M’Cheyne Bible Reading Plan
Moabu tan Israẹli jẹ
25 Nígbà tí àwọn Israẹli dúró ní Ṣittimu, àwọn ènìyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àgbèrè pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin Moabu, 2 tí ó pè wọ́n sí ibi ẹbọ òrìṣà wọn. Àwọn ènìyàn náà jẹun wọ́n sì foríbalẹ̀ níwájú òrìṣà wọn. 3 Báyìí ni Israẹli ṣe darapọ̀ mọ́ wọn tí wọ́n sì jọ ń sin Baali-Peori. Ìbínú Olúwa sì ru sí wọn.
4 Olúwa sọ fún Mose pé; “Mú gbogbo àwọn olórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, pa wọ́n kí o sì fi wọ́n kọ́ sórí igi ní gbangba nínú oòrùn níwájú Olúwa, kí ìbínú Olúwa lè kúrò ní ọ̀dọ̀ Israẹli.”
5 Mose sọ fún àwọn onídàájọ́ Israẹli, “Ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ pa arákùnrin rẹ̀ èyí tí ó darapọ̀ ní fífi orí balẹ̀ fún Baali-Peori.”
6 Nítòótọ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin Israẹli sì mú obìnrin Midiani wá síwájú ojú Mose àti gbogbo ìjọ ti Israẹli wọ́n sì ń sọkún ní àbáwọlé àgọ́ ìpàdé. 7 Nígbà tí Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni, àlùfáà, rí èyí, ó fi ìjọ sílẹ̀, pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ní ọwọ́ rẹ̀. 8 Ó sì tẹ̀lé arákùnrin Israẹli yìí lọ sínú àgọ́. Ó sì fi ọ̀kọ̀ gún àwọn méjèèjì ní àgúnyọ láti ara ọkùnrin Israẹli àti sí ara obìnrin náà. Nígbà náà ni àjàkálẹ̀-ààrùn lórí àwọn ọmọ Israẹli sì dúró; 9 ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ó kú nínú àjàkálẹ̀-ààrùn náà jẹ́ ẹgbàá-méjìlá. (24,000).
10 Olúwa sì tún sọ fún Mose pé, 11 “Finehasi ọmọ Eleasari ọmọ Aaroni, àlùfáà, ti yí ìbínú mi padà kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli: nítorí tí ó ní ìtara bí èmi náà ti ní ìtara fún iyì mi láàrín wọn, kí ó lè jẹ́ pé èmi ló pa wọ́n run nínú ìtara mi sí wọn. 12 Nítorí náà sọ fún un pé èmi ṣe májẹ̀mú àlàáfíà mi pẹ̀lú rẹ̀. 13 Òun àti irú-ọmọ rẹ̀ yóò ní májẹ̀mú láéláé fún iṣẹ́ àlùfáà, nítorí pé ó ní ìtara fún Ọlọ́run rẹ̀ láti fi yẹ́ Ọlọ́run sí, ó sì ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli.”
14 Orúkọ ọmọ Israẹli tí a pa pẹ̀lú obìnrin Midiani náà ni Simri, ọmọ Salu, olórí ilé kan nínú àwọn ọmọ Simeoni. 15 Orúkọ ọmọbìnrin Midiani náà tí a pa ní Kosbi ọmọbìnrin Suri, tí ṣe olóyè àwọn ẹ̀yà kan nínú ìdílé kan ní Midiani.
16 Olúwa sì tún sọ fún Mose pé, 17 “Ka àwọn ará Midiani sí ọ̀tá, kí o sì pa wọ́n, 18 nítorí pé wọ́n ṣe sí yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá nígbà tí wọ́n tàn yín nípa ìṣẹ̀lẹ̀ Peori, àti arábìnrin wọn Kosbi ọmọbìnrin ìjòyè Midiani kan, obìnrin tí a pa nígbà tí àjàkálẹ̀-ààrùn ṣẹlẹ̀ nítorí Peori.”
Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu. Orin.
68 Kí Ọlọ́run kí ó dìde, kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó fọ́nká;
kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ kí ó sá níwájú rẹ̀.
2 Bí ìjì ti ń fẹ́ èéfín lọ,
kí ó fẹ́ wọn lọ;
bí ìda ti í yọ́ níwájú iná,
kí olùṣe búburú ṣègbé níwájú Ọlọ́run.
3 Ṣùgbọ́n kí inú olódodo kí ó dùn
kí ó sì kún fún ayọ̀ níwájú Ọlọ́run;
kí inú wọn kí ó dùn, kí ó sì kún fún ayọ̀.
4 Ẹ kọrin sí Ọlọ́run,
ẹ kọrin ìyìn sí i,
ẹ la ọ̀nà fún ẹni tí ń rékọjá ní aginjù.
Olúwa ni orúkọ rẹ̀, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú rẹ̀.
5 Baba àwọn aláìní baba àti onídàájọ́ àwọn opó ni Ọlọ́run ní ibùgbé
rẹ̀ mímọ́
6 Ọlọ́run gbé aláìlera
kalẹ̀ nínú ìdílé,
ó darí àwọn ẹlẹ́wọ̀n pẹ̀lú orin,
ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ní ń gbé nínú ilẹ̀ gbígbẹ.
7 Nígbà tí ìwọ bá jáde lónìí níwájú àwọn ènìyàn rẹ, Ọlọ́run,
tí ń kọjá lọ láàrín aginjù, Sela.
8 Ilẹ̀ mì títí,
àwọn ọ̀run ń rọ òjò jáde,
níwájú Ọlọ́run,
ẹni Sinai,
níwájú Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli.
9 Ìwọ fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò, Ọlọ́run;
ìwọ tu ilẹ̀ ìní rẹ̀ lára nígbà tí ó rẹ̀ ẹ́ tan.
10 Àwọn ènìyàn rẹ tẹ̀dó síbẹ̀
nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní rẹ, Ọlọ́run, ìwọ pèsè fún àwọn aláìní.
11 Olúwa ti pàṣẹ ọ̀rọ̀,
púpọ̀ ní ogun àwọn ẹni tí ó ń ròyìn rẹ̀.
12 “Àwọn ọba àti àwọn ológun yára sálọ;
Obìnrin tí ó sì jókòó ni ilé ní ń pín ìkógun náà.
13 Nígbà tí ẹ̀yin dùbúlẹ̀ láàrín agbo ẹran,
nígbà náà ni ẹ̀yin ó dàbí ìyẹ́ àdàbà ti a bò ní fàdákà,
àti ìyẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú wúrà pupa.”
14 Nígbà tí Olódùmarè fọ́n àwọn ọba ká ní ilẹ̀ náà,
ó dàbí òjò dídi ní Salmoni.
15 Òkè Baṣani jẹ́ òkè Ọlọ́run;
òkè tí ó ní orí púpọ̀ ni òkè Baṣani.
16 Kí ló dé tí ẹ̀yin fi ń ṣe ìlara,
ẹ̀yin òkè wúwo, òkè tí Ọlọ́run ti fẹ́ láti jẹ ọba
níbi tí Ọlọ́run fúnrarẹ̀ yóò máa gbé títí láé?
17 Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ni kẹ̀kẹ́ ogun Ọlọ́run
ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún;
Olúwa ń bẹ láàrín wọn, ní Sinai ni ibi mímọ́ rẹ̀.
18 Ìwọ ti gòkè sí ibi gíga
ìwọ ti di ìgbèkùn ní ìgbèkùn lọ;
ìwọ ti gba ẹ̀bùn fún ènìyàn:
nítòótọ́, fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ pẹ̀lú,
Kí Olúwa Ọlọ́run lè máa bá wọn gbé.
19 Olùbùkún ni Olúwa,
Ọlọ́run Olùgbàlà wa,
ẹni tí ó ń fi ojoojúmọ́ gba ẹrù wa rù. Sela.
20 Ọlọ́run wa jẹ́ Ọlọ́run tó ń gbàlà
àti sí Olúwa Olódùmarè ni ó ń gbà wá lọ́wọ́ ikú.
21 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò tẹ orí àwọn ọ̀tá rẹ̀,
àti agbárí onírun àwọn tó ń tẹ̀síwájú nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn
22 Olúwa wí pé, “Èmi ó mú wọn wá láti Baṣani;
èmi ó mú wọn wá láti ibú omi Òkun,
23 Kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó le pọ́n ní inú ẹ̀jẹ̀ àwọn ọ̀tá rẹ,
àti ahọ́n àwọn ajá rẹ ní ìpín tiwọn lára àwọn ọ̀tá rẹ.”
24 Wọ́n ti rí ìrìn rẹ, Ọlọ́run,
ìrìn Ọlọ́run mi àti ọba mi ní ibi mímọ́ rẹ̀.
25 Àwọn akọrin ní iwájú,
tí wọn ń lu ṣaworo
26 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa ní ẹgbẹgbẹ́;
àní fún Olúwa ẹ̀yin tí ó ti orísun Israẹli wá.
27 Níbẹ̀ ní ẹ̀yà kékeré Benjamini wà, tí ó ń darí wọn,
níbẹ̀ ni àwọn ọmọ-aládé Juda,
níbẹ̀ ni àwọn ọmọ-aládé Sebuluni àti tí Naftali.
28 Pàṣẹ agbára rẹ, Ọlọ́run;
fi agbára rẹ hàn wá, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe ní ìṣáájú.
29 Nítorí tẹmpili rẹ ni Jerusalẹmu
àwọn ọba yóò mú ẹ̀bùn wá fún ọ.
30 Bá àwọn ẹranko búburú wí,
tí ń gbé láàrín eèsún
ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akọ màlúù
pẹ̀lú àwọn ọmọ màlúù
títí olúkúlùkù yóò fi foríbalẹ̀ pẹ̀lú ìwọ̀n fàdákà:
tú àwọn ènìyàn tí ń ṣe inú dídùn sí ogun ká
31 Àwọn ọmọ-aládé yóò wá láti Ejibiti;
Etiopia yóò na ọwọ́ rẹ̀ sí Ọlọ́run.
32 Kọrin sí Ọlọ́run, ẹ̀yin ìjọba ayé,
kọrin ìyìn sí Olúwa, Sela.
33 Sí ẹni tí ń gun ọ̀run dé ọ̀run àtijọ́ lókè,
tó ń fọhùn rẹ̀, ohùn ńlá.
34 Kéde agbára Ọlọ́run,
ọláńlá rẹ̀ wà lórí Israẹli,
tí agbára rẹ̀ wà lójú ọ̀run.
35 Ìwọ ní ẹ̀rù, Ọlọ́run, ní ibi mímọ́ rẹ;
Ọlọ́run Israẹli fi agbára àti okun fún àwọn ènìyàn rẹ.
Olùbùkún ní Ọlọ́run!
Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Moabu
15 (A)Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Moabu:
A pa Ari run ní Moabu,
òru kan ní a pa á run!
A pa Kiri run ní Moabu,
òru kan ní a pa á run!
2 Diboni gòkè lọ sí tẹmpili rẹ̀,
sí àwọn ibi gíga rẹ̀ láti sọkún,
Moabu pohùnréré lórí Nebo àti Medeba.
Gbogbo orí ni a fá
gbogbo irùngbọ̀n ni a gé dànù.
3 Wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ní ojú òpópónà,
ní àwọn òrùlé àti àwọn gbàgede ìlú.
Wọ́n pohùnréré
Wọ́n dọ̀bálẹ̀ pẹ̀lú ẹkún.
4 Heṣboni àti Eleale ké sóde,
ohùn wọn ni a gbọ́ títí fi dé Jahasi.
Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ogun Moabu ṣe kígbe
tí ọkàn wọn sì rẹ̀wẹ̀sì.
5 Ọkàn mi kígbe sókè lórí Moabu;
àwọn ìsáǹsá rẹ sálà títí dé Soari,
títí fi dé Eglati-Ṣeliṣi.
Wọ́n gòkè lọ títí dé Luhiti
wọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń lọ,
Ní òpópónà tí ó lọ sí Horonaimu
wọ́n ń pohùnréré ìparun wọn
6 Gbogbo omi Nimrimu ni ó ti gbẹ
àwọn koríko sì ti gbẹ,
gbogbo ewéko ti tán
ewé tútù kankan kò sí mọ́.
7 Báyìí gbogbo ọrọ̀ tí wọ́n ti ní
tí wọ́n sì tò jọ
wọ́n ti kó wọn kọjá lọ lórí i gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́
odò Poplari.
8 Gbohùngbohùn ń gba igbe wọn dé
ìpẹ̀kun ilẹ̀ Moabu;
ìpohùnréré wọn lọ títí dé Eglaimu,
igbe ẹkún wọn ni a gbọ́ títí dé kànga Elimu.
9 Omi Dimoni kún fún ẹ̀jẹ̀,
síbẹ̀ èmi ó tún mu ohun tí ó jù báyìí lọ wá sórí Dimoni—
kìnnìún kan wá sórí àwọn ìsáǹsá Moabu
àti lórí àwọn tí ó tún ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ náà.
Àwọn aya àti àwọn ọkọ
3 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín; pé, bí ẹnikẹ́ni ba tilẹ̀ ń ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láì sọ̀rọ̀ nípa ìwà àwọn aya wọn. 2 Nígbà tí wọ́n bá ń wo ìwà rere pẹ̀lú ẹ̀rù yín: 3 Kí ọ̀ṣọ́ yín má ṣe jẹ́ ọ̀ṣọ́ òde, tí irun dídì, àti wúrà lílò, tàbí ti aṣọ wíwọ̀; 4 Ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni tí ó fi ara sin ní ọkàn, nínú ọ̀ṣọ́ àìdíbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ẹ̀mí tútù, èyí tí i ṣe iyebíye níwájú Ọlọ́run. 5 Nítorí báyìí ni àwọn obìnrin mímọ́ ìgbàanì pẹ̀lú, tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, fi ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, wọn a máa tẹríba fún àwọn ọkọ wọn. 6 (A)Gẹ́gẹ́ bí Sara ti gbọ́ ti Abrahamu, tí ó ń pè é ní olúwa rẹ̀. Ọmọbìnrin ẹni tí ẹ̀yin jẹ́, bí ẹ̀yin bá ń ṣe rere, tí ohunkóhun kò sí dẹ́rùbà yín.
7 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa fi òye ba àwọn aya yín gbé, ẹ máa fi ọlá fún aya, bi ohun èlò ti kò lágbára, àti pẹ̀lú bí àjùmọ̀jogún oore-ọ̀fẹ́ ìyè; kí àdúrà yín má bà á ní ìdènà.
Jíjìyà fún ṣíṣe iṣẹ́ rere
8 Lákòótan, kí gbogbo yín jẹ́ onínú kan, ẹ máa bá ara yín kẹ́dùn, ẹ ní ìfẹ́ ará, ẹ máa ṣe ìyọ́nú, ẹ ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ 9 Ẹ má ṣe fi búburú san búburú, tàbí fi èébú san èébú: ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa súre; nítorí èyí ni a pè yín sí, kí ẹ̀yin lè jogún ìbùkún. 10 (B)Nítorí,
“Ẹni tí yóò bá fẹ́ ìyè,
ti yóò sì rí ọjọ́ rere,
kí o pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi,
àti ètè rẹ̀ mọ́ kúrò nínú sísọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn:
11 Kí ó yà kúrò nínú ibi, kí ó sì máa ṣe rere;
kí ó máa wá àlàáfíà, kí ó sì máa lépa rẹ̀.
12 Nítorí ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo,
etí rẹ̀ sì ṣí sí ẹ̀bẹ̀ wọn:
ṣùgbọ́n ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú.”
13 Tá nì yóò sì ṣe yín ní ibi, bí ẹ̀yin bá jẹ́ onítara sí ohun rere? 14 (C)Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá jìyà nítorí òdodo, a ti bùkún yín. “Ẹ má ṣe bẹ̀rù ìhàlẹ̀ wọn, kí ẹ má sì ṣe kọminú.” 15 Ṣùgbọ́n ẹ bọ̀wọ̀ fún Kristi bí Olúwa ní ọkàn yín: kí ẹ sì múra tan nígbà gbogbo láti dá olúkúlùkù lóhùn tí ń béèrè ìrètí tí o ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn tútù àti ìbẹ̀rù. 16 Kí ẹ máa ni ẹ̀rí ọkàn rere bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ yín ní ibi, kí ojú lè ti àwọn tí ń kẹ́gàn ìwà rere yín nínú Kristi. 17 Nítorí ó sàn, bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ẹ jìyà fún ṣíṣe rere ju fún ṣíṣe búburú lọ. 18 Nítorí tí Kristi pẹ̀lú jìyà lẹ́ẹ̀kan nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòótọ́ fún àwọn aláìṣòótọ́, kí a lè mú wa dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí a pa nínú ara, ṣùgbọ́n tí a sọ di ààyè nínú ẹ̀mí: 19 Nínú èyí tí ó lọ pẹ̀lú tí ó sì wàásù fún àwọn ẹ̀mí nínú túbú: 20 (D)àwọn tí ó ṣe aláìgbọ́ràn nígbà kan, nígbà tí sùúrù Ọlọ́run dúró pẹ́ ní sá à kan ní ọjọ́ Noa, nígbà tí wọ́n fi kan ọkọ̀ nínú èyí tí a gba ọkàn díẹ̀ là nípa omi, èyí ni ẹni mẹ́jọ. 21 Àpẹẹrẹ èyí ti ń gbà yín là nísinsin yìí pẹ̀lú, àní ìtẹ̀bọmi, kì í ṣe wíwẹ́ èérí ti ara nù, bí kò ṣe ìdáhùn ẹ̀rí ọkàn rere si Ọlọ́run, nípa àjíǹde Jesu Kristi. 22 Ẹni tí ó lọ sí ọ̀run, tí ó sì ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run: pẹ̀lú àwọn angẹli, àwọn aláṣẹ, àti àwọn alágbára sì tẹríba lábẹ́ rẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.