M’Cheyne Bible Reading Plan
Omi Ìwẹ̀nùmọ́
19 Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé: 2 “Èyí ni ohun tí òfin Olúwa pàṣẹ béèrè lọ́wọ́ yín: Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí wọn mú ẹgbọrọ ọ̀dọ́ màlúù pupa tí kò lábùkù tàbí àbàwọ́n, lára èyí tí a kò tí ì di àjàgà mọ́. 3 Ẹ mú fún Eleasari àlùfáà, yóò sì mu jáde lọ sí ẹ̀yìn ibùdó kí ó sì pa á ní ojú rẹ. 4 Nígbà náà ni Eleasari àlùfáà yóò mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sórí ìka ọwọ́ rẹ̀ yóò sì wọn lẹ́ẹ̀méje ní ọ̀kánkán iwájú àgọ́ ìpàdé. 5 Ní ojú rẹ̀ ni àlùfáà yóò ti sun ọ̀dọ́ abo màlúù yìí: awọ ara rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹran-ara àti ìgbẹ́ rẹ̀. 6 Àlùfáà yóò mú igi kedari, hísópù àti òwú òdòdó yóò sì jù wọ́n sí àárín ọ̀dọ́ abo màlúù tí a ń sun. 7 Lẹ́yìn náà, àlùfáà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ ara rẹ̀ pẹ̀lú omi lẹ́yìn náà ó lè wá sínú àgọ́. Ṣùgbọ́n yóò jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. 8 Ẹni tí ó sun ún náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀ pẹ̀lú omi, òun náà yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.
9 “Ẹni tó wà ní mímọ́ ni yóò kó eérú ọ̀dọ́ màlúù náà lọ sí ibi tí a yà sí mímọ́ lẹ́yìn ibùdó. Kí gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli kó o pamọ́ fún lílò fún omi ìwẹ̀nùmọ́. Ó jẹ́ ìwẹ̀nùmọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. 10 Ọkùnrin tí ó kó eérú ọ̀dọ́ abo màlúù náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, òun náà yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà láéláé fún àwọn ọmọ Israẹli àti fún àwọn àjèjì tí ó ń gbé láàrín wọn.
11 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú ẹnikẹ́ni, yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje. 12 Ó gbọdọ̀ wẹ ara rẹ̀ pẹ̀lú omi ní ọjọ́ kẹta àti ní ọjọ́ keje; nígbà náà ni yóò jẹ́ mímọ́. Ṣùgbọ́n tí ó bá jẹ́ pé kò wẹ ara rẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kẹta àti ní ọjọ́ keje yóò jẹ́ aláìmọ́. 13 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú ẹnìkan tí kò sì wẹ ara rẹ̀ mọ́, ó ba àgọ́ Olúwa jẹ́. A ó ké irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ọmọ Israẹli. Nítorí pé a kò tí ì wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ lé e lórí, ó jẹ́ aláìmọ́, àìmọ́ rẹ̀ sì wà lára rẹ̀.
14 “Èyí ni òfin tí ó jẹ mọ́ bí ènìyàn bá kú nínú àgọ́: Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ inú àgọ́ àti ẹni tí ó wà nínú àgọ́ yóò di aláìmọ́ fún ọjọ́ méje, 15 Gbogbo ohun èlò tí a kò bá fi omọrí dé ni yóò jẹ́ aláìmọ́.
16 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá wà ní ìta tí ó sì fi ọwọ́ kan ẹni tí a fi idà pa tàbí ẹni tí ó kú ikú àtọ̀runwá, tàbí bí ẹnìkan bá fi ọwọ́ kan egungun òkú ènìyàn tàbí isà òkú, yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje.
17 “Fún aláìmọ́ ènìyàn, mú eérú díẹ̀ lára eérú ọrẹ ìwẹ̀nùmọ́ sínú ìgò, kí o sì da omi tó ń sàn lé e lórí. 18 Nígbà náà, ọkùnrin tí a yà sí mímọ́ yóò mú hísópù díẹ̀ yóò rì í sínú omi yóò sì fi wọ́n àgọ́ àti gbogbo ohun èlò tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ àti àwọn ènìyàn tí ó wà níbẹ̀. O gbọdọ̀ tún fi wọ́n ẹnikẹ́ni tí ó fi ọwọ́ kan egungun òkú ènìyàn tàbí isà òkú, tàbí ẹni tí ó kú ikú ara rẹ̀, tàbí ẹni tí ó kú ikú àti ọ̀run wá. 19 Ọkùnrin tí ó mọ́ ni kí ó bu omi wọ́n àwọn ènìyàn aláìmọ́ ní ọjọ́ kẹta àti ọjọ́ keje, ní ọjọ́ keje ó gbọdọ̀ wẹ ara rẹ̀ mọ́, Ẹni tí a wẹ̀mọ́ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀ pẹ̀lú omi, ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà yóò mọ́. 20 Ṣùgbọ́n bí ẹni tí ó bá jẹ́ aláìmọ́ kò bá wẹ ara rẹ̀ mọ́, a gbọdọ̀ gé e kúrò nínú ìjọ ènìyàn, nítorí wí pé ó ti ba àgọ́ Olúwa jẹ́. A kò tí ì fi omi ìwẹ̀nùmọ́ sí ara rẹ̀, ó sì jẹ́ aláìmọ́. 21 Èyí jẹ́ ìlànà láéláé fún wọn.
“Ọkùnrin tí ó wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ àti ẹnikẹ́ni tí ó fi ọwọ́ kan omi ìwẹ̀nùmọ́ yóò di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. 22 Gbogbo ohun tí ẹni tí ó jẹ́ aláìmọ́ bá fi ọwọ́ kàn yóò di àìmọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ọwọ́ kàn án yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.”
Fún adarí orin. Ti ohùn “Àdàbà lórí Óákù òkè réré.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí àwọn ará Filistini ka mọ́ ní Gati.
56 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, nítorí àwọn ènìyàn ń fi ìgbónára lépa mi;
ní gbogbo ọjọ́ ni wọn ń kọjú ìjà
sí mi, wọn ń ni mi lára.
2 Àwọn ọ̀tá mi ń lé mi ní gbogbo ọjọ́,
àwọn ènìyàn ń kọjú ìjà sí mi nínú ìgbéraga wọn.
3 Nígbà tí ẹ̀rù bà ń bà mí,
èmi o gbẹ́kẹ̀lé ọ.
4 Nínú Ọlọ́run èmi yóò máa yìn ọ̀rọ̀ rẹ,
nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi; ẹ̀rù kì yóò bà mí
kí ni ẹran-ara lè ṣe sí mi?
5 Wọn ń yí ọ̀rọ̀ mí ní gbogbo ọjọ́,
wọn ń gbèrò nígbà gbogbo láti ṣe mí níbi.
6 Wọn kó ara wọn jọ, wọ́n ba
Wọ́n ń ṣọ́ ìgbésẹ̀ mi
wọn ń làkàkà láti gba ẹ̀mí mi.
7 San ẹ̀san iṣẹ́ búburú wọ́n fún wọn;
Ní ìbínú rẹ, Ọlọ́run, wọ́ àwọn ènìyàn náà bọ́ sílẹ̀.
8 Kọ ẹkún mi sílẹ̀;
kó omijé mi sí ìgò rẹ,
wọ́n kò ha sí nínú ìkọ̀sílẹ̀ rẹ bí?
9 Nígbà náà ni àwọn ọ̀tá mi yóò pẹ̀yìndà
nígbà tí mo bá pè fún ìrànlọ́wọ́
nípa èyí ni mo mọ̀ pé Ọlọ́run ń bẹ fún mi.
10 Nínú Ọlọ́run, ẹni tí mo yìn ọ̀rọ̀ rẹ̀
nínú Olúwa, ẹni tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀:
11 Nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi:
ẹ̀rù kì yóò bà mí.
Kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi?
12 Mo jẹ́ ẹ̀jẹ́ lábẹ́ rẹ Ọlọ́run:
èmi o mú ìyìn mi wá fún ọ.
13 Nítorí ìwọ tí gbà mí lọ́wọ́ ikú
àti ẹsẹ̀ mi lọ́wọ́ ìṣubú,
kí èmí lè máa rìn níwájú Ọlọ́run
ní ìmọ́lẹ̀ àwọn alààyè.
Fún adarí orin. Ní ohùn “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí ó sá níwájú Saulu lọ sínú ihò òkúta.
57 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, ṣàánú fún mi,
nítorí nínú rẹ ni ààbò ọkàn mí wà.
Èmi o fi ààbò mí sí ibi ìyẹ́ apá rẹ
títí tí ewu yóò fi kọjá lọ.
2 Mo kígbe sókè sí Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ,
sí Ọlọ́run tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ fún mi.
3 Òun yóò ránṣẹ́ láti ọ̀run wá,
yóò sì gbà mí, bí ẹni tí ń fẹ́ gbé mi mì
tilẹ̀ ń kẹ́gàn mi.
Ọlọ́run yóò rán àánú rẹ̀ àti òdodo rẹ̀ jáde.
4 Mo wà ní àárín àwọn kìnnìún;
mo dùbúlẹ̀ ni abẹ́ àwọn ẹ̀dá búburú,
àwọn ènìyàn tí eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ àti ọfà
ẹni tí ahọ́n rẹ̀ jẹ́ idà mímú.
5 Kí a yìn ọ́ Ọlọ́run, ju ọ̀run lọ,
kí ògo rẹ kò ju ti gbogbo ayé lọ.
6 Wọ́n ti ta àwọ̀n sílẹ̀ fún ẹsẹ̀ mi:
a tẹ orí ọkàn mi ba nínú ìtìjú,
wọ́n gbẹ́ kòtò sí ọ̀nà mi:
ṣùgbọ́n wọ́n ti jì síbẹ̀ fún ara wọn.
7 (A)Ọkàn mi ti múra Ọlọ́run;
ọkàn mi ti múra, èmi ó kọrin, èmi ó si máa kọrin ìyìn.
8 Jí, ìwọ ọkàn mi!
Jí, ohun orin èlò àti dùùrù!
Èmi tìkára mi, yóò sì jí ní kùtùkùtù.
9 Èmi ó máa yìn ọ́, Olúwa, láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;
èmi ó máa kọrin sí ọ láàrín àwọn ènìyàn.
10 Nítorí títóbi ní ìfẹ́ rẹ, tí ó dé ọ̀run;
òtítọ́ rẹ tàn dé àwọsánmọ̀.
11 Gbígbéga ni ọ́, Ọlọ́run, ju àwọn ọ̀run lọ;
kí ògo rẹ kí ó ju gbogbo ayé lọ.
Isaiah àti ọmọ rẹ jẹ ààmì
8 Olúwa sọ fún mi pé, mú ìwé ńlá kan, kí o sì fi kálàmù ìkọ̀wé lásán kọ Maha-Ṣalali-Haṣi-Basi: 2 Èmi yóò sì mú Uriah àlùfáà àti Sekariah ọmọ Jeberekiah gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí òtítọ́ wá sí ọ̀dọ̀ mi.
3 Lẹ́yìn náà, mo lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì obìnrin náà, ó sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Olúwa sì wí fún mi pé, “Pe orúkọ rẹ̀ ní Maha-Ṣalali-Haṣi-Basi. 4 Kí ọmọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń sọ pé ‘Baba mi’ tàbí ‘Ìyá mi’ gbogbo ọrọ̀ Damasku àti ìkógun ti Samaria ni ọba àwọn Asiria yóò ti kó lọ.”
5 Olúwa sì tún sọ fún mi pé:
6 Nítorí pé àwọn ènìyàn yìí ti kọ
omi Ṣiloa tí ń sàn jẹ́ẹ́jẹ́ sílẹ̀
tí wọ́n sì ń yọ̀ nínú Resini
àti ọmọ Remaliah,
7 Ǹjẹ́ nítorí náà kíyèsi i, Olúwa ń fa omi odò tí ó le,
tí ó sì pọ̀ wá sórí wọn,
àní, ọba Asiria àti gbogbo ògo rẹ̀,
yóò sì wá sórí gbogbo ọ̀nà odò rẹ̀,
yóò sì gun orí gbogbo bèbè rẹ̀,
8 yóò sì gbá àárín Juda kọjá,
yóò sì ṣàn bò ó mọ́lẹ̀, yóò sì mú un dọ́rùn.
Nínà ìyẹ́ apá rẹ̀ yóò sì bo gbogbo ìbú ilẹ̀ rẹ̀,
ìwọ Emmanueli.
9 Ké ariwo ogun, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, kí a sì fọ́ ọ yín túútúú,
fetísílẹ̀, ẹ̀yin ilẹ̀ jíjìn réré.
Ẹ palẹ̀mọ́ fún ogun, kí a sì fọ́ ọ túútúú!
10 Ẹ gbìmọ̀ pọ̀, yóò sì di asán;
Ẹ gbèrò ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n kì yóò dúró,
nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa.
Bẹ̀rù Ọlọ́run
11 Olúwa bá mi sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ̀ o ìkìlọ̀ fún mi pé, èmi kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Ó wí pé:
12 (A)“Má ṣe pe èyí ní ọ̀tẹ̀
gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn yìí pè ní ọ̀tẹ̀,
má ṣe bẹ̀rù ohun tí wọ́n bá bẹ̀rù,
má sì ṣe fòyà rẹ̀.
13 Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni Ẹni tí ìwọ yóò kà sí mímọ́,
Òun ni kí o bẹ̀rù
Òun ni kí àyà rẹ̀ fò ọ́,
14 (B)Òun yóò sì jẹ́ ibi mímọ́
ṣùgbọ́n fún ilé Israẹli méjèèjì ni yóò jẹ́, òkúta tí í mú ni kọsẹ̀
àti àpáta tí ó mú wọn ṣubú
àti fún àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ni yóò jẹ́ tàkúté àti ìdẹ̀kùn.
15 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni yóò kọsẹ̀,
wọn yóò ṣubú wọn yóò sì fọ́ yángá,
okùn yóò mú wọn, ọwọ́ yóò sì tẹ̀ wọ́n.”
16 Di májẹ̀mú náà
kí o sì fi èdìdì di òfin náà láàrín àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi.
17 (C)Èmi yóò dúró de Olúwa,
ẹni tí ó ń fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún ilé Jakọbu.
Mo fi ìgbẹ́kẹ̀lé mi sínú rẹ.
18 Èmi nìyí, àti àwọn ọmọ tí Olúwa fi fún mi. Àwa jẹ́ ààmì àti àpẹẹrẹ ní Israẹli láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ẹni tí ó ń gbé ní òkè Sioni.
19 Nígbà tí àwọn ènìyàn bá sọ fún un yín pé kí ẹ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀ àti àwọn oṣó, ti máa ń kún tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ǹjẹ́ kò ha yẹ kí àwọn ènìyàn béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run wọn bí? Èéṣe tí ẹ fi ń bá òkú sọ̀rọ̀ ní orúkọ alààyè? 20 Sí òfin àti májẹ̀mú! Bí wọn kò bá sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ yìí, wọn kò rí ìmọ́lẹ̀ ọjọ́. 21 Nínú ìnilára àti ebi, ni wọn yóò máa kọjá lọ láàrín ilẹ̀ náà, nígbà tí ebi bá pa wọ́n, nígbà yìí ni wọn yóò máa kanra, wọn yóò wòkè, wọn yóò sì fi ọba àti Ọlọ́run wọn ré. 22 Nígbà náà ni wọn yóò sì wolẹ̀, wọn yóò sì rí ìpọ́njú, òkùnkùn àti ìpòrúru tí ó ba ni lẹ́rù, a ó sì sọ wọ́n sínú òkùnkùn biribiri.
A bí ọmọ kan fún wa
9 (D)Síbẹ̀síbẹ̀, kò ní sí ìpòrúru kankan mọ́ fún àwọn tí ó wà nínú ìbànújẹ́. Nígbà kan rí ó rẹ ilẹ̀ Sebuluni sílẹ̀ àti ilẹ̀ Naftali pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ iwájú, yóò bu ọ̀wọ̀ fún Galili ti àwọn aláìkọlà, ní ọ̀nà Òkun, ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ Jordani.
2 Àwọn ènìyàn tí ń rìn nínú òkùnkùn
ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá;
Lórí àwọn tí ń gbé nínú ilẹ̀ òjìji ikú,
ní ara wọn ni ìmọ́lẹ̀ mọ́ sí.
3 Ìwọ ti sọ orílẹ̀-èdè di ńlá;
wọ́n sì yọ̀ níwájú rẹ
gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ti í yọ ayọ̀ ìkórè,
gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ti í yọ̀
nígbà tí à ń pín ìkógun.
4 Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí a ṣẹ́gun Midiani,
ìwọ ti fọ́ ọ túútúú
àjàgà ti ń pa wọ́n lẹ́rù,
ọ̀pá tí ó dábùú èjìká wọn,
ọ̀gọ aninilára wọn.
5 Gbogbo bàtà jagunjagun tí a ti lò lójú ogun
àti gbogbo ẹ̀wù tí a yí nínú ẹ̀jẹ̀,
ni yóò wà fún ìjóná,
àti ohun èlò iná dídá.
6 Nítorí a bí ọmọ kan fún wa,
a fi ọmọkùnrin kan fún wa,
ìjọba yóò sì wà ní èjìká rẹ̀.
A ó sì máa pè é ní: Ìyanu
Olùdámọ̀ràn, Ọlọ́run Alágbára
Baba ayérayé, Ọmọ ọba aládé Àlàáfíà.
7 Ní ti ìgbòòrò Ìjọba rẹ̀ àti àlàáfíà rẹ̀ ni kì yóò ní ìpẹ̀kun.
Yóò jẹ ọba lórí ìtẹ́ Dafidi
àti lórí ẹ̀kún un rẹ̀ gbogbo,
nípa ìfìdímúlẹ̀ àti ìgbéró rẹ̀,
pẹ̀lú òtítọ́ àti òdodo
láti ìgbà náà lọ àti títí láéláé.
Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun
ni yóò mú èyí ṣẹ.
Ojúsàájú jẹ́ èèwọ̀
2 Ẹ̀yin ará mi, gẹ́gẹ́ bí onígbàgbọ́ nínú ògo Olúwa wá Jesu Kristi, ẹ máa ṣe ojúsàájú ẹnikẹ́ni. 2 Nítorí bí ọkùnrin kan bá wá sí ìpéjọpọ̀ yín, pẹ̀lú òrùka wúrà àti aṣọ dáradára, tí tálákà kan sì wá pẹ̀lú nínú aṣọ èérí; 3 tí ẹ̀yin sì bu ọlá fún ẹni tí ó wọ aṣọ dáradára tí ẹ sì wí pé, “Ìwọ jókòó níhìn-ín yìí ní ibi dáradára” tí ẹ sì wí fún tálákà náà pé, “Ìwọ dúró níbẹ̀” tàbí “jókòó níhìn-ín lábẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ mi,” 4 ẹyin kò ha ń dá ara yín sí méjì nínú ara yín, ẹ̀yin kò sì di onídàájọ́ tí ó ní èrò búburú bí?
5 Ẹ fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́: Ọlọ́run kò ha ti yan àwọn tálákà ayé yìí láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́, àti ajogún ìjọba náà, tí ó ti ṣe ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ? 6 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti bu tálákà kù. Àwọn ọlọ́rọ̀ kò ha ń pọ́n yin lójú bí; wọn kò ha sì ń wọ́ yín lọ sílé ẹjọ́? 7 Wọn kò ha ń sọ ọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ rere nì tí a fi ń pè yín bí?
8 (A)Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń mú olú òfin nì ṣẹ gẹ́gẹ́ bí Ìwé mímọ́, èyí tí ó wí pé, “Ìwọ fẹ́ ẹni kejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ,” ẹ̀yin ń ṣe dáradára. 9 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń ṣe ojúsàájú ènìyàn, ẹ̀yin ń dẹ́ṣẹ̀, a sì ń dá yín lẹ́bi nípa òfin bí arúfin. 10 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa gbogbo òfin mọ́, tí ó sì rú ọ̀kan, ó jẹ̀bi rírú gbogbo rẹ̀. 11 (B)Nítorí ẹni tí ó wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà,” òun ni ó sì wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn.” Ǹjẹ́ bí ìwọ kò ṣe panṣágà, ṣùgbọ́n tí ìwọ pànìyàn, ìwọ jásí arúfin.
12 Ẹ máa sọ̀rọ̀, ẹ sì máa hùwà, bí àwọn tí a ó fi òfin òmìnira dá lẹ́jọ́. 13 Nítorí ẹni tí kò ṣàánú, ni a ó ṣe ìdájọ́ fún láìsí àánú; àánú ń ṣògo lórí ìdájọ́.
Ìgbàgbọ́ àti àwọn iṣẹ́
14 Èrè kí ni ó jẹ́, ará mi, bí ẹni kan wí pé òun ní ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n tí kò ní àwọn iṣẹ́ láti fihan? Ìgbàgbọ́ náà lè gbà á là bí? 15 Bí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá wà ní àìní aṣọ, tí ó sì ṣe àìní oúnjẹ òòjọ́, 16 Tí ẹni kan nínú yín sì wí fún pé, “Máa lọ ní àlàáfíà, kí ara rẹ kí ó má ṣe tutù, kí ó sì yó,” ṣùgbọ́n ẹ kò fi nǹkan wọ̀n-ọn-nì ti ara ń fẹ́ fún wọn; èrè kí ni ó jẹ́? 17 Bẹ́ẹ̀ sì ni ìgbàgbọ́, bí kò bá ní iṣẹ́ rere, ó kú nínú ara rẹ̀.
18 Ṣùgbọ́n ẹnìkan lè wí pé, “Ìwọ ní ìgbàgbọ́, èmi sì ní iṣẹ́:”
Fi ìgbàgbọ́ rẹ hàn mí ní àìsí iṣẹ́, èmi ó sì fi ìgbàgbọ́ mi hàn ọ́ nípa iṣẹ́ rere mi. 19 Ìwọ gbàgbọ́ pé Ọlọ́run kan ní ó ń bẹ; ó dára! Àwọn ẹ̀mí èṣù pẹ̀lú gbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n sì wárìrì.
20 Ṣùgbọ́n, ìwọ aláìmòye ènìyàn, ìwọ ha fẹ́ ní ìdánilójú pé, ìgbàgbọ́ ní àìsí iṣẹ́ rere asán ni? 21 (C)Kí ha í ṣe nípa iṣẹ́ ni a dá Abrahamu baba wa láre, nígbà tí ó fi Isaaki ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ lórí pẹpẹ? 22 Ìwọ rí i pé ìgbàgbọ́ rẹ bá iṣẹ́ rìn, àti pé nípa iṣẹ́ rere ni a sọ ìgbàgbọ́ di pípé. 23 (D)Ìwé Mímọ́ sì ṣẹ́ tí ó wí pé, “Abrahamu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un,” a sì pè é ní ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. 24 Ǹjẹ́ ẹ̀yin rí i pé nípa iṣẹ́ rere ni à ń dá ènìyàn láre, kì í ṣe nípa ìgbàgbọ́ nìkan.
25 (E)Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú kí a dá Rahabu panṣágà láre nípa iṣẹ́ bí, nígbà tí ó gba àwọn ayọ́lẹ̀wò, tí ó sì rán wọn jáde gba ọ̀nà mìíràn? 26 Nítorí bí ara ní àìsí ẹ̀mí ti jẹ́ òkú, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú ni ìgbàgbọ́ ní àìsí iṣẹ́ jẹ́ òkú.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.