dúró de Ọlọ́run mi.
(A)Àwọn tí ó kórìíra mi láìnídìí
    wọ́n ju irun orí mi; lọ
púpọ̀ ni àwọn ọ̀tá mi láìnídìí,
    àwọn tí ń wá láti pa mí run
A fi ipá mú mi
    láti san ohun tí èmi kò jí.

Ìwọ mọ òmùgọ̀ mi, Ọlọ́run;
    ẹ̀bi mi kò pamọ́ lójú rẹ.

Má ṣe dójútì àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ
    nítorí mi,
Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun;
    Má ṣe jẹ́ kí àwọn tó ń wá ọ dààmú nítorí mi,
Ọlọ́run Israẹli.
Nítorí rẹ ni mo ń ru ẹ̀gàn,
    ìtìjú sì bo ojú mi.
Mo jẹ́ àjèjì si àwọn arákùnrin mi;
    àlejò sí àwọn arákùnrin ìyá mi;
(B)Nítorí ìtara ilé rẹ jẹ mí run,
    àti ẹ̀gàn àwọn tí ń gàn ọ́ ṣubú lù mí.
10 Nígbà tí mo sọkún
    tí mo sì ń fi àwẹ̀ jẹ ara mi ní ìyà
èyí náà sì dín ẹ̀gàn mi kù;
11 Nígbà tí mo wọ aṣọ àkísà,
    àwọn ènìyàn ń pa òwe mọ́ mi.
12 Àwọn tí ó jókòó ní ẹnu ibodè ń bú mi,
    mo sì di orin àwọn ọ̀mùtí.

13 Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni
    ìwọ ni èmi ń gbàdúrà mi sí Olúwa,
ní ìgbà ìtẹ́wọ́gbà
    Ọlọ́run, nínú ìfẹ́ títóbi rẹ,
dá mi lóhùn pẹ̀lú ìgbàlà rẹ tí ó dájú.
14 Gbà mí kúrò nínú ẹrẹ̀,
    Má ṣe jẹ́ kí n rì;
gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi,
    kúrò nínú ibú omi.
15 Má ṣe jẹ́ kí ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀
    bẹ́ẹ̀ ni má ṣe jẹ́ kí ọ̀gbìn gbé mi mì
kí o má sì ṣe jẹ́ kí ihò pa ẹnu rẹ̀ dé mọ́ mi.

16 Dá mí lóhùn, Olúwa, nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ;
    nínú ọ̀pọ̀ àánú rẹ yípadà sí mi.
17 Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ fún ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ:
    yára dá mi lóhùn, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú.
18 Súnmọ́ tòsí kí o sì gbà mí là;
    rà mí padà nítorí àwọn ọ̀tá mi.

19 Ìwọ ti mọ ẹ̀gàn mi, ìtìjú mi àti àìlọ́lá;
    Gbogbo àwọn ọ̀tá mi wà níwájú rẹ.
20 Ẹ̀gàn ba ọkàn mi jẹ́, wọ́n fi mí sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́
    Mo ń wá aláàánú, ṣùgbọ́n kò sí,
    mo ń wá olùtùnú, ṣùgbọ́n n kò rí ẹnìkankan.
21 Wọ́n fi òróró fún mi pẹ̀lú ohun jíjẹ mi,
    àti ní òùngbẹ mi, wọ́n fi ọtí kíkan fún mi.

22 Jẹ́ kí tábìlì wọn kí ó di ìkẹ́kùn
    ní iwájú wọn, kí ó sì di okùn dídẹ
    fún àwọn tó wà ní àlàáfíà.
23 Kí ojú wọn kì í ó ṣókùnkùn, kí wọn má ṣe ríran,
    kí ẹ̀yin wọn di títẹ̀ títí láé.
24 (C)Tú ìbínú rẹ jáde sí wọn;
    kí ìbínú gbígbóná rẹ bò wọ́n mọ́lẹ̀.
25 (D)Kí ibùjókòó wọn di ahoro;
    kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé nínú wọn.
26 Nítorí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí ẹni tí ìwọ ti lù,
    àti ìrora àwọn tí ó ti ṣèṣe
27 Fi ẹ̀sùn kún ẹ̀sùn wọn;
    Má ṣe jẹ́ kí wọn pín nínú ìgbàlà rẹ.
28 (E)Jẹ́ kí a yọ wọ́n kúrò nínú ìwé ìyè
    kí á má kà wọ́n pẹ̀lú àwọn olódodo.

29 Ṣùgbọ́n tálákà àti ẹni-ìkáàánú ni èmí,
    Ọlọ́run, jẹ́ kí ìgbàlà rẹ gbé mi lékè.

30 Èmi yóò fi orin gbé orúkọ Ọlọ́run ga
    èmi yóò fi ọpẹ́ gbé orúkọ rẹ̀ ga.
31 Eléyìí tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn ju ọ̀dá màlúù lọ
    ju akọ màlúù pẹ̀lú ìwo rẹ̀ àti bàtà rẹ̀.
32 Àwọn òtòṣì yóò rí, wọn yóò sì yọ̀:
    Ẹ̀yin yóò wá Ọlọ́run, ọkàn yín yóò sì wà láààyè!
33 Olúwa, gbọ́ ti aláìní,
    kì ó sì kọ àwọn ìgbèkùn sílẹ̀.

34 Kí ọ̀run àti ayé yìn ín,
    Òkun àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀,
35 Nítorí tí Ọlọ́run yóò gba Sioni là
    yóò sì tún àwọn ìlú Juda wọ̀nyí kọ́.
Kí wọn ó lè máa gbé ibẹ̀,
    kí wọn ó lè máa ní ní ilẹ̀ ìní.
36 Àwọn ọmọ ọmọ ọ̀dọ̀ ni yóò máa jogún rẹ̀,
    àwọn tí ó fẹ́ orúkọ rẹ ni yóò máa gbé inú rẹ̀.

Isaiah 16

16 Fi ọ̀dọ́-àgùntàn ṣe ẹ̀bùn
    ránṣẹ́ sí aláṣẹ ilẹ̀ náà,
láti Sela, kọjá ní aginjù,
    lọ sí orí òkè ọ̀dọ́mọbìnrin Sioni.
Gẹ́gẹ́ bí alárìnkiri ẹyẹ
    tí a tì jáde kúrò nínú ìtẹ́,
bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn obìnrin Moabu
    ní àwọn ìwọdò Arnoni.

“Fún wa ní ìmọ̀ràn
    ṣe ìpinnu fún wa.
Jẹ́ kí òjìji rẹ dàbí òru,
    ní ọ̀sán gangan.
Fi àwọn ìsáǹsá pamọ́,
    má ṣe fi àwọn aṣàtìpó han
Jẹ́ kí àwọn ìsáǹsá Moabu gbé pẹ̀lú rẹ,
    jẹ́ ààbò fún wọn kúrò lọ́wọ́ ìparun.”

Aninilára yóò wá sí òpin,
    ìparun yóò dáwọ́ dúró;
    òfinràn yóò pòórá kúrò lórí ilẹ̀.
Nínú ìfẹ́ a ó fi ìdí ìjọba kan múlẹ̀,
    ní òdodo ọkùnrin kan yóò jókòó lórí rẹ̀
ẹnìkan láti ilé Dafidi wá.
    Ẹni yóò ṣe ìdájọ́, yóò sì máa wá ìdájọ́,
    yóò sì máa yára wá ohun tí í ṣe òdodo.

Àwa ti gbọ́ nípa ìgbéraga Moabu,
    ìwọ̀sí ìgbéraga rẹ̀ àti fùlenge fùlenge,
gààrù rẹ̀ àti àfojúdi rẹ̀,
    ṣùgbọ́n ìfọ́nnu rẹ̀ jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.
Nítorí náà ni àwọn ará Moabu hu,
    wọ́n jùmọ̀ hu lórí Moabu.
Sọkún kí o sì banújẹ́
    fún àkàrà díndín Kiri-Hareseti.
Gbogbo pápá oko Heṣboni ti gbẹ,
    bákan náà ni àjàrà Sibma rí.
Àwọn aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè
    wọ́n tẹ àwọn àyànfẹ́ àjàrà mọ́lẹ̀,
èyí tí ó ti fà dé Jaseri
    ó sì ti tàn dé agbègbè aginjù.
Àwọn èhíhù rẹ̀ fọ́n jáde,
    ó sì lọ títí ó fi dé Òkun.
Nítorí náà mo sọkún, gẹ́gẹ́ bí Jaseri ṣe sọkún,
    fún àwọn àjàrà Sibma.
Ìwọ Heṣboni, Ìwọ Eleale,
    mo bomirin ọ́ pẹ̀lú omi ojú!
Igbe ayọ̀ lórí àwọn èso pípọ́n rẹ
    àti lórí ìkórè èyí tí o ti mọ́wọ́dúró.
10 Ayọ̀ àti ìdùnnú ni a ti mú kúrò
    nínú ọgbà-igi eléso rẹ;
kò sí ẹnìkan tí ó kọrin tàbí
    kígbe nínú ọgbà àjàrà:
ẹnikẹ́ni kò fún ọtí níbi ìfúntí,
    nítorí mo ti fi òpin sí gbogbo igbe.
11 Ọkàn mi kérora fún Moabu gẹ́gẹ́ bí i dùùrù,
    àní tọkàntọkàn mi fún ìlú Kiri-Hareseti.
12 Nígbà tí Moabu farahàn ní ibi gíga rẹ̀,
    ó ṣe ara rẹ̀ ní wàhálà lásán;
Nígbà tí ó lọ sí ojúbọ rẹ̀ láti gbàdúrà
    òfo ni ó jásí.

13 Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa Moabu. 14 Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí Olúwa wí pé: “Láàrín ọdún mẹ́ta gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀fà tí ó wà lábẹ́ ìdè ọgbà rẹ̀ ti máa kà á, ògo Moabu àti àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn rẹ̀ ni a ó kẹ́gàn, àwọn tí ó sálà nínú rẹ̀ yóò kéré níye, wọn yóò sì jẹ́ akúrẹtẹ̀.”

1 Peteru 4

Ìgbé ayé fún Ọlọ́run

Ǹjẹ́ bí Kristi ti jìyà fún wa nípa ti ará, irú kan náà ni kí ẹ̀yin fi hámọ́ra; nítorí ẹni tí ó bá ti jìyà nípa ti ara, ó ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀; Kí ẹ̀yin má ṣe fi ìgbà ayé yín ìyókù wà nínú ara mọ́ sí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ènìyàn bí kò ṣe sí ìfẹ́ Ọlọ́run. Nítorí ìgbà tí ó ti kọjá ti tó fún ṣíṣe ìfẹ́ àwọn aláìkọlà, rínrìn nínú ìwà wọ̀bìà, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ọtí àmupara, ìréde òru, kíkó ẹ̀gbẹ́ ọ̀mùtí, àti ìbọ̀rìṣà tí í ṣe ohun ìríra. Èyí tí ó yà wọ́n lẹ́nu pé ẹ̀yin kò ba wọn súré sínú irú àṣejù ìwà wọ̀bìà wọ́n, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ yín ní búburú. Àwọn ẹni tí yóò jíyìn fún ẹni tí ó ti múra láti ṣe ìdájọ́ alààyè àti òkú. Nítorí èyí ní a sá ṣe wàásù ìhìnrere fún àwọn òkú, kí a lè ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ènìyàn nípa ti ara, ṣùgbọ́n kí wọ́n lè wà láààyè si Ọlọ́run nípa tí Ẹ̀mí.

Ṣùgbọ́n òpin ohun gbogbo kù sí dẹ̀dẹ̀; nítorí náà kí ẹ̀yin wà ní àìrékọjá, kí ẹ sì máa ṣọ́ra nínú àdúrà. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ní ìfẹ́ tí ó gbóná láàrín ara yín: nítorí ìfẹ́ ni ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀. Ẹ máa ṣe ara yín ni àlejò láìsí ìkùnsínú. 10 Bí olúkúlùkù ti rí ẹ̀bùn gbà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa ṣe ìpín fún ni rẹ̀ láàrín ara yín, bí ìríjú rere tí onírúurú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. 11 Bí ẹnikẹ́ni ba ń sọ̀rọ̀, kí o máa sọ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bí ẹnikẹ́ni bá ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, kí ó ṣe é bí agbára tí Ọlọ́run fi fún un, kí a lè máa yin Ọlọ́run lógo ní ohun gbogbo nípa Jesu Kristi, ẹni tí ògo àti ìjọba wà fún láé àti láéláé. Àmín.

Jíjìyà fun jíjẹ́ onígbàgbọ́

12 Olùfẹ́, ẹ má ṣe ka ìdánwò gbígbóná ti ń bẹ láàrín yín láti dán yín wò bi ẹni pé ohun àjèjì ni ó dé bá yín: 13 Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí ẹ̀yin tí jẹ́ alábápín ìyà Kristi, ẹ máa yọ̀, kí ẹ̀yin lè yọ ayọ̀ púpọ̀ nígbà tí a bá fi ògo rẹ̀ hàn. 14 (A)Bí a bá gàn yín nítorí orúkọ Kristi, ẹni ìbùkún ni yín: nítorí Ẹ̀mí Ògo àti ti Ọlọ́run bà lé yín. 15 Ṣùgbọ́n ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín jìyà bí apànìyàn, tàbí bí olè, tàbí bí olùṣe búburú, tàbí bí ẹni tí ń tojú bọ̀ ọ̀ràn ẹlòmíràn. 16 Ṣùgbọ́n bí ó bá jìyà bí Kristiani kí ojú má ṣe tì í: ṣùgbọ́n kí ó kúkú yin Ọlọ́run lógo nítorí ti o orúkọ yìí. 17 Nítorí ti ìgbà náà dé, tí ìdájọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ láti ilé Ọlọ́run wá: bí ó bá sì tètè tí ọ̀dọ̀ wa bẹ̀rẹ̀, ìgbẹ̀yìn àwọn tí kò gba ìhìnrere Ọlọ́run yó ha ti rí?

18 (B)“Bí ó bá ṣe pé agbára káká ni a fi gba olódodo là,
    níbo ni aláìwà-bí-Ọlọ́run àti ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò yọjú sí?”

19 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí àwọn tí ń jìyà gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run ni ṣíṣe rere, fi ọkàn wọn lè Ẹlẹ́dàá olóòtítọ́ lọ́wọ́.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.