Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Gẹnẹsisi 11

Ilé ìṣọ́ Babeli

11 Lẹ́yìn náà, gbogbo àgbáyé sì ń sọ èdè kan ṣoṣo. Bí àwọn ènìyàn ṣe ń tẹ̀síwájú lọ sí ìhà ìlà-oòrùn, wọ́n rí pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan ní ilẹ̀ Ṣinari (Babeli), wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀.

Wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a mọ bíríkì kí a sì sún wọ́n jìnà.” Bíríkì ni wọ́n ń lò ní ipò òkúta, àti ọ̀dà-ilẹ̀ tí wọn ń lò láti mú wọn papọ̀ dípò ẹfun (òkúta láìmù tí wọ́n fi ń ṣe símẹ́ńtì àti omi). Nígbà náà ni wọ́n wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tẹ ìlú kan dó fún ara wa, kí a sì kọ́ ilé ìṣọ́ kan tí yóò kan ọ̀run, kí a ba à lè ní orúkọ (òkìkí) kí a má sì tú káàkiri sórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”

Ṣùgbọ́n, Olúwa sọ̀kalẹ̀ láti wo ìlú àti ilé ìṣọ́ tí àwọn ènìyàn náà ń kọ́. Olúwa wí pé, “Bí àwọn ènìyàn bá ń jẹ́ ọ̀kan àti èdè kan tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ yìí, kò sí ohun tí wọ́n gbèrò tí wọn kò ní le ṣe yọrí. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a sọ̀kalẹ̀ lọ, kí a da èdè wọn rú kí èdè wọn má ba à yé ara wọn mọ́.”

Ọlọ́run sì tú wọn ká sórí ilẹ̀ gbogbo, wọ́n sì ṣíwọ́ ìlú náà tí wọn ń tẹ̀dó. Ìdí èyí ni a fi pè é ní Babeli[a] nítorí ní ibẹ̀ ni Ọlọ́run ti da èdè gbogbo ayé rú, tí ó sì tú àwọn ènìyàn ká sí gbogbo orí ilẹ̀ ayé.

Ìran Ṣemu tó fi dé ti Abramu

10 Wọ̀nyí ni ìran Ṣemu.

Ọdún méjì lẹ́yìn ìkún omi, tí Ṣemu pé ọgọ́rùn-ún ọdún (100) ni ó bí Arfakṣadi. 11 Lẹ́yìn tí ó bí Arfakṣadi, Ṣemu tún wà láààyè fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún (500), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

12 Nígbà tí Arfakṣadi pé ọdún márùn-dínlógójì (35) ni ó bí Ṣela. 13 Arfakṣadi sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Ṣela, ó sì bí àwọn ọmọbìnrin àti àwọn ọmọkùnrin mìíràn.

14 Nígbà tí Ṣela pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni ó bí Eberi. 15 Ṣela sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Eberi tán, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

16 Eberi sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (34), ó sì bí Pelegi. 17 Eberi sì wà láààyè fún irínwó ó-lé-ọgbọ̀n ọdún (430) lẹ́yìn tí ó bí Pelegi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

18 Nígbà tí Pelegi pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni ó bí Reu. 19 Pelegi sì tún wà láààyè fún igba ó-lé-mẹ́sàn án ọdún (209) lẹ́yìn tí ó bí Reu, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

20 Nígbà tí Reu pé ọdún méjìlélọ́gbọ̀n (32) ni ó bí Serugu. 21 Reu tún wà láààyè lẹ́yìn tí ó bí Serugu fún igba ó-lé-méje ọdún (207), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn.

22 Nígbà tí Serugu pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni ó bí Nahori. 23 Serugu sì wà láààyè fún igba ọdún (200) lẹ́yìn tí ó bí Nahori, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

24 Nígbà tí Nahori pé ọmọ ọdún mọ́kàn-dínlọ́gbọ̀n (29), ó bí Tẹra. 25 Nahori sì wà láààyè fún ọdún mọ́kàn-dínlọ́gọ́fà (119) lẹ́yìn ìbí Tẹra, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.

26 Lẹ́yìn tí Tẹra pé ọmọ àádọ́rin ọdún (70) ó bí Abramu, Nahori àti Harani.

27 Wọ̀nyí ni ìran Tẹra.

Tẹra ni baba Abramu, Nahori àti Harani, Harani sì bí Lọti. 28 Harani sì kú ṣáájú Tẹra baba rẹ̀ ní ilẹ̀ ìbí rẹ̀ ní Uri ti ilẹ̀ Kaldea. 29 Abramu àti Nahori sì gbéyàwó. Orúkọ aya Abramu ni Sarai, nígbà tí aya Nahori ń jẹ́ Milka, tí ṣe ọmọ Harani. Harani ni ó bí Milka àti Iska. 30 Sarai sì yàgàn, kò sì bímọ.

31 Tẹra sì mú ọmọ rẹ̀ Abramu àti Lọti ọmọ Harani, ọmọ ọmọ rẹ̀, ó sì mú Sarai tí i ṣe aya ọmọ rẹ̀. Abramu pẹ̀lú gbogbo wọn sì jáde kúrò ní Uri ti Kaldea láti lọ sí ilẹ̀ Kenaani. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọn dé Harani wọ́n tẹ̀dó síbẹ̀.

32 Nígbà tí Tẹra pé ọmọ igba ó-lé-márùn-ún ọdún (205) ni ó kú ní Harani.

Matiu 10

Jesu rán àwọn méjìlá jáde

10 (A)Jesu sì pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá sí ọ̀dọ̀; ó fún wọn ní àṣẹ láti lé ẹ̀mí àìmọ́ jáde àti láti ṣe ìwòsàn ààrùn àti àìsàn gbogbo.

Orúkọ àwọn aposteli méjèèjìlá náà ni wọ̀nyí:

ẹni àkọ́kọ́ ni Simoni ẹni ti a ń pè ni Peteru àti arákùnrin rẹ̀ Anderu;

Jakọbu[a] ọmọ Sebede àti arákùnrin rẹ̀ Johanu.

Filipi àti Bartolomeu;

Tomasi àti Matiu agbowó òde;

Jakọbu ọmọ Alfeu àti Taddeu;

Simoni ọmọ ẹgbẹ́ Sealoti, Judasi Iskariotu, ẹni tí ó da Jesu.

(B)Àwọn méjèèjìlá wọ̀nyí ni Jesu ran, ó sì pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe lọ sì ọ̀nà àwọn kèfèrí, ẹ má ṣe wọ̀ ìlú àwọn ará Samaria Ẹ kúkú tọ̀ àwọn àgùntàn ilé Israẹli tí ó nù lọ. Bí ẹ̀yin ti ń lọ, ẹ máa wàásù yìí wí pé: ‘Ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.’ Ẹ máa ṣe ìwòsàn fún àwọn aláìsàn, ẹ si jí àwọn òkú dìde, ẹ sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́, kí ẹ sì máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà á, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fi fún ni.

“Ẹ má ṣe mú wúrà tàbí fàdákà tàbí idẹ sínú àpò ìgbànú yín; 10 Ẹ má ṣe mú àpò fún ìrìnàjò yín, kí ẹ má ṣe mú ẹ̀wù méjì, tàbí bàtà, tàbí ọ̀pá; oúnjẹ oníṣẹ́ yẹ fún un. 11 Ìlúkílùú tàbí ìletòkíletò tí ẹ̀yin bá wọ̀, ẹ wá ẹni ti ó bá yẹ níbẹ̀ rí, níbẹ̀ ni kí ẹ sì gbé nínú ilé rẹ̀ títí tí ẹ̀yin yóò fi kúrò níbẹ̀. 12 Nígbà tí ẹ̀yin bá sì wọ ilé kan, ẹ kí i wọn. 13 Bí ilé náà bá sì yẹ, kí àlàáfíà yín kí ó bà sórí rẹ̀; ṣùgbọ́n bí kò bá yẹ, kí àlàáfíà yín kí ó padà sọ́dọ̀ yín. 14 Bí ẹnikẹ́ni tí kò bá sì gbà yín, tàbí tí kò gba ọ̀rọ̀ yín, ẹ gbọn eruku ẹ̀ṣẹ̀ yín sílẹ̀ tí ẹ bá ń kúrò ní ilé tàbí ìlú náà. 15 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, yóò sàn fún ìlú Sodomu àti Gomorra ní ọjọ́ ìdájọ́ ju àwọn ìlú náà lọ.

16 “Mò ń rán yín lọ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn sáàrín ìkookò. Nítorí náà, kí ẹ ní ìṣọ́ra bí ejò, kí ẹ sì ṣe onírẹ̀lẹ̀ bí àdàbà. 17 (C)Ẹ ṣọ́ra lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn nítorí wọn yóò fi yín le àwọn ìgbìmọ̀ ìgbèríko lọ́wọ́ wọn yóò sì nà yín nínú Sinagọgu. 18 Nítorí orúkọ mi, a ó mú yín lọ síwájú àwọn baálẹ̀ àti àwọn ọba, bí ẹlẹ́rìí sí wọn àti àwọn aláìkọlà. 19 Nígbà tí wọ́n bá mú yín, ẹ má ṣe ṣàníyàn ohun tí ẹ ó sọ tàbí bí ẹ ó ṣe sọ ọ́. Ní ojú kan náà ni a ó fi ohun tí ẹ̀yin yóò sọ fún yín. 20 Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀yin ni ó sọ ọ́, bí kò ṣe Ẹ̀mí Baba yín tí ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ yín.

21 (D)“Arákùnrin yóò sì fi arákùnrin fún pípa. Baba yóò fi àwọn ọmọ rẹ̀ fún ikú pa. Àwọn ọmọ yóò ṣọ̀tẹ̀ sí òbí wọn, wọn yóò sì mú kí a pa wọ́n. 22 Gbogbo ènìyàn yóò sì kórìíra yín nítorí mi, ṣùgbọ́n gbogbo ẹni tí ó bá dúró ṣinṣin dé òpin ni a ó gbàlà. 23 Nígbà tí wọn bá ṣe inúnibíni sì i yín ní ìlú kan, ẹ sálọ sì ìlú kejì. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹ̀yin kò tì í le la gbogbo ìlú Israẹli já tán kí Ọmọ Ènìyàn tó dé.

24 (E)“Akẹ́kọ̀ọ́ kì í ju olùkọ́ rẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ọ̀dọ̀ kì í ju ọ̀gá rẹ̀ lọ. 25 Ó tọ́ fún akẹ́kọ̀ọ́ láti dàbí olùkọ́ rẹ̀ àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ láti rí bí ọ̀gá rẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá pe baálé ilé ní Beelsebulu, mélòó mélòó ni ti àwọn ènìyàn ilé rẹ̀!

26 (F)(G) “Nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí kò sí ohun tó ń bọ̀ tí kò ní í fi ara hàn, tàbí ohun tó wà ní ìkọ̀kọ̀ tí a kò ní mọ̀ ni gbangba. 27 Ohun tí mo bá wí fún yín ní òkùnkùn, òun ni kí ẹ sọ ní ìmọ́lẹ̀. Èyí tí mo sọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sì etí yín ni kí ẹ kéde rẹ́ lórí òrùlé. 28 Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ó le pa ara nìkan; ṣùgbọ́n tí wọn kò lè pa ẹ̀mí. Ẹ bẹ̀rù Ẹni tí ó le pa Ẹ̀mí àti ara run ní ọ̀run àpáàdì. 29 Ológoṣẹ́ méjì kọ́ ni à ń tà ní owó idẹ wẹ́wẹ́ kan? Síbẹ̀ kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò ṣubú lu ilẹ̀ lẹ́yìn Baba yin. 30 Àti pé gbogbo irun orí yín ni a ti kà pé. 31 Nítorí náà, ẹ má ṣe fòyà; ẹ̀yin ní iye lórí ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.

32 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú ènìyàn, òun náà ni èmi yóò jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú Baba mi ní ọ̀run. 33 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sẹ́ mí níwájú àwọn ènìyàn, òun náà ni èmi náà yóò sọ wí pé n kò mọ̀ níwájú Baba mi ní ọ̀run.

34 (H)“Ẹ má ṣe rò pé mo mú àlàáfíà wá sí ayé, Èmi kò mú àlàáfíà wá bí kò ṣe idà. 35 Nítorí èmi wá láti ya

“ ‘ọmọkùnrin ní ipa sí baba rẹ̀,
    ọmọbìnrin ní ipa sí ìyá rẹ̀,
àti aya ọmọ sí ìyakọ rẹ̀…
36     Ará ilé ènìyàn ni yóò sì máa ṣe ọ̀tá rẹ̀.’

37 (I)“Ẹni tí ó bá fẹ́ baba rẹ̀ tàbí ìyá rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi, ẹni tí ó ba fẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi; 38 Ẹni tí kò bá gbé àgbélébùú rẹ̀ kí ó tẹ̀lé mi kò yẹ ní tèmi. 39 Ẹni tí ó bá wa ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nú nítorí tèmi ni yóò rí i.

40 (J)“Ẹni tí ó bá gbà yín, ó gbà mí, ẹni tí ó bá sì gbà mí gba ẹni tí ó rán mi. 41 Ẹni tí ó ba gba wòlíì, nítorí pé ó jẹ́ wòlíì yóò jẹ èrè wòlíì, ẹni tí ó bá sì gba olódodo nítorí ti ó jẹ́ ènìyàn olódodo, yóò jẹ èrè olódodo. 42 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ago omi tútù fún ọ̀kan nínú àwọn onírẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí mu nítorí tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kò ní pàdánù èrè rẹ̀.”

Esra 10

Ìjẹ́wọ́ ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn

10 Nígbà tí Esra ń gbàdúrà tí ó sì ń jẹ́wọ́, ti ó ń sọkún ti ó sì ń gbárayílẹ̀ níwájú ilé Ọlọ́run, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ Israẹli ọkùnrin, obìnrin àti àwọn ọmọdé pagbo yí i ká. Àwọn náà ń sọkún kíkorò. Nígbà náà ni Ṣekaniah ọmọ Jehieli, ọ̀kan lára ìran Elamu, sọ fún Esra pé, Àwa ti jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wa nípa fífẹ́ àwọn obìnrin àjèjì láàrín àwọn ènìyàn tí ó wà yí wa ká. Ṣùgbọ́n síbẹ̀ náà, ìrètí sì wà fún Israẹli Ní ṣinṣin yìí, ẹ jẹ́ kí a dá májẹ̀mú níwájú Ọlọ́run wa láti lé àwọn obìnrin yìí àti àwọn ọmọ wọn lọ. Gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn Esra olúwa mi àti ti àwọn tí ó bẹ̀rù àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wa. Ẹ jẹ́ kí a ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin. Dìde, nítorí, ọ̀rọ̀ tìrẹ ni èyí. Gbogbo wà yóò wá pẹ̀lú rẹ, mú ọkàn le kí o sì ṣe é.

Nígbà náà ni Esra dìde, ó sì fi àwọn aṣíwájú àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi àti gbogbo Israẹli sí abẹ́ ìbúra, láti ṣe ohun tí wọ́n dá lábàá. Wọ́n sì búra. Nígbà náà ni Esra padà sẹ́yìn kúrò níwájú ilé Ọlọ́run, ó sì lọ sí iyàrá Jehohanani ọmọ Eliaṣibu. Nígbà tí ó wà níbẹ̀, kò jẹ oúnjẹ bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu omi, nítorí ó sì ń káàánú fún àìṣòótọ́ àwọn ìgbèkùn.

Ìkéde kan jáde lọ jákèjádò Juda àti Jerusalẹmu fún gbogbo àwọn ìgbèkùn láti péjọ sí Jerusalẹmu. Ẹnikẹ́ni tí ó ba kọ̀ láti jáde wá láàrín ọjọ́ mẹ́ta yóò pàdánù ohun ìní rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìpinnu àwọn ìjòyè àti àwọn àgbàgbà, àti pé a ó lé òun fúnrarẹ̀ jáde kúrò láàrín ìpéjọpọ̀ àwọn ìgbèkùn.

Láàrín ọjọ́ mẹ́ta náà, gbogbo àwọn ọkùnrin Juda àti Benjamini tí péjọ sí Jerusalẹmu. Ní ogúnjọ́ oṣù kẹsànán, gbogbo àwọn ènìyàn jókòó sí ìta gbangba iwájú ilé Ọlọ́run, wọ́n wà nínú ìbànújẹ́ ńlá nítorí ọ̀ràn yìí, àti nítorí òjò púpọ̀ tó tì rọ̀. 10 Nígbà náà ni àlùfáà Esra dìde, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ti ṣe àìṣòótọ́, ẹ ti fẹ́ obìnrin àjèjì, ẹ ti dá kún ẹ̀bi Israẹli. 11 Nísinsin yìí, ẹ jẹ́wọ́ níwájú Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba yín, kí ẹ sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò láàrín àwọn ènìyàn tí ó yí i yín ká àti láàrín àwọn ìyàwó àjèjì yín.”

12 Àpéjọpọ̀ ènìyàn náà sì dáhùn lóhùn rara pé: ohun tí ó sọ dára! A gbọdọ̀ ṣe bí o ti wí. 13 Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ni ó wà ni ibi yìí síbẹ̀ àkókò òjò ni; àwa kò sì lè dúró ní ìta. Yàtọ̀ sí èyí, a kò le è yanjú ọ̀rọ̀ yìí láàrín ọjọ́ kan tàbí ọjọ́ méjì, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa pọ̀ jọjọ lórí àwọn nǹkan wọ̀nyí. 14 Jẹ́ kí àwọn ìjòyè wa ṣojú fún gbogbo ìjọ ènìyàn, lẹ́yìn náà, jẹ́ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú àwọn ìlú wa tí ó ti fẹ́ obìnrin àjèjì wá ní àsìkò tí a yàn, pẹ̀lú àwọn àgbàgbà àti àwọn onídàájọ́ ìlú kọ̀ọ̀kan, títí ìbínú gíga Ọlọ́run wa lórí ọ̀rọ̀ yìí yóò fi kúrò ní orí wa. 15 Jonatani ọmọ Asaheli àti Jahseiah ọmọ Tikfa nìkan pẹ̀lú àtìlẹ́yìn Meṣullamu àti Ṣabbetai ará Lefi, ni wọ́n tako àbá yìí.

16 Nígbà náà ni àwọn ìgbèkùn ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe fi ẹnu kò sí. Àlùfáà Esra yan àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé, ẹnìkọ̀ọ̀kan láti ìdílé kọ̀ọ̀kan, gbogbo wọn ni a sì mọ̀ pẹ̀lú orúkọ wọn. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹwàá, wọ́n jókòó láti ṣe àyẹ̀wò àwọn ẹjọ́ náà, 17 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kìn-ín-ní ni wọn parí pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì.

Àwọn tó jẹ̀bi ẹ̀sùn ìgbéyàwó pẹ̀lú àjèjì

18 Lára ìran àwọn àlùfáà àwọn wọ̀nyí fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì:

Nínú ìran Jeṣua ọmọ Josadaki, àti àwọn arákùnrin rẹ:

Maaseiah, Elieseri, Jaribi àti Gedaliah. 19 Gbogbo wọn ni wọ́n ṣe ìpinnu láti lé àwọn ìyàwó wọn lọ, wọ́n sì fi àgbò kan láàrín agbo ẹran lélẹ̀ fún ẹ̀bi wọn gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀.

20 Nínú ìran Immeri:

Hanani àti Sebadiah.

21 Nínú ìran Harimu:

Maaseiah, Elijah, Ṣemaiah, Jehieli àti Ussiah.

22 Nínú ìran Paṣuri:

Elioenai, Maaseiah, Iṣmaeli, Netaneli, Josabadi àti Eleasa.

23 Lára àwọn ọmọ Lefi:

Josabadi, Ṣimei, Kelaiah (èyí tí í ṣe Kelita), Petahiah, Juda àti Elieseri.

24 Nínú àwọn akọrin:

Eliaṣibu.

Nínú àwọn aṣọ́nà:

Ṣallumu, Telemu àti Uri.

25 Àti lára àwọn ọmọ Israẹli tókù:

Nínú ìran Paroṣi:

Ramiah, Issiah, Malkiah, Mijamini, Eleasari, Malkiah àti Benaiah.

26 Nínú ìran Elamu:

Mattaniah, Sekariah, Jehieli, Abdi, Jerimoti àti Elijah.

27 Nínú àwọn ìran Sattu:

Elioenai, Eliaṣibu, Mattaniah, Jerimoti, Sabadi àti Asisa.

28 Nínú àwọn ìran Bebai:

Jehohanani, Hananiah, Sabbai àti Atlai.

29 Nínú àwọn ìran Bani:

Meṣullamu, Malluki, Adaiah, Jaṣubu, Ṣeali àti Jerimoti.

30 Nínú àwọn Pahati-Moabu:

Adma, Kelali, Benaiah, Maaseiah, Mattaniah, Besaleli, Binnui àti Manase.

31 Nínú àwọn ìran Harimu:

Elieseri, Iṣiah, Malkiah àti Ṣemaiah, Simeoni, 32 Benjamini, Malluki àti Ṣemariah.

33 Nínú àwọn ìran Haṣumu:

Mattenai, Mattatta, Sabadi, Elifaleti, Jeremai, Manase àti Ṣimei.

34 Nínú àwọn ìran Bani:

Maadai, Amramu, Ueli, 35 Benaiah, Bediah, Keluhi 36 Faniah, Meremoti, Eliaṣibu, 37 Mattaniah, Mattenai àti Jaasu.

38 Àti Bani, àti Binnui:

Ṣimei, 39 Ṣelemiah, Natani, Adaiah, 40 Maknadebai, Sasai, Ṣarai, 41 Asareeli, Ṣelemiah, Ṣemariah, 42 Ṣallumu, Amariah àti Josẹfu.

43 Nínú àwọn ìran Nebo:

Jeieli, Mattitiah, Sabadi, Sebina, Jaddai, Joeli àti Benaiah.

44 Gbogbo àwọn wọ̀nyí ló fẹ́ obìnrin àjèjì, àwọn mìíràn nínú wọn sì bi ọmọ ní ipasẹ̀ àwọn ìyàwó wọ̀nyí.

Ìṣe àwọn Aposteli 10

Àwọn ìpè Korneliu fún Peteru

10 (A)Ọkùnrin kan sì wà ni Kesarea ti a ń pè ní Korneliu, balógun ọ̀rún ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tí a ń pè ni Itali. Olùfọkànsìn, àti ẹni ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run tilétilé rẹ̀ gbogbo, ẹni tí ó ń tọrẹ àánú púpọ̀ fún àwọn ènìyàn, tí ó sì ń gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà gbogbo. Níwọ́n wákàtí kẹsànán ọjọ́, ó rí nínú ìran kedere angẹli Ọlọ́run kan wọlé tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Korneliu!”

Nígbà tí ó sì tẹjúmọ́ ọn, ti ẹ̀rù sì bà á, ó ní, “Kín ni, Olúwa?”

Ó sì wí fún un pé, “Àdúrà rẹ àti ọrẹ-àánú, tìrẹ gòkè lọ síwájú Ọlọ́run fún ìrántí. Sì rán ènìyàn nísinsin yìí lọ sí Joppa, kí wọn sì pe Simoni wá, ẹni ti àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru. Ó wọ̀ sí ilé Simoni aláwọ, tí ilé rẹ̀ wà létí Òkun; òun ni yóò sọ fún ọ bí ìwọ ó ti ṣe.”

Nígbà tí angẹli náà tí ó bá Korneliu sọ̀rọ̀ sì fi i sílẹ̀ lọ ó pe méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ ilé rẹ̀, àti ọmọ-ogun olùfọkànsìn kan, nínú àwọn ti ó máa ń dúró tì í nígbà gbogbo. Nígbà tí ó sì tí ṣàlàyé ohun gbogbo fún wọn, ó rán wọn lọ sí Joppa.

Ìran Peteru

Ni ọjọ́ kejì bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà àjò wọn, tí wọ́n sì súnmọ́ ilé náà, Peteru gun òkè ilé lọ láti gbàdúrà ni ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́: 10 Ebi sì pa á gidigidi, ó sì ń fẹ́ láti jẹun: ó bọ́ sí ojúran. 11 Ó sì rí ọ̀run ṣí, ohun èlò kan si sọ̀kalẹ̀ bí gọgọwú ńlá, tí a ti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, sọ̀kalẹ̀ sí ilẹ̀: 12 Nínú rẹ̀ ni onírúurú ẹranko ẹlẹ́ṣẹ̀ mẹ́rin wà, àti ohun tí ń rákò ni ayé àti ẹyẹ ojú ọ̀run. 13 Ohùn kan si fọ̀ sí i pe, “Dìde, Peteru; máa pa kí o sì máa jẹ.”

14 Ṣùgbọ́n Peteru dáhùn pé, “rara, Olúwa; nítorí èmi kò jẹ ohun èèwọ̀ àti aláìmọ́ kan rí.”

15 Ohùn kan sì tún fọ̀ sí i lẹ́ẹ̀méjì pé, “Ohun tí Ọlọ́run bá ti wẹ̀mọ́, ìwọ má ṣe pè é ní èèwọ̀ mọ́.”

16 Èyí sì ṣe lẹ́ẹ̀mẹ́ta; lójúkan náà a sì gbé ohun èlò náà padà lọ sókè ọ̀run.

Korneliu ránṣẹ́ sí Peteru

17 Bí Peteru sì ti ń dààmú nínú ara rẹ̀ bí òun bá ti mọ̀ ìran tí òun ri yìí sí, si wò ó, àwọn ọkùnrin tí a rán wá láti ọ̀dọ̀ Korneliu dé. Wọ́n ń béèrè ilé Simoni, wọ́n dúró ní ẹnu-ọ̀nà. 18 Wọn nahùn béèrè bí Simoni tí a ń pè ní Peteru, wọ̀ níbẹ̀.

19 Bí Peteru sì ti ń ronú ìran náà, Ẹ̀mí wí fún un pé, “Wò ó, àwọn ọkùnrin mẹ́ta ń wá ọ. 20 Ǹjẹ́ dìde, sọ̀kalẹ̀ kí ó sì bá wọn lọ, má ṣe kó ara ró láti bá wọn lọ: nítorí èmi ni ó rán wọn.”

21 Nígbà náà ni Peteru sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn ọkùnrin náà tí a rán, ó sì wí pé, “Wò ó, èmi ni ẹni tí ẹ̀yin ń wá: kín ni ìdí rẹ̀ ti ẹ fi wá?”

22 Wọ́n sì wí pé, “Korneliu balógun ọ̀rún, ọkùnrin olóòtítọ́, àti ẹni ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì ní orúkọ rere lọ́dọ̀ gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn Júù, òun ni a ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kọ́ nípasẹ̀ angẹli mímọ́, láti ránṣẹ́ pè ọ́ wá sí ilé rẹ̀ àti láti gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ.” 23 Nígbà náà ni Peteru pè wọ́n wọlé, ó gbà wọ́n lálejò.

Peteru ní ilé Korneliu

Ní ọjọ́ kejì, ó sì dìde, ó bá wọn lọ, díẹ̀ nínú àwọn ti o ti gbàgbọ́ ní Joppa sì bá a lọ pẹ̀lú. 24 Lọ́jọ́ kejì wọ́n sì wọ Kesarea, Korneliu sì ti ń retí wọn, ó sì ti pe àwọn ìbátan àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ jọ. 25 Ó sì ṣe bí Peteru ti ń wọlé, Korneliu pàdé rẹ̀, ó wólẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó sì foríbalẹ̀ fún un. 26 Ṣùgbọ́n Peteru gbé e dìde, ó ni, “Dìde ènìyàn ni èmi tìkára mi pẹ̀lú.”

27 Bí ó sì ti ń bá a sọ̀rọ̀, ó wọlé ó sì rí àwọn ènìyàn púpọ̀ tí wọ́n péjọ. 28 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin mọ̀ bí ó ti jẹ́ èèwọ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ Júù, láti bá ẹni tí ó jẹ́ ará ilẹ̀ mìíràn kẹ́gbẹ́, tàbí láti tọ̀ ọ́ wá; ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fihàn mi pé, ki èmi má ṣe pé ẹnikẹ́ni ni èèwọ̀ tàbí aláìmọ́. 29 Nítorí náà ni mo sì ṣe wá ní àìjiyàn, bí a ti ránṣẹ́ pè mi: ǹjẹ́ mo béèrè, nítorí kín ní ẹ̀yin ṣe ránṣẹ́ pè mi?”

30 Korneliu sì dáhùn pé, “Ní ìjẹrin, mo ń ṣe àdúrà wákàtí kẹsànán ọjọ́ ni ilé mi títí di idayìí, sì wò ó, ọkùnrin kan aláṣọ, àlà dúró níwájú mi. 31 Ó sì wí pé, ‘Korneliu, a gbọ́ àdúrà rẹ, ọrẹ-àánú rẹ̀ sì wà ni ìrántí níwájú Ọlọ́run. 32 Ǹjẹ́ ránṣẹ́ lọ sí Joppa, kí ó sì pe Simoni wá, ẹni ti àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru; ó wọ̀ ní ilé Simoni aláwọ létí Òkun.’ 33 Nítorí náà ni mo sì ṣe ránṣẹ́ sì ọ lójúkan náà, ìwọ sì ṣeun tí ó fi wá. Gbogbo wa pé níwájú Ọlọ́run nísinsin yìí, láti gbọ́ ohun gbogbo, ti a pàṣẹ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.”

34 Peteru sì ya ẹnu rẹ, ó sì wí pé, “Nítòótọ́ mo wòye pé, Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú ènìyàn. 35 Ṣùgbọ́n ni gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, ti ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo, ẹni ìtẹ́wọ́gbà ni lọ́dọ̀ rẹ̀. 36 Ẹyin mọ ọrọ̀ tí Ọlọ́run rán sí àwọn ọmọ Israẹli láti kéde ìròyìn ayọ̀ àlàáfíà nípasẹ̀ Jesu Kristi, ẹni ti ṣe Olúwa ohun gbogbo 37 Ẹ̀yin náà mọ ọ̀rọ̀ náà tí a kéde rẹ̀ yíká gbogbo Judea, tí a bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ láti Galili, lẹ́yìn bamitiisi ti Johanu wàásù rẹ̀. 38 Àní Jesu ti Nasareti, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti da Ẹ̀mí Mímọ́ àti agbára le lórí; ẹni tí ó ń kiri ṣe oore, ó ń ṣe ìmúláradá gbogbo àwọn tí èṣù sì ń pọ́n lójú; nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.

39 “Àwa sì ni ẹlẹ́rìí gbogbo ohun tí ó ṣe, ní ilẹ̀ àwọn Júù, àti ni Jerusalẹmu. Ẹni tí wọ́n pa nípa gbígbékọ́ sí orí igi. 40 Òun ni Ọlọ́run jí dìde ni ọjọ́ kẹta ó sì fi i hàn gbangba. 41 Kì í ṣe fún gbogbo ènìyàn ni o ri, bí kò ṣe fún àwa ti a jẹ́ ẹlẹ́rìí ti a ti ọwọ́ Ọlọ́run yàn tẹ̀lé, ti a bá a jẹ, ti a sì bá à mu lẹ́yìn ìgbà ti ó jíǹde kúrò nínú òkú. 42 Ó sì pàṣẹ fún wa láti wàásù fún àwọn ènìyàn, àti láti jẹ́rìí pé, òun ni a ti ọwọ́ Ọlọ́run yàn ṣe onídàájọ́ ààyè àti òkú. 43 Òun ni gbogbo àwọn wòlíì jẹ́rìí sì pé, ẹnikẹ́ni ti ó bá gbà á gbọ́ yóò rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà nípa orúkọ rẹ̀.”

44 Bí Peteru sì ti ń sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lẹ́nu, Ẹ̀mí Mímọ́ bà lé gbogbo àwọn ti ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. 45 Ẹnu sì yà àwọn onígbàgbọ́ ti a ti kọ nílà tí wọ́n bá Peteru wá, nítorí ti a tu ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ sórí àwọn aláìkọlà pẹ̀lú. 46 Nítorí wọ́n gbọ́, wọ́n ń fọ onírúurú èdè, wọn sì yin Ọlọ́run lógo.

Nígbà náà ni Peteru dáhùn wí pé, 47 “Ẹnikẹ́ni ha lè ṣòfin pe, kí a má bamitiisi àwọn wọ̀nyí tí wọ́n gba Ẹ̀mí Mímọ́ bí àwa?” 48 Ó sì pàṣẹ kí a bamitiisi wọn ni orúkọ Jesu Kristi. Nígbà náà ni wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó dúró ni ọjọ́ mélòó kan.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.