Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Lefitiku 24

Òróró òun àkàrà tí a tẹ́ síwájú Olúwa

24 (A)Olúwa sọ fún Mose pé “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli láti mú òróró tí ó mọ́ tí a fún láti ara olifi wá láti fi tan iná, kí fìtílà lè máa jò láì kú. Lẹ́yìn aṣọ ìkélé ti ibi àpótí ẹ̀rí tí ó wà ní inú àgọ́ ìpàdé, ni kí Aaroni ti tan iná náà níwájú Olúwa, láti ìrọ̀lẹ́ di àárọ̀ lójoojúmọ́. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀. Àwọn Àtùpà tí wọ́n wà lórí ojúlówó ọ̀pá fìtílà tí a fi wúrà ṣe níwájú Olúwa ni kí ó máa jó lójoojúmọ́.

(B)“Mú ìyẹ̀fun dáradára, kí o sì ṣe ìṣù àkàrà méjìlá, kí o lo ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n efa (èyí jẹ́ lítà mẹ́rin ààbọ̀) fún ìṣù kọ̀ọ̀kan. Tò wọ́n sí ọ̀nà ìlà méjì, mẹ́fàmẹ́fà ní ìlà kọ̀ọ̀kan lórí tábìlì tí a fi ojúlówó wúrà bọ̀. Èyí tí ó wà níwájú Olúwa. Ẹ fi ojúlówó tùràrí sí ọnà kọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ìpín ìrántí láti dípò àkàrà, àti láti jẹ ẹbọ sísun sí Olúwa. Àkàrà yìí ni kí ẹ gbé wá síwájú Olúwa nígbàkúgbà, lọ́ṣọ̀ọ̀ṣẹ̀, nítorí tí àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú ayérayé. Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ló ni í. Wọ́n gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́ torí pé ó jẹ́ ipa tí ó mọ́ jùlọ ti ìpín wọn ojoojúmọ́ nínú ọrẹ tí a fi iná ṣe sí Olúwa.”

Ìṣọ̀rọ̀-òdì àti ìjìyà rẹ̀

10 Ọmọkùnrin kan wà tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Israẹli baba rẹ̀ sì jẹ́ ará Ejibiti. Ó jáde lọ láàrín àwọn ọmọ Israẹli, ìjà sì ṣẹlẹ̀ nínú àgọ́ láàrín òun àti ọmọ Israẹli kan. 11 Ọmọkùnrin arábìnrin Israẹli náà sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Olúwa pẹ̀lú èpè: Wọ́n sì mú un tọ Mose wá. (Orúkọ ìyá rẹ̀ ní Ṣelomiti, ọmọbìnrin Debiri, ti ẹ̀yà Dani). 12 Wọ́n fi í sínú túbú kí Olúwa to sọ ohun tí wọn yóò ṣe fún wọn.

13 Olúwa sì sọ fún Mose pé: 14 “Mú asọ̀rọ̀-òdì náà jáde wá sẹ́yìn àgọ́, kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ pé ó ṣépè gbé ọwọ́ wọn lórí ọkùnrin náà láti fihàn pé ó jẹ̀bi. Lẹ́yìn náà ni kí gbogbo àpéjọpọ̀, sọ ọ́ ní òkúta pa. 15 Sọ fún àwọn ará Israẹli pé: ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ṣépè lé Ọlọ́run rẹ̀, yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. 16 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Olúwa ni kí ẹ pa, kí gbogbo àpéjọpọ̀ sọ ọ́ ní òkúta pa, yálà àlejò ni tàbí ọmọ bíbí Israẹli, bí ó bá ti sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Olúwa, pípa ni kí ẹ pa á.

17 “ ‘Ẹni tí ó bá gba ẹ̀mí ènìyàn pípa ni kí ẹ pa á. 18 Ẹni tí ó bá gba ẹ̀mí ẹran ọ̀sìn ẹlòmíràn, kí ó dá a padà—ẹ̀mí dípò ẹ̀mí. 19 (C)Bí ẹnìkan bá pa ẹnìkejì rẹ̀ lára: ohunkóhun tí ó ṣe ni kí ẹ ṣe sí i. 20 Ẹ̀yà fún ẹ̀yà, ojú fún ojú, eyín fún eyín; bí òun ti ṣe àbùkù sí ara ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni kí a ṣe sí i. 21 Ẹni tí ó bá sì lu ẹran pa, kí ó sán an padà; ẹni tí ó bá sì lu ènìyàn pa, a ó pa á. 22 (D)Òfin kan náà ló wà fún àlejò àti fún ọmọ Israẹli. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”

23 Nígbà náà ni Mose sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì mú asọ̀rọ̀-òdì náà lọ sí ẹ̀yìn àgọ́: wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa. Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe ohun tí Olúwa pàṣẹ fún Mose.

Saamu 31

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

31 Nínú rẹ̀, Olúwa ni mo ti rí ààbò;
    Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí;
    gbà mí nínú òdodo rẹ.
Tẹ́ etí rẹ sí mi,
    gbà mí kíákíá;
jẹ́ àpáta ààbò mi,
    jẹ́ odi alágbára láti gbà mí.
Ìwọ pàápàá ni àpáta àti ààbò mi,
    nítorí orúkọ rẹ, máa ṣe olùtọ́ mi, kí o sì ṣe amọ̀nà mi.
Yọ mí jáde kúrò nínú àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ fún mi,
    nítorí ìwọ ni ìsádi mi.
Ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé;
    ìwọ ni o ti rà mí padà, Olúwa, Ọlọ́run òtítọ́.

Èmi ti kórìíra àwọn ẹni tí ń fiyèsí òrìṣà tí kò níye lórí;
    ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.
Èmi yóò yọ̀, inú mi yóò dùn nínú ìfẹ́ ńlá rẹ,
    nítorí ìwọ ti rí ìbìnújẹ́ mi
    ìwọ ti mọ̀ ọkàn mi nínú ìpọ́njú.
Pẹ̀lú, ìwọ kò sì fà mi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́
    ìwọ ti fi ẹsẹ̀ mi lé ibi ààyè ńlá.

Ṣàánú fún mi, ìwọ Olúwa, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú;
    ojú mi fi ìbìnújẹ́ sùn,
    ọkàn àti ara mi pẹ̀lú.
10 Èmi fi ìbànújẹ́ lo ọjọ́ mi
    àti àwọn ọdún mi pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn;
agbára mi ti kùnà nítorí òsì mi,
    egungun mi sì ti rún dànù.
11 Èmi di ẹni ẹ̀gàn láàrín àwọn ọ̀tá mi gbogbo,
    pẹ̀lúpẹ̀lú láàrín àwọn aládùúgbò mi,
mo sì di ẹ̀rù fún àwọn ojúlùmọ̀ mi;
    àwọn tí ó rí mi ní òde ń yẹra fún mi.
12 Èmi ti di ẹni ìgbàgbé kúrò ní ọkàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ti kú;
    Èmi sì dàbí ohun èlò tí ó ti fọ́.
13 (A)Nítorí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpayà tí ó yí mi ká;
    tí wọn gbìmọ̀ pọ̀ sí mi,
wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí mi
    láti gba ẹ̀mí mi.

14 Ṣùgbọ́n èmí gbẹ́kẹ̀lé ọ, ìwọ Olúwa
    Mo sọ wí pé, “Ìwọ ní Ọlọ́run mi.”
15 Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ rẹ;
    gbà mí kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá mi
    àti àwọn onínúnibíni.
16 Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ lára;
    Gbà mí nínú ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.
17 Má ṣe jẹ́ kí ojú ki ó tì mí, Olúwa;
    nítorí pé mo ké pè ọ́;
jẹ́ kí ojú kí ó ti ènìyàn búburú;
    jẹ́ kí wọ́n lọ pẹ̀lú ìdààmú sí isà òkú.
18 Jẹ́ kí àwọn ètè irọ́ kí ó dákẹ́ jẹ́ẹ́,
    pẹ̀lú ìgbéraga àti ìkẹ́gàn,
    wọ́n sọ̀rọ̀ àfojúdi sí olódodo.

19 Báwo ni títóbi oore rẹ̀ ti pọ̀ tó,
    èyí tí ìwọ ti ní ní ìpamọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ,
èyí tí ìwọ rọ̀jò rẹ̀ níwájú àwọn ènìyàn
    tí wọ́n fi ọ́ ṣe ibi ìsádi wọn.
20 Ní abẹ́ ìbòòji iwájú rẹ ni ìwọ pa wọ́n mọ́ sí
    kúrò nínú ìdìmọ̀lù àwọn ènìyàn;
ní ibùgbé rẹ, o mú wọn kúrò nínú ewu
    kúrò nínú ìjà ahọ́n.

21 Olùbùkún ni Olúwa,
    nítorí pé ó ti fi àgbà ìyanu ìfẹ́ tí ó ní sí mi hàn,
    nígbà tí mo wà ní ìlú tí wọ́n rọ̀gbà yíká.
22 Èmí ti sọ nínú ìdágìrì mi,
    “A gé mi kúrò ní ojú rẹ!”
Síbẹ̀ ìwọ ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú
    nígbà tí mo ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.

23 Ẹ fẹ́ Olúwa, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́!
    Olúwa pa olódodo mọ́,
    ó sì san án padà fún agbéraga ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
24 Jẹ́ alágbára, yóò sì mú yín ní àyà le
    gbogbo ẹ̀yin tí ó dúró de Olúwa.

Oniwaasu 7

Ọgbọ́n

Orúkọ rere sàn ju ìpara olóòórùn dídùn lọ
    ọjọ́ ikú sì dára ju ọjọ́ tí a bí ènìyàn lọ
Ó dára láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀
    ju ibi àsè
nítorí pé ikú jẹ́ àyànmọ́ gbogbo ènìyàn
    kí alààyè ní èyí ní ọkàn.
Ìbànújẹ́ dára ju ẹ̀rín lọ,
    ó le è mú kí ojú rẹ̀ dàrú,
    ṣùgbọ́n yóò jẹ́ kí àyà rẹ le.
Ọkàn ọlọ́gbọ́n wà ní ilé ọ̀fọ̀,
    ṣùgbọ́n ọkàn òmùgọ̀ ní ilé àríyá.
Ó dára láti gba ìbáwí ọlọ́gbọ́n,
    ju fífetísílẹ̀ sí orin òmùgọ̀ lọ.
Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gún ti ń dún lábẹ́ ìkòkò
    ni ẹ̀rín òmùgọ̀,
    Asán sì ni eléyìí pẹ̀lú.
Ìrẹ́jẹ a máa sọ ọlọ́gbọ́n di òmùgọ̀,
    àbẹ̀tẹ́lẹ̀ sì máa ń ba ìwà jẹ́ ni.

Òpin ọ̀rọ̀ dára ju ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ lọ,
    sùúrù sì dára ju ìgbéraga lọ.
Má ṣe yára bínú ní ọkàn rẹ
    nítorí pé orí ẹsẹ̀ òmùgọ̀ ni ìbínú ń gbé.

10 Má ṣe sọ wí pé, “Kí ni ìdí tí àtijọ́ fi dára ju èyí?”
    Nítorí pé, kò mú ọgbọ́n wá láti béèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀.

11 Ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ogún ìní jẹ́ ohun tí ó dára
    ó sì ṣe àwọn tí ó rí oòrùn láǹfààní.
12 Ọgbọ́n jẹ́ ààbò
    gẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ ààbò
ṣùgbọ́n àǹfààní òye ni èyí
    pé ọgbọ́n a máa tọ́jú ẹ̀mí ẹni tí ó bá ní.

13 Wo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe:

“Ta ni ó le è to
    ohun tí ó ti ṣe ní wíwọ́?”
14 Nígbà tí àkókò bá dára, jẹ́ kí inú rẹ dùn,
    ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kò bá dára, rò ó
Ọlọ́run tí ó dá èkínní
    náà ni ó dá èkejì
nítorí náà, ènìyàn kò le è ṣàwárí
    ohun kankan nípa ọjọ́ iwájú rẹ̀.

15 Nínú ayé àìní ìtumọ̀ yìí ni mo ti rí gbogbo èyí:

Ènìyàn olóòtítọ́, ọkùnrin olódodo ń parun nínú òtítọ́ rẹ̀
    ìkà ènìyàn sì ń gbé ìgbé ayé pípẹ́ nínú ìkà rẹ̀.
16 Má ṣe jẹ́ olódodo jùlọ
    tàbí ọlọ́gbọ́n jùlọ
    kí ló dé tí o fi fẹ́ pa ara rẹ run?
17 Ìwọ ma ṣe búburú jùlọ kí ìwọ má sì ṣe aṣiwèrè
    Èéṣe tí ìwọ yóò fi kú kí ọjọ́ rẹ tó pé
18 Ó dára láti mú ọ̀kan
    kí o má sì ṣe fi èkejì sílẹ̀
    Ọkùnrin tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run yóò bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àrékérekè.

19 Ọgbọ́n máa ń mú kí ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbára
    ju alákòóso mẹ́wàá lọ ní ìlú.

20 Kò sí olódodo ènìyàn kan láyé
    tí ó ṣe ohun tí ó tọ́ tí kò dẹ́ṣẹ̀ rárá.

21 Má ṣe kíyèsi gbogbo ọ̀rọ̀ tí ènìyàn ń sọ
    bí bẹ́ẹ̀ kọ́, o le è gbọ́ pé ìránṣẹ́ rẹ ń ṣépè fún ọ.
22 Tí o sì mọ̀ nínú ọkàn rẹ
    pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìwọ fúnrarẹ̀ ti ṣépè fún àwọn ẹlòmíràn.

23 Gbogbo èyí ni mo ti dánwò nípa ọgbọ́n, tí mo sì wí pé,

“Mo pinnu láti jẹ́ ọlọ́gbọ́n”
    ṣùgbọ́n eléyìí ti jù mí lọ.
24 Ohun tí ó wù kí ọgbọ́n le è jẹ́,
    ó ti lọ jìnnà, ó sì jinlẹ̀
    ta ni ó le è ṣe àwárí rẹ̀?
25 Mo wá rò ó nínú ọkàn mi láti mọ̀,
    láti wá àti láti ṣàwárí ọgbọ́n
àti ìdí ohun gbogbo, àti láti mọ ìwà àgọ́
    búburú àti ti ìsínwín tàbí òmùgọ̀.

26 Mo rí ohun tí ó korò ju ikú lọ
    obìnrin tí ó jẹ́ ẹ̀bìtì,
tí ọkàn rẹ̀ jẹ́ tàkúté
    tí ọwọ́ rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀wọ̀n,
ọkùnrin tí ó bá tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn yóò le è yọ sílẹ̀
    ṣùgbọ́n ẹni dẹ́ṣẹ̀ kò le è bọ́ nínú tàkúté rẹ̀.

27 Oniwaasu wí pé, “Wò ó” eléyìí ni ohun tí mo ti ṣàwárí:

“Mímú ohun kan pọ̀ mọ́ òmíràn láti ṣàwárí ìdí ohun gbogbo.
28     Nígbà tí mo sì ń wá a kiri
ṣùgbọ́n tí n kò rí i
    mo rí ọkùnrin tí ó dúró dáradára kan láàrín ẹgbẹ̀rún
ṣùgbọ́n n kò rí obìnrin,
    kankan kí ó dúró láàrín gbogbo wọn.
29 Eléyìí nìkan ni mo tí ì rí:
    Ọlọ́run dá ìran ènìyàn dáradára,
    ṣùgbọ́n ènìyàn ti lọ láti ṣàwárí ohun púpọ̀.”

2 Timotiu 3

Ìwà àwọn ènìyàn ni ọjọ́ ìkẹyìn

Ṣùgbọ́n èyí ni kí o mọ̀: pé ní ìkẹyìn ọjọ́ ìgbà ewu yóò dé. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ti ara wọn, olùfẹ́ owó, afọ́nnu, agbéraga, asọ̀rọ̀ búburú, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìmọ́. Aláìnífẹ̀ẹ́, aláìlèdáríjì, abanijẹ́, aláìlè-kó-aràwọn-níjánu, òǹrorò, aláìnífẹ̀ẹ́ ohun rere, oníkúpani, alágídí, ọlọ́kàn gíga, olùfẹ́ fàájì ju olùfẹ́ Ọlọ́run lọ. Àwọn tí wọn ní àfarawé ìwà-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n tí wọn sẹ́ agbára rẹ̀; yẹra kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú.

Nítorí nínú irú èyí ni àwọn ti ń rákò wọ inú ilé, tí wọ́n sì ń di àwọn obìnrin aláìlọ́gbọ́n tí a di ẹ̀ṣẹ̀ rù ní ìgbèkùn, tí a sì ń fi onírúurú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ fà kiri Wọ́n ń fi ìgbà gbogbo kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n kò sì lè dé ojú ìmọ̀ òtítọ́. (A)Ǹjẹ́ gẹ́gẹ́ bí Janesi àti Jamberi ti kọ ojú ìjà sí Mose náà ni wọ́n kọjú ìjà sí òtítọ́: àwọn ènìyàn tí inú wọn díbàjẹ́, àwọn ẹni ìtanù ní ti ọ̀ràn ìgbàgbọ́. Ṣùgbọ́n wọn kì yóò lọ síwájú ju bẹ́ẹ̀ lọ: Nítorí òmùgọ̀ wọn yóò farahàn fún gbogbo ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ti àwọn méjì yìí náà, ti yọrí si.

Ọ̀rọ̀ ìyànjú Paulu sí Timotiu

10 Ṣùgbọ́n ìwọ ti mọ ẹ̀kọ́ mi, ìgbésí ayé mi, ìpinnu, ìgbàgbọ́, ìpamọ́ra, ìfẹ́ sùúrù. 11 (B)Inúnibíni, ìyà; àwọn ohun tí ó dé bá mi ní Antioku, ní Ikoniomu ní Lysra; àwọn inúnibíni tí mo faradà: Olúwa sì gbà mi kúrò nínú gbogbo wọn. 12 Nítòótọ́, gbogbo àwọn tí ó fẹ́ máa gbé ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run nínú Kristi Jesu yóò faradà inúnibíni 13 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú, àti àwọn ẹlẹ́tàn yóò máa burú síwájú sí i, wọn ó máa tannijẹ, a ó sì máa tàn wọ́n jẹ. 14 Ṣùgbọ́n ìwọ dúró nínú nǹkan wọ̀nyí tí ìwọ ti kọ́, tí a sì ti jẹ́ kí ojú rẹ dá ṣáṣá sí, kí ìwọ sì mọ̀ ọ̀dọ̀ ẹni tí ìwọ gbé kọ́ wọn. 15 Àti pé láti ìgbà ọmọdé ni ìwọ ti mọ Ìwé Mímọ́, tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n sí ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jesu. 16 Gbogbo ìwé mímọ́ ni ó ní ìmísí Ọlọ́run tí ó sì ní èrè fún ẹ̀kọ́, fún ìbániwí, fún ìtọ́ni, fún ìkọ́ni tí ó wà nínú òdodo. 17 Kí ènìyàn Ọlọ́run lè pé, tí a ti múra sílẹ̀ pátápátá fun iṣẹ́ rere gbogbo.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.