Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Lefitiku 9

Àwọn àlùfáà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́

Ní ọjọ́ kẹjọ, Mose pe Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn àgbàgbà Israẹli. Ó sọ fún Aaroni pé, “Mú akọ ọmọ màlúù kan wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti àgbò kan fún ẹbọ sísun, kí méjèèjì jẹ́ aláìlábùkù, kí o sì mú wọn wá sí iwájú Olúwa. Kí o sì sọ fún àwọn ará Israẹli pé, ‘Ẹ mú òbúkọ kan wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọmọ màlúù àti ọ̀dọ́-àgùntàn kan, kí méjèèjì jẹ́ ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù fún ẹbọ sísun, àti akọ màlúù kan àti àgbò kan fún ẹbọ àlàáfíà àti ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi òróró pò láti fi rú ẹbọ ní iwájú Olúwa. Nítorí pé Olúwa yóò farahàn yín ní òní.’ ”

Wọ́n kó gbogbo àwọn nǹkan tí Mose pàṣẹ wá sí iwájú àgọ́ ìpàdé, gbogbo ìjọ ènìyàn sì súnmọ́ tòsí, wọ́n sì dúró níwájú Olúwa. Nígbà náà ni Mose wí pé, “Ohun tí Olúwa pàṣẹ fún yín láti ṣe nìyìí, kí ògo Olúwa bá à lè farahàn yín.”

Mose sọ fún Aaroni pé, “Wá sí ibi pẹpẹ kí o sì rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti ẹbọ sísun rẹ, kí o sì ṣe ètùtù fún ara rẹ àti fún àwọn ènìyàn; rú ẹbọ ti àwọn ènìyàn náà, kí o sì ṣe ètùtù fún wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ.”

Aaroni sì wá sí ibi pẹpẹ, ó pa akọ ọmọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀. Àwọn ọmọ Aaroni sì mú ẹ̀jẹ̀ náà tọ̀ ọ́ wá, ó sì ti ìka ọwọ́ rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, ó fi sí orí ìwo pẹpẹ, ó sì da ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ. 10 Ó sun ọ̀rá, kíndìnrín àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, èyí tó mú láti inú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, lórí pẹpẹ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose. 11 Ó sì sun ara ẹran àti awọ rẹ̀ ní ẹ̀yìn ibùdó.

12 Lẹ́yìn èyí ó pa ẹran tó wà fún ẹbọ sísun. Àwọn ọmọ Aaroni sì mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó sì wọn yí pẹpẹ náà ká. 13 Wọ́n sì ń mú ẹbọ sísun náà fún un ní ègé kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú orí rẹ̀, ó sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ. 14 Ó fọ nǹkan inú rẹ̀ àti ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sun wọ́n lórí ẹbọ sísun tó wà lórí pẹpẹ.

15 Aaroni mú ẹbọ tó jẹ́ ti àwọn ènìyàn wá. Ó mú òbúkọ èyí tó dúró fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn ó sì pa á, ó fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ti àkọ́kọ́.

16 Ó mú ẹbọ sísun wá, ó sì rú u gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí a fi lélẹ̀. 17 Ó tún mu ẹbọ ohun jíjẹ wá, ó bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú rẹ̀, ó sì sun ún lórí pẹpẹ ní àfikún ẹbọ sísun tí àárọ̀.

18 (A)Ó pa akọ màlúù àti àgbò bí ẹbọ àlàáfíà fún àwọn ènìyàn. Àwọn ọmọ Aaroni sì mú ẹ̀jẹ̀ ẹran náà tọ̀ ọ́ wá, ó sì wọn yí pẹpẹ náà ká. 19 Ṣùgbọ́n ọ̀rá akọ màlúù àti àgbò náà: ìrù rẹ̀ tí ó lọ́ràá, básí ọ̀rá, ọ̀rá kíndìnrín, àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀: 20 gbogbo rẹ̀ ni wọ́n kó lórí igẹ̀ ẹran náà. Aaroni sì sun ọ̀rá náà lórí pẹpẹ. 21 Aaroni fi igẹ̀ àti itan ọ̀tún ẹran náà níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì bí Mose ṣe pa á láṣẹ.

22 (B)Aaroni sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí àwọn ènìyàn, ó sì súre fún wọn. Lẹ́yìn tó sì ti rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ sísun àti ẹbọ àlàáfíà, ó sọ̀kalẹ̀.

23 Mose àti Aaroni sì wọ inú àgọ́ ìpàdé. Nígbà tí wọ́n jáde, wọ́n súre fún àwọn ènìyàn, ògo Olúwa sì farahàn sí gbogbo ènìyàn, 24 Iná sì jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ó sì jó ẹbọ sísun àti ọ̀rá orí pẹpẹ. Nígbà tí gbogbo ènìyàn sì rí èyí wọ́n hó ìhó ayọ̀, wọ́n sì dojúbolẹ̀.

Saamu 10

10 Èéha ti ṣe, Olúwa, tí ìwọ fi dúró ní òkè réré?
    Èéha ti ṣe, tí ìwọ fi ara rẹ pamọ́ ní ìgbà ìpọ́njú?

Nínú àrékérekè ni ènìyàn búburú tí mu aláìlera,
    ẹni ti ó mú nínú ìdẹ̀kùn àrékérekè rẹ̀.
Nítorí ènìyàn búburú ń ṣògo ìfẹ́ inú ọkàn rẹ̀;
    Ó bùkún olójúkòkòrò, ó sì ń kẹ́gàn Olúwa
Ènìyàn búburú kò lè rí nínú ìgbéraga rẹ̀;
    kò sí ààyè fún Ọlọ́run nínú gbogbo èrò rẹ̀;
Ọ̀nà rẹ̀ ń gún régé nígbà gbogbo;
    òun ń gbéraga, òfin rẹ̀ sì jìnnà sí i;
    òun kẹ́gàn àwọn ọ̀tá rẹ̀.
O wí fún ara rẹ̀, “Kò sí ohun tí ó lè mì mí;
    Inú mi yóò máa dùn nígbà gbogbo, èmi kò sì ní ní wàhálà.”

(A)Ẹnu rẹ̀ kún fún ègún àti irọ́ àti ìtànjẹ;
    wàhálà àti ohun búburú wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀.
Ó lúgọ ní bùba nítòsí ìletò;
    Ògo níbi ìkọ̀kọ̀ láti pa aláìṣẹ̀.
Ojú rẹ̀ ń ṣọ́ àwọn tálákà ní ìkọ̀kọ̀.
    Ó ba ní ní bùba bí i kìnnìún nínú pàǹtí;
Ó ba ní bùba láti mú àwọn aláìní ìrànwọ́;
    ó mú àwọn aláìlólùrànlọ́wọ́, ó sì wọ́ wọn lọ sínú àwọ̀n rẹ̀.
10 Ó ba, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀;
    kí tálákà ba à le bọ́ sí ọwọ́ agbára rẹ̀.
11 Ó wí fún ara rẹ̀, “Ọlọ́run ti gbàgbé;
    Ó pa ojú rẹ̀ mọ́, òun kì yóò rí i láéláé.”

12 Dìde, Olúwa! Gbé ọwọ́ rẹ sókè, Ọlọ́run.
    Má ṣe gbàgbé àwọn olùpọ́njú.
13 Èéṣe tí ènìyàn búburú ṣe ń kẹ́gàn Ọlọ́run?
    Èéṣe tí o fi wí nínú ọkàn ara rẹ̀,
    “Kò ní pè mí láti ṣe ìṣirò”?
14 Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni ó rí wàhálà àti ìrora;
    Ìwọ rò láti fi sí ọwọ́ rẹ.
Tálákà fi ara rẹ̀ jì fún ọ;
    Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìní baba.
15 Ṣẹ́ apá àwọn ènìyàn búburú àti ènìyàn ibi;
    pè é láti wá ṣírò fún ìwà ìkà rẹ̀
    tí a kò le è rí.

16 Olúwa ń jẹ ọba láé àti láéláé;
    àwọn orílẹ̀-èdè yóò ṣègbé lórí ilé rẹ.
17 Ìwọ́ gbọ́, Olúwa, ìfẹ́ àwọn tí a ni lára;
    Ìwọ gbà wọ́n níyànjú, ó sì gbọ́ igbe wọn,
18 Láti ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní baba àti àwọn ti a ni lára,
    kí ọkùnrin, tí ó wà ní ayé,
    kí ó má ṣe dẹ́rùbà ni mọ́.

Òwe 24

24 Má ṣe ṣe ìlara àwọn ènìyàn búburú
    má ṣe jẹ́ kí àwùjọ wọn wù ọ́;
Nítorí ọkàn wọn ń gbèrò ohun búburú,
    ètè wọn sì ń sọ̀rọ̀ nípa dídá rúgúdù sílẹ̀.

Nípa ọgbọ́n ni ilé di kíkọ́
    nípa òye sì ni ó ti fìdímúlẹ̀;
Nípa ìmọ̀ ni àwọn yàrá rẹ̀ kún
    pẹ̀lú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí ó lẹ́wà tí ó sì ṣọ̀wọ́n.

Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbára púpọ̀,
    ènìyàn tí ó ní ìmọ̀ sì ń ní agbára sí i
Láti jagun, ó nílò ìtọ́sọ́nà:
    nínú ìṣẹ́gun ni ọ̀pọ̀ onígbìmọ̀.

Ọgbọ́n ga ju fún aṣiwèrè
    àti gbọ̀ngàn ìlú níbi ibodè kò ní ohun tí yóò wí.

Ẹni tí ń pète ibi
    ni a ó mọ̀ bí ènìyàn ibi.
Ète òmùgọ̀ ènìyàn jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,
    àwọn ènìyàn sì kórìíra ẹlẹ́gàn.

10 Bí ìwọ bá dákú lásìkò ìdààmú
    báwo ni agbára rẹ ha ti kéré tó!
11 Gba àwọn tí a ń wọ́ lọ sí ibi ikú là;
    fa àwọn tó ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lọ sí ibi ìparun padà.
12 Bí ìwọ bá wí pé, “Ṣùgbọ́n a kò mọ nǹkan kan nípa èyí,”
    ǹjẹ́ ẹni tí ń díwọ̀n ọkàn kò kíyèsi i? Ǹjẹ́ ẹni tí ń ṣọ́ ẹ̀mí rẹ kò mọ̀ ọ́n?
    Ǹjẹ́ kò ní san án fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ti ṣe?

13 Jẹ oyin, ìwọ ọmọ mi, nítorí tí ó dára,
    oyin láti inú afárá oyin dùn lẹ́nu.
14 Mọ̀ pẹ̀lú pé ọgbọ́n pẹ̀lú dùn fún ọkàn rẹ
    bí ìwọ bá rí i ìrètí ọjọ́ iwájú wà fún ọ
    ìrètí rẹ kì yóò sì já ṣófo.

15 Má ṣe ba ní ibùba bí ènìyàn búburú
    láti gba ibùjókòó olódodo,
    má ṣe fi ibi ìsinmi rẹ̀ ṣe ìjẹ;
16 nítorí bí olódodo ènìyàn bá tilẹ̀ ṣubú ní ìgbà
    méje, yóò tún padà dìde sá á ni,
    ṣùgbọ́n ìdààmú yóò fa ènìyàn búburú lulẹ̀.

17 Má ṣe yọ̀ nígbà tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú;
nígbà tí ó bá kọsẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kí ó yọ̀.
18 Àìṣe bẹ́ẹ̀ Olúwa yóò rí i yóò sì bínú
    yóò sì yí ìbínú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

19 Má ṣe fòyà nítorí àwọn ènìyàn ibi
    tàbí jowú àwọn ènìyàn búburú,
20 nítorí ẹni ibi kò ní ìrètí ọjọ́ iwájú
    a ó sì pa fìtílà àwọn ènìyàn búburú kú.

21 Bẹ̀rù Olúwa àti ọba, ọmọ mi,
    má sì ṣe darapọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí kunkun.
22 Nítorí àwọn méjèèjì yóò rán ìparun òjijì sórí wọn,
    ta ni ó sì mọ irú ìyọnu tí wọ́n lè mú wá?

Àwọn ọrọ̀ ọlọ́gbọ́n mìíràn

23 Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú tún jẹ́ ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n:

    láti ṣe ojúsàájú níbi ìdájọ́ kò dára rárá:
24 Ẹnikẹ́ni tí ó wí fún ẹlẹ́bi pé, “Ìwọ lo jàre”
    àwọn ènìyàn yóò ṣẹ́ èpè fún un àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì kọ̀ ọ́.
25 Ṣùgbọ́n yóò dára fún àwọn tí ń dá ẹlẹ́bi lẹ́bi,
    ọ̀pọ̀ ìbùkún yóò sì wá sórí wọn.

26 Ìdáhùn òtítọ́
    dàbí ìfẹnu-koni-ní-ẹnu.

27 Parí gbogbo iṣẹ́ ajé rẹ
    sì rí i pé oko rẹ ti ṣe dáradára;
    lẹ́yìn náà kọ́ ilé rẹ.

28 Má ṣe rojọ́ èké mọ́ aládùúgbò rẹ láìnídìí,
    tàbí kí o fi ètè rẹ tannijẹ.
29 Má ṣe wí pé, “Èmi yóò ṣe é fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún mi;
    Èmi yóò san ohun tí ó ṣe fún mi padà fún un.”

30 Mo kọjá níbi oko ọ̀lẹ,
    mo kọjá níbi ọgbà àjàrà aláìgbọ́n ènìyàn;
31 ẹ̀gún ti hù ní ibi gbogbo,
    koríko ti gba gbogbo oko náà
32 Mo fi ọkàn mi sí nǹkan tí mo kíyèsi
    mo sì kẹ́kọ̀ọ́ lára ohun tí mo rí;
33 oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀,
    ìkáwọ́gbera díẹ̀ láti sinmi
34 Òsì yóò sì dé bá ọ bí adigunjalè
    àti àìní bí olè.

1 Tẹsalonika 3

Timotiu

(A)Nítorí ìdí èyí, nígbà tí ara mi kò gbà á mọ́, mo pinnu láti nìkan dúró ní ìlú Ateni. (B)Awa sì rán Timotiu, arákùnrin àti alábáṣiṣẹ́pọ̀ wa nínú Ọlọ́run nínú ìhìnrere Kristi, láti fi ẹsẹ yín múlẹ̀, àti láti tù yín nínú ní ti ìgbàgbọ́ yín. (C)Láìsí àní àní, ẹ mọ̀ gbangba pé, irú ìṣòro báwọ̀nyí wà nínú ètò Ọlọ́run fún àwọn tí ó gbàgbọ́, kí a má ba dààmú. (D)Tó bẹ́ẹ̀ tí a fi kìlọ̀ fún yín pé ìjìyà inúnibíni yóò dé. Ó sì rí bẹ́ẹ̀ nítòótọ́. (E)Bí mo wí tẹ́lẹ̀, nígbà tí ara mi kò gba á mọ́, mo sì ránṣẹ́ kí èmi kí ó lè mọ́ ìgbàgbọ́ yín, kí olùdánwò nì má ba à dán an yín wò lọ́nàkọnà, kí làálàá wa sì jásí asán.

Ọ̀rọ̀ ìyànjú Timotiu nínú ìròyìn

(F)Nísinsin yìí, Timotiu ti dé pẹ̀lú ìròyìn ayọ̀ wí pé, ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ yín ṣì lágbára bí i ti àtẹ̀yìnwá. Inú wa dùn láti gbọ́ wí pé ẹ ṣì ń rántí ìbágbé wa láàrín yín pẹ̀lú ayọ̀. Timotiu tún fi yé wa pé bí ó ti mú wa lọ́kàn tó láti rí i yín, ni ó ṣe ẹ̀yin pàápàá. Nítorí náà, ẹ̀yin ará, inú wá dùn jọjọ nínú gbogbo ìyọnu àti ìjìyà wa níbí nítorí pé àwa mọ̀ nísinsin yìí pé, ẹ̀yin dúró gbọningbọnin fún Olúwa. Nítorí àwa yè nísinsin yìí, bí ẹ̀yin bá dúró ṣinṣin nínú Olúwa. Kò ṣe é ṣe fún wa láti dá ọpẹ́ tán lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí ayọ̀ àti ìfẹ́ tí ó máa ń kún ọkàn wa nípa àdúrà wa fún un yín. 10 Nítorí pé àwa ń gbàdúrà fún un yín lọ̀sán-án àti lóru. Èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àtúnṣe ibi tí ìgbàgbọ́ yín bá kù sí.

11 À ń gbàdúrà wí pé, kí ó wu Ọlọ́run pàápàá àti Olúwa wa Jesu Kristi láti rán wa padà sí ọ̀dọ̀ yín lẹ́ẹ̀kan sí í. 12 A sì béèrè pé, kí Ọlọ́run ràn yín lọ́wọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí ìfẹ́ yín yóò fi gbòòrò tí yóò sì sàn kan olúkúlùkù yín. Èyí yóò jẹ́ àpẹẹrẹ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ àwa náà ṣe sàn kan ẹ̀yin náà. 13 (G)Kí ó lè fi ọkàn yín balẹ̀ ní àìlábùkù nínú ìwà mímọ́ níwájú Ọlọ́run àti Baba wa. Nígbà náà, ẹ ó ní ìgboyà láti dúró níwájú rẹ̀ láìṣẹ̀, ní ọjọ́ tí Olúwa wa Jesu Kristi yóò padà wá pẹ̀lú àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.