Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Lefitiku 26

Èrè ìgbọ́ràn

26 (A)‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ mọ ère òrìṣà, tàbí kí ẹ̀yin gbe ère kalẹ̀ tàbí kí ẹ̀yin gbẹ́ ère òkúta: kí ẹ̀yin má sì gbẹ́ òkúta tí ẹ̀yin yóò gbé kalẹ̀ láti sìn. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.

(B)“ ‘Ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́ kí ẹ̀yin sì bọ̀wọ̀ fún ibi mímọ́ mi: Èmi ni Olúwa.

(C)“ ‘Bí ẹ̀yin bá tẹ̀lé àṣẹ mi, tí ẹ̀yin sì ṣọ́ra láti pa òfin mi mọ́. Èmi yóò rọ̀jò fún yín ní àkókò rẹ̀, kí ilẹ̀ yín le mú èso rẹ̀ jáde bí ó tí yẹ kí àwọn igi eléso yín so èso. Èrè oko yín yóò pọ̀ dé bi pé ẹ ó máa pa ọkà títí di àsìkò ìkórè igi eléso, ẹ̀yin yóò sì máa gbé ní ilẹ̀ yín láìléwu.

“ ‘Èmi yóò fún yín ní àlàáfíà ní ilẹ̀ yín, ẹ̀yin yóò sì sùn láìsí ìbẹ̀rù ẹnikẹ́ni. Èmi yóò mú kí gbogbo ẹranko búburú kúrò ní ilẹ̀ náà: bẹ́ẹ̀ ni idà kì yóò la ilẹ̀ yín já. Ẹ̀yin yóò lé àwọn ọ̀tá yín: wọn yóò sì tipa idà kú. Àwọn márùn-ún péré nínú yín yóò máa ṣẹ́gun ọgọ́rùn-ún ènìyàn: Àwọn ọgọ́rùn-ún yóò sì máa ṣẹ́gun ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá: Àwọn ọ̀tá yín yóò tipa idà kú níwájú yín.

“ ‘Èmi yóò fi ojúrere wò yín: Èmi yóò mú kí ẹ bí sí i, èmi yóò jẹ́ kí ẹ pọ̀ sí i: Èmi yóò sì pa májẹ̀mú mi mọ́ pẹ̀lú yín. 10 Àwọn èrè oko yín yóò pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin ó máa jẹ èrè ọdún tí ó kọjá, ẹ̀yin ó sì kó wọn jáde: kí ẹ̀yin lè rí ààyè kó tuntun sí. 11 (D)Èmi yóò kọ́ àgọ́ mímọ́ mi sí àárín yín. Èmi kò sì ní kórìíra yín. 12 Èmi yóò wà pẹ̀lú yín: Èmi yóò máa jẹ́ Ọlọ́run yín: Ẹ̀yin yóò sì máa jẹ́ ènìyàn mi. 13 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti: kí ẹ̀yin má ba à jẹ́ ẹrú fún wọn mọ́. Mo sì já ìdè àjàgà yín: mo sì mú kí ẹ̀yin máa rìn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a gbé lórí sókè.

Ìjìyà fún àìgbọ́ràn

14 (E)“ ‘Bí ẹ̀yin kò bá fetí sí mi tí ẹ̀yin kò sì ṣe gbogbo òfin wọ̀nyí. 15 Bí ẹ̀yin bá kọ àṣẹ mi tí ẹ̀yin sì kórìíra òfin mi, tí ẹ̀yin sì kùnà láti pa ìlànà mi mọ́, nípa èyí tí ẹ̀yin ti ṣẹ̀ sí májẹ̀mú mi. 16 Èmi yóò ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí yín: Èmi yóò mú ìpayà òjijì bá yín: àwọn ààrùn afiniṣòfò, àti ibà afọ́nilójú, tí í pa ni díẹ̀díẹ̀. Ẹ̀yin yóò gbin èso ilẹ̀ yín lásán: nítorí pé àwọn ọ̀tá yín ni yóò jẹ gbogbo ohun tí ẹ̀yin ti gbìn. 17 Èmi yóò dojúkọ yín títí tí ẹ̀yin ó fi di ẹni ìkọlù; àwọn tí ó kórìíra yín ni yóò sì ṣe àkóso lórí yín. Ìbẹ̀rù yóò mú yín dé bi pé ẹ̀yin yóò máa sá káàkiri nígbà tí ẹnikẹ́ni kò lé yín.

18 “ ‘Bí ẹ̀yin kò bá wá gbọ́ tèmi lẹ́yìn gbogbo èyí: Èmi yóò fi kún ìyà yín ní ìlọ́po méje nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín. 19 Èmi yóò fọ́ agbára ìgbéraga yín: ojú ọ̀run yóò le koko bí irin: ilẹ̀ yóò sì le bí idẹ (òjò kò ní rọ̀: ilẹ̀ yín yóò sì le). 20 Ẹ ó máa lo agbára yín lásán torí pé ilẹ̀ yín kì yóò so èso, bẹ́ẹ̀ ni àwọn igi yín kì yóò so èso pẹ̀lú.

21 “ ‘Bí ẹ bá tẹ̀síwájú láì gbọ́ tèmi, Èmi yóò tún fa ìjayà yín le ní ìgbà méje gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ yín. 22 Èmi yóò rán àwọn ẹranko búburú sí àárín yín, wọn yóò sì pa àwọn ọmọ yín, wọn yóò run agbo ẹran yín, díẹ̀ nínú yín ni wọn yóò ṣẹ́kù kí àwọn ọ̀nà yín lè di ahoro.

23 “ ‘Bí ẹ kò bá tún yípadà lẹ́yìn gbogbo ìjìyà wọ̀nyí, tí ẹ sì tẹ̀síwájú láti lòdì sí mi. 24 Èmi náà yóò lòdì sí yín. Èmi yóò tún fa ìjìyà yín le ní ìlọ́po méje ju ti ìṣáájú. 25 Èmi yóò mú idà wá bá yín nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín láti fi gbẹ̀san májẹ̀mú mi tí ẹ kò pamọ́. Bí ẹ ba sálọ sí ìlú yín fún ààbò: Èmi yóò rán àjàkálẹ̀-ààrùn sí àárín yín: Àwọn ọ̀tá yín, yóò sì ṣẹ́gun yín. 26 Èmi yóò dá ìpèsè oúnjẹ yín dúró, dé bi pé: inú ààrò kan ni obìnrin mẹ́wàá yóò ti máa se oúnjẹ yín. Òṣùwọ̀n ni wọn yóò fi máa yọ oúnjẹ yín: Ẹ ó jẹ ṣùgbọ́n, ẹ kò ní yó.

27 “ ‘Lẹ́yìn gbogbo èyí, bí ẹ kò bá gbọ́ tèmi, tí ẹ sì lòdì sí mi, 28 Ní ìbínú mi èmi yóò korò sí yín, èmi tìkára mi yóò fìyà jẹ yín ní ìgbà méje nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín. 29 Ebi náà yóò pa yín dé bi pé ẹ ó máa jẹ ẹran-ara àwọn ọmọ yín ọkùnrin, àti àwọn ọmọ yín obìnrin. 30 Èmi yóò wó àwọn pẹpẹ òrìṣà yín, lórí òkè níbi tí ẹ ti ń sìn: Èmi yóò sì kó òkú yín jọ, sórí àwọn òkú òrìṣà yín. Èmi ó sì kórìíra yín. 31 Èmi yóò sọ àwọn ìlú yín di ahoro, èmi yóò sì ba àwọn ilé mímọ́ yín jẹ́. Èmi kì yóò sì gbọ́ òórùn dídùn yín mọ́. 32 Èmi yóò pa ilẹ̀ yín run dé bi pé ẹnu yóò ya àwọn ọ̀tá yín tí ó bá gbé ilẹ̀ náà. 33 Èmi yóò sì tú yín ká sínú àwọn orílẹ̀-èdè: Èmi yóò sì yọ idà tì yín lẹ́yìn, ilẹ̀ yín yóò sì di ahoro: àwọn ìlú yín ni a ó sì parun. 34 Ilẹ̀ náà yóò ní ìsinmi (tí kò ni lákòókò ìsinmi rẹ̀) fún gbogbo ìgbà tí ẹ fi wà ní ilẹ̀ àjèjì tí ẹ kò fi lò ó. Ilẹ̀ náà yóò sinmi láti fi dípò ọdún tí ẹ kọ̀ láti fún un. 35 Níwọ́n ìgbà tí ẹ kò lò ó, ilẹ̀ náà yóò ní ìsinmi tí kò ní lákòókò ìsinmi rẹ̀ lákokò tí ẹ fi ń gbé orí rẹ̀.

36 “ ‘Èmi yóò jẹ́ kí ó burú fún àwọn tí ó wà ní ilẹ̀ ìgbèkùn dé bi pé ìró ewé tí ń mì lásán yóò máa lé wọn sá. Ẹ ó máa sá bí ẹni tí ń sá fún idà. Ẹ ó sì ṣubú láìsí ọ̀tá láyìíká yín 37 Wọn yóò máa ṣubú lu ara wọn, bí ẹni tí ń sá fún idà nígbà tí kò sí ẹni tí ń lé yín. Ẹ̀yin kì yóò sì ní agbára láti dúró níwájú ọ̀tá yín. 38 Ẹ̀yin yóò ṣègbé láàrín àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà. Ilẹ̀ ọ̀tá yín yóò sì jẹ yín run. 39 Àwọn tí ó ṣẹ́kù nínú yín ni yóò ṣòfò dànù ní ilẹ̀ ọ̀tá yín torí ẹ̀ṣẹ̀ yín àti ti àwọn baba ńlá yín.

40 (F)“ ‘Bí wọ́n bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti ti baba ńlá wọn, ìwà ìṣọ̀tẹ̀ wọn àti bí wọ́n ti ṣe lòdì sí mi. 41 Èyí tó mú mi lòdì sí wọn tí mo fi kó wọn lọ sí ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn. Nígbà tí wọ́n bá rẹ àìkọlà àyà wọn sílẹ̀ tí wọ́n bá sì gba ìbáwí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 42 Nígbà náà ni Èmi yóò rántí májẹ̀mú mi pẹ̀lú Jakọbu àti pẹ̀lú Isaaki àti pẹ̀lú Abrahamu, Èmi yóò sì rántí ilẹ̀ náà. 43 Àwọn ènìyàn náà yóò sì fi ilẹ̀ náà sílẹ̀, yóò sì ní ìsinmi rẹ̀ nígbà tí ó bá wà lófo láìsí wọn níbẹ̀. Wọn yóò sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn torí pé wọ́n kọ àwọn òfin mi. Wọ́n sì kórìíra àwọn àṣẹ mi. 44 Pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, nígbà tí wọ́n bá wà nílé àwọn ọ̀tá wọn, èmi kì yóò ta wọ́n nù, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò kórìíra wọn pátápátá: èyí tí ó lè mú mi dá májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn. Èmi ni Ọlọ́run wọn 45 Nítorí wọn, èmi ó rántí májẹ̀mú mi tí mo ti ṣe pẹ̀lú baba ńlá wọn. Àwọn tí mo mú jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti lójú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè láti jẹ́ Ọlọ́run wọn. Èmi ni Olúwa.’ ”

46 Ìwọ̀nyí ni òfin àti ìlànà tí Olúwa fún Mose ní orí òkè Sinai láàrín òun àti àwọn ọmọ Israẹli.

Saamu 33

33 Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin olódodo
    ìyìn si yẹ fún ẹni dídúró ṣinṣin.
Ẹ yin Olúwa pẹ̀lú dùùrù;
    ẹ máa fi ohun èlò olókùn mẹ́wàá kọrin sí i.
Ẹ kọ orin tuntun sí i;
    ẹ máa fi ọgbọọgbọ́n lu ohun èlò orin sí i, pẹ̀lú ariwo.

Nítorí pé ọ̀rọ̀ Olúwa dúró ṣinṣin,
    gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ni à ń ṣe nínú òtítọ́.
Ó fẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́;
    ilé ayé kún fún ìdúró ṣinṣin àti àánú Olúwa.

Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ṣe dá àwọn ọ̀run,
    àti gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ogun wọn nípa ìmísí ẹnu rẹ̀.
Ó kó àwọn omi Òkun jọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà nínú ìgò;
    ó sì fi ibú ṣe ilé ìṣúra gbogbo.
Jẹ́ kí gbogbo ayé kí ó bẹ̀rù Olúwa:
    jẹ́ kí gbogbo àwọn olùgbé ayé kí ó wà nínú ìbẹ̀rù rẹ̀.
Nítorí tí ó sọ̀rọ̀, ó sì ti rí bẹ́ẹ̀; ó pàṣẹ
    ó sì dúró ṣinṣin.

10 Olúwa ti mú ìmọ̀ràn àwọn orílẹ̀-èdè wá sí asán;
    ó sì mú àrékérekè àwọn ènìyàn di ṣíṣákì í.
11 Ìgbìmọ̀ Olúwa dúró títí ayérayé,
    àní ìrò inú rẹ̀ láti ìrandíran ni.

12 Ìbùkún ni fún orílẹ̀-èdè náà, Ọlọ́run ẹni tí Olúwa jẹ́ tirẹ̀,
    àti àwọn ènìyàn náà tí ó ti yàn ṣe ìní rẹ̀.
13 Olúwa wò láti ọ̀run wá;
    Ó sì rí gbogbo ìran ènìyàn.
14 Níbi tí ó ti jókòó lórí ìtẹ́
    Ó wo gbogbo àwọn olùgbé ayé
15 ẹni tí ó ṣe àyà wọn bákan náà,
    ó sì kíyèsi ìṣe wọn.

16 A kò gba ọba kan là nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ogun;
    kò sì sí jagunjagun tí a gbà sílẹ̀ nípa agbára ńlá rẹ̀.
17 Ohun asán ni ẹṣin fún ìṣẹ́gun;
    bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi agbára ńlá rẹ̀ gbani sílẹ̀.
18 Wò ó, ojú Olúwa wà lára àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
    àti lára àwọn tí ó ní ìrètí nínú ìfẹ́ rẹ̀ tí ó dúró ṣinṣin.
19 Láti gba ọkàn wọn kúrò lọ́wọ́ ikú
    àti láti pa wọ́n mọ́ láààyè lọ́wọ́ ìyàn.

20 Ọkàn wa dúró de Olúwa;
    òun ni ìrànlọ́wọ́ wa àti asà wa.
21 Ọkàn wa yọ̀ nínú rẹ̀,
    nítorí pé, àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ rẹ mímọ́.
22 Kí àánú rẹ, Olúwa, kí ó wà lára wa,
    àní gẹ́gẹ́ bí àwa ti ń ṣe ìrètí nínú rẹ.

Oniwaasu 9

Àyànmọ́ kan náà fún gbogbo wọn

Nígbà náà ni mo wá ronú lórí gbogbo èyí, tí mo sì parí rẹ̀ pé, olóòtọ́ àti ọlọ́gbọ́n àti ohun tí wọ́n ń ṣe wà ní ọwọ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kò sí ènìyàn tí ó mọ̀ bóyá ìfẹ́ tàbí ìríra ni ó ń dúró de òun. Àyànmọ́ kan náà ni gbogbo wọn yàn—olóòtọ́ àti ènìyàn búburú, rere àti ibi, mímọ́ àti àìmọ́, àwọn tí ó ń rú ẹbọ àti àwọn tí kò rú ẹbọ.

Bí ó ti rí pẹ̀lú ènìyàn rere
    bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí pẹ̀lú ẹni tó dẹ́ṣẹ̀
bí ó ti rí pẹ̀lú àwọn tí ó ń ṣe ìbúra
    bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí pẹ̀lú àwọn tí ó ń bẹ̀rù láti ṣe ìbúra.

Ohun búburú ni èyí jẹ́ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn. Ìpín kan ṣoṣo ni ó ń dúró de gbogbo wọn, ọkàn ènìyàn pẹ̀lú kún fún ibi, ìsínwín sì wà ní ọkàn wọn nígbà tí wọ́n wà láààyè àti nígbà tí wọ́n bá darapọ̀ mọ́ òkú. Ẹnikẹ́ni tí ó wà láàrín alààyè ní ìrètí—kódà ààyè ajá sàn dáradára ju òkú kìnnìún lọ!

Nítorí pé ẹni tí ó wà láààyè mọ̀ wí pé àwọn yóò kú
    ṣùgbọ́n òkú kò mọ ohun kan
wọn kò ní èrè kankan mọ́,
    àti pé kódà ìrántí wọn tí di ohun ìgbàgbé.
Ìfẹ́ wọn, ìríra wọn
    àti ìlara wọn ti parẹ́:
láéláé kọ́ ni wọn yóò tún ní ìpín
    nínú ohunkóhun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn.

Lọ jẹ oúnjẹ rẹ pẹ̀lú ayọ̀, kí o sì mu ọtí wáìnì rẹ pẹ̀lú inú dídùn dé ọkàn, nítorí pé ìsinsin yìí ni Ọlọ́run ṣíjú àánú wo ohun tí o ṣe. Máa wọ aṣọ funfun nígbàkúgbà kí o sì máa fi òróró yan orí rẹ nígbà gbogbo. Máa jẹ ayé pẹ̀lú ìyàwó rẹ, ẹni tí o fẹ́ràn, ní gbogbo ọjọ́ ayé àìní ìtumọ̀ yí tí Ọlọ́run ti fi fún ọ lábẹ́ oòrùn—gbogbo ọjọ́ àìní ìtumọ̀ rẹ. Nítorí èyí ni ìpín tìrẹ ní ayé àti nínú iṣẹ́ wàhálà rẹ ní abẹ́ oòrùn. 10 Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, ṣe é pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ, nítorí kò sí iṣẹ́ ṣíṣe tàbí ìpinnu tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú isà òkú níbi tí ò ń lọ.

11 Mo ti rí ohun mìíràn lábẹ́ oòrùn

Eré ìje kì í ṣe fún ẹni tí ó yára
    tàbí ogun fún alágbára
bẹ́ẹ̀ ni oúnjẹ kò wà fún ọlọ́gbọ́n
    tàbí ọrọ̀ fún ẹni tí ó ní òye
    tàbí ojúrere fún ẹni tí ó ní ìmọ̀;
ṣùgbọ́n ìgbà àti èsì ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.

12 Síwájú sí i, kò sí ẹni tí ó mọ ìgbà tí àkókò rẹ̀ yóò dé:

Gẹ́gẹ́ bí a ti ń mú ẹja nínú àwọ̀n búburú
    tàbí tí a ń mú ẹyẹ nínú okùn
gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni a ń mú ènìyàn ní àkókò ibi
    tí ó ṣubú lù wọ́n láìròtẹ́lẹ̀.

Ọgbọ́n dára ju òmùgọ̀ lọ

13 Mo sì tún rí àpẹẹrẹ ọgbọ́n tí ó dùn mọ́ mi lábẹ́ oòrùn: 14 Ìlú kékeré kan tí ènìyàn díẹ̀ wà nínú rẹ̀ wà ní ìgbà kan rí. Ọba alágbára kan sì ṣígun tọ ìlú náà lọ, ó yí i po, ó sì kọ́ ilé ìṣọ́ tí ó tóbi lòdì sí i. 15 Ṣùgbọ́n, tálákà ọkùnrin tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n kan ń gbé ní ìlú náà, ó sì gba gbogbo ìlú u rẹ̀ là pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀. Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó rántí ọkùnrin tálákà náà. 16 Nítorí náà mo sọ wí pé “Ọgbọ́n dára ju agbára.” Ṣùgbọ́n a kẹ́gàn ọgbọ́n ọkùnrin tálákà náà, wọn kò sì mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe.

17 Ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn a máa wà ní ìmúṣẹ
    ju igbe òmùgọ̀ alákòóso lọ.
18 Ọgbọ́n dára ju ohun èlò ogun lọ,
    ṣùgbọ́n ẹnìkan tó dẹ́ṣẹ̀ a máa ba ohun dídára púpọ̀ jẹ́.

Titu 1

Paulu, ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti aposteli Jesu Kristi, gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run àti ìmọ̀ òtítọ́ irú èyí tí í máa darí ènìyàn sí ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run— ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ tí ó dúró lórí ìrètí iyè àìnípẹ̀kun, èyí tí Ọlọ́run tí kì í purọ́ ti ṣe ìlérí rẹ̀ ṣáájú kí ayé tó bẹ̀rẹ̀, àti pé ní àkókò tirẹ̀, òun ti fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ hàn nínú ìwàásù tí a fi lé mi lọ́wọ́ nípa àṣẹ Ọlọ́run Olùgbàlà wa.

(A)Sí Titu, ọmọ mi tòótọ́ nínú ìgbàgbọ́ wa kan náà.

Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run baba àti Kristi Jesu Olùgbàlà wa.

Iṣẹ́ Titu sí Krete

Ìdí tí mo fi fi ọ́ sílẹ̀ ní Krete ni pé kí o lè ṣe àṣepé àwọn iṣẹ́ tó ṣẹ́kù. Mo sì ń rọ̀ ọ́ kí o yan àwọn alàgbà ní ìlú kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí mo ṣe darí rẹ̀. Ẹni tí yóò jẹ́ alàgbà gbọdọ̀ jẹ́ aláìlábùkù, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ onìyàwó kan, ọmọ wọn náà gbọdọ̀ jẹ́ onígbàgbọ́ tí kò ní ẹ̀sùn ìwà ipá tàbí ẹ̀sùn àìgbọ́ràn kankan. Alábojútó jẹ́ ẹni tí a gbé iṣẹ́ Ọlọ́run lé lọ́wọ́, nítorí náà, kò gbọdọ̀ ní àbùkù kankan tàbí agbéraga, oníjà, kò gbọdọ̀ jẹ́ ọ̀mùtí tàbí alágídí tàbí olójúkòkòrò. Wọ́n ní láti jẹ́ olùfẹ́ àlejò ṣíṣe, olùfẹ́ ohun tí ó dára. Wọ́n ní láti jẹ́ ẹni tí ó kò ara rẹ̀ ní ìjánu, ẹni dúró ṣinṣin, ọlọ́kàn mímọ́, àti ẹni oníwàtítọ́. Ó gbọdọ̀ di ẹ̀kọ́ nípa ìdúró ṣinṣin mú dáradára gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ ọ, kí ó lè fi ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Nípa èyí, yóò lè fi ìdí òtítọ́ múlẹ̀ fún àwọn alátakò.

10 Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ọlọ̀tẹ̀, asọ̀rọ̀ asán àti ẹlẹ́tàn pàápàá jùlọ láàrín àwọn onílà. 11 Ó gbọdọ̀ pa wọ́n lẹ́nu mọ́, nítorí wí pé wọ́n ń pa agbo Ọlọ́run run, nípasẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tí kò jẹ́ èyí tí wọ́n ń kọ́ni. Èyí ni wọ́n ń ṣe fún ère àìṣòdodo. 12 Ọ̀kan nínú àwọn wòlíì wọn pàápàá sọ wí pé. “Òpùrọ́ ní àwọn ará Krete, wọ́n jẹ́ ẹranko búburú tí kò sé tù lójú, ọ̀lẹ, àti oníwọra”. 13 Òtítọ́ ni ẹ̀rí yìí. Nítorí náà, bá wọn wí gidigidi, kí wọn ba à lè yè koro nínú ìgbàgbọ́ 14 kí àwọn má ṣe fiyèsí ìtàn lásán ti àwọn Júù, àti òfin àwọn ènìyàn tí wọ́n yípadà kúrò nínú òtítọ́. 15 Sí ọlọ́kàn mímọ́, ohun gbogbo ló jẹ́ mímọ́, ṣùgbọ́n àwọn tó ti díbàjẹ́ tí wọ́n kò sí ka ohunkóhun sí mímọ́. Nítòótọ́, àti ọkàn àti ẹ̀rí ọkàn wọn ló ti díbàjẹ́. 16 Wọ́n ń fẹnu sọ wí pé àwọn mọ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n wọ́n sẹ́ ẹ nípa ìṣe wọn. Wọ́n díbàjẹ́, wọn si jẹ aláìgbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò wúlò lọ́nàkọnà ní ti iṣẹ́ rere gbogbo.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.