M’Cheyne Bible Reading Plan
Àwọn ọmọ Kohati
4 (A)Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé: 2 “Ka iye àwọn ọmọ Kohati láàrín àwọn ọmọ Lefi nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn. 3 Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé.
4 “Wọ̀nyí ni iṣẹ́ ìsìn àwọn ọmọ Kohati nínú àgọ́ àjọ, láti tọ́jú àwọn ohun èlò mímọ́ jùlọ. 5 Nígbà tí àgọ́ yóò bá tẹ̀síwájú, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò wọ inú rẹ̀, wọn yóò sí aṣọ ìbòrí rẹ̀, wọn yóò sì fi bo àpótí ẹ̀rí. 6 Wọn yóò sì fi awọ ewúrẹ́ bò ó, lórí awọ ewúrẹ́ yìí ni wọn ó tẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.
7 “Lórí tábìlì àkàrà ìfihàn ni kí wọn ó na aṣọ aláró kan sí, kí wọn kí ó sì fi àwopọ̀kọ́ sórí rẹ̀, àti ṣíbí àti àwokòtò àti ìgò fún ọrẹ ohun mímu; àti àkàrà ìgbà gbogbo ní kí ó wà lórí rẹ̀. 8 Lórí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọn yóò da, wọn ó tún fi awọ ewúrẹ́ bò ó, wọn ó sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.
9 “Kí wọn kí ó sì mú aṣọ aláwọ̀ aláró kan, kí wọn kí ó sì fi bo ọ̀pá fìtílà àti fìtílà rẹ̀, àti alumagaji rẹ̀, àti àwo alumagaji rẹ̀, àti gbogbo ohun èlò òróró rẹ̀, èyí tí wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀. 10 Kí wọn ó fi awọ ẹran yí fìtílà àti gbogbo ohun èlò rẹ, kí wọn kí ó sì gbé e lé orí férémù tí wọn yóò fi gbé e.
11 “Ní orí pẹpẹ wúrà ni kí wọn ó tẹ́ aṣọ aláró kan sí, wọn yóò sì fi awọ seali bò ó, kí wọ́n sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.
12 “Kí wọn kó gbogbo ohun èlò tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ ìsìn ní ibi mímọ́, kí wọn ó fi aṣọ aláwọ̀ búlúù yìí, kí wọn ó sì fi awọ seali bò ó, kí wọn ó sì fi gbé wọn ka orí férémù.
13 “Kí wọn ó kó eérú kúrò lórí pẹpẹ idẹ, kí wọn ó sì tẹ́ aṣọ aláwọ̀ àlùkò lé e lórí. 14 Nígbà náà ni kí wọn ó kó gbogbo ohun èlò fún iṣẹ́ ìsìn níbi pẹpẹ, títí dórí àwo iná, fọ́ọ̀kì ẹran, ọkọ́ eérú àti àwokòtò. Kí wọn ó fi awọ ewúrẹ́ bo gbogbo rẹ̀, kí wọn ó sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.
15 “Lẹ́yìn tí Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti parí bíbo ibi mímọ́ àti gbogbo ohun èlò ibi mímọ́, nígbà tí àgọ́ bá sì ṣetán láti tẹ̀síwájú, kí àwọn ọmọ Kohati bọ́ síwájú láti gbé e, ṣùgbọ́n wọn kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ohun mímọ́ kankan, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ wọn ó kú. Àwọn ọmọ Kohati ni yóò gbé gbogbo ohun tó wà nínú àgọ́ ìpàdé.
16 “Iṣẹ́ Eleasari ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ni ṣíṣe àbojútó òróró fìtílà, tùràrí dídùn, ẹbọ ohun jíjẹ ìgbà gbogbo àti òróró ìtasórí: Kí ó jẹ́ alábojútó gbogbo ohun tó jẹ mọ́ àgọ́ àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ohun èlò ibi mímọ́.”
17 Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé, 18 “Rí i pé a kò gé ẹ̀yà Kohati kúrò lára àwọn ọmọ Lefi: 19 Nítorí kí wọ́n lè yè, kí wọ́n má ba à kú nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ tòsí àwọn ohun mímọ́ jùlọ: Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni kí ó wọ ibi mímọ́ láti pín iṣẹ́ oníkálùkù àti àwọn ohun tí wọn yóò gbé. 20 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Kohati kò gbọdọ̀ wọlé láti wo àwọn ohun mímọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ ìṣẹ́jú kan, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò kú.”
Àwọn ọmọ Gerṣoni
21 Olúwa sọ fún Mose pé: 22 “Tún ka iye àwọn ọmọ Gerṣoni nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn. 23 Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé.
24 “Èyí ni iṣẹ́ ìsìn ìdílé àwọn ọmọ Gerṣoni, bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ àti ní ẹrù rírù: 25 Àwọn ni yóò máa ru àwọn aṣọ títa ti àgọ́, ti àgọ́ ìpàdé àti ìbòrí rẹ̀, àti awọ ewúrẹ́ tí a fi bò ó, aṣọ títa ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, 26 Aṣọ títa ti àgbàlá tó yí àgọ́ àti pẹpẹ ká, aṣọ títa ti ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé sí àgbàlá, okùn àti àwọn ohun èlò iṣẹ́ ìsìn, àti ohun gbogbo tí à ń lò fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn ó máa sìn. Àwọn ọmọ Gerṣoni ni yóò ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ pẹ̀lú àwọn nǹkan wọ̀nyí. 27 Gbogbo iṣẹ́ ìsìn àwọn ọmọ Gerṣoni yálà ni iṣẹ́ ṣíṣe tàbí ní ẹrù rírù ni, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóò máa darí wọn; ìwọ ni kí o sì yàn ẹrù tí oníkálùkù yóò rù fún un. 28 Èyí ni iṣẹ́ ìdílé àwọn Gerṣoni ni àgọ́ ìpàdé Itamari, ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ni yóò sì jẹ alábojútó iṣẹ́ wọn.
Àwọn ọmọ Merari
29 “Ka iye àwọn ọmọ Merari nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn. 30 Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé. 31 Iṣẹ́ tí wọn yóò sì máa ṣe nínú àgọ́ ìpàdé nìyìí: gbígbẹ́ àwọn férémù àgọ́, pákó ìdábùú rẹ̀, òpó àti ihò òpó rẹ̀, 32 Pẹ̀lú gbogbo òpó tó yí àgbàlá ká àti ohun èlò tó jẹ mọ́ lílò wọn kí o sì yan ohun tí oníkálùkù yóò rù fún un; 33 Èyí ni iṣẹ́ ìsìn ìdílé àwọn ọmọ Merari, bí wọn yóò ti máa ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé lábẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà.”
Àbájáde kíka àwọn ọmọ Lefi
34 Mose àti Aaroni pẹ̀lú àwọn olórí ìjọ ènìyàn ka àwọn ọmọ Kohati nípa ìdílé àti ilé baba wọn.
35 Gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ ìpàdé. 36 Iye wọn nípa ìdílé jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlá ó-dínàádọ́ta (2,750). 37 Èyí ni àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Kohati tó ń ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé; tí Mose àti Aaroni kà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose.
38 Wọ́n ka àwọn ọmọ Gerṣoni nípa ìdílé àti ilé baba wọn.
39 Gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta, gbogbo àwọn tó lè ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé. 40 Iye wọn nípa ìdílé àti ilé baba wọn jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá ó-lé-ọgbọ̀n (2,630). 41 Èyí jẹ́ àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Gerṣoni, àwọn tó ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé. Mose àti Aaroni ṣe bí àṣẹ Olúwa.
42 Wọ́n ka àwọn ọmọ Merari nípa ìdílé àti ilé baba wọn.
43 Gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, àwọn tó ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé. 44 Iye wọn nípa ìdílé àti ilé baba wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rìndínlógún (3,200). 45 Èyí ni àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Merari. Mose àti Aaroni kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mose.
46 Gbogbo àwọn tí a kà nínú àwọn ọmọ Lefi, ti Mose àti Aaroni àti àwọn olórí Israẹli kà, nípa ìdílé wọn àti gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn. 47 Gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìsìn tó sì ń ru àwọn ẹrù inú Àgọ́ Ìpàdé. 48 Àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá lé lẹ́gbàarin ó dín ogún (8,580). 49 Wọ́n yan iṣẹ́ àti àwọn ohun tí ẹni kọ̀ọ̀kan yóò máa gbé fún un gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ láti ẹnu Mose.
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
Saamu Dafidi. Ẹ̀bẹ̀.
38 Olúwa, Má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ,
bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe fi ìyà jẹ mí nínú ìrunú rẹ̀.
2 Nítorí tí ọfà rẹ kàn mọ́ mi ṣinṣin,
ọwọ́ rẹ sì kì mí mọ́lẹ̀.
3 Kò sí ibi yíyè ní ara à mi, nítorí ìbínú rẹ;
kò sí àlàáfíà nínú egungun mi nítorí i ẹ̀ṣẹ̀ mi.
4 Nítorí àìṣedéédéé mi ti borí mi mọ́lẹ̀;
wọ́n tó ìwọ̀n bi àjàgà tí ó wúwo jù fún mi.
5 Ọgbẹ́ mi ń rùn ó sì díbàjẹ́
nítorí òmùgọ̀ mi.
6 Èmi ń jòwèrè, orí mi tẹ̀ ba gidigidi
èmi ń ṣọ̀fọ̀ rìn kiri ní gbogbo ọjọ́.
7 Nítorí ẹ̀gbẹ́ mi kún fún ìgbóná tí ń jóni
kò sì ṣí ibi yíyè ní ara mi,
8 Ara mi hù, a sì wó mi jẹ́gẹjẹ̀gẹ;
mo kérora nítorí ìrúkèrúdò àyà mi.
9 Olúwa, gbogbo ìfẹ́ mi ń bẹ níwájú rẹ;
ìmí ẹ̀dùn mi kò sápamọ́ fún ọ.
10 Àyà mi ń mí hẹlẹ, agbára mi yẹ̀ mí sílẹ̀;
bí ó ṣe ti ìmọ́lẹ̀ ojú mi ni, ó ti lọ kúrò lára mi.
11 Àwọn ọ̀rẹ́ mi àti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi dúró lókèèrè réré kúrò níbi ìpọ́njú mi,
àwọn alábágbé mi, dúró lókèèrè.
12 Àwọn tí n wá ẹ̀mí mi dẹ okùn sílẹ̀ fún mi;
àti àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára ń sọ̀rọ̀ nípa ìparun,
wọ́n sì ń gbèrò ẹ̀tàn ní gbogbo ọjọ́.
13 Ṣùgbọ́n mo dàbí adití odi, èmi kò gbọ́ ọ̀rọ̀;
àti bí odi, tí kò le sọ̀rọ̀.
14 Nítòótọ́, mo rí bí ọkùnrin tí kò gbọ́rọ̀,
àti bí ẹnu ẹni tí kò sí ìjiyàn.
15 Ṣùgbọ́n sí ọ Olúwa, ìwọ ni mo dúró dè;
ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run mi, ẹni tí yóò dáhùn.
16 Nítorí tí mo gbàdúrà, “Gbóhùn mi, kí wọn má ba à yọ̀ mí;
nígbà tí ẹsẹ̀ mi bá yọ̀ wọn yóò máa gbé ara wọn ga sí mi.”
17 Nítorí tí mo ti ṣetán láti ṣubú,
ìrora mi sì wà pẹ̀lú mi nígbà gbogbo.
18 Mo jẹ́wọ́ ìrékọjá mi;
àánú sì ṣe mí fún ẹ̀ṣẹ̀ mi.
19 Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí pàtàkì, wọ́n lágbára púpọ̀,
ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó kórìíra mi lọ́nà òdì.
20 Àwọn tí wọn ń fi ibi san rere fún mi
àwọn ni ọ̀tá mi
nítorí pé mò ń tọ ìre lẹ́yìn.
21 Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, ìwọ Olúwa!
Ọlọ́run mi, Má ṣe jìnnà sí mi.
22 Yára láti ràn mí lọ́wọ́,
Olúwa, Olùgbàlà mi.
Olólùfẹ́
2 Èmi ni ìtànná Ṣaroni
bí ìtànná lílì àwọn Àfonífojì.
Olólùfẹ́
2 Bí ìtànná lílì ní àárín ẹ̀gún
ni olólùfẹ́ mi ní àárín àwọn wúńdíá.
Olólùfẹ́
3 Bí igi ápù láàrín àwọn igi inú igbó,
ni olólùfẹ́ mí láàrín àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin
Mo fi ayọ̀ jókòó ní abẹ́ òjìji rẹ̀,
Èso rẹ̀ sì dùn mọ́ mi ní ẹnu.
4 Ó mú mi lọ sí ibi gbọ̀ngàn àsè,
ìfẹ́ sì ni ọ̀págun rẹ̀ lórí mi.
5 Fi agbára adùn àkàrà dá mi dúró.
Fi èso ápù tù mi lára
nítorí àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí.
6 Ọwọ́ òsì rẹ ń bẹ lábẹ́ orí mi
ọwọ́ ọ̀tún rẹ sì ń gbà mí mọ́ra
7 Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu,
mo fi abo egbin àti ọmọ àgbọ̀nrín fi yín bú
kí ẹ má ṣe ru ìfẹ́ olùfẹ́ mi sókè
kí ẹ má sì ṣe jí i títí yóò fi wù ú.
8 Gbọ́ ohùn olùfẹ́ mi!
Wò ó! Ibí yìí ni ó ń bọ̀.
Òun ń fò lórí àwọn òkè ńlá,
Òun bẹ́ lórí àwọn òkè kéékèèkéé
9 Olùfẹ́ mi dàbí abo egbin tàbí ọmọ àgbọ̀nrín
Wò ó! Níbẹ̀ ni ó wà lẹ́yìn ògiri wa
Ó yọjú ní ojú fèrèsé
Ó ń fi ara rẹ̀ hàn lójú fèrèsé ọlọ́nà
10 Olùfẹ́ mi fọhùn ó sì sọ fún mi pé,
“Dìde, Olólùfẹ́ mi,
arẹwà mi, kí o sì wà pẹ̀lú mi.
11 Wò ó! Ìgbà òtútù ti kọjá;
òjò ti rọ̀ dawọ́, ó sì ti lọ.
12 Àwọn òdòdó fi ara hàn lórí ilẹ̀
àsìkò ìkọrin àwọn ẹyẹ dé
a sì gbọ́ ohùn àdàbà ní ilẹ̀ wa.
13 Igi ọ̀pọ̀tọ́ mú èso tuntun jáde,
àwọn àjàrà nípa ìtànná wọ́n fún ni ní òórùn dídùn,
Dìde, wá, Olólùfẹ́ mi;
Arẹwà mi nìkan ṣoṣo, wá pẹ̀lú mi.”
Olùfẹ́
14 Àdàbà mi wà nínú pàlàpálá òkúta,
ní ibi ìkọ̀kọ̀ ní orí òkè gíga,
fi ojú rẹ hàn mí,
jẹ́ kí èmi gbọ́ ohùn rẹ;
Nítorí tí ohùn rẹ dùn,
tí ojú rẹ sì ní ẹwà.
15 Bá wa mú àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀,
àní àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kéékèèkéé
tí ń ba ọgbà àjàrà jẹ́,
àwọn ọgbà àjàrà wa tó ní ìtànná.
Olólùfẹ́
16 Olùfẹ́ mi ni tèmi èmi sì ni tirẹ̀;
Ó ń jẹ láàrín àwọn koríko lílì.
17 Títí ìgbà ìtura ọjọ́
títí òjìji yóò fi fò lọ,
yípadà, olùfẹ́ mi,
kí o sì dàbí abo egbin
tàbí ọmọ àgbọ̀nrín
lórí òkè Beteri.
Ìkìlọ̀ láti ṣe ìgbọ́ràn
2 Nítorí náà, ó yẹ kí àwa máa fi iyè sí àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì gidigidi tí àwa ti gbọ́, kí a má ba à gbá wa lọ kúrò nínú wọn nígbà kan. 2 Nítorí bí ọ̀rọ̀ tí a tí ẹnu àwọn angẹli sọ bá sì dúró ṣinṣin, àti tí olúkúlùkù ẹ̀ṣẹ̀ sí òfin àti àìgbọ́ràn gba ìjìyà tí ó tọ́ sí i, 3 kín ni ohun náà tí ó mú wa lérò pé a lè bọ́ kúrò nínú ìjìyà bí a kò bá náání ìgbàlà ńlá yìí? Ìgbàlà tí Olúwa fúnrarẹ̀ kọ́kọ́ kéde, èyí tí a sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún wa láti ọwọ́ àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà lẹ́nu rẹ̀. 4 Ọlọ́run jẹ́rìí sí i nípa àwọn iṣẹ́ ààmì àti ìyanu àti oríṣìíríṣìí iṣẹ́ agbára àti nípa ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ tí a pín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀.
Jesu bí arákùnrin rẹ̀
5 Nítorí pé, kì í ṣe abẹ́ ìṣàkóso àwọn angẹli ni ó fi ayé tí ń bọ̀, tí àwa ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ sí. 6 (A)Ṣùgbọ́n ibìkan wà tí ẹnìkan tí jẹ́rìí pé:
“Kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣe ìrántí rẹ̀,
tàbí ọmọ ènìyàn, tí ìwọ fi ń bẹ̀ ẹ́ wò?
7 Ìwọ dá a ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju àwọn angẹli lọ;
ìwọ fi ògo àti ọlá de e ni adé,
ìwọ sì fi í jẹ olórí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ:
8 Ìwọ fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.”
Ní ti fífi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n àwa kò ì tí ì rí ohun kan tí ó kù tí kò sí ní abẹ́ àkóso rẹ̀. Síbẹ̀ nísinsin yìí àwa kò ì tí ì rí pé ó fi ohun gbogbo sábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀ 9 Ṣùgbọ́n àwa rí Jesu ẹni tí a rẹ̀ sílẹ̀ díẹ̀ ju àwọn angẹli lọ fún àkókò díẹ̀, àní Jesu, ẹni tí a fi ògo àti ọlá dé ní adé nítorí ìjìyà wa; kí ó lè tọ́ ikú wò fún olúkúlùkù ènìyàn nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.
10 Nítorí pé ó yẹ fún Ọlọ́run, nítorí nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo ṣẹ̀ wà, láti mú àwọn ọmọ púpọ̀ wá sínú ògo, láti ṣe balógun ìgbàlà wọn ni àṣepé nípa ìjìyà. 11 Nítorí àti ẹni tí ń sọ ni di mímọ́ àti àwọn tí a ń sọ di mímọ́, láti ọ̀dọ̀ ẹnìkan ṣoṣo ni gbogbo wọn ti wá: Nítorí èyí ni kò ṣe tijú láti pè wọ́n ni arákùnrin. 12 (B)Àti wí pé,
“Èmi ó sọ̀rọ̀ orúkọ rẹ̀ fún àwọn ará mi,
ni àárín ìjọ ni èmi yóò kọrin ìyìn rẹ̀.”
13 (C)Àti pẹ̀lú,
“Èmi yóò gbẹ́kẹ̀ mi lé e.”
Àti pẹ̀lú,
“Kíyèsi í, èmi rèé, èmi àti àwọn ọmọ tí Ọlọ́run fi fún mi.”
14 Ǹjẹ́ ni ìwọ̀n bí àwọn ọmọ tí ṣe alábápín ará àti ẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni òun pẹ̀lú sì ṣe alábápín nínú ohun kan náà; kí ó lè ti ipa ikú rẹ̀ pa ẹni tí ó ní agbára ikú run, èyí ni èṣù. 15 Kí o sì lè gba gbogbo àwọn tí ó tìtorí ìbẹ̀rù ikú wà lábẹ́ ìdè lọ́jọ́ ayé wọn gbogbo kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù. 16 (D)Nítorí pé, nítòótọ́, kì í ṣe àwọn angẹli ni ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún, ṣùgbọ́n àwọn irú-ọmọ Abrahamu ni ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún. 17 Nítorí náà, ó yẹ pé nínú ohun gbogbo kí ó dàbí àwọn ará rẹ̀, kí ó lè jẹ́ aláàánú àti olóòtítọ́ alábojútó Àlùfáà nínú ohun tí i ṣe ti Ọlọ́run, kí o lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn. 18 Nítorí níwọ̀n bí òun tìkára rẹ̀ ti jìyà tí a sì ti dán an wò, òun ní agbára láti ran àwọn tí a ń dánwò lọ́wọ́.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.