Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

M’Cheyne Bible Reading Plan

The classic M'Cheyne plan--read the Old Testament, New Testament, and Psalms or Gospels every day.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Gẹnẹsisi 13

Ìpinyà Abramu àti Lọti

13 Abramu sì gòkè láti Ejibiti lọ sí ìhà gúúsù, pẹ̀lú aya rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní àti Lọti pẹ̀lú. Abramu sì ti di ọlọ́rọ̀ gidigidi; ní ẹran ọ̀sìn, ó ní fàdákà àti wúrà.

Láti gúúsù, ó ń lọ láti ibìkan sí ibòmíràn títí ó fi dé ilẹ̀ Beteli, ní ibi tí àgọ́ rẹ̀ ti wà ní ìṣáájú rí, lágbedeméjì Beteli àti Ai. Ní ibi pẹpẹ tí ó ti tẹ́ síbẹ̀ ní ìṣáájú, níbẹ̀ ni Abramu sì ń ké pe orúkọ Olúwa.

Àti Lọti pẹ̀lú, tí ó ń bá Abramu rìn kiri, ní agbo ẹran, ọ̀wọ́ ẹran àti àgọ́. Ṣùgbọ́n ilẹ̀ náà kò le gbà wọ́n tí wọ́n bá ń gbé pọ̀, nítorí, ohun ìní wọn pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, dé bi wí pé wọn kò le è gbé pọ̀. Èdè-àìyedè sì bẹ̀rẹ̀ láàrín àwọn darandaran Abramu àti ti Lọti. Àwọn ará Kenaani àti àwọn ará Peresi sì ń gbé ní ilẹ̀ náà nígbà náà.

Abramu sì wí fún Lọti pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí èdè-àìyedè kí ó wà láàrín èmi àti ìrẹ, àti láàrín àwọn darandaran wa, nítorí pé ẹbí kan ni àwa ṣe. Gbogbo ilẹ̀ ha kọ́ nìyí níwájú rẹ? Jẹ́ kí a pínyà. Bí ìwọ bá lọ sí apá ọ̀tún, èmi yóò lọ sí apá òsì, bí ó sì ṣe òsì ni ìwọ lọ, èmi yóò lọ sí apá ọ̀tún.”

10 (A)Lọti sì gbójú sókè, ó sì ri wí pé gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani ni omi rin dáradára bí ọgbà Olúwa, bí ilẹ̀ Ejibiti, ní ọ̀nà Soari. (Èyí ní ìṣáájú kí Olúwa tó pa Sodomu àti Gomorra run). 11 Nítorí náà Lọti yan gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani yìí fún ara rẹ̀, ó sì ń lọ sí ọ̀nà ìlà-oòrùn. Òun àti Abramu sì pínyà. 12 Abramu ń gbé ni ilẹ̀ Kenaani, Lọti sì jókòó ní ìlú agbègbè Àfonífojì náà, ó sì pàgọ́ rẹ̀ títí dé Sodomu. 13 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Sodomu jẹ́ ènìyàn búburú, wọn sì ń dẹ́ṣẹ̀ gidigidi ni iwájú Olúwa.

14 Olúwa sì wí fún Abramu lẹ́yìn ìpinyà òun àti Lọti pé, “Gbé ojú rẹ sókè nísinsin yìí, kí o sì wò láti ibi tí o gbé wà a nì lọ sí ìhà àríwá àti sí ìhà gúúsù, sí ìlà-oòrùn àti sí ìwọ̀ rẹ̀. 15 (B)Gbogbo ilẹ̀ tí ìwọ ń wò o nì ni èmi ó fi fún ọ àti irú-ọmọ rẹ láéláé. 16 Èmi yóò mú kí irú-ọmọ rẹ kí ó pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó bá ṣe pé ẹnikẹ́ni bá le è ka erùpẹ̀ ilẹ̀, nígbà náà ni yóò tó lè ka irú-ọmọ rẹ. 17 Dìde, rìn òró àti ìbú ilẹ̀ náà já, nítorí ìwọ ni Èmi yóò fi fún.”

18 Nígbà náà ni Abramu kó àgọ́ rẹ̀, ó sì wá, ó sì jókòó ní ẹ̀gbẹ́ igi ńlá igbó Mamre, tí ó wà ní Hebroni. Níbẹ̀ ni ó gbé tẹ́ pẹpẹ kan sí fún Olúwa.

Matiu 12

Olúwa ọjọ́ ìsinmi

12 (A)(B) Ní àkókò náà ni Jesu ń la àárín oko ọkà kan lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ebi sì ń pa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i ya orí ọkà, wọ́n sì ń jẹ ẹ́. Nígbà tí àwọn Farisi rí èyí. Wọ́n wí fún pé, “Wò ó! Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ ń ṣe ohun tí kò bá òfin mu ní ọjọ́ ìsinmi.”

(C)Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò ha ka ohun tí Dafidi ṣe nígbà tí ebi ń pa á àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ó wọ inú ilé Ọlọ́run, òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ àkàrà tí a yà sọ́tọ̀, èyí tí kò yẹ fún wọn láti jẹ, bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà nìkan. Tàbí ẹ̀yin kò ti kà á nínú òfin pé ní ọjọ́ ìsinmi, àwọn àlùfáà tí ó wà ní tẹmpili ń ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́ tí wọ́n sì wà láìjẹ̀bi. Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, ẹni tí ó pọ̀ ju tẹmpili lọ wà níhìn-ín. Bí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí, ‘Àánú ni èmi ń fẹ́ kì í ṣe ẹbọ,’ ẹ̀yin kì bá tí dá aláìlẹ́ṣẹ̀ lẹ́bi. Nítorí pé Ọmọ Ènìyàn jẹ́ Olúwa ọjọ́ ìsinmi.”

(D)Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀ ó lọ sí Sinagọgu wọn, 10 ọkùnrin kan tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ wà níbẹ̀. Wọ́n ń wá ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kan Jesu, wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ó tọ́ láti mú ènìyàn láradá ní ọjọ́ ìsinmi?”

11 (E)Ó dá wọn lóhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ wí pé bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ní àgùntàn kan ṣoṣo, tí ó sì bọ́ sínú kòtò ní ọjọ́ ìsinmi, ǹjẹ́ kì yóò dìímú, kí ó sì fà á jáde. 12 Ǹjẹ́ mélòó mélòó ní ènìyàn ní iye lórí ju àgùntàn kan lọ! Nítorí náà ó yẹ láti ṣe rere ní ọjọ́ ìsinmi.”

13 Nígbà náà, ó sì wí fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ,” bí òun sì ti nà án, ọwọ́ rẹ̀ sì bọ̀ sí ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ èkejì. 14 (F)Síbẹ̀ àwọn Farisi jáde lọ pe ìpàdé láti dìtẹ̀ mú un àti bí wọn yóò ṣe pa Jesu.

Ìránṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn

15 (G)Nígbà tí Jesu sì mọ̀, ó yẹra kúrò níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì mú gbogbo àwọn aláìsàn láradá. 16 Ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n kí ó má ṣe fi òun hàn. 17 Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ èyí tí wòlíì Isaiah sọ nípa rẹ̀ pé:

18 (H)“Ẹ wo ìránṣẹ́ mi ẹni tí mo yàn.
    Àyànfẹ́ mi ni ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi;
èmi yóò fi ẹ̀mí mi fún un.
    Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ àwọn kèfèrí.
19 Òun kì yóò jà, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò kígbe;
    ẹnikẹ́ni kì yóò gbọ́ ohùn rẹ ní ìgboro.
20 Koríko odò títẹ̀ kan ni òun kì yóò fọ́,
    àti òwú-fìtílà tí ń jó tan an lọ lòun kì yóò fẹ́ pa.
Títí yóò fi mú ìdájọ́ dé ìṣẹ́gun.
21     Ní orúkọ rẹ̀ ni gbogbo kèfèrí yóò fi ìrètí wọn sí.”

Jesu àti Beelsebulu

22 (I)(J) Nígbà náà ni wọ́n mú ọkùnrin kan tó ni ẹ̀mí èṣù tọ̀ ọ́ wá, tí ó afọ́jú, tí ó tún ya odi. Jesu sì mú un láradá kí ó le sọ̀rọ̀, ó sì ríran. 23 Ẹnu sì ya gbogbo àwọn ènìyàn. Wọ́n wí pé, “Èyí ha lè jẹ́ Ọmọ Dafidi bí?”

24 (K)Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Farisi gbọ́ èyí, wọ́n wí pé, “Nípa Beelsebulu nìkan, tí í ṣe ọba ẹ̀mí èṣù ni ọkùnrin yìí fi lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”

25 Jesu tí ó mọ èrò wọn, ó wí fún wọn pé, “Ìjọbakíjọba tí ó bá yapa sí ara rẹ̀ yóò parun, ìlúkílùú tàbí ilékílé tí ó bá yapa sí ara rẹ̀ kì yóò dúró. 26 Bí èṣù bá sì ń lé èṣù jáde, a jẹ́ wí pé, ó ń yapa sí ara rẹ̀. Ìjọba rẹ yóò ha ṣe le dúró? 27 Àti pé, bi èmi bá ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde nípa Beelsebulu, nípa ta ni àwọn ènìyàn yín fi ń lé wọn jáde? Nítorí náà ni wọn yóò ṣe má ṣe ìdájọ́ yín. 28 Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé nípa Ẹ̀mí Ọlọ́run ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, a jẹ́ pé ìjọba Ọlọ́run ti dé bá yín.

29 “Tàbí, báwo ni ẹnikẹ́ni ṣe lè wọ ilé alágbára lọ kí ó sì kó ẹrù rẹ̀, bí kò ṣe pé ó kọ́kọ́ di alágbára náà? Nígbà náà ni ó tó lè kó ẹrù rẹ̀ lọ.

30 (L)“Ẹni tí kò bá wà pẹ̀lú mi, òun lòdì sí mi, ẹni tí kò bá mi kójọpọ̀ ń fọ́nká. 31 Nítorí èyí, mo wí fún yín, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àti ọ̀rọ̀-òdì ni a yóò dárí rẹ̀ jí ènìyàn, ṣùgbọ́n ìṣọ̀rọ̀-òdì-sí Ẹ̀mí Mímọ́ kò ní ìdáríjì. 32 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀-òdì sí Ọmọ ènìyàn, a ó dáríjì í, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀-òdì sí ẹ̀mí mímọ́, a kì yóò dáríjì í, ìbá à ṣe ní ayé yìí tàbí ní ayé tí ń bọ̀.

33 (M)“E sọ igi di rere, èso rẹ̀ a sì di rere tàbí kí ẹ sọ igi di búburú, èso rẹ a sì di búburú, nítorí nípa èso igi ni a ó fi mọ̀ igi. 34 Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀, báwo ni ẹ̀yin tí ẹ jẹ búburú ṣe lè sọ̀rọ̀ rere? Ọkàn ènìyàn ni ó ń darí irú ọ̀rọ̀ tí ó lè jáde lẹ́nu rẹ̀. 35 Ẹni rere láti inú yàrá ìṣúra rere ọkàn rẹ̀ ní mú ohun rere jáde wá: àti ẹni búburú láti inú ìṣúra búburú ni; mu ohun búburú jáde wá. 36 Ṣùgbọ́n, mo sọ èyí fún yín, ẹ̀yin yóò jíyìn gbogbo ìsọkúsọ yín ní ọjọ́ ìdájọ́. 37 Nítorí nípa ọ̀rọ̀ ẹnu yín ni a fi dá yin láre, nípa ọ̀rọ̀ ẹnu yín sì ni a ó fi dá yin lẹ́bi.”

Ààmì Jona

38 (N)Nígbà náà ni, díẹ̀ nínú àwọn Farisi àti àwọn olùkọ́ òfin wí fún pé “Olùkọ́, àwa fẹ́ rí iṣẹ́ ààmì kan lọ́dọ̀ rẹ̀”.

39 Ó sì dá wọn lóhùn wí pé “Ìran búburú àti ìran panṣágà ń béèrè ààmì; ṣùgbọ́n kò sí ààmì tí a ó fi fún un, bí kò ṣe ààmì Jona wòlíì. 40 Bí Jona ti gbé inú ẹja ńlá fún ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀mí Ọmọ Ènìyàn yóò gbé ní inú ilẹ̀ fún ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta. 41 Àwọn ará Ninefe yóò dìde pẹ̀lú ìran yìí ní ọjọ́ ìdájọ́. Wọn yóò sì dá a lẹ́bi. Nítorí pé wọ́n ronúpìwàdà nípa ìwàásù Jona. Ṣùgbọ́n báyìí ẹni tí ó pọ̀jù Jona wà níhìn-ín yìí. 42 Ọbabìnrin gúúsù yóò sì dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ sí ìran yìí yóò sì dá a lẹ́bi; nítorí tí ó wá láti ilẹ̀ ìkangun ayé láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n láti ẹnu Solomoni. Ṣùgbọ́n báyìí ẹni tí ó pọ̀jù Solomoni ń bẹ níhìn-ín yìí.

43 (O)“Nígbà tí ẹ̀mí búburú kan bá jáde lára ènìyàn, a máa rìn ní ibi gbígbẹ́, a máa wá ibi ìsinmi, kò sì ní rí i. 44 Nígbà náà ni ẹ̀mí náà yóò wí pé, ‘Èmi yóò padà sí ara ọkùnrin tí èmí ti wá.’ Bí ó bá sì padà, tí ó sì bá ọkàn ọkùnrin náà ni òfìfo, a gbà á mọ́, a sì ṣe é ní ọ̀ṣọ́. 45 Nígbà náà ni yóò lọ, yóò sì mú ẹ̀mí méje mìíràn pẹ̀lú ara rẹ̀, tí ó burú ju òun fúnra rẹ̀ lọ. Gbogbo wọn yóò sì wá sí inú rẹ̀, wọn yóò máa gbé ibẹ̀. Ìgbẹ̀yìn ọkùnrin náà a sì burú ju ìṣáájú rẹ̀ lọ; Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí fún ìran búburú yìí pẹ̀lú.”

Ìyá Jesu àti àwọn arákùnrin rẹ̀

46 (P)(Q) Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn, wò ó, ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ dúró lóde, wọ́n fẹ́ bá a sọ̀rọ̀. 47 Nígbà náà ni ẹnìkan wí fún un pé, “Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ ń dúró dè ọ́ lóde wọ́n ń fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀.”

48 Ó sì fún ni èsì pé, “Ta ni ìyá mi? Ta ni àwọn arákùnrin mi?” 49 Ó nawọ́ sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí pé, “Wò ó, ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi ni wọ̀nyí.” 50 (R)Nítorí náà, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run, ni arákùnrin mi àti arábìnrin mi àti ìyá mi.”

Nehemiah 2

Artasasta rán Nehemiah lọ Jerusalẹmu

Ní oṣù Nisani (oṣù kẹrin) ní ogún ọdún ìjọba ọba Artasasta, nígbà tí a gbé wáìnì wá fún un, mo gbé wáìnì náà mo fi fún ọba, ìbànújẹ́ kò hàn ní ojú mi rí ní iwájú rẹ̀. Nítorí náà ni ọba béèrè lọ́wọ́ mi pé “Èéṣe tí ojú rẹ fi fàro nígbà tí kò rẹ̀ ọ́? Èyí kì í ṣe ohun mìíràn bí kò ṣe ìbànújẹ́ ọkàn.”

Ẹ̀rù bà mí gidigidi, Ṣùgbọ́n mo wí fún ọba pé, “Kí ọba kí ó pẹ́! Èéṣe tí ojú mi ko ṣe ní fàro, nígbà tí ìlú tí a sin àwọn baba mi sí wà ní ahoro, tí a sì ti fi iná run àwọn ibodè rẹ̀?”

Ọba wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?”

Nígbà náà, ni mo gbàdúrà sí Ọlọ́run ọ̀run, mo sì dá ọba lóhùn pé, “Ti ó bá wu ọba, tí ìránṣẹ́ rẹ bá sì rí ojúrere ní ojú rẹ, jẹ́ kí ó rán mi lọ sí ìlú náà ní Juda níbi tí a sin àwọn baba mi nítorí kí èmi lè tún un kọ́.”

Nígbà náà ni ọba, pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ tí ó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, bi mí pé, “Báwo ni ìrìnàjò náà yóò ṣe pẹ́ ọ tó, nígbà wo sì ni ìwọ yóò padà?” Ó dùn mọ́ ọba láti rán mi lọ, bẹ́ẹ̀ ni mo dá àkókò kan.

Mo sì tún wí fún ọba pé, “Bí ó bá wu ọba, kí ó fún mi ní lẹ́tà sí àwọn baálẹ̀ òkè odò Eufurate kí wọ́n le mú mi kọjá títí èmi yóò fi dé Juda láìléwu Kí èmi sì gba lẹ́tà kan lọ́wọ́ fún Asafu, olùṣọ́ igbó ọba, nítorí kí ó lè fún mi ní igi láti fi ṣe àtẹ́rígbà fún ibodè ilé ìṣọ́ tẹmpili àti fún odi ìlú náà àti fún ilé tí èmi yóò gbé?” Nítorí ọwọ́ àánú Ọlọ́run mi wà lórí mi, ọba fi ìbéèrè mi fún mi. Bẹ́ẹ̀ ni mo lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn baálẹ̀ agbègbè Eufurate, mo sì fún wọn ní àwọn lẹ́tà ọba. Ọba sì ti rán àwọn ológun àti àwọn ẹlẹ́ṣin ogun pẹ̀lú mi.

10 Nígbà tí Sanballati ará Horoni àti Tobiah ará a Ammoni tí wọ́n jẹ́ ìjòyè gbọ́ nípa èyí pé, ẹnìkan wá láti mú ìtẹ̀síwájú bá àlàáfíà àwọn ará Israẹli inú bí wọn gidigidi.

Nehemiah bẹ àwọn odi Jerusalẹmu wò

11 Mo sì lọ sí Jerusalẹmu, lẹ́yìn ìgbà tí mo dúró níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta. 12 Mo jáde ní òru pẹ̀lú àwọn ọkùnrin díẹ̀. Èmi kò sì sọ fún ẹnìkankan ohun tí Ọlọ́run mi ti fi sí ọkàn mi láti ṣe fún Jerusalẹmu. Kò sí ẹranko kankan pẹ̀lú mi, bí kò ṣe ọ̀kan ṣoṣo tí mo gùn.

13 Ní òru, mo jáde lọ sí Àfonífojì ibodè sí ìhà kànga Jakali àti sí ẹnu Ibodè Ààtàn àti ẹnu ibodè rẹ̀ èyí tí ó ti wó odi Jerusalẹmu tí ó lulẹ̀, tí a ti fi iná sun. 14 Nígbà náà ni mo lọ sí ẹnu ibodè orísun àti sí adágún omi ọba, ṣùgbọ́n kò sí ààyè tó fún ẹranko mi láti kọjá; 15 Bẹ́ẹ̀ ni mo gòkè àfonífojì ní òru, mo ń wo odi. Ní ìparí, mo padà sẹ́yìn, mo sì tún wọlé láti ibodè Àfonífojì. 16 Àwọn olórí kò mọ ibi tí mo lọ tàbí mọ ohun tí mo ń ṣe, nítorí èmi kò tí ì sọ fún àwọn ará Júù tàbí àwọn àlùfáà tàbí àwọn ọlọ́lá tàbí àwọn ìjòyè tàbí ẹnikẹ́ni mìíràn tí yóò máa ṣe iṣẹ́ náà.

17 Nígbà náà ni mo sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí wàhálà tí a ni: Jerusalẹmu wà nínú ìparun, ibodè rẹ̀ ni a sì ti fi iná jó. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tún odi Jerusalẹmu mọ, àwa kò sì ní jẹ́ ẹni ẹ̀gàn mọ́”. 18 Èmi sì tún sọ fún wọn nípa bí ọwọ́ àánú Ọlọ́run mi ṣe wà lára mi àti ohun tí ọba ti sọ fún mi.

Wọ́n dáhùn wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a bẹ̀rẹ̀ àtúnmọ rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere yìí.

19 Ṣùgbọ́n nígbà tí Sanballati ará a Horoni, Tobiah ara olóyè Ammoni àti Geṣemu ará a Arabia gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n fi wá ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì fi wá ṣe ẹ̀sín. Wọ́n béèrè pé, “Kí ni èyí tí ẹ ń ṣe yìí? Ṣé ẹ ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọba ni?”

20 Mo dá wọn lóhùn, mo wí fún wọn pé, “Ọlọ́run ọ̀run yóò fún wa ní àṣeyọrí. Àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ láti tún un mọ, ṣùgbọ́n fún un yin, ẹ̀yin kò ní ìpín tàbí ipa tàbí ẹ̀tọ́ ohunkóhun tí ó jẹ mọ́ ìtàn ní Jerusalẹmu.”

Ìṣe àwọn Aposteli 12

Peteru bọ́ kúrò ní ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú ìyanu

12 Ní àkókò ìgbà náà ni Herodu ọba sì nawọ́ rẹ̀ mú àwọn kan nínú ìjọ, pẹ̀lú èrò láti pọ́n wọn lójú. Ó sì fi idà pa Jakọbu arákùnrin Johanu. Nígbà tí ó sì rí pé èyí dùn mọ́ àwọn Júù nínú, ó sì nawọ́ mú Peteru pẹ̀lú. Ó sì jẹ́ ìgbà àjọ àìwúkàrà. Nígbà tí o sì mú un, ó fi i sínú túbú, ó fi lé àwọn ẹ̀ṣọ́ mẹ́rin ti ọmọ-ogun lọ́wọ́ láti máa ṣọ́ ọ. Herodu ń rò láti mú un jáde fún àwọn ènìyàn lẹ́yìn ìrékọjá fún ìdájọ́.

Nítorí náà wọn fi Peteru pamọ́ sínú túbú; ṣùgbọ́n ìjọ ń fi ìtara gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run fún un.

Ní òru náà gan an ti Herodu ìbá sì mú un jáde, Peteru ń sùn láàrín àwọn ọmọ-ogun méjì, a fi ẹ̀wọ̀n méjì dè é, ẹ̀ṣọ́ sí wà ní ẹnu-ọ̀nà, wọ́n ń ṣọ́ túbú náà. Sì wò ó, angẹli Olúwa farahàn, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ nínú túbú; ó sì lu Peteru pẹ́pẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó jí i, ó ni, “Dìde kánkán!” Ẹ̀wọ̀n sí bọ́ sílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ Peteru.

Angẹli náà sì wí fún un pé, “Di àmùrè rẹ̀, kí ó sì wọ sálúbàtà rẹ!” Peteru sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ó sì wí fún un pé, “Da aṣọ rẹ́ bora, ki ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn!” Peteru sì jáde, ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn; kò sí mọ̀ pé ohun tí a ṣe láti ọwọ́ angẹli náà jẹ́ òtítọ́, ṣùgbọ́n ó ṣe bí òun wà lójú ìran. 10 Nígbà tí wọ́n kọjá ìṣọ́ èkínní àti èkejì, wọ́n dé ẹnu-ọ̀nà ìlẹ̀kùn irin tí ó lọ sí ìlú. Ó sí tìkára rẹ̀ ṣí sílẹ̀ fún wọn: wọ́n sì jáde, wọ́n ń gba ọ̀nà ìgboro kan lọ; lójúkan náà angẹli náà sì fi í sílẹ̀ lọ.

11 Nígbà tí ojú Peteru sì wálẹ̀, ó ní, “Nígbà yìí ni mo tó mọ̀ nítòótọ́ pé, Olúwa rán angẹli rẹ̀, ó sì gbà mi lọ́wọ́ Herodu àti gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn Júù ń retí!”

12 Nígbà tó sì rò ó, ó lọ sí ilé Maria ìyá Johanu, tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Marku; níbi tí àwọn ènìyàn púpọ̀ péjọ sí, tí wọn ń gbàdúrà. 13 Bí ó sì ti kan ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà, ọmọbìnrin kan tí a n pè ní Roda wá láti dáhùn. 14 Nígbà tí ó sì ti mọ ohùn Peteru, kò ṣí ìlẹ̀kùn nítorí tí ayọ̀ kún ọkàn rẹ̀ gidigidi, ṣùgbọ́n ó súré wọ ilé, ó sísọ pé, Peteru dúró ní ẹnu-ọ̀nà.

15 Wọ́n sì wí fún un pé, “Ìwọ ń ṣe òmùgọ̀!” Ṣùgbọ́n ó tẹnumọ́ ọn gidigidi pé bẹ́ẹ̀ ni sẹ́. Wọn sì wí pé, “Angẹli rẹ̀ ni!”

16 Ṣùgbọ́n Peteru ń kànkùn síbẹ̀, nígbà tí wọn sì ṣí ìlẹ̀kùn, wọ́n rí i, ẹnu sì yá wọ́n. 17 Ṣùgbọ́n ó juwọ́ sí wọn pé kí wọn dákẹ́, ó sì ròyìn fún wọn bí Olúwa ti mú òun jáde kúrò nínú túbú. Ó sì wí pé “Ẹ ro èyí fún Jakọbu àti àwọn arákùnrin yòókù!” Ó sì jáde, ó lọ sí ibòmíràn.

18 Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ìrúkèrúdò díẹ̀ kọ́ ni ó wà láàrín àwọn ọmọ-ogun nípa ohun tí ó dé bá Peteru. 19 Nígbà tí Herodu sì wá a kiri, tí kò sì rí i, ó wádìí àwọn ẹ̀ṣọ́, ó pàṣẹ pé, kí a pa wọ́n.

Ikú Herodu

Herodu sì sọ̀kalẹ̀ láti Judea lọ sí Kesarea, ó sì wà níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. 20 Herodu sí ń bínú gidigidi sí àwọn ará Tire àti Sidoni; ṣùgbọ́n wọ́n fi ìmọ̀ ṣọ̀kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nígbà tí wọn sì ti tu Bilasitu ìwẹ̀fà ọba lójú, wọn ń bẹ̀bẹ̀ fún àlàáfíà, nítorí pé ìlú ọba náà ni ìlú tí wọ́n ti ń gba oúnjẹ.

21 Ni ọjọ́ àfiyèsí kan, Herodu sì wà nínú aṣọ ìgúnwà rẹ̀, ni orí ìtẹ́ rẹ̀, ó sì ń bá àwọn àjọ ènìyàn sọ̀rọ̀ ní gbangba. 22 Àwọn ènìyàn sì hó wí pé, “Ohùn ọlọ́run ni èyí, kì í sì í ṣe ti ènìyàn!” 23 Lójúkan náà, nítorí ti Herodu kò fi ògo fún Ọlọ́run, angẹli Olúwa lù ú, ó sì kú, ìdin sì jẹ ẹ́.

24 Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbilẹ̀, ó sì bí sí i.

25 Barnaba àti Saulu sì padà wá láti Jerusalẹmu, nígbà ti wọ́n sì parí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn, wọn sì mú Johanu ẹni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Marku wá pẹ̀lú wọn.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.