M’Cheyne Bible Reading Plan
Ẹ̀jẹ̀ jíjẹ jẹ́ èèwọ̀
17 Olúwa sọ fún Mose pé: 2 “Sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli: ohun tí Ọlọ́run pàṣẹ nìyí: 3 Bí ẹnikẹ́ni nínú ìdílé Israẹli bá pa màlúù tàbí ọ̀dọ́-àgùntàn tàbí àgbò nínú ibùdó tàbí bí ó bá pa á lẹ́yìn ibùdó 4 tí kò sì mú un wá sí ibi àgọ́ ìpàdé láti fi rú ẹbọ sí Olúwa níwájú àgọ́ ìpàdé: ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni kí ẹ kà sí ẹni náà lọ́rùn: torí pé ó ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀: ẹni náà ni a ó sì gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 5 Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí àwọn ọmọ Israẹli le è máa mú ẹbọ wọn tí wọn ti rú ní ìta gbangba wá sí iwájú Olúwa: wọ́n gbọdọ̀ mú un wá síwájú àlùfáà àní sí Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé: kí wọ́n sì rú wọn gẹ́gẹ́ bí ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa. 6 Àlùfáà náà yóò sì fi ẹ̀jẹ̀ náà wọ́n ibi pẹpẹ Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, yóò sì sun ọ̀rá rẹ̀ ní òórùn dídùn sí Olúwa. 7 Nítorí náà, kí wọn má ṣe rú ẹbọ wọn sí ère ẹranko mọ́, nínú èyí tí wọ́n ti ṣe àgbèrè tọ̀ lọ. Èyí yóò sì jẹ́ ìlànà títí láé láti ìran dé ìran wọn tí ń bọ̀.
8 “Kí ó sọ fún wọn pé: ‘Ọkùnrin yówù kí ó jẹ́ ní ìdílé Israẹli tàbí ti àwọn àlejò tí ń gbé láàrín wọn tí ó bá rú ẹbọ sísun tàbí ṣe ẹbọ 9 tí kò sì mú un wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé láti fi rú ẹbọ sí Olúwa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.
10 (A)“ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ẹ̀jẹ̀ yálà nínú ìdílé Israẹli tàbí àwọn àlejò tí ń gbé láàrín wọn: Èmi yóò bínú sí irú ẹni náà tí ó jẹ ẹ̀jẹ̀: èmi yóò sì gé e kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 11 Nítorí pé nínú ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí ẹ̀dá wà, èmi sì ti fi fún yín lórí pẹpẹ fún ètùtù ọkàn yín: nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ni a fi ń ṣe ètùtù fún ẹ̀mí ènìyàn. 12 Ìdí nìyí tí mo fi sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ọ̀kankan nínú yín kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àlejò kan tí ń ṣe àtìpó nínú yín kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀.
13 “ ‘Ẹnikẹ́ni yálà nínú àwọn ọmọ Israẹli tàbí àlejò tí ń gbé láàrín wọn, tí ó bá pa ẹranko tàbí ẹyẹ tí ó yẹ fún jíjẹ gbọdọ̀ ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ kí ó sì bò ó mọ́lẹ̀. 14 Torí pé ẹ̀mí gbogbo ẹ̀dá ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, torí náà ni mo fi kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli pé wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ohun abẹ̀mí kankan: torí pé nínú ẹ̀jẹ̀ ohun abẹ̀mí wọ̀nyí ni ẹ̀mí wọn wà: ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́ ni a ó gé kúrò.
15 “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohun tí ó kú sílẹ̀ fúnrarẹ̀: tàbí èyí tí ẹranko búburú pa kálẹ̀ yálà onílé tàbí àlejò: ó ní láti fọ aṣọ rẹ̀. Kí ó sì fi omi wẹ ara rẹ̀: yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí di àṣálẹ́ lẹ́yìn èyí ni yóò tó di mímọ́. 16 Ṣùgbọ́n bí ó bá kọ̀ láti wẹ ara rẹ̀ tí kò sì fọ aṣọ rẹ̀ náà: ẹ̀bi rẹ̀ yóò wà lórí ara rẹ̀.’ ”
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
20 Kí Olúwa kí ó gbóhùn rẹ ní ọjọ́ ìpọ́njú;
kí orúkọ Ọlọ́run Jakọbu kí ó dáàbò bò ọ́.
2 Kí ó rán ìrànlọ́wọ́ sí ọ, láti ibi mímọ́
kí ó sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Sioni wá.
3 Kí ó sì rántí gbogbo ẹbọ rẹ
kí ó sì gba ẹbọ sísun rẹ. Sela
4 Kí ó fi fún ọ gẹ́gẹ́ bi ti èrò ọkàn rẹ
kí ó sì mú gbogbo ìmọ̀ rẹ ṣẹ.
5 Àwa yóò hó fún ayọ̀ nígbà tí o bá di aṣẹ́gun
àwa yóò gbé àsíá wa sókè ní orúkọ Ọlọ́run wa.
Kí Ọlọ́run kí ó mú gbogbo ìbéèrè rẹ̀ ṣẹ.
6 Nísinsin yìí, èmi mọ̀ wí pé:
Olúwa pa ẹni ààmì òróró rẹ̀ mọ́.
Yóò gbọ́ láti ọ̀run mímọ́ rẹ̀ wá
pẹ̀lú agbára ìgbàlà ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.
7 Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé kẹ̀kẹ́, àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé ẹṣin,
ṣùgbọ́n àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa Ọlọ́run wa.
8 Wọ́n wólẹ̀, ní eékún, wọ́n sì ṣubú,
ṣùgbọ́n àwa dìde, a sì dúró ṣinṣin.
9 Olúwa, fi ìṣẹ́gun fún ọba!
Dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń kígbe pè!
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
21 Háà! Olúwa, ọba yóò yọ̀ nínú agbára rẹ,
àti ní ìgbàlà rẹ, yóò ti yọ̀ pẹ́ tó!
2 Nítorí pé ìwọ ti fi ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ fún un,
bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò sì dùn ún ní ìbéèrè ẹnu rẹ̀. Sela.
3 Ìwọ ti fi àwọn ìbùkún oore kò ó ni ọ̀nà
ìwọ fi adé wúrà dé e ní orí.
4 Ó béèrè fún ìyè, ìwọ sì fi fún un,
àní ọjọ́ gígùn títí ayérayé.
5 Ògo rẹ̀ pọ̀ nípasẹ̀ ìṣẹ́gun tí o fi fún un;
ìwọ sì jẹ́ kí iyì ọláńlá rẹ̀ wà lára rẹ.
6 Dájúdájú, ìwọ ti fi ìbùkún ayérayé fún un:
ìwọ sì mú inú rẹ̀ dùn pẹ̀lú ayọ̀ ojú u rẹ̀.
7 Ọba ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa;
nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọ̀gá-ògo tí kì í kùnà
kì yóò sípò padà.
8 Ọwọ́ rẹ yóò wá gbogbo àwọn ọ̀tá a rẹ rí;
ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò wá àwọn tí o kórìíra rẹ rí.
9 Nígbà tí ìwọ bá yọ
ìwọ yóò mú wọn dàbí iná ìléru.
Olúwa yóò gbé wọn mì nínú ìbínú rẹ̀,
àti pé iná rẹ̀ yóò jó wọn run.
10 Ìwọ yóò pa ìrandíran wọn run kúrò lórí ilẹ̀,
àti irú-ọmọ wọn kúrò láàrín àwọn ọmọ ènìyàn.
11 Bí o tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n ro èrò ibi sí ọ
wọ́n sì ń pète ìwà ìkà, wọn kì yóò ṣe àṣeyọrí.
12 Nítorí pé ìwọ yóò mú wọn yí ẹ̀yìn wọn padà
nígbà tí o bá pinnu láti ta wọ́n ní ọfà.
13 Gbígbéga ni ọ́ Olúwa, nínú agbára rẹ;
a ó kọrin, a ó yín agbára a rẹ̀.
31 Àwọn ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ ti Lemueli ọba,
ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ìyá rẹ̀ kọ́ ọ.
2 “Gbọ́ ìwọ ọmọ mi, gbọ́ ìwọ ọmọ inú mi!
Gbọ́ ìwọ ọmọ ẹ̀jẹ́ mi.
3 Má ṣe lo agbára rẹ lórí obìnrin,
okun rẹ lórí àwọn tí ó pa àwọn ọba run.
4 “Kì í ṣe fún àwọn ọba, ìwọ Lemueli
kì í ṣe fún ọba láti mu ọtí wáìnì
kì í ṣe fún alákòóso láti máa wá ọtí líle
5 Kí wọn má ba à mu ọtí yó kí wọn sì gbàgbé ohun tí òfin wí
kí wọn sì fi ẹ̀tọ́ àwọn tí ara ń ni dù wọ́n
6 Fi ọtí líle fún àwọn tí ń ṣègbé
wáìnì fún àwọn tí ó wà nínú ìrora;
7 Jẹ́ kí wọn mu ọtí kí wọn sì gbàgbé òsì wọn
kí wọn má sì rántí òsì wọn mọ́.
8 “Sọ̀rọ̀ lórúkọ àwọn tí kò le sọ̀rọ̀ fúnrawọn
fún ẹ̀tọ́ àwọn ẹni tí ń parun
9 Sọ̀rọ̀ kí o sì ṣe ìdájọ́ àìṣègbè
jà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà àti aláìní.”
10 Ta ni ó le rí aya oníwà rere?
Ó níye lórí ju iyùn lọ
11 Ọkọ rẹ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé púpọ̀ nínú rẹ̀
kò sì ṣí ìwà rere tí kò pé lọ́wọ́ rẹ̀.
12 Ire ní ó ń ṣe fún un, kì í ṣe ibi
ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.
13 Ó sa aṣọ irun àgùntàn olówùú àti ọ̀gbọ̀
Ó sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìyárí.
14 Ó dàbí ọkọ̀ ojú omi tí àwọn oníṣòwò;
ó ń gbé oúnjẹ rẹ̀ wá láti ọ̀nà jíjìn
15 Ó dìde nígbà tí òkùnkùn sì kùn;
ó ṣe oúnjẹ fún ìdílé rẹ̀
àti ìpín oúnjẹ fún àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀.
16 Ó kíyèsi oko kan, ó sì rà á;
nínú ohun tí ó ń wọlé fún un ó gbin ọgbà àjàrà rẹ̀
17 Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ tagbára tagbára
apá rẹ̀ le koko fún iṣẹ́
18 Ó rí i pé òwò òun pé
fìtílà rẹ̀ kì í sì í kú ní òru
19 Ní ọwọ́ rẹ̀, ó di kẹ̀kẹ́ òwú mú
ó sì na ọwọ́ rẹ̀ di ìrànwú mú
20 O la ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn tálákà
ó sì na ọwọ́ rẹ̀ sí àwọn aláìní.
21 Nígbà tí òjò-dídì rọ̀, kò bẹ̀rù nítorí ìdílé rẹ̀
nítorí gbogbo wọn ni ó wọ aṣọ tí ó nípọn.
22 Ó ṣe aṣọ títẹ́ fún ibùsùn rẹ̀;
ẹ̀wù dáradára àti elése àlùkò ni aṣọ rẹ̀
23 A bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ ní ẹnu ibodè ìlú
níbi tí ó ń jókòó láàrín àwọn àgbàgbà ìlú
24 Ó ń ṣe àwọn aṣọ dáradára ó sì ń tà wọ́n
ó sì ń kó ọjà fún àwọn oníṣòwò
25 Agbára àti ọlá ni ó wò ọ́ láṣọ
ó le fi ọjọ́ iwájú rẹ́rìn-ín.
26 A sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n
ìkọ́ni òtítọ́ sì ń bẹ létè e rẹ̀
27 Ó ń bojútó gbogbo ètò ilé rẹ̀
kì í sì í jẹ oúnjẹ ìmẹ́lẹ́
28 Àwọn ọmọ rẹ̀ dìde wọ́n sì pè é ní alábùkún
ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú ń gbóríyìn fún un
29 “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin ní ń ṣe nǹkan ọlọ́lá
ṣùgbọ́n ìwọ ju gbogbo wọn lọ”
30 Ojú dáradára a máa tan ni, ẹwà sì jẹ́ asán
nítorí obìnrin tí ó bẹ̀rù Olúwa yẹ kí ó gba oríyìn
31 Sì fún un ní èrè tí ó tọ́ sí i
kí o sì jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ̀ fún un ní ìyìn ní ẹnu ibodè ìlú.
Àwọn ẹ̀kọ́ lórí ìsìn
2 Nítorí náà mo gbà yín níyànjú ṣáájú ohun gbogbo, pé kí a máa bẹ̀bẹ̀, kí a máa gbàdúrà, kí a máa ṣìpẹ̀, àti kí a máa dúpẹ́ nítorí gbogbo ènìyàn. 2 Fún àwọn ọba, àti gbogbo àwọn tí ó wà ni ipò àṣẹ, kí a lè máa lo ayé wa ní àlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ pẹ̀lú nínú gbogbo ìwà-bí-Ọlọ́run àti ìwà mímọ́. 3 Nítorí èyí dára, ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọ́run Olùgbàlà wa; 4 Ẹni tí ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn ní ìgbàlà kí wọ́n sì wá sínú ìmọ̀ òtítọ́. 5 Nítorí Ọlọ́run kan ní ń bẹ, onílàjà kan pẹ̀lú láàrín Ọlọ́run àti ènìyàn, àní Kristi Jesu ọkùnrin náà. 6 Ẹni ti ó fi ara rẹ̀ ṣe ìràpadà fún gbogbo ènìyàn—ẹ̀rí tí a fi fún ni ní àkókò tó yẹ. 7 Nítorí èyí tí a yàn mi ṣe oníwàásù, aposteli òtítọ́ ni èmi ń sọ, èmi kò ṣèké olùkọ́ àwọn aláìkọlà nínú ìgbàgbọ́ àti òtítọ́.
8 Mo fẹ́ kí àwọn ọkùnrin máa gbàdúrà níbi gbogbo, kí wọ́n máa gbé ọwọ́ mímọ́ sókè, ní àìbínú àti àìjiyàn. 9 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí àwọn obìnrin fi aṣọ ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ṣe ara wọn ní ọ̀ṣọ́, ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti pẹ̀lú ìwà àìrékọjá; kì í ṣe pẹ̀lú irun dídì, tàbí wúrà, tàbí peali, tàbí aṣọ olówó iyebíye, 10 bí kò ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ rere, èyí tí ó yẹ fún àwọn obìnrin tó jẹ́wọ́ pé wọ́n sin Ọlọ́run.
11 Jẹ́ kí obìnrin máa fi ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìtẹríba gbogbo kọ́ ẹ̀kọ́. 12 Ṣùgbọ́n èmi kò fi àṣẹ fún obìnrin láti máa kọ́ni, tàbí láti pàṣẹ lórí ọkùnrin, bí kò ṣe kí ó dákẹ́ jẹ́ẹ́. 13 (A)Nítorí Adamu ni a kọ́ dá, lẹ́yìn náà, Efa. 14 (B)Adamu kọ́ ni a tànjẹ, ṣùgbọ́n obìnrin náà ni a tàn tí ó sì di ẹlẹ́ṣẹ̀. 15 Ṣùgbọ́n a ó gbà àwọn obìnrin là nípa ìbímọ wọn, bí wọ́n bá dúró nínú ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àti ìwà mímọ́ pẹ̀lú ìwà àìrékọjá.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.