M’Cheyne Bible Reading Plan
Ìràpadà ohun tí ó jẹ́ ti Olúwa
27 Olúwa sọ fún Mose pé. 2 “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé: ‘Bí ẹnìkan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ pàtàkì láti ya ènìyàn kan sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run nípa sísan iye tí ó tó, 3 kí iye owó ọkùnrin láti ọmọ ogún ọdún sí ọgọ́ta ọdún jẹ́ àádọ́ta òṣùwọ̀n ṣékélì fàdákà, gẹ́gẹ́ bí òṣùwọ̀n ṣékélì ti ibi mímọ́ Olúwa; 4 Bí ẹni náà bá jẹ obìnrin, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ ọgbọ̀n òṣùwọ̀n ṣékélì. 5 Bí ẹni náà bá jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún sí ogún ọdún, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ ogún ṣékélì fún ọkùnrin àti òṣùwọ̀n ṣékélì mẹ́wàá fún obìnrin. 6 Bí ẹni náà bá jẹ́ ọmọ oṣù kan sí ọdún márùn-ún, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ òṣùwọ̀n ṣékélì fàdákà márùn-ún fún ọkùnrin àti òṣùwọ̀n ṣékélì fàdákà mẹ́ta fún obìnrin. 7 Bí ẹni náà bá jẹ́ ọmọ ọgọ́ta ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ òṣùwọ̀n ṣékélì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún fún ọkùnrin àti òṣùwọ̀n ṣékélì mẹ́wàá fún obìnrin. 8 Bí ẹnìkan tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ bá tálákà púpọ̀ dé bi pé kò lè san iye owó náà, kí a mú ẹni náà wá síwájú àlùfáà, àlùfáà yóò sì dá iye owó tí ó lè san lé e gẹ́gẹ́ bí agbára ẹni náà tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́.
9 “ ‘Bí ẹ̀jẹ́ tí ó jẹ́ bá jẹ́ ẹranko èyí tí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fún Olúwa, irú ẹran bẹ́ẹ̀ tí a bá fi fún Olúwa di mímọ́. 10 Ẹni tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ náà kò gbọdọ̀ pàrọ̀ ẹran mìíràn, yálà kí ó pàrọ̀ èyí tí ó dára sí èyí tí kò dára tàbí èyí tí kò dára sí èyí tí ó dára. Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀ ti Olúwa ni ẹranko méjèèjì. 11 Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ ní ti ẹranko àìmọ́ tí a fi tọrẹ: èyí tí kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà bí i ọrẹ fún Olúwa. Kí ọkùnrin náà mú ọrẹ náà lọ fún àlùfáà. 12 Kí àlùfáà díye lé e, gẹ́gẹ́ bí ó ti dára tàbí bí ó ti bàjẹ́ sí. Iye owó náà ni kí ó jẹ́. 13 Bí ẹni náà bá fẹ́ rà á padà: ó gbọdọ̀ san iye owó rẹ̀ àti ìdá ogún iye owó náà láfikún.
14 “ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ya ilẹ̀ rẹ̀ sí mímọ́ fún Olúwa: kí àlùfáà kó sọ iye tí yóò san gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ náà ti dára tàbí bàjẹ́ sí: iye owó náà ni kí ó jẹ́. 15 Bí ẹni tí ó yá ilé náà sí mímọ́ bá fẹ́ rà á padà. Jẹ́ kí ó fi ìdámárùn-ún owó ìdíyelé rẹ̀ kún ún, yóò si jẹ́ tirẹ̀.
16 “ ‘Bí ẹnìkan bá sì ya ara ilẹ̀ ìdílé rẹ̀ sí mímọ́ fún Olúwa. Iye tí ó bá jẹ́ ni kí wọ́n ṣètò gẹ́gẹ́ bí iye èso tí a ó fi gbìn ín. Àádọ́ta ṣékélì fàdákà fún òṣùwọ̀n homeri irúgbìn barle. 17 Bí ó ba ṣe pé ní ọdún ìdásílẹ̀ ni ó ya ilẹ̀ náà sí mímọ́. Iye owó tí wọn sọtẹ́lẹ̀ náà ni kí o san. 18 Bí ó bá ya ilẹ̀ náà sí mímọ́ lẹ́yìn ọdún ìdásílẹ̀ kí àlùfáà sọ iye owó tí yóò san fún ọdún tókù kí ọdún ìdásílẹ̀ mìíràn tó pé iye owó tí ó gbọdọ̀ jẹ yóò dínkù. 19 Bí ẹni tí ó ya ilẹ̀ sí mímọ́ bá fẹ́ rà á padà: kí ó san iye owó náà pẹ̀lú àfikún ìdámárùn-ún. Ilẹ̀ náà yóò sì di tirẹ̀. 20 Bí kò bá ra ilẹ̀ náà padà tàbí bí ó bá tà á fún ẹlòmíràn kò le è ri rà padà mọ́. 21 Bí a bá fi ilẹ̀ náà sílẹ̀ ní ọdún ìdásílẹ̀ yóò di mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ tí a fi fún Olúwa. Yóò sì di ohun ìní àlùfáà.
22 “ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ya ilẹ̀ tí ó ti rà tí kì í ṣe ilẹ̀ ìdílé rẹ̀ sí mímọ́ fún Olúwa. 23 Kí àlùfáà sọ iye tí ó tọ títí di ọdún ìdásílẹ̀. Kí ọkùnrin náà sì san iye owó náà ní ọjọ́ náà gẹ́gẹ́ bí ohun mímọ́ sí Olúwa. 24 Ní ọdún ìdásílẹ̀ ilẹ̀ náà yóò padà di ti ẹni tí ó ni í, lọ́wọ́ ẹni tí a ti rà á. 25 Gbogbo iye owó wọ̀nyí gbọdọ̀ wà ní ìbámu pẹ̀lú ṣékélì ibi mímọ́, ogún gera.
26 “ ‘Kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ ya gbogbo àkọ́bí ẹran sọ́tọ̀. Èyí jẹ́ ti Olúwa nípasẹ̀ òfin àkọ́bí: yálà akọ màlúù ni tàbí àgùntàn, ti Olúwa ni. 27 Bí ó bá jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹran tí kò mọ́, nígbà náà ni kí ó rà á padà gẹ́gẹ́ bí ìdíyelé rẹ̀, kí ó sì fi ìdámárùn-ún lé e, tàbí bí a kò bá rà á padà kí ẹ tà á gẹ́gẹ́ bí ìdíyelé rẹ̀.
28 (A)“ ‘Ohun tí a bá yà sí mímọ́ pátápátá láti ọwọ́ ẹnikẹ́ni sí Olúwa tàbí ẹranko tàbí ilẹ̀ tí ó jogún: òun kò gbọdọ̀ tà á kí ó rà á padà. Gbogbo ohun ìyàsọ́tọ̀ bẹ́ẹ̀ di mímọ́ jùlọ fún Olúwa.
29 “ ‘Ẹni tí ẹ bá ti yà sọ́tọ̀ fún pípa, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ rà á padà, pípa ni kí ẹ pa á.
30 (B)“ ‘Gbogbo ìdámẹ́wàá ilẹ̀ náà yálà tí èso ilẹ̀ ni, tàbí tí èso igi, ti Olúwa ni. Mímọ́ ni fún Olúwa. 31 Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ra ìdámẹ́wàá nǹkan rẹ̀ padà: o gbọdọ̀ fi márùn-ún kún un. 32 Gbogbo ìdámẹ́wàá àgbò àti ẹran ọ̀sìn, àní ìdámẹ́wàá ẹran tó bá kọjá lábẹ́ ọ̀pá darandaran kí ó jẹ́ mímọ́ fún Olúwa. 33 Ènìyàn kò gbọdọ̀ wádìí bóyá ó dára tàbí kò dára, kò sì gbọdọ̀ pààrọ̀ rẹ̀. Bí ó bá pààrọ̀ rẹ̀: àti èyí tí ó pààrọ̀ àti èyí tí ó fi pààrọ̀ ni kí ó jẹ́ mímọ́. Wọn kò gbọdọ̀ rà á padà.’ ”
34 Àwọn àṣẹ wọ̀nyí ni Olúwa pa fún Mose fún àwọn ọmọ Israẹli ní orí òkè Sinai.
Tí Dafidi. Nígbà tí ó díbọ́n bí ẹni tí ń ṣe wèrè níwájú Abimeleki, ẹni tí ó lé e lọ, ó sì jáde lọ.
34 Èmi yóò máa fi ìbùkún fún Olúwa nígbà gbogbo;
ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi títí láé.
2 Ọkàn mí yóò máa ṣògo nínú Olúwa;
jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ gbọ́ kí inú wọn kí ó sì máa dùn.
3 Gbé Olúwa ga pẹ̀lú mi;
kí ẹ sì jẹ́ kí a jọ gbé orúkọ rẹ̀ lékè.
4 Èmi wá Olúwa, ó sì dá mi lóhùn;
Ó sì gbà mí kúrò nínú ìbẹ̀rù mi gbogbo.
5 Wọ́n wò ó, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ wọn;
ojú kò sì tì wọ́n.
6 Ọkùnrin olùpọ́njú yí kígbe, Olúwa sì gbóhùn rẹ̀;
ó sì gbà á là kúrò nínú gbogbo ìpọ́njú rẹ̀.
7 Angẹli Olúwa yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká
ó sì gbà wọ́n.
8 Tọ́ ọ wò kí o sì rí i wí pé Olúwa dára;
ẹni ayọ̀ ni ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ààbò nínú rẹ̀.
9 Ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́,
nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
10 Àwọn ọmọ kìnnìún a máa ṣe aláìní ebi a sì máa pa wọ́n;
ṣùgbọ́n àwọn tí ó wá Olúwa kì yóò ṣe aláìní ohun tí ó dára.
11 Wá, ẹ̀yin ọmọ mi, fi etí sí mi;
èmi yóò kọ́ ọ yín ní ẹ̀rù Olúwa.
12 (A)Ta ni nínú yín tí ń fẹ́ ìyè, tí ó sì ń fẹ́ ọjọ́ púpọ̀;
kí ó lè gbádùn ọjọ́ rere?
13 Pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi
àti ètè rẹ̀ kúrò ní ẹ̀tàn sísọ.
14 Yà kúrò nínú ibi kí o sì ṣe rere;
wá àlàáfíà, kí o sì lépa rẹ̀.
15 Ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo;
etí i rẹ̀ sì ṣí sí ẹkún wọn.
16 Ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú;
láti ké ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.
17 Nígbà tí olódodo bá ké fún ìrànlọ́wọ́,
Olúwa a máa gbọ́, a sì yọ wọ́n jáde láti inú gbogbo wàhálà wọn.
18 Olúwa súnmọ́ etí ọ̀dọ̀ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn;
ó sì gba irú àwọn tí í ṣe oníròra ọkàn là.
19 Ìpọ́njú àwọn olódodo pọ̀,
ṣùgbọ́n Olúwa gbà wọ́n kúrò nínú gbogbo rẹ̀.
20 Ó pa gbogbo egungun wọn mọ́;
kò sí ọ̀kan tí ó dá nínú wọn.
21 Ibi ni ó mú ikú ìkà wá,
àti àwọn tí ó kórìíra olódodo ni yóò jẹ̀bi.
22 Olúwa ra ọkàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ padà;
kò sí ọ̀kan nínú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé tí yóò jẹ̀bi.
10 Gẹ́gẹ́ bí òkú eṣinṣin tí ń fún òróró ìkunra ní òórùn búburú,
bẹ́ẹ̀ náà ni òmùgọ̀ díẹ̀ ṣe ń bo ọgbọ́n àti ọlá mọ́lẹ̀.
2 Ọkàn ọlọ́gbọ́n a máa ṣí sí ohun tí ó tọ̀nà,
ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ sí ohun tí kò dára.
3 Kódà bí ó ti ṣe ń rìn láàrín ọ̀nà,
òmùgọ̀ kò ní ọgbọ́n
a sì máa fihan gbogbo ènìyàn bí ó ti gọ̀ tó.
4 Bí ìbínú alákòóso bá dìde lòdì sí ọ,
ma ṣe fi ààyè rẹ sílẹ̀;
ìdákẹ́ jẹ́ẹ́jẹ́ le è tú àṣìṣe ńlá.
5 Ohun ibi kan wà tí mo ti rí lábẹ́ oòrùn,
irú àṣìṣe tí ó dìde láti ọ̀dọ̀ alákòóso.
6 A gbé aṣiwèrè sí ọ̀pọ̀ ipò tí ó ga jùlọ,
nígbà tí ọlọ́rọ̀ gba àwọn ààyè tí ó kéré jùlọ.
7 Mo ti rí ẹrú lórí ẹṣin,
nígbà tí ọmọ-aládé ń fi ẹsẹ̀ rìn bí ẹrú.
8 Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́ kòtò, ó le è ṣubú sínú rẹ̀;
ẹnikẹ́ni tí ó bá la inú ògiri, ejò le è ṣán an.
9 Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbe òkúta le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn;
ẹnikẹ́ni tí ó bá la ìtì igi le è ní ìpalára láti ipasẹ̀ wọn.
10 Bí àáké bá kú
tí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kò sì sí ní pípọ́n;
yóò nílò agbára púpọ̀
ṣùgbọ́n ọgbọ́n orí ni yóò mú àṣeyọrí wá.
11 Bí ejò bá ṣán ni kí a tó lo oògùn rẹ̀,
kò sí èrè kankan fún olóògùn rẹ̀.
12 Ọ̀rọ̀ tí ó wá láti ẹnu ọlọ́gbọ́n a máa ní oore-ọ̀fẹ́
ṣùgbọ́n ètè òmùgọ̀ fúnrarẹ̀ ni yóò parun.
13 Ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ òmùgọ̀;
ìparí rẹ̀ sì jẹ́ ìsínwín búburú.
14 Wèrè a sì máa ṣàfikún ọ̀rọ̀.
Kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí ó ń bọ̀
ta ni ó le è sọ fún un ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀?
15 Iṣẹ́ aṣiwèrè a máa dá a lágara
kò sì mọ ojú ọ̀nà sí ìlú.
16 Ègbé ni fún ọ, ìwọ ilẹ̀ tí ọba ń ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀
àti tí àwọn ọmọ-aládé ń ṣe àsè ní òwúrọ̀.
17 Ìbùkún ni fún ọ, ìwọ ilẹ̀ èyí tí ọba rẹ̀ jẹ́
ọmọ ọlọ́lá, àti tí àwọn ọmọ-aládé ń jẹun ní àsìkò tí ó yẹ,
fún ìlera, tí kì í ṣe fún ìmutípara.
18 Bí ènìyàn bá ń lọ́ra, àjà ilé a máa jì
bí ọwọ́ rẹ̀ bá ń ṣe ọ̀lẹ, ilé a máa jó.
19 Ẹ̀rín rínrín ni a ṣe àsè fún,
wáìnì a máa mú ayé dùn,
ṣùgbọ́n owó ni ìdáhùn sí ohun gbogbo.
20 Ma ṣe bú ọba, kódà nínú èrò rẹ,
tàbí kí o ṣépè fún ọlọ́rọ̀ ní ibi ibùsùn rẹ,
nítorí pé ẹyẹ ojú ọ̀run le è gbé ọ̀rọ̀ rẹ
ẹyẹ tí ó sì ní ìyẹ́ apá le è fi ẹjọ́ ohun tí o sọ sùn.
Àwọn ẹ̀kọ́ tí a gbọdọ̀ kọ́ ní onírúurú àkójọpọ̀
2 Ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ máa kọ́ni ní ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro lórí ìgbé ayé onígbàgbọ́ tòótọ́. 2 Kọ́ àwọn àgbà ọkùnrin lẹ́kọ̀ọ́ láti ní ìrònú àti láti jẹ́ ẹni àpọ́nlé àti ẹni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. Wọn gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí ó jinlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́, nínú ìfẹ́ àti nínú ìpamọ́ra.
3 Bákan náà, ni kí ó kọ́ àwọn àgbà obìnrin lẹ́kọ̀ọ́ láti kọ́ bí à a tí gbé ìgbé ayé ẹni ọ̀wọ̀, wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ afọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ tàbí olùfẹ́ ọtí mímu, ṣùgbọ́n wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ olùkọ́ni ní ohun rere. 4 Nípa èyí, wọ́n yóò lè máa kọ́ àwọn ọ̀dọ́bìnrin láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọkọ wọn àti àwọn ọmọ wọn, 5 láti jẹ́ ẹni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti ọlọ́kàn mímọ́, kí wọ́n máa ṣe ojúṣe wọn nínú ilé, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ onínúrere, kí wọ́n sì máa tẹríba fún àwọn ọkọ wọ́n, kí ẹnikẹ́ni máa ba à sọ̀rọ̀-òdì sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
6 Bákan náà, rọ àwọn ọ̀dọ́ ọkùnrin láti kó ara wọn ni ìjánu. 7 Nínú ohun gbogbo fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí alápẹẹrẹ ohun rere. Nínú ẹ̀kọ́ rẹ fi àpẹẹrẹ ìwà pípé hàn, ẹni tó kún ojú òṣùwọ̀n 8 ọ̀rọ̀ tí ó yè kooro, tí a kò lè dá lẹ́bi, kí ojú kí ó ti ẹni tí ó ń sòdì, ní àìní ohun búburú kan láti wí sí wa.
9 Kọ́ àwọn ẹrú láti ṣe ìgbọ́ràn sí àwọn olówó wọn nínú ohun gbogbo, láti máa gbìyànjú láti tẹ́ wọn lọ́rùn, wọn kò gbọdọ̀ gbó olówó wọn lẹ́nu, 10 wọn kò gbọdọ̀ jà wọ́n lólè ohunkóhun, ṣùgbọ́n kí wọ́n jẹ́ ẹni tó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, kí wọn ó làkàkà ní gbogbo ọ̀nà láti jẹ́ kí ìkọ́ni nípa Ọlọ́run àti Olùgbàlà ní ìtumọ̀ rere.
11 Nítorí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tó mú ìgbàlà wà ti fi ara hàn fún gbogbo ènìyàn. 12 Ó ń kọ́ wa láti sẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ayé, kí a sì máa wà ní àìrékọjá, ní òdodo àti ní ìwà-bí-Ọlọ́run ní ayé ìsinsin yìí, 13 bí a ti ń wọ́nà fún ìrètí tó ní bùkún, èyí ń ní ìfarahàn ògo Ọlọ́run wa tí ó tóbi àti Olùgbàlà wa Jesu Kristi. 14 (A)Ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún wa láti rà fún ìràpadà kúrò nínú ìwà búburú gbogbo àti kí ó sì le wẹ̀ àwọn ènìyàn kan mọ́ fún ara rẹ̀ fún ìní ohun tìkára rẹ̀, àwọn tó ń ní ìtara fún iṣẹ́ rere.
15 Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni kí ìwọ kí ó máa kọ wọn. Gbani níyànjú kí ó sì máa fi gbogbo àṣẹ bá ni wí. Máa jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó gàn ọ́.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.