Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Numeri 21

A pa ìlú Aradi run

21 (A)Nígbà tí ọba Aradi ará Kenaani, tí ń gbé ní gúúsù gbọ́ wí pé Israẹli ń bọ̀ wá ní ojú ọ̀nà Atarimu, ó bá Israẹli jà ó sì fi agbára mú díẹ̀ lára wọn. Nígbà náà ni Israẹli jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa pé: “Bí o bá lè fi àwọn ènìyàn yìí lé wa lọ́wọ́, gbogbo ìlú wọn ni a ó parun.” Olúwa gbọ́ ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli, ó sì fi àwọn ará Kenaani lé wọn lọ́wọ́. Wọ́n pa wọ́n run pátápátá; torí náà ni a ṣe ń pe ibẹ̀ ní Horma.

Ejò idẹ

Wọ́n rin ìrìnàjò láti òkè Hori lọ sí ọ̀nà tó lọ sí Òkun Pupa, láti kọjá yípo Edomu. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn bínú ní ojú ọ̀nà; wọ́n sì sọ̀rọ̀ lòdì sí Ọlọ́run àti Mose, wọ́n wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde láti Ejibiti kí a ba le wá kú sí aginjù yìí? Kò sí oúnjẹ! Kò sì sí omi! Àwa sì kórìíra oúnjẹ tí kò dára yìí!”

Nígbà náà ni Olúwa rán ejò olóró sí àárín wọn; wọ́n gé àwọn ènìyàn jẹ, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Israẹli sì kú. Àwọn ènìyàn sì wá sí ọ̀dọ̀ Mose wọn wí pé, “A ti dá ẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí asọ̀rọ̀-òdì sí Olúwa àti sí ìwọ pẹ̀lú. Gba àdúrà pé kí Olúwa mú ejò náà kúrò lọ́dọ̀ wa.” Nígbà náà ni Mose gbàdúrà fún àwọn ènìyàn.

Olúwa sọ fún Mose pé, “Rọ ejò, a ó sì gbé e kọ́ sókè lórí igi, ẹni tí ejò bá ti gé jẹ lè wò ó yóò sì yè.” Nígbà náà ni Mose sì rọ ejò onírin ó sì gbé e kọ́ sórí igi, Bí ejò bá sì bu ẹnikẹ́ni jẹ bí ó bá ti wò ó yóò sì yè.

Ìrìnàjò sí Moabu

10 Àwọn ọmọ Israẹli tẹ̀síwájú wọ́n sì péjọ sí Obotu. 11 Wọ́n gbéra ní Obotu wọ́n sì pa ibùdó sí Iye-Abarimu, ní aginjù tí ó kọjú sí Moabu ní ìdojúkọ ìlà-oòrùn. 12 Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti gbéra wọ́n sì pa ibùdó ní Àfonífojì Seredi. 13 Láti ibẹ̀ lọ, wọn ṣí, wọ́n sì dó sí ìhà kejì Arnoni, tí ó wà ní aginjù tí ó wà ní agbègbè ilẹ̀ àwọn ọmọ Amori. Arnoni jẹ́ ààlà fún ilẹ̀ Moabu, láàrín Moabu àti Amori. 14 Ìdí nìyìí tí ìwé ogun Olúwa se wí pé:

“…Wahebu ní Sufa, Òkun pupa àti
ní odò Arnoni 15     àti ní ìṣàn odò
tí ó darí sí ibùjókòó Ari
    tí ó sì fi ara ti ìpínlẹ̀ Moabu.”

16 Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ rìn dé Beeri, èyí ni kànga tí Olúwa sọ fún Mose, “Kó àwọn ènìyàn jọ èmi ó sì fún wọn ní omi.”

17 Nígbà náà ni Israẹli kọ orin yìí pé:

“Sun jáde, ìwọ kànga!
    Ẹ máa kọrin nípa rẹ̀,
18 nípa kànga tí àwọn ọmọ-aládé gbẹ́,
    nítorí àwọn ọlọ́lá ènìyàn ni ó gbẹ́ ẹ;
    tí àwọn ọlọ́lá àwọn ènìyàn sì fi ọ̀pá aládé àti ọ̀pá oyè wọn gbẹ́.”

Nígbà náà wọ́n kúrò láti aginjù lọ sí Mattana, 19 láti Mattana lọ sí Nahalieli, láti Nahalieli lọ sí Bamoti, 20 àti láti Bamoti lọ sí àfonífojì ní Moabu níbi tí òkè Pisga, tí ó wà ní òkè ilé omi ti kọjú sí aginjù.

Ìṣẹ́gun Sihoni àti Ogu

21 (B)Israẹli rán oníṣẹ́ láti sọ fún Sihoni ọba àwọn ará Amori wí pé:

22 “Jẹ́ kí a kọjá ní orílẹ̀-èdè rẹ. A kò ní kọjá sí inú oko pápá tàbí ọgbà àjàrà àbí mu omi láti inú kànga. A máa gba òpópónà náà ti ọba títí tí a ó fi la ilẹ̀ rẹ kọjá.”

23 Ṣùgbọ́n Sihoni kò ní jẹ́ kí àwọn Israẹli kọjá ní ilẹ̀ wọn. Ó pe àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ jọ wọ́n sì wọ́de ogun lọ sí aginjù nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Nígbà tí ó dé Jahasi, ó bá àwọn ọmọ Israẹli jà. 24 Àmọ́, Israẹli ṣẹ́gun, wọn fi ojú idà pa wọ́n, wọ́n sì gba ilẹ̀ láti ọwọ́ Arnoni lọ dé Jabbok, títí tí ó fi dé ilẹ̀ àwọn ará Ammoni, nítorí pé ààlà wọn jẹ́ olódi. 25 Israẹli sì gba gbogbo ìlú Amori wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ pẹ̀lú Heṣboni, àti gbogbo ibùgbé ìlú tó yí i ká. 26 Heṣboni ni ìlú Sihoni ọba àwọn ará Amori, ẹni tí ó bá ọba Moabu ti tẹ́lẹ̀ jà tí ó sì gba gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ títí dé Arnoni.

27 Ìdí nìyìí tí akọrin sọ wí pé:

“Wá sí Heṣboni kí ẹ jẹ́ kí a tún un kọ́;
    jẹ́ kí ìlú Sihoni padà bọ̀ sípò.

28 “Iná jáde láti Heṣboni,
    ọ̀wọ́-iná láti Sihoni.
Ó jó Ari àti Moabu run,
    àti ìlú àwọn olùgbé ibi gíga Arnoni.
29 Ègbé ní fún ọ, ìwọ Moabu!
    Ẹ ti parun, ẹ̀yin ènìyàn Kemoṣi!
Ó ti fi ọmọ rẹ̀ ọkùnrin sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá
    àti ọmọ rẹ̀ obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìgbèkùn
    fún Sihoni ọba àwọn Amori.

30 “Ṣùgbọ́n àti bì wọ́n ṣubú;
    A ti pa ìjẹgàba Heṣboni run, a pa wọ́n run títí dé Diboni.
A sì ti bì wọ́n lulẹ̀ títí dé Nofa,
    tí ó sì fi dé Medeba.”

31 Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli sì ń gbé ní ilẹ̀ Amori.

32 Lẹ́yìn ìgbà tí Mose rán ayọ́lẹ̀wò lọ sí Jaseri, àwọn ọmọ Israẹli sì gba àwọn agbègbè tó yí wọn ká wọ́n sì lé àwọn Amori tó wà níbẹ̀ jáde. 33 (C)Nígbà náà wọ́n pẹ̀yìndà wọ́n sì gòkè lọ sí Baṣani, Ogu ọba ti Baṣani àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí ó wọ́de ogun jáde láti pàdé wọn ní ojú ogun ní Edrei.

34 Olúwa sọ fún Mose pé, “Má ṣe bẹ̀rù rẹ̀, nítorí tí mó tí fi òun lé ọ lọ́wọ́, àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, àti ilẹ̀ rẹ̀. kí ìwọ kí ó ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe sí Sihoni ọba Amori ẹni tí ó ń jẹ ọba ní Heṣboni.”

35 Wọ́n sì pa á, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, wọn kò fi ku ẹnìkan fún un láàyè. Wọ́n sì gba ìní ilẹ̀ rẹ̀.

Saamu 60-61

Fún adarí orin. Tí ohùn “Lílì ti Májẹ̀mú.” Miktamu ti Dafidi. Fún ìkọ́ni. Nígbà tí ó bá Aramu-Naharaimu àti Siria-Soba jà, àti nígbà tí Joabu yípadà tí ó sì pa ẹgbẹ̀rún méjìlá àwọn ará Edomu ní Àfonífojì Iyọ̀.

60 Ìwọ ti kọ̀ wá sílẹ̀,
    Ọlọ́run, ìwọ ti tú wa ká,
ìwọ ti bínú nísinsin yìí, tún ara rẹ yípadà sí wa.
Ìwọ ti mú ilẹ̀ wárìrì, ìwọ ti fọ́ ọ;
    mú fífọ́ rẹ̀ bọ̀ sípò, nítorí tí ó mì.
Ìwọ ti fi ìgbà ewu han àwọn ènìyàn rẹ;
    Ìwọ fún wa ní wáìnì tí ó máa ń ta wá gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n.
Àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, ní ìwọ fi ọ̀págun fún
    kí a lè fihàn nítorí òtítọ́. Sela.

(A)Fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbà wá, kí o sì ràn wá lọ́wọ́,
    kí a lè gba àwọn tí o fẹ́ là.
Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀:
    “Ní ayọ̀, èmi ó pọ Ṣekemu jáde
    èmi ó sì wọ́n Àfonífojì Sukkoti.
Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase;
    Efraimu ni àṣíborí mi,
    Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi.
Moabu ní ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi,
    lórí Edomu ní mo bọ́ bàtà mi sí;
    lórí Filistia ni mo kígbe ayọ̀.”

Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi nì?
    Ta ni yóò tọ́ mí lọ sí Edomu?
10 Kì í ha ń ṣe ìwọ, Ọlọ́run, tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀
    tí o kò sì bá ogun wa jáde mọ́?
11 Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ lórí àwọn ọ̀tá,
    nítorí asán ni ìrànlọ́wọ́ ènìyàn.
12 Nípa Ọlọ́run ni a óò ní ìṣẹ́gun,
    yóò sì tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.

Fún adarí orin. Ohun èlò orin olókùn. Ti Dafidi.

61 Gbọ́ ẹkún mi, Ọlọ́run;
    Tẹ́tí sí àdúrà mi.

Láti òpin ayé wá ni èmi yóò pè ọ́,
    mo pè nígbà àyà mi ń ṣàárẹ̀;
    mú mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ.
Nítorí ìwọ ti jẹ́ ibi ààbò mi,
    ilé ìṣọ́ agbára àwọn ọ̀tá.

Mo ń lépa láti máa gbé nínú àgọ́ rẹ títí láé
    kí n sì rí ààbò níbi ìyẹ́ apá rẹ.
Nítorí ìwọ ti gbọ́ àwọn ẹ̀jẹ́ mi, Ọlọ́run;
    Ìwọ ti fún mi ní ogún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ.

Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn,
    ọdún rẹ̀ fún ìrandíran.
Kí ó máa jẹ ọba níwájú Ọlọ́run títí láé;
    pèsè àánú àti òtítọ́ rẹ tí yóò máa ṣe ìtọ́jú rẹ.

Nígbà náà ni èmi ó máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ títí láé
    kí n san ẹ̀jẹ́ mi ní ojoojúmọ́.

Isaiah 10:5-34

Ìdájọ́ Ọlọ́run Lórí Asiria

(A)“Ègbé ni fún àwọn ará Asiria, ọ̀gọ ìbínú mi,
    ní ọwọ́ ẹni tí kùmọ̀ ìbínú mi wà!
Mo rán an sí orílẹ̀-èdè aláìní Ọlọ́run
    Mo dojú rẹ̀ kọ àwọn ènìyàn tí ó mú mi bínú
láti já ẹrù gbà, àti láti kó ìkógun
    láti tẹ̀ mọ́lẹ̀ bí amọ̀ ní ojú òpópó.
Ṣùgbọ́n, èyí kì í ṣe ohun tí ó fẹ́ ṣe,
    èyí kọ́ ni ohun tí ó ní lọ́kàn;
èrò rẹ̀ ni láti parun,
    láti fi òpin sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè.
‘Kì í ha ṣe pé ọba ni gbogbo àwọn aláṣẹ mi?’ ni Olúwa wí.
‘Kì í ha ṣe pé Kalno dàbí i Karkemiṣi?
    Hamati kò ha dàbí i Arpadi,
    àti Samaria bí i Damasku?
10 Gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ mi ti gbá ìjọba àwọn òrìṣà mú,
    ìjọba tí ère rẹ̀ pọ̀ ju ti Jerusalẹmu àti Samaria lọ.
11 Èmi kì yóò a bá Jerusalẹmu wí àti àwọn ère rẹ̀?’ ”
    Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ṣe sí Samaria àti àwọn ère rẹ̀?

12 Nígbà tí Olúwa ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ sí òkè Sioni àti Jerusalẹmu, yóò sọ wí pé, “Èmi yóò fi ìyà jẹ ọba Asiria nítorí gààrù àyà rẹ̀ àti ìgbéraga ojú rẹ̀. 13 Nítorí ó sọ pé:

“ ‘Pẹ̀lú agbára ọwọ́ mi ni mo fi ṣe èyí
    àti pẹ̀lú ọgbọ́n ọ̀n mi, nítorí mo ní òye.
Mo mú ààlà àwọn orílẹ̀-èdè kúrò,
    Mo sì ti kó ìṣúra wọn.
    Gẹ́gẹ́ bí alágbára kan, mo borí àwọn ọba wọn.
14 Bí ènìyàn ti í tọwọ́ bọ ìtẹ́ ẹyẹ,
    bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ mi tẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè.
Bí ènìyàn ti í kó ẹyin tí a kọ̀sílẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni mo kó àwọn orílẹ̀-èdè
kò sí èyí tí ó fi apá lu apá,
    tàbí kí ó ya ẹnu láti dún.’ ”

15 Ǹjẹ́ àáké le gbé ara rẹ̀ sókè kọjá ẹni tí ó ń fì í,
    tàbí kí ayùn fọ́nnu sí ẹni tí ó ń lò ó?
Àfi bí ẹni pé ọ̀pá ó na ẹni tí ó gbé e sókè,
    tàbí kí kùmọ̀ lu èyí tí kì í ṣe igi.
16 Nítorí náà, ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
    yóò rán ààrùn ìrẹ̀dànù sórí
àwọn akíkanjú jagunjagun,
    lábẹ́ ògo rẹ̀ ni iná kan yóò ti sọ
    gẹ́gẹ́ bí iná ajónirun.
17 Ìmọ́lẹ̀ Israẹli yóò di iná,
    Ẹni Mímọ́ rẹ̀ yóò jẹ́ ọ̀wọ́-iná,
ní ọjọ́ kan ṣoṣo yóò jó yóò sì run
    àti ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n.
18 Gbogbo ẹwà igbó o rẹ̀, àti àwọn pápá ọlọ́ràá
    gbogbo rẹ̀ ni yóò run pátápátá,
gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ṣàìsàn ti í ṣòfò dànù.
19 Àwọn igi tí yóò kù nínú igbó o rẹ̀
    yóò kéré níye,
    tí ọ̀dọ́mọdé yóò fi le kọ̀ wọ́n sílẹ̀.

Àwọn ìyókù Israẹli

20 Ní ọjọ́ náà, àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Israẹli,
    Àwọn tí ó yè ní ilé e Jakọbu,
kò ní gbẹ́kẹ̀lé ẹni náà
    tí ó lù wọ́n bolẹ̀,
ṣùgbọ́n ní òtítọ́ yóò gbẹ́kẹ̀lé Olúwa
    Ẹni Mímọ́ Israẹli.
21 Àwọn ìyókù yóò padà, àwọn ìyókù ti Jakọbu
    yóò padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Alágbára.
22 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn rẹ, ìwọ Israẹli
    dàbí yanrìn ní Òkun,
ẹni díẹ̀ ni yóò padà.
    A ti pàṣẹ ìparun
    àkúnwọ́sílẹ̀ àti òdodo.
23 Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú un ṣẹ,
    ìparun tí a ti pàṣẹ rẹ̀ lórí
    gbogbo ilẹ̀ náà.

24 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí,

    “Ẹ̀yin ènìyàn mi tí ó ń gbé Sioni,
Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn Asiria,
    tí ó ń fi ọ̀pá lù yín,
tí wọ́n sì ń gbé ọ̀gọ tì yín bí
    Ejibiti ti ṣe.
25 Láìpẹ́, ìbínú mi sí i yín yóò wá sí òpin
    n ó sì dojú ìrunú mi kọ wọ́n,
    fún ìparun wọn.”

26 Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò nà wọ́n ní ẹgba.
    Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe lu Midiani
ní òkè Orebu,
    yóò sì gbé ọ̀pá rẹ̀ lé orí omi
    gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní Ejibiti.
27 Ní ọjọ́ náà, a ó gbé ẹrù wọn kúrò ní èjìká a yín,
    àti àjàgà a wọn kúrò ní ọrùn un yín
a ó fọ́ àjàgà náà,
    nítorí pé ẹ̀yin ó ti sanra.

28 Wọ́n wọ Aiati,
    Wọ́n gba Migroni kọjá
    Wọ́n kó nǹkan pamọ́ sí Mikmasi.
29 Wọ́n ti rékọjá ọ̀nà, wọ́n wí pé,
    “Àwa ó tẹ̀dó sí Geba lóru yìí.”
Rama mì tìtì
    Gibeah ti Saulu sálọ.
30 Gbé ohùn rẹ sókè, ìwọ ọmọbìnrin Galimu!
    Dẹ etí sílẹ̀, ìwọ Laiṣa!
    Ìwọ òtòṣì Anatoti!
31 Madmena ti fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ
    Àwọn ènìyàn Gebimu ti fi ara pamọ́.
32 Ní ọjọ́ yìí, wọn yóò dúró ní Nobu
    wọn yóò kan sáárá,
ní òkè ọmọbìnrin Sioni
    ní òkè Jerusalẹmu.

33 Wò ó, Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
    yóò kán ẹ̀ka náà sọnù pẹ̀lú agbára.
Àwọn igi ọlọ́lá ni a ó gé lulẹ̀
    àwọn tí ó ga gogoro ni a ó rẹ̀ sílẹ̀.
34 Òun yóò gé igbó dídí pẹ̀lú àáké,
    Lebanoni yóò ṣubú níwájú Alágbára náà.

Jakọbu 4

Ìyọ̀ǹda ara ẹni fún Ọlọ́run

Níbo ni ogun ti wá, níbo ni ìjà sì ti wá láàrín yín? Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara yín ha kọ́ ni tí ó ń jagun nínú àwọn ẹ̀yà ara yín bí? Ẹ̀yin ń fẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ẹ kò sì ní: ẹ̀yin ń pànìyàn, ẹ sì ń ṣe ìlara, ẹ kò sì le ní: ẹ̀yin ń jà, ẹ̀yin sì ń jagun; ẹ kò ní, nítorí tí ẹ̀yin kò béèrè. Ẹ̀yin béèrè, ẹ kò sì rí gbà, nítorí tí ẹ̀yin ṣì béèrè, kí ẹ̀yin kí ó lè lò ó fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara yín.

Ẹ̀yin panṣágà ọkùnrin, àti panṣágà obìnrin, ẹ kò mọ̀ pé ìbárẹ́ ayé ìṣọ̀tá Ọlọ́run ni? Nítorí náà ẹni tí ó bá fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé di ọ̀tá Ọlọ́run. Ẹ̀yin ṣe bí Ìwé mímọ́ sọ lásán pé, Ẹ̀mí tí ó fi sínú wa ń jowú gidigidi lórí wa? (A)Ṣùgbọ́n ó fún ni ní oore-ọ̀fẹ́ sí i. Nítorí náà ni ìwé mímọ́ ṣe wí pé,

“Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn agbéraga,
    ṣùgbọ́n ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀ ọkàn.”

Nítorí náà, ẹ tẹríba fún Ọlọ́run. Ẹ kọ ojú ìjà sí èṣù, òun ó sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín. Ẹ súnmọ́ Ọlọ́run, òun ó sì súnmọ́ yín. Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀; ẹ sì ṣe ọkàn yín ní mímọ́, ẹ̀yin oníyèméjì. Ẹ banújẹ́, ẹ ṣọ̀fọ̀, kí ẹ sì hu fún ẹkún. Ẹ jẹ́ kí ẹ̀rín yín kí ó di ọ̀fọ̀, àti ayọ̀ yín kí ó di ìbànújẹ́. 10 Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú Olúwa, òun ó sì gbé yín ga.

11 Ará, ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ ibi sí ara yín. Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ibi sí arákùnrin rẹ̀, tí ó ń dá arákùnrin rẹ̀ lẹ́jọ́, ó ń sọ̀rọ̀ ibi sí òfin, ó sì ń dá òfin lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń dá òfin lẹ́jọ́, ìwọ kì í ṣe olùfẹ́ òfin, bí kò ṣe onídàájọ́. 12 Aṣòfin àti onídàájọ́ kan ṣoṣo ní ó ń bẹ, àní ẹni tí ó lè gbàlà tí ó sì le parun, ṣùgbọ́n ta ni ìwọ tí ó ń dá ẹnìkejì rẹ lẹ́jọ́?

Má ṣe ìlérí nípa ọjọ́ ọ̀la

13 Ẹ wá nísinsin yìí, ẹ̀yin tí ó ń wí pé, “Lónìí tàbí lọ́la àwa ó lọ sí ìlú báyìí, a ó sì ṣe ọdún kan níbẹ̀, a ó sì ṣòwò, a ó sì jèrè.” 14 Nígbà tí ẹ̀yin kò mọ ohun tí yóò hù lọ́la. Kí ni ẹ̀mí yín? Ìkùùkuu sá à ni yín, tí ó hàn nígbà díẹ̀, lẹ́yìn náà a sì túká lọ. 15 Èyí tí ẹ̀ bá fi wí pé, “Bí Olúwa bá fẹ́, àwa yóò wà láààyè, àwa ó sì ṣe èyí tàbí èyí i nì.” 16 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin ń gbéraga nínú ìfọ́nnu yín, gbogbo irú ìfọ́nnu bẹ́ẹ̀, ibi ni. 17 Nítorí náà ẹni tí ó bá mọ rere í ṣe tí kò sì ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni fún un.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.